ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ábúrámù kúrò ní Háránì lọ sí Kénáánì (1-9)

        • Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúrámù (7)

      • Ábúrámù àti Sáráì ní Íjíbítì (10-20)

Jẹ́nẹ́sísì 12:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 24:3; Iṣe 7:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2014, ojú ìwé 9

    11/1/2001, ojú ìwé 31

    8/15/2001, ojú ìwé 15-16

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 74-75

Jẹ́nẹ́sísì 12:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 13:14, 16; 15:1, 5; 17:5; 22:17, 18; Di 26:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 14

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2014, ojú ìwé 9

    3/15/2013, ojú ìwé 20-21

    8/15/2001, ojú ìwé 15-16

    2/1/1998, ojú ìwé 8-9

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 30

Jẹ́nẹ́sísì 12:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yóò gba ìbùkún fún ara wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:29, 30
  • +Iṣe 3:25; Ga 3:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2020 ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2014, ojú ìwé 9

    3/15/2013, ojú ìwé 20-21

    2/1/1998, ojú ìwé 8-9

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 30

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 47

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 83

Jẹ́nẹ́sísì 12:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 17

Jẹ́nẹ́sísì 12:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 11:29
  • +Jẹ 11:31
  • +Jẹ 13:5, 6
  • +Jẹ 26:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 14

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 30

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 17

Jẹ́nẹ́sísì 12:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:15, 16
  • +Jẹ 35:4; Di 11:29, 30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 18

Jẹ́nẹ́sísì 12:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:15; 21:12; 28:13, 14; Ro 9:7; Ga 3:16
  • +Jẹ 13:14, 15; 15:1, 7; 17:1, 8; Di 34:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 14

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 18-19

    2/1/1998, ojú ìwé 8-9

    2/2020, ojú ìwé 5-6

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 83-84, 101

Jẹ́nẹ́sísì 12:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:16-19; 31:13
  • +Jẹ 13:1, 3; Joṣ 7:2
  • +Jẹ 8:20; 35:2, 3
  • +Jẹ 26:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 19

    2/2020, ojú ìwé 5-6

Jẹ́nẹ́sísì 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:1; 24:62

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 19

Jẹ́nẹ́sísì 12:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kó lè máa gbé ibẹ̀ bí àjèjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:13
  • +Jẹ 26:1, 2

Jẹ́nẹ́sísì 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:7

Jẹ́nẹ́sísì 12:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 14-15

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 20

    2/1/1992, ojú ìwé 31

Jẹ́nẹ́sísì 12:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí ọkàn mi lè wà láàyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2020, ojú ìwé 5

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2017, ojú ìwé 13

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 14-15

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 20-21

Jẹ́nẹ́sísì 12:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 15

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2015, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 12:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:14; 24:34, 35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2017 ojú ìwé 15

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2011, ojú ìwé 16-17

    8/15/2001, ojú ìwé 21

Jẹ́nẹ́sísì 12:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyọnu àjàkálẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 11:29; 17:15; 23:2, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 21

Jẹ́nẹ́sísì 12:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2001, ojú ìwé 21

Jẹ́nẹ́sísì 12:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    2/1/1992, ojú ìwé 31

Jẹ́nẹ́sísì 12:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:14

Àwọn míì

Jẹ́n. 12:1Joṣ 24:3; Iṣe 7:3, 4
Jẹ́n. 12:2Jẹ 13:14, 16; 15:1, 5; 17:5; 22:17, 18; Di 26:5
Jẹ́n. 12:3Jẹ 27:29, 30
Jẹ́n. 12:3Iṣe 3:25; Ga 3:8
Jẹ́n. 12:4Heb 11:8
Jẹ́n. 12:5Jẹ 11:29
Jẹ́n. 12:5Jẹ 11:31
Jẹ́n. 12:5Jẹ 13:5, 6
Jẹ́n. 12:5Jẹ 26:3
Jẹ́n. 12:6Iṣe 7:15, 16
Jẹ́n. 12:6Jẹ 35:4; Di 11:29, 30
Jẹ́n. 12:7Jẹ 3:15; 21:12; 28:13, 14; Ro 9:7; Ga 3:16
Jẹ́n. 12:7Jẹ 13:14, 15; 15:1, 7; 17:1, 8; Di 34:4
Jẹ́n. 12:8Jẹ 28:16-19; 31:13
Jẹ́n. 12:8Jẹ 13:1, 3; Joṣ 7:2
Jẹ́n. 12:8Jẹ 8:20; 35:2, 3
Jẹ́n. 12:8Jẹ 26:25
Jẹ́n. 12:9Jẹ 20:1; 24:62
Jẹ́n. 12:10Sm 105:13
Jẹ́n. 12:10Jẹ 26:1, 2
Jẹ́n. 12:11Jẹ 26:7
Jẹ́n. 12:13Jẹ 20:11, 12
Jẹ́n. 12:16Jẹ 20:14; 24:34, 35
Jẹ́n. 12:17Jẹ 11:29; 17:15; 23:2, 19
Jẹ́n. 12:19Jẹ 20:11, 12
Jẹ́n. 12:20Sm 105:14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 12:1-20

