Jónà
4 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú sì bí i gan-an. 2 Torí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jèhófà, ṣebí ohun tí mo rò nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi ló wá ṣẹlẹ̀ yìí? Torí ẹ̀ ni mo ṣe kọ́kọ́ sá lọ sí Táṣíṣì.+ Mo ti mọ̀ pé Ọlọ́run tó máa ń gba tẹni rò* ni ọ́, o jẹ́ aláàánú, o kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi, inú rẹ kì í sì í dùn sí àjálù. 3 Jèhófà, jọ̀ọ́ gbẹ̀mí* mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n wà láàyè.”+
4 Jèhófà bi í pé: “Ṣé ó yẹ kí inú bí ẹ tó báyìí?”
5 Jónà wá jáde kúrò nínú ìlú náà, ó sì lọ jókòó sí apá ìlà oòrùn ìlú náà. Ó ṣe àtíbàbà kan síbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó sábẹ́ rẹ̀ kó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.+ 6 Lẹ́yìn náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí ewéko akèrègbè* kan hù bo àtíbàbà tí Jónà ṣe, kó lè ṣíji bo orí rẹ̀, kí ara sì tù ú. Inú Jónà dùn gan-an sí ewéko tó hù yìí.
7 Àmọ́ bí ilẹ̀ ọjọ́ kejì ṣe ń mọ́ bọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí kòkòrò mùkúlú kan jẹ ewéko akèrègbè náà, ó sì rọ. 8 Nígbà tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí í ràn, Ọlọ́run tún mú kí afẹ́fẹ́ tó gbóná fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, oòrùn sì pa Jónà lórí débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú. Ó ń sọ ṣáá pé kí òun kú,* ó sì ń sọ pé: “Ó sàn kí n kú ju kí n wà láàyè.”+
9 Ọlọ́run wá bi Jónà pé: “Ṣé ó yẹ kí inú bí ẹ tó báyìí torí ewéko akèrègbè yìí?”+
Ó fèsì pé: “Ó tọ́ kí n bínú, kódà inú ń bí mi débi pé mi ò kọ̀ kí n kú.” 10 Àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé: “O káàánú ewéko akèrègbè tí o kò ṣiṣẹ́ fún, tí kì í ṣe ìwọ lo mú kó hù; ó hù ní alẹ́, ó sì kú lọ́jọ́ kejì. 11 Ṣé kò wá yẹ kí n ṣàánú Nínéfè tó jẹ́ ìlú ńlá,+ tí àwọn èèyàn ibẹ̀ lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000), tí wọn ò sì mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí èyí tí kò tọ́,* títí kan ọ̀pọ̀ ẹran tó wà níbẹ̀?”+