ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sírà

      • Wọ́n tún pẹpẹ kọ́, wọ́n sì rú àwọn ẹbọ (1-6)

      • Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ńpìlì kọ́ (7-9)

      • Wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀ (10-13)

Ẹ́sírà 3:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 19

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 189

Ẹ́sírà 3:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hag 1:1
  • +Ẹsr 1:7, 8; Lk 3:23, 27
  • +1Kr 3:17; Mt 1:12
  • +Ẹk 20:24; 40:29

Ẹ́sírà 3:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 4:4
  • +Nọ 28:3, 4

Ẹ́sírà 3:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:16; Le 23:34
  • +Ẹk 29:38; Nọ 29:12, 13

Ẹ́sírà 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:39, 42
  • +Nọ 10:10; Sm 81:3
  • +Di 16:16
  • +Di 12:5, 6

Ẹ́sírà 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 29:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 19

Ẹ́sírà 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:17
  • +Ẹsr 5:8
  • +Joṣ 19:46, 48; 1Kr 22:3, 4; 2Kr 2:10, 16
  • +Ẹsr 1:2, 3; 6:3, 4

Ẹ́sírà 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 7:6, 7

Ẹ́sírà 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 3:18

Ẹ́sírà 3:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aro.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 4:9
  • +Nọ 10:8
  • +1Kr 6:31, 32; 23:5; 25:1

Ẹ́sírà 3:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:21; Ne 12:24
  • +1Kr 16:34; 2Kr 7:3

Ẹ́sírà 3:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:22; Hag 2:3
  • +Sm 126:1, 6; Ais 35:10; Sek 4:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 16

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 18

Àwọn míì

Ẹ́sírà 3:11Ọb 8:2
Ẹ́sírà 3:2Hag 1:1
Ẹ́sírà 3:2Ẹsr 1:7, 8; Lk 3:23, 27
Ẹ́sírà 3:21Kr 3:17; Mt 1:12
Ẹ́sírà 3:2Ẹk 20:24; 40:29
Ẹ́sírà 3:3Ẹsr 4:4
Ẹ́sírà 3:3Nọ 28:3, 4
Ẹ́sírà 3:4Ẹk 23:16; Le 23:34
Ẹ́sírà 3:4Ẹk 29:38; Nọ 29:12, 13
Ẹ́sírà 3:5Ẹk 29:39, 42
Ẹ́sírà 3:5Nọ 10:10; Sm 81:3
Ẹ́sírà 3:5Di 16:16
Ẹ́sírà 3:5Di 12:5, 6
Ẹ́sírà 3:6Nọ 29:1
Ẹ́sírà 3:71Ọb 5:17
Ẹ́sírà 3:7Ẹsr 5:8
Ẹ́sírà 3:7Joṣ 19:46, 48; 1Kr 22:3, 4; 2Kr 2:10, 16
Ẹ́sírà 3:7Ẹsr 1:2, 3; 6:3, 4
Ẹ́sírà 3:8Ne 7:6, 7
Ẹ́sírà 3:9Ne 3:18
Ẹ́sírà 3:10Sek 4:9
Ẹ́sírà 3:10Nọ 10:8
Ẹ́sírà 3:101Kr 6:31, 32; 23:5; 25:1
Ẹ́sírà 3:11Ẹk 15:21; Ne 12:24
Ẹ́sírà 3:111Kr 16:34; 2Kr 7:3
Ẹ́sírà 3:121Ọb 6:22; Hag 2:3
Ẹ́sírà 3:12Sm 126:1, 6; Ais 35:10; Sek 4:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́sírà 3:1-13

Ẹ́sírà

3 Nígbà tí oṣù keje+ pé, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan. 2 Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà àti Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ dìde, wọ́n sì mọ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè máa rú àwọn ẹbọ sísun lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.

3 Nítorí náà, wọ́n mọ pẹpẹ náà sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń bà wọ́n,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà lórí rẹ̀, àwọn ẹbọ sísun òwúrọ̀ àti ti ìrọ̀lẹ́.+ 4 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀,+ ojoojúmọ́ ni wọ́n sì máa ń rú iye ẹbọ sísun tó yẹ kí wọ́n rú lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.+ 5 Lẹ́yìn èyí, wọ́n rú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo + àti ẹbọ tó wà fún àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn tó wà fún gbogbo àsìkò àjọyọ̀ tí a yà sí mímọ́+ fún Jèhófà, títí kan àwọn ọrẹ àtinúwá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fínnúfíndọ̀ mú wá+ fún Jèhófà. 6 Láti ọjọ́ kìíní oṣù keje,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀.

7 Wọ́n fún àwọn agékùúta+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà+ lówó, wọ́n tún kó oúnjẹ àti ohun mímu pẹ̀lú òróró fún àwọn ọmọ Sídónì àti àwọn ará Tírè, torí wọ́n kó gẹdú igi kédárì láti Lẹ́bánónì gba orí òkun wá sí Jópà,+ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kírúsì ọba Páṣíà fún wọn.+

8 Ní ọdún kejì, lẹ́yìn tí wọ́n wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù, ní oṣù kejì, Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì àti Jéṣúà ọmọ Jèhósádákì àti ìyókù àwọn arákùnrin wọn, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú gbogbo àwọn tó jáde wá sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn+ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà; wọ́n yan àwọn ọmọ Léfì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè láti jẹ́ alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà. 9 Torí náà, Jéṣúà àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Kádímíélì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Júdà, dara pọ̀ láti máa bójú tó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, bákan náà, àwọn ọmọ Hénádádì+ àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, tí àwọn náà jẹ́ ọmọ Léfì dara pọ̀ mọ́ wọn.

10 Nígbà tí àwọn kọ́lékọ́lé fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀,+ àwọn àlùfáà wọ aṣọ iṣẹ́ wọn, wọ́n mú kàkàkí+ dání, àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn àwọn ọmọ Ásáfù mú síńbálì* dání, wọ́n dìde dúró láti yin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì fi lélẹ̀.+ 11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀. 12 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú àwọn olórí agbo ilé, ìyẹn àwọn àgbààgbà tó mọ bí ilé náà ṣe rí tẹ́lẹ̀,+ sunkún kíkankíkan nígbà tí wọ́n rí i tí à ń fi ìpìlẹ̀ ilé yìí lélẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì ń kígbe ayọ̀ bí ohùn wọn ṣe ròkè tó.+ 13 Nítorí náà, àwọn èèyàn ò mọ ìyàtọ̀ nínú igbe ayọ̀ àti igbe ẹkún náà, torí igbe àwọn èèyàn náà ròkè débi pé àwọn tó wà ní ibi tó jìnnà réré ń gbọ́ igbe wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́