16 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan dá yín lẹ́jọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń mu+ tàbí lórí àjọyọ̀ kan tí ẹ ṣe tàbí òṣùpá tuntun+ tàbí sábáàtì.+17 Àwọn nǹkan yẹn jẹ́ òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀,+ àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.+
5 Àwọn èèyàn yìí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí àpẹẹrẹ àti òjìji+ àwọn nǹkan ti ọ̀run;+ bí a ṣe pàṣẹ fún Mósè láti ọ̀run, nígbà tó fẹ́ kọ́ àgọ́ náà pé: Torí Ó sọ pé: “Rí i pé o ṣe gbogbo nǹkan bí ohun tí mo fi hàn ọ́ lórí òkè.”+
10Nígbà tó jẹ́ pé Òfin ní òjìji+ àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀,+ àmọ́ tí kì í ṣe bí àwọn nǹkan náà ṣe máa rí gan-an, kò lè* sọ àwọn tó ń wá sí tòsí di pípé láé nípasẹ̀ àwọn ẹbọ kan náà tí wọ́n ń rú léraléra láti ọdún dé ọdún.+