Jóṣúà
8 Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Má bẹ̀rù, má sì jáyà.+ Kó gbogbo ọkùnrin ogun, kí ẹ sì gòkè lọ bá ìlú Áì jà. Wò ó, mo ti fi ọba Áì lé yín lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, ìlú rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀.+ 2 Ohun tí o ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀ gẹ́lẹ́ ni kí o ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀,+ àmọ́ ẹ lè kó ẹrù ìlú náà àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ fún ara yín. Kí ẹ lúgọ sí ẹ̀yìn ìlú náà.”
3 Jóṣúà àti gbogbo ọkùnrin ogun wá lọ bá ìlú Áì jà. Jóṣúà yan àwọn jagunjagun tó lákíkanjú tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000), ó sì ní kí wọ́n lọ ní òru. 4 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ wò ó, ẹ lúgọ sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má jìnnà jù sí ìlú náà, kí gbogbo yín sì múra sílẹ̀. 5 Èmi àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú mi máa sún mọ́ ìlú náà, tí wọ́n bá sì jáde wá bá wa jà bíi ti tẹ́lẹ̀,+ a máa sá fún wọn. 6 Tí wọ́n bá ti tẹ̀ lé wa, a máa tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà, torí wọ́n á sọ pé, ‘Wọ́n ń sá fún wa bíi ti tẹ́lẹ̀.’+ A sì máa sá fún wọn. 7 Kí ẹ̀yin gbéra níbi tí ẹ lúgọ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà; Jèhófà Ọlọ́run yín máa fi lé yín lọ́wọ́. 8 Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ dáná sun ún.+ Ohun tí Jèhófà sọ ni kí ẹ ṣe. Ẹ wò ó, mo ti pàṣẹ fún yín.”
9 Jóṣúà wá ní kí wọ́n lọ, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọ́n máa lúgọ sí; wọ́n dúró sí àárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì, lápá ìwọ̀ oòrùn Áì, Jóṣúà sì sun ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn náà mọ́jú.
10 Lẹ́yìn tí Jóṣúà dìde ní àárọ̀ kùtù, tó sì kó àwọn ọmọ ogun jọ,* òun àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ṣáájú wọn lọ sí Áì. 11 Gbogbo àwọn ọkùnrin ogun+ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gòkè lọ, wọ́n sì forí lé iwájú ìlú náà. Wọ́n pàgọ́ sí àríwá ìlú Áì, àfonífojì wà láàárín àwọn àti ìlú Áì. 12 Ní àkókò yẹn, ó ti ní kí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin lọ lúgọ+ sí àárín Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì, lápá ìwọ̀ oòrùn ìlú náà. 13 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ogun náà pàgọ́ sí apá àríwá ìlú náà,+ àwọn ọmọ ogun tó wà lẹ́yìn pàgọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn ìlú náà,+ Jóṣúà sì lọ sí àárín àfonífojì* náà ní òru yẹn.
14 Gbàrà tí ọba Áì rí èyí, òun àtàwọn ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní àárọ̀ kùtù láti bá Ísírẹ́lì jagun ní ibì kan tí wọ́n ti lè rí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú náà látòkè. Àmọ́ kò mọ̀ pé wọ́n ti lúgọ de òun ní ẹ̀yìn ìlú náà. 15 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Áì gbéjà kò wọ́n, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì sá gba ọ̀nà aginjù.+ 16 Ni wọ́n bá pe gbogbo àwọn tó wà nínú ìlú náà pé kí wọ́n jọ lépa wọn; bí wọ́n sì ṣe ń lé Jóṣúà ni Ísírẹ́lì ń tàn wọ́n jìnnà sí ìlú náà. 17 Kò sí ọkùnrin kankan ní ìlú Áì àti Bẹ́tẹ́lì tí kò jáde láti lépa Ísírẹ́lì. Wọ́n ṣí ìlú náà sílẹ̀ gbayawu, wọ́n sì lé Ísírẹ́lì lọ.
18 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Na ọ̀kọ̀* tó wà lọ́wọ́ rẹ sí ìlú Áì,+ torí pé màá fi ìlú náà lé ọ lọ́wọ́.”+ Ni Jóṣúà bá na ọ̀kọ̀ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sí ìlú náà. 19 Gbàrà tó na ọwọ́ rẹ̀, àwọn tó lúgọ yára dìde, wọ́n sáré wọnú ìlú náà, wọ́n sì gbà á. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n dáná sun ìlú náà.+
20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Áì wo ẹ̀yìn, tí wọ́n rí èéfín tó ń tinú ìlú náà lọ sókè, wọn ò ní okun láti sá lọ sí ibì kankan. Àwọn tó ti ń sá lọ sí ọ̀nà aginjù bá ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì kọjú sí àwọn tó ń lé wọn. 21 Nígbà tí Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé àwọn tó lúgọ ti gba ìlú náà, tí wọ́n sì rí i tí èéfín ń tinú ìlú náà lọ sókè, wọ́n bá yíjú pa dà, wọ́n sì gbéjà ko àwọn ọmọ ogun Áì. 22 Àwọn yòókù jáde láti ìlú náà wá pàdé wọn, èyí mú kí àwọn ọmọ ogun Áì há sí àárín wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà ní iwájú àti ẹ̀yìn wọn, wọ́n pa wọ́n débi pé ẹnì kankan ò yè bọ́ tàbí kó sá mọ́ wọn lọ́wọ́.+ 23 Àmọ́ wọ́n mú ọba Áì+ láàyè, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Jóṣúà.
24 Lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì pa gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú Áì tán níbi gbalasa, nínú aginjù tí wọ́n lé wọn lọ, tí wọ́n sì ti fi idà pa gbogbo wọn láìṣẹ́ ku ẹnì kan, gbogbo Ísírẹ́lì pa dà sí Áì, wọ́n sì fi idà pa á run. 25 Gbogbo àwọn tí wọ́n pa lọ́jọ́ yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000), látorí ọkùnrin dórí obìnrin, gbogbo ará ìlú Áì. 26 Jóṣúà kò gbé ọwọ́ tó fi na ọ̀kọ̀+ náà wálẹ̀ títí ó fi pa gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú Áì run.+ 27 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrù ìlú náà fún ara wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà.+
28 Jóṣúà wá dáná sun ìlú Áì, ó sọ ọ́ di òkìtì àwókù,+ bó sì ṣe wà nìyẹn títí dòní. 29 Ó gbé ọba Áì kọ́ sórí òpó igi* títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn sì ti fẹ́ wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ pé kí wọ́n sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi.+ Wọ́n sì jù ú síbi àbáwọlé ẹnubodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta lé e lórí pelemọ, ó sì wà níbẹ̀ títí dòní.
30 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan sí Òkè Ébálì+ fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 31 bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bó sì ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin+ Mósè pé kó jẹ́: “Pẹpẹ tí wọ́n fi àwọn odindi òkúta ṣe, tí wọn ò fi irinṣẹ́ èyíkéyìí gbẹ́.”+ Wọ́n rú àwọn ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí rẹ̀ sí Jèhófà.+
32 Lẹ́yìn náà, ó kọ ẹ̀dà Òfin+ tí Mósè kọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ sára àwọn òkúta náà níbẹ̀. 33 Gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn àgbààgbà wọn, àwọn olórí àtàwọn adájọ́ wọn dúró sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àpótí náà, níwájú àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, tí wọ́n ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà. Àwọn àjèjì àtàwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà wà níbẹ̀.+ Ìdajì wọn dúró síwájú Òkè Gérísímù, ìdajì tó kù sì wà níwàjú Òkè Ébálì+ (bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ tẹ́lẹ̀),+ láti súre fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì. 34 Lẹ́yìn náà, ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin+ náà sókè, àwọn ìbùkún+ àti àwọn ègún+ tó wà nínú rẹ̀, bí wọ́n ṣe kọ gbogbo rẹ̀ sínú ìwé Òfin náà. 35 Kò sí ọ̀rọ̀ kankan nínú gbogbo ohun tí Mósè pa láṣẹ tí Jóṣúà kò kà sókè níwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì,+ títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé àtàwọn àjèjì+ tó ń gbé* láàárín wọn.+