ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó fi Ísákì rúbọ (1-19)

        • Àwọn èèyàn yóò rí ìbùkún gbà torí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù (15-18)

      • Ìdílé Rèbékà (20-24)

Jẹ́nẹ́sísì 22:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/1998, ojú ìwé 6

Jẹ́nẹ́sísì 22:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:16
  • +Jẹ 17:19; Joṣ 24:3; Ro 9:7
  • +2Kr 3:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 23

    2/1/2009, ojú ìwé 18

    8/15/2007, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 22:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 18

Jẹ́nẹ́sísì 22:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2016, ojú ìwé 7

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 18

Jẹ́nẹ́sísì 22:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀bẹ ìpẹran.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2017, ojú ìwé 32

Jẹ́nẹ́sísì 22:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:29; 1Pe 1:18, 19

Jẹ́nẹ́sísì 22:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 10:17, 18

Jẹ́nẹ́sísì 22:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀bẹ ìpẹran.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:17

Jẹ́nẹ́sísì 22:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:17-19; Jem 2:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2020, ojú ìwé 2

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 18

    4/15/1998, ojú ìwé 6

Jẹ́nẹ́sísì 22:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Yóò Pèsè; Jèhófà Yóò Rí sí I.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 22:2; 2Kr 3:1

Jẹ́nẹ́sísì 22:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 6:13, 14
  • +Jo 3:16; Ro 8:32; Heb 11:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2012, ojú ìwé 23-24

Jẹ́nẹ́sísì 22:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Tàbí “àwọn ìlú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 13:14, 16; 15:1, 5; Iṣe 3:25
  • +Sm 2:8; Da 2:44

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2008, ojú ìwé 21

    9/15/2004, ojú ìwé 9

    6/1/2004, ojú ìwé 11

    5/15/2000, ojú ìwé 15-16

    2/1/1998, ojú ìwé 9-12, 17-18

Jẹ́nẹ́sísì 22:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:15; Ro 9:7; Ga 3:16
  • +Ga 3:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2020 ojú ìwé 14-15

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2018, ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2009, ojú ìwé 4

    4/1/2009, ojú ìwé 12

    9/1/2000, ojú ìwé 20

    5/15/2000, ojú ìwé 15-16

    2/1/1998, ojú ìwé 9-12, 14

    7/1/1995, ojú ìwé 11

    1/15/1995, ojú ìwé 18-19

    3/15/1994, ojú ìwé 18

    4/15/1992, ojú ìwé 7-8

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 311-312

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 89, 180

Jẹ́nẹ́sísì 22:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:31

Jẹ́nẹ́sísì 22:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 11:26, 29

Jẹ́nẹ́sísì 22:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:20

Jẹ́nẹ́sísì 22:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:15; Ro 9:10

Jẹ́nẹ́sísì 22:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Àwọn míì

Jẹ́n. 22:1Heb 11:17
Jẹ́n. 22:2Jo 3:16
Jẹ́n. 22:2Jẹ 17:19; Joṣ 24:3; Ro 9:7
Jẹ́n. 22:22Kr 3:1
Jẹ́n. 22:8Jo 1:29; 1Pe 1:18, 19
Jẹ́n. 22:9Jo 10:17, 18
Jẹ́n. 22:10Heb 11:17
Jẹ́n. 22:12Heb 11:17-19; Jem 2:21
Jẹ́n. 22:14Jẹ 22:2; 2Kr 3:1
Jẹ