Ìsíkíẹ́lì
32 Ní ọdún kejìlá, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, kọ orin arò* nípa Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì sọ fún un pé,
‘O dà bí ọmọ kìnnìún tó lágbára* ní àwọn orílẹ̀-èdè,
Àmọ́ wọ́n ti pa ọ́ lẹ́nu mọ́.
O dà bí ẹran ńlá inú òkun,+ ò ń jà gùdù nínú odò rẹ,
Ò ń fi ẹsẹ̀ rẹ da omi rú, o sì ń dọ̀tí àwọn odò.’*
3 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Màá da àwọ̀n mi bò ọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó kóra jọ,
Wọ́n á sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ síta.
4 Èmi yóò pa ọ́ tì sórí ilẹ̀;
Màá jù ọ́ sórí pápá gbalasa.
Màá mú kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé ọ,
Màá sì fi ọ́ bọ́ àwọn ẹran inú igbó ní gbogbo ayé.+
5 Èmi yóò ju ẹran rẹ sórí àwọn òkè,
Màá sì fi ara rẹ tó ṣẹ́ kù kún inú àwọn àfonífojì.+
6 Màá fi ẹ̀jẹ̀ rẹ tó ń tú jáde rin ilẹ̀ náà títí dé orí àwọn òkè,
Yóò sì kún inú àwọn odò.’*
7 ‘Tí òpin bá sì ti dé bá ọ, èmi yóò bo ojú ọ̀run, màá sì mú kí àwọn ìràwọ̀ wọn ṣókùnkùn.
8 Èmi yóò mú kí gbogbo orísun ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run ṣókùnkùn torí rẹ,
Èmi yóò sì mú kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
9 ‘Èmi yóò mú kí ìdààmú bá ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tí mo bá mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míì,
Lọ sí àwọn ilẹ̀ tí o kò mọ̀.+
10 Èmi yóò mú kí ẹnu ya ọ̀pọ̀ èèyàn,
Ìbẹ̀rù á sì mú kí àwọn ọba wọn gbọ̀n rìrì torí rẹ nígbà tí mo bá fi idà mi níwájú wọn.
Kálukú wọn á máa gbọ̀n jìnnìjìnnì, torí ẹ̀mí ara rẹ̀,
Ní ọjọ́ tí o bá ṣubú.’
11 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Idà ọba Bábílónì yóò wá sórí rẹ.+
12 Èmi yóò mú kí idà àwọn jagunjagun tó lákíkanjú pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ,
Àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn.+
Wọ́n á rẹ ìgbéraga Íjíbítì wálẹ̀, wọ́n á sì run gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.+
13 Màá pa gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi rẹ̀ tó pọ̀ run,+
Ẹsẹ̀ èèyàn tàbí pátákò ẹran ọ̀sìn kankan kò sì ní dà wọ́n rú mọ́.’+
14 ‘Ní àkókò yẹn, èmi yóò mú kí omi wọn tòrò,
Màá sì mú kí odò wọn ṣàn bí òróró’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
15 ‘Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Íjíbítì di ahoro, tí wọ́n kó gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ lọ,+
Nígbà tí mo bá pa gbogbo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀,
Wọ́n á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
16 Orin arò nìyí, ó sì dájú pé àwọn èèyàn máa kọ ọ́;
Àwọn ọmọbìnrin àwọn orílẹ̀-èdè máa kọ ọ́.
Wọ́n á kọ ọ́ nítorí Íjíbítì àti nítorí gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
17 Ní ọdún kejìlá, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, pohùn réré ẹkún torí àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ, kí o sì mú un lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀, òun àti àwọn ọmọbìnrin àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára, pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
19 “‘Ta ni ìwọ fi ẹwà rẹ jù lọ? Lọ sísàlẹ̀, kí o lọ dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́!’*
20 “‘Wọ́n á ṣubú sí àárín àwọn tí wọ́n fi idà pa.+ Wọ́n ti fà á lé idà lọ́wọ́; ẹ wọ́ ọ lọ, pẹ̀lú gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.
21 “‘Láti inú Isà Òkú* ni àwọn jagunjagun tó lákíkanjú jù lọ yóò ti bá òun àti àwọn tó ń ràn án lọ́wọ́ sọ̀rọ̀. Ó dájú pé wọ́n á lọ sí ìsàlẹ̀, wọ́n á sì dùbúlẹ̀ bí àwọn aláìdádọ̀dọ́* tí wọ́n fi idà pa. 22 Ásíríà àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ wà níbẹ̀. Sàréè wọn yí i ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa.+ 23 Ìsàlẹ̀ kòtò* ni àwọn sàréè rẹ̀ wà, àwọn èèyàn rẹ̀ sì yí sàréè rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa, torí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè.
24 “‘Élámù+ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ wà níbẹ̀ tí wọ́n yí sàréè rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n fi idà pa. Wọ́n ti lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ láìdádọ̀dọ́,* àwọn tí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. Ojú á wá tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.* 25 Wọ́n ti ṣe ibùsùn fún un láàárín àwọn tí wọ́n pa, tòun ti gbogbo èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ tó yí sàréè rẹ̀ ká. Aláìdádọ̀dọ́* ni gbogbo wọn, tí wọ́n fi idà pa, torí wọ́n ń dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè; ojú á sì tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.* Àárín àwọn tí wọ́n pa ni wọ́n gbé e sí.
26 “‘Ibẹ̀ ni Méṣékì àti Túbálì+ àti gbogbo èèyàn wọn* tó pọ̀ rẹpẹtẹ wà. Sàréè wọn* yí i ká. Aláìdádọ̀dọ́* ni gbogbo wọn, wọ́n fi idà gún wọn pa, torí wọ́n dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. 27 Ṣé wọn ò ní dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tí kò dádọ̀dọ́,* tí wọ́n ti ṣubú, tí wọ́n sì lọ sínú Isà Òkú* pẹ̀lú àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń jagun? Wọ́n á fi idà wọn sábẹ́ orí wọn,* wọ́n á sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn sórí egungun wọn, torí pé àwọn jagunjagun tó lákíkanjú yìí dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè. 28 Àmọ́ ní tìrẹ, wọn yóò tẹ̀ ọ́ rẹ́ láàárín àwọn aláìdádọ̀dọ́,* ìwọ yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa.
29 “‘Édómù+ wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ìjòyè rẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé, láìka bí wọ́n ṣe lágbára sí, wọ́n dùbúlẹ̀ sáàárín àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn náà yóò dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́*+ àti àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
30 “‘Gbogbo àwọn ìjòyè* àríwá wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ará Sídónì,+ tí wọ́n fi ìtìjú lọ sísàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n pa, láìka bí wọ́n ṣe fi agbára wọn dẹ́rù bani sí. Wọn yóò dùbúlẹ̀ láìdádọ̀dọ́* pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa, ojú á sì tì wọ́n pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*
31 “‘Fáráò yóò rí gbogbo nǹkan yìí, gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ̀ yóò sì tù ú nínú;+ wọn yóò fi idà pa Fáráò àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
32 “‘Torí pé ó dẹ́rù bani ní ilẹ̀ alààyè, Fáráò àti àwọn èèyàn rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ yóò lọ sinmi pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́,* pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”