Sáàmù 140:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bíi ti ejò;+Oró paramọ́lẹ̀ wà lábẹ́ ètè wọn.+ (Sélà) Òwe 12:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni,Àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.+ Òwe 18:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Ẹnu òmùgọ̀ ni ìparun rẹ̀,+Ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ẹ̀mí* rẹ̀.