ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Jèhóáṣì di ọba Júdà (1-3)

      • Jèhóáṣì tún tẹ́ńpìlì ṣe (4-16)

      • Àwọn ará Síríà gbógun wá (17, 18)

      • Wọ́n pa Jèhóáṣì (19-21)

2 Àwọn Ọba 12:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:16; 2Ọb 10:30
  • +2Ọb 11:2; 1Kr 3:10, 11
  • +2Kr 24:1, 2

2 Àwọn Ọba 12:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:52

2 Àwọn Ọba 12:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 31:12
  • +Ẹk 30:13; 2Kr 24:9
  • +Ẹk 25:2; 35:21

2 Àwọn Ọba 12:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ojúlùmọ̀ wọn.”

  • *

    Tàbí “sán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 24:7

2 Àwọn Ọba 12:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 24:5

2 Àwọn Ọba 12:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:4; 2Kr 23:1; 24:15
  • +2Kr 24:6

2 Àwọn Ọba 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 24:8; Mk 12:41; Lk 21:1
  • +2Kr 24:10

2 Àwọn Ọba 12:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kó owó náà sínú àwọn àpò.” Ní Héb., “di owó náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 24:11

2 Àwọn Ọba 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:4-6; 2Kr 24:12

2 Àwọn Ọba 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:2; 2Kr 5:12
  • +2Kr 24:14

2 Àwọn Ọba 12:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:7

2 Àwọn Ọba 12:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 5:15
  • +Le 7:7; Nọ 18:8

2 Àwọn Ọba 12:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Hásáélì dojú kọ Jerúsálẹ́mù láti gbéjà kò ó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:15; 2Ọb 8:13; 10:32
  • +1Kr 18:1
  • +2Kr 24:23

2 Àwọn Ọba 12:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:18; 2Ọb 16:8; 18:15

2 Àwọn Ọba 12:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Bẹti-mílò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 24:25, 26; 25:27
  • +2Sa 5:9; 1Ọb 9:15, 24; 2Kr 32:5

2 Àwọn Ọba 12:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 14:1, 5
  • +2Kr 24:27

Àwọn míì

2 Ọba 12:11Ọb 19:16; 2Ọb 10:30
2 Ọba 12:12Ọb 11:2; 1Kr 3:10, 11
2 Ọba 12:12Kr 24:1, 2
2 Ọba 12:3Nọ 33:52
2 Ọba 12:42Kr 31:12
2 Ọba 12:4Ẹk 30:13; 2Kr 24:9
2 Ọba 12:4Ẹk 25:2; 35:21
2 Ọba 12:52Kr 24:7
2 Ọba 12:62Kr 24:5
2 Ọba 12:72Ọb 11:4; 2Kr 23:1; 24:15
2 Ọba 12:72Kr 24:6
2 Ọba 12:92Kr 24:8; Mk 12:41; Lk 21:1
2 Ọba 12:92Kr 24:10
2 Ọba 12:102Kr 24:11
2 Ọba 12:112Ọb 22:4-6; 2Kr 24:12
2 Ọba 12:13Nọ 10:2; 2Kr 5:12
2 Ọba 12:132Kr 24:14
2 Ọba 12:152Ọb 22:7
2 Ọba 12:16Le 5:15
2 Ọba 12:16Le 7:7; Nọ 18:8
2 Ọba 12:171Ọb 19:15; 2Ọb 8:13; 10:32
2 Ọba 12:171Kr 18:1
2 Ọba 12:172Kr 24:23
2 Ọba 12:181Ọb 15:18; 2Ọb 16:8; 18:15
2 Ọba 12:202Kr 24:25, 26; 25:27
2 Ọba 12:202Sa 5:9; 1Ọb 9:15, 24; 2Kr 32:5
2 Ọba 12:212Ọb 14:1, 5
2 Ọba 12:212Kr 24:27
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 12:1-21

Àwọn Ọba Kejì

12 Ní ọdún keje Jéhù,+ Jèhóáṣì+ di ọba, ó sì fi ogójì (40) ọdún ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibáyà láti Bíá-ṣébà.+ 2 Jèhóáṣì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí àlùfáà Jèhóádà fi ń tọ́ ọ sọ́nà. 3 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga+ kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.

