Míkà
Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ ohun tó tọ́?
2 Àmọ́ ẹ kórìíra ohun rere,+ ẹ sì fẹ́ràn ohun búburú;+
Ẹ bó àwọn èèyàn mi láwọ, ẹ sì ṣí ẹran kúrò lára egungun wọn.+
3 Ẹ tún jẹ ẹran ara àwọn èèyàn mi,+
Ẹ sì bó wọn láwọ,
Ẹ fọ́ egungun wọn, ẹ sì rún un sí wẹ́wẹ́,+
Bí ohun tí wọ́n sè nínú ìkòkò,* bí ẹran nínú ìkòkò oúnjẹ.
4 Ní àkókò yẹn, wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,
Àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn.
5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí nípa àwọn wòlíì tó ń ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà,+
Tí wọ́n ń kéde ‘Àlàáfíà!’+ nígbà tí wọ́n bá ń rí nǹkan jẹ,*+
Àmọ́ tí wọ́n ń gbógun ti* ẹni tí kò fún wọn ní nǹkan kan jẹ:
Oòrùn yóò wọ̀ lórí àwọn wòlíì,
Ojúmọmọ yóò sì ṣókùnkùn fún wọn.+
Gbogbo wọn máa bo ẹnu* wọn,
Torí pé Ọlọ́run kò ní dá wọn lóhùn.’”
8 Ní tèmi, ẹ̀mí Jèhófà ti fún mi ní agbára,
Ó ti jẹ́ kí n lè ṣe ìdájọ́ òdodo, ó sì ti fún mi lókun,
Kí n lè sọ fún Jékọ́bù nípa ọ̀tẹ̀ tó dì, kí n sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún un.
9 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù
Àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì,+
Tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń yí gbogbo ọ̀rọ̀ po,+
10 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ Síónì, tí ẹ sì ń fi àìṣòdodo kọ́ Jerúsálẹ́mù.+
Síbẹ̀ wọ́n gbára lé Jèhófà,* wọ́n ń sọ pé:
“Ṣebí Jèhófà wà pẹ̀lú wa?+
Àjálù kankan ò lè dé bá wa.”+