ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì gba ìlú Kéílà sílẹ̀ (1-12)

      • Sọ́ọ̀lù lépa Dáfídì (13-15)

      • Jónátánì fún Dáfídì lókun (16-18)

      • Díẹ̀ ló kù kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù tẹ Dáfídì (19-29)

1 Sámúẹ́lì 23:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:20, 44

1 Sámúẹ́lì 23:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 30:8; 2Sa 5:19; Sm 37:5

1 Sámúẹ́lì 23:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:5
  • +1Sa 13:5; 14:52

1 Sámúẹ́lì 23:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 6:39
  • +1Sa 14:6; 2Sa 5:19

1 Sámúẹ́lì 23:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 23:1

1 Sámúẹ́lì 23:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:20

1 Sámúẹ́lì 23:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tà á sọ́wọ́ mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 23:14

1 Sámúẹ́lì 23:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 27:21; 1Sa 30:7

1 Sámúẹ́lì 23:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:19

1 Sámúẹ́lì 23:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”

1 Sámúẹ́lì 23:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:1, 2; 25:13; 30:9

1 Sámúẹ́lì 23:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:20, 55; 1Sa 23:19; 26:1
  • +1Sa 18:29; 20:33; 27:1

1 Sámúẹ́lì 23:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù ń ba Dáfídì torí pé.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

1 Sámúẹ́lì 23:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó sì fún ọwọ́ rẹ̀ lókun nínú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:5; Owe 17:17

1 Sámúẹ́lì 23:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:13; 2Sa 2:4; 5:3
  • +1Sa 20:31; 24:17, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/1/1993, ojú ìwé 24

1 Sámúẹ́lì 23:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:3; 20:42

1 Sámúẹ́lì 23:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀; aginjù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 10:26
  • +1Sa 26:1; Sm 54:àkọlé
  • +1Sa 23:15
  • +1Sa 26:3
  • +1Sa 23:24

1 Sámúẹ́lì 23:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wu ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 54:3

1 Sámúẹ́lì 23:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agbo ilé.”

1 Sámúẹ́lì 23:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 23:14
  • +Joṣ 15:20, 55; 1Sa 25:2, 3
  • +Di 1:7

1 Sámúẹ́lì 23:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:2; Sm 54:3
  • +1Sa 23:28

1 Sámúẹ́lì 23:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 31:22
  • +Sm 17:9

1 Sámúẹ́lì 23:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 54:7

1 Sámúẹ́lì 23:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:20, 62; Sol 1:14

Àwọn míì

1 Sám. 23:1Joṣ 15:20, 44
1 Sám. 23:21Sa 30:8; 2Sa 5:19; Sm 37:5
1 Sám. 23:31Sa 22:5
1 Sám. 23:31Sa 13:5; 14:52
1 Sám. 23:4Ond 6:39
1 Sám. 23:41Sa 14:6; 2Sa 5:19
1 Sám. 23:51Sa 23:1
1 Sám. 23:61Sa 22:20
1 Sám. 23:71Sa 23:14
1 Sám. 23:9Nọ 27:21; 1Sa 30:7
1 Sám. 23:101Sa 22:19
1 Sám. 23:131Sa 22:1, 2; 25:13; 30:9
1 Sám. 23:14Joṣ 15:20, 55; 1Sa 23:19; 26:1
1 Sám. 23:141Sa 18:29; 20:33; 27:1
1 Sám. 23:16Sm 37:5; Owe 17:17
1 Sám. 23:171Sa 16:13; 2Sa 2:4; 5:3
1 Sám. 23:171Sa 20:31; 24:17, 20
1 Sám. 23:181Sa 18:3; 20:42
1 Sám. 23:191Sa 10:26
1 Sám. 23:191Sa 26:1; Sm 54:àkọlé
1 Sám. 23:191Sa 23:15
1 Sám. 23:191Sa 26:3
1 Sám. 23:191Sa 23:24
1 Sám. 23:20Sm 54:3
1 Sám. 23:241Sa 23:14
1 Sám. 23:24Joṣ 15:20, 55; 1Sa 25:2, 3
1 Sám. 23:24Di 1:7
1 Sám. 23:251Sa 26:2; Sm 54:3
1 Sám. 23:251Sa 23:28
1 Sám. 23:26Sm 31:22
1 Sám. 23:26Sm 17:9
1 Sám. 23:28Sm 54:7
1 Sám. 23:29Joṣ 15:20, 62; Sol 1:14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 23:1-29

Sámúẹ́lì Kìíní

23 Nígbà tó yá, wọ́n sọ fún Dáfídì pé: “Àwọn Filísínì ń bá Kéílà+ jà, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rù ní àwọn ibi ìpakà.” 2 Torí náà, Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé:+ “Ṣé kí n lọ mú àwọn Filísínì yìí balẹ̀?” Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Lọ mú àwọn Filísínì náà balẹ̀, kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.” 3 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Dáfídì sọ fún un pé: “Wò ó! Bí a ṣe wà níbí ní Júdà,+ ẹ̀rù ṣì ń bà wá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ká lọ sí Kéílà láti dojú kọ ìlà ogun àwọn Filísínì!”+ 4 Torí náà, Dáfídì wádìí lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Jèhófà sì dá a lóhùn pé: “Dìde; lọ sí Kéílà torí màá fi àwọn Filísínì náà lé ọ lọ́wọ́.”+ 5 Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ bá lọ sí Kéílà, ó sì bá àwọn Filísínì jà; ó kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ, ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, Dáfídì sì gba àwọn tó ń gbé ní Kéílà+ sílẹ̀.

