-
Ìsíkíẹ́lì 1:5-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Àwọn ohun tó dà bí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ wà nínú rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì rí bí èèyàn. 6 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.+ 7 Ẹsẹ̀ wọn rí gbọọrọ, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn dà bíi ti ọmọ màlúù, wọ́n sì ń kọ mànà bíi bàbà dídán.+ 8 Wọ́n ní ọwọ́ èèyàn lábẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní ojú àti ìyẹ́. 9 Àwọn ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn. Wọn kì í yà síbì kankan bí wọ́n ṣe ń lọ; iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ.+
10 Bí ojú wọn ṣe rí nìyí: Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú èèyàn, ojú kìnnìún+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ojú akọ màlúù+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ojú+ idì.+
-