ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 61:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà.

      Gbogbo ara mi* máa yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.+

      Torí ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí;+

      Ó ti fi aṣọ òdodo* bò mí lára,

      Bí ọkọ ìyàwó tó wé láwàní bíi ti àlùfáà+

      Àti bí ìyàwó tó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.

  • Éfésù 5:25-27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún un,+ 26 kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́, kí ó fi omi wẹ̀ ẹ́ mọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,+ 27 kí ó lè mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ògo, láìní ìdọ̀tí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irú àwọn nǹkan yìí,+ àmọ́ kí ó jẹ́ mímọ́ kí ó má sì lábààwọ́n.+

  • Ìfihàn 14:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Àwọn yìí kò fi obìnrin sọ ara wọn di aláìmọ́; kódà, wúńdíá ni wọ́n.+ Àwọn ló ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lọ síbikíbi tó bá ń lọ.+ A rà wọ́n+ látinú aráyé, wọ́n sì jẹ́ àkọ́so+ fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́