6 Nígbà tí Ábíátárì+ ọmọ Áhímélékì sá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Kéílà, éfódì kan wà lọ́wọ́ rẹ̀. 7 Wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dáfídì ti wá sí Kéílà.” Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́,*+ nítorí ó ti há ara rẹ̀ mọ́ bó ṣe wá sínú ìlú tó ní àwọn ilẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.” 8 Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù pe gbogbo àwọn èèyàn náà sí ogun, láti lọ sí Kéílà, kí wọ́n sì dó ti Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. 9 Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù ń gbìmọ̀ ibi sí òun, ó sọ fún àlùfáà Ábíátárì pé: “Mú éfódì wá.”+ 10 Dáfídì wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù fẹ́ wá sí Kéílà láti pa ìlú náà run nítorí mi.+ 11 Ṣé àwọn olórí* Kéílà máa fi mí lé e lọ́wọ́? Ṣé Sọ́ọ̀lù máa wá lóòótọ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ṣe gbọ́? Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ.” Ni Jèhófà bá fèsì pé: “Ó máa wá.” 12 Dáfídì béèrè pé: “Ṣé àwọn olórí Kéílà máa fi èmi àti àwọn ọkùnrin mi lé Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́?” Jèhófà dáhùn pé: “Wọ́n á fi yín lé e lọ́wọ́.”

13 Ní kíá, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dìde, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ni wọ́n,+ wọ́n kúrò ní Kéílà, wọ́n sì ń lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá lè lọ. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà, kò wá a lọ mọ́. 14 Dáfídì ń gbé ní aginjù ní àwọn ibi tó ṣòroó dé, ní agbègbè olókè tó wà ní aginjù Sífù.+ Gbogbo ìgbà ni Sọ́ọ̀lù ń wá a kiri,+ àmọ́ Jèhófà kò fi lé e lọ́wọ́. 15 Dáfídì mọ̀ pé* Sọ́ọ̀lù ti jáde lọ láti gba ẹ̀mí* òun nígbà tí Dáfídì ṣì wà ní aginjù Sífù ní Hóréṣì.

16 Ni Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù bá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, ó sì ràn án lọ́wọ́ kí ó lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà.+ 17 Ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, torí pé Sọ́ọ̀lù bàbá mi kò ní rí ọ mú; ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì,+ èmi ni màá di igbá kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.”+ 18 Àwọn méjèèjì wá dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà, Dáfídì dúró sí Hóréṣì, Jónátánì sì gba ilé rẹ̀ lọ.

19 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Sífù lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n sọ pé: “Ṣebí tòsí wa ni Dáfídì fara pa mọ́ sí,+ ní àwọn ibi tó ṣòroó dé ní Hóréṣì,+ lórí òkè Hákílà,+ tó wà ní gúúsù* Jéṣímónì.*+ 20 Ìgbàkígbà tó bá wù ọ́* láti wá, ìwọ ọba, o lè wá, a ó sì fà á lé ọba lọ́wọ́.”+ 21 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí ẹ ti ṣàánú mi. 22 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lọ bá mi wá ọ̀gangan ibi tó wà, kí ẹ wádìí lọ́wọ́ ẹni tó bá rí i níbẹ̀, nítorí mo ti gbọ́ pé alárèékérekè ni. 23 Ẹ fara balẹ̀ wá gbogbo ibi tó máa ń fara pa mọ́ sí, kí ẹ sì mú ẹ̀rí bọ̀ wá fún mi. Nígbà náà, màá bá yín lọ, tó bá sì wà ní ilẹ̀ náà, màá wá a jáde láàárín gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Júdà.”

24 Nítorí náà, wọ́n ṣáájú Sọ́ọ̀lù lọ sí Sífù,+ nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣì wà ní aginjù Máónì+ ní Árábà+ ní apá gúúsù Jéṣímónì. 25 Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá a wá.+ Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì, ní kíá, ó lọ sí ibi àpáta,+ ó sì dúró sí aginjù Máónì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́, ó lépa Dáfídì wọ inú aginjù Máónì. 26 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe dé ẹ̀gbẹ́ kan òkè náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì òkè náà. Dáfídì ṣe kánkán+ kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́, àmọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti gbá wọn mú.+ 27 Ṣùgbọ́n òjíṣẹ́ kan wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Tètè máa bọ̀, nítorí àwọn Filísínì ti wá kó ẹrù ní ilẹ̀ wa!” 28 Ni Sọ́ọ̀lù ò bá lépa Dáfídì mọ́,+ ó sì lọ gbéjà ko àwọn Filísínì. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Àpáta Ìpínyà.

29 Lẹ́yìn náà, Dáfídì kúrò níbẹ̀, ó sì dúró sí àwọn ibi tó ṣòroó dé ní Ẹ́ń-gédì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́