Jẹ́nẹ́sísì

12 Jèhófà sì sọ fún Ábúrámù pé: “Kúrò ní ilẹ̀ rẹ, kí o kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ àti ilé bàbá rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.+ 2 Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá, màá sì bù kún ọ. Màá mú kí orúkọ rẹ di ńlá, ó sì máa jẹ́ ìbùkún.+ 3 Màá súre fún àwọn tó ń súre fún ọ, màá sì gégùn-ún fún ẹni tó bá gégùn-ún fún ọ,+ ó dájú pé gbogbo ìdílé tó wà lórí ilẹ̀ yóò rí ìbùkún gbà* nípasẹ̀ rẹ.”+

4 Torí náà, Ábúrámù gbéra, bí Jèhófà ṣe sọ fún un, Lọ́ọ̀tì sì bá a lọ. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) ni Ábúrámù nígbà tó kúrò ní Háránì.+ 5 Ábúrámù mú Sáráì+ ìyàwó rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀,+ ó kó gbogbo ẹrù tí wọ́n ti ní+ àti àwọn èèyàn* tó jẹ́ tiwọn ní Háránì, wọ́n sì forí lé ilẹ̀ Kénáánì.+ Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì, 6 Ábúrámù rin ilẹ̀ náà já títí dé ibi tí Ṣékémù+ wà, nítòsí àwọn igi ńlá tó wà ní Mórè.+ Àwọn ọmọ Kénáánì wà ní ilẹ̀ náà nígbà yẹn. 7 Jèhófà wá fara han Ábúrámù, ó sì sọ pé: “Ọmọ* rẹ+ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí.”+ Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tó fara hàn án. 8 Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè olókè tó wà ní ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó pa àgọ́ rẹ̀ síbẹ̀, Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà, Áì+ sì wà ní ìlà oòrùn. Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.+ 9 Lẹ́yìn náà, Ábúrámù kó kúrò níbẹ̀, ó sì gba ọ̀nà Négébù+ lọ, ó ń pa àgọ́ láti ibì kan dé ibòmíì.

10 Ìyàn wá mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì gbéra lọ sí Íjíbítì kó lè gbé ibẹ̀ fúngbà díẹ̀,*+ torí ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.+ 11 Bó ṣe fẹ́ wọ Íjíbítì, ó sọ fún Sáráì ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Mo mọ̀ pé o rẹwà gan-an lóbìnrin.+ 12 Tí àwọn ará Íjíbítì bá sì rí ọ, ó dájú pé wọ́n á sọ pé, ‘Ìyàwó rẹ̀ nìyí.’ Wọ́n á pa mí, àmọ́ wọ́n á dá ọ sí. 13 Jọ̀ọ́, sọ fún wọn pé àbúrò mi ni ọ́, kí nǹkan kan má bàa ṣe mí torí rẹ, kí wọ́n lè dá ẹ̀mí mi sí.”*+

14 Gbàrà tí Ábúrámù wọ Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì rí i pé obìnrin náà rẹwà gan-an. 15 Àwọn ìjòyè Fáráò pẹ̀lú rí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn rẹ̀ dáadáa fún Fáráò, débi pé wọ́n mú obìnrin náà lọ sí ilé Fáráò. 16 Fáráò tọ́jú Ábúrámù dáadáa nítorí obìnrin náà, Ábúrámù sì wá ní àwọn àgùntàn, màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin àti àwọn ràkúnmí.+ 17 Jèhófà fi àjàkálẹ̀ àrùn* kọ lu Fáráò àti agbo ilé rẹ̀ nítorí Sáráì, ìyàwó Ábúrámù.+ 18 Ni Fáráò bá pe Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí o ò sọ fún mi pé ìyàwó rẹ ni? 19 Kí ló dé tí o sọ pé, ‘Àbúrò+ mi ni,’ tó fi jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí n fi ṣe aya? Ìyàwó rẹ nìyí. Mú un, kí o sì máa lọ!” 20 Ni Fáráò bá pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ nípa Ábúrámù, wọ́n sì ní kí Ábúrámù àti ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ìlú náà pẹ̀lú gbogbo ohun tó ní.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́