12 “Kó wá mú ìkóná+ tí ẹyin iná tó ń jó látorí pẹpẹ+ níwájú Jèhófà kún inú rẹ̀, pẹ̀lú ẹ̀kúnwọ́ tùràrí onílọ́fínńdà+ méjì tó dáa, kó sì kó wọn wá sẹ́yìn aṣọ ìdábùú.+
3 Áńgẹ́lì míì dé, ó dúró níbi pẹpẹ,+ ó gbé àwo tùràrí tí wọ́n fi wúrà ṣe* dání, a sì fún un ní tùràrí tó pọ̀ gan-an+ pé kó sun ún lórí pẹpẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe+ tó wà níwájú ìtẹ́ náà bí gbogbo àwọn ẹni mímọ́ ṣe ń gbàdúrà.