4 Jèhóáṣì sọ fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gba gbogbo owó tó jẹ́ ọrẹ mímọ́+ tí wọ́n bá mú wá sí ilé Jèhófà, ìyẹn owó tí wọ́n ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan mú wá,+ owó tí àwọn àlùfáà gbà lọ́wọ́ àwọn* tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo owó tó bá wá látọkàn kálukú láti mú wá sí ilé Jèhófà.+ 5 Àwọn àlùfáà yóò fúnra wọn gbà á lọ́wọ́ àwọn tó ń dáwó fún wọn,* wọ́n á sì lò ó láti fi ṣàtúnṣe ibikíbi tí wọ́n bá rí pé ó bà jẹ́* lára ilé náà.”+

6 Títí di ọdún kẹtàlélógún Ọba Jèhóáṣì, àwọn àlùfáà kò tíì ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé náà.+ 7 Torí náà, Ọba Jèhóáṣì pe àlùfáà Jèhóádà+ àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé náà? Ní báyìí, ẹ má gba owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń dáwó fún yín àfi tí ẹ bá máa lò ó láti ṣàtúnṣe ilé náà.”+ 8 Torí náà, àwọn àlùfáà gbà pé àwọn ò ní gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà mọ́ àti pé àwọn ò ní tún ilé náà ṣe.

9 Ni àlùfáà Jèhóádà bá gbé àpótí kan,+ ó lu ihò sí ọmọrí rẹ̀, ó sì gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ lápá ọ̀tún téèyàn bá wọ inú ilé Jèhófà. Ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà máa ń kó gbogbo owó tí àwọn èèyàn bá mú wá sí ilé Jèhófà sí.+ 10 Nígbàkigbà tí wọ́n bá rí i pé owó ti pọ̀ nínú àpótí náà, akọ̀wé ọba àti àlùfáà àgbà á wá, wọ́n á kó owó náà,* wọ́n á sì ka owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà.+ 11 Wọ́n á kó owó tí wọ́n kà náà fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn, ní tiwọn á wá san án fún àwọn oníṣẹ́ igi àti àwọn kọ́lékọ́lé tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Jèhófà,+ 12 títí kan àwọn mọlémọlé àti àwọn agbẹ́kùúta. Wọ́n tún ra ẹ̀là gẹdú àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé Jèhófà, wọ́n sì ná owó náà sórí àwọn àtúnṣe míì tó jẹ mọ́ ilé náà.

13 Àmọ́, wọn kò fi ìkankan lára owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà ṣe àwọn bàsíà fàdákà, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́, àwọn kàkàkí+ tàbí ohun èlò èyíkéyìí tó jẹ́ wúrà tàbí fàdákà láti lò wọ́n ní ilé Jèhófà.+ 14 Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà nìkan ni wọ́n ń fún ní owó náà, wọ́n á sì fi tún ilé Jèhófà ṣe. 15 Wọn kì í sọ pé kí àwọn ọkùnrin náà ṣe ìṣirò owó tí wọ́n ní kí wọ́n fún àwọn òṣìṣẹ́, torí pé wọ́n ṣeé fọkàn tán.+ 16 Àmọ́ ṣá o, wọn kì í mú owó ẹbọ ẹ̀bi+ àti owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ilé Jèhófà; ti àwọn àlùfáà ni.+

17 Ìgbà náà ni Hásáẹ́lì+ ọba Síríà lọ bá Gátì+ jà, ó sì gbà á, lẹ́yìn náà ó pinnu láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.*+ 18 Ni Jèhóáṣì ọba Júdà bá kó gbogbo ọrẹ mímọ́ tí Jèhóṣáfátì, Jèhórámù àti Ahasáyà, àwọn baba ńlá rẹ̀, àwọn ọba Júdà, ti yà sí mímọ́ àti àwọn ọrẹ mímọ́ tirẹ̀ àti gbogbo wúrà tí wọ́n rí ní àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà àti ilé* ọba, ó sì kó wọn ránṣẹ́ sí Hásáẹ́lì ọba Síríà.+ Nítorí náà, ó fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀.

19 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóáṣì àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 20 Àmọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhóáṣì dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì pa á ní ilé Òkìtì,*+ ní ọ̀nà tó lọ sí Síílà. 21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, Jósákà ọmọ Ṣíméátì àti Jèhósábádì ọmọ Ṣómà, ló ṣá a balẹ̀, tí wọ́n sì pa á.+ Wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì, Amasááyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́