ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà

      • Àwọn olórin àti àwọn akọrin ilé Ọlọ́run (1-31)

1 Kíróníkà 25:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aro.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 16:41, 42; 2Kr 5:11, 12; 35:15
  • +1Sa 10:5
  • +1Kr 15:16

1 Kíróníkà 25:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 16:41, 42
  • +1Kr 15:16, 18
  • +Ef 5:19

1 Kíróníkà 25:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 15:16, 19

1 Kíróníkà 25:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìwo rẹ̀.”

1 Kíróníkà 25:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 13:8; 15:16; 16:5

1 Kíróníkà 25:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 16:33

1 Kíróníkà 25:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 2
  • +1Kr 25:1, 3

1 Kíróníkà 25:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 2

1 Kíróníkà 25:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 2

1 Kíróníkà 25:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 4

1 Kíróníkà 25:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 4

1 Kíróníkà 25:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 4

1 Kíróníkà 25:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 25:1, 4

Àwọn míì

1 Kíró. 25:11Kr 16:41, 42; 2Kr 5:11, 12; 35:15
1 Kíró. 25:11Sa 10:5
1 Kíró. 25:11Kr 15:16
1 Kíró. 25:31Kr 16:41, 42
1 Kíró. 25:31Kr 15:16, 18
1 Kíró. 25:3Ef 5:19
1 Kíró. 25:41Kr 15:16, 19
1 Kíró. 25:61Kr 13:8; 15:16; 16:5
1 Kíró. 25:8Owe 16:33
1 Kíró. 25:91Kr 25:1, 2
1 Kíró. 25:91Kr 25:1, 3
1 Kíró. 25:101Kr 25:1, 2
1 Kíró. 25:121Kr 25:1, 2
1 Kíró. 25:201Kr 25:1, 4
1 Kíró. 25:291Kr 25:1, 4
1 Kíró. 25:301Kr 25:1, 4
1 Kíró. 25:311Kr 25:1, 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kíróníkà 25:1-31

Kíróníkà Kìíní

25 Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì+ sọ́tọ̀ láti máa fi háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti síńbálì*+ sọ tẹ́lẹ̀. Orúkọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ni, 2 látinú àwọn ọmọ Ásáfù: Sákúrì, Jósẹ́fù, Netanáyà àti Áṣárélà, àwọn ọmọ Ásáfù lábẹ́ ìdarí Ásáfù, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ lábẹ́ àṣẹ ọba. 3 Látinú Jédútúnì,+ àwọn ọmọ Jédútúnì ni: Gẹdaláyà, Séérì, Jeṣáyà, Ṣíméì, Haṣabáyà àti Matitáyà,+ wọ́n jẹ́ mẹ́fà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn Jédútúnì, ẹni tó ń fi háàpù sọ tẹ́lẹ̀, láti máa dúpẹ́ àti láti máa yin Jèhófà.+ 4 Látinú Hémánì,+ àwọn ọmọ Hémánì ni: Bùkáyà, Matanáyà, Úsíélì, Ṣẹ́búẹ́lì, Jérímótì, Hananáyà, Hánáánì, Élíátà, Gídálítì, Romamuti-ésérì, Joṣibẹ́káṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì. 5 Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Hémánì, aríran ọba tó bá ti kan ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run tòótọ́ láti gbé e* ga; torí náà, Ọlọ́run tòótọ́ fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá (14) àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 6 Gbogbo wọn wà lábẹ́ ìdarí bàbá wọn láti máa kọrin ní ilé Jèhófà pẹ̀lú síńbálì, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́.

Àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba ni Ásáfù, Jédútúnì àti Hémánì.

7 Àwọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn tí a ti kọ́ níṣẹ́ orin láti máa kọrin sí Jèhófà jẹ́ igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288), gbogbo wọn jẹ́ ọ̀jáfáfá. 8 Torí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ lórí iṣẹ́ wọn, bí ti ẹni kékeré ṣe rí bẹ́ẹ̀ ni ti ẹni ńlá, bíi ti ọ̀jáfáfá náà sì ni ti akẹ́kọ̀ọ́.

9 Kèké tó kọ́kọ́ jáde jẹ́ ti Ásáfù fún Jósẹ́fù,+ ìkejì fún Gẹdaláyà+ (òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ méjìlá [12]); 10 ìkẹta fún Sákúrì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 11 ìkẹrin fún Ísíráì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 12 ìkarùn-ún fún Netanáyà,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 13 ìkẹfà fún Bùkáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 14 ìkeje fún Jéṣárélà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 15 ìkẹjọ fún Jeṣáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 16 ìkẹsàn-án fún Matanáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 17 ìkẹwàá fún Ṣíméì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 18 ìkọkànlá fún Ásárẹ́lì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 19 ìkejìlá fún Haṣabáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 20 ìkẹtàlá fún Ṣúbáélì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 21 ìkẹrìnlá fún Matitáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 22 ìkẹẹ̀ẹ́dógún fún Jérémótì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 23 ìkẹrìndínlógún fún Hananáyà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 24 ìkẹtàdínlógún fún Joṣibẹ́káṣà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 25 ìkejìdínlógún fún Hánáánì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 26 ìkọkàndínlógún fún Málótì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 27 ogún fún Élíátà, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 28 ìkọkànlélógún fún Hótírì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 29 ìkejìlélógún fún Gídálítì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 30 ìkẹtàlélógún fún Máhásíótì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12); 31 ìkẹrìnlélógún fún Romamuti-ésérì,+ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá (12).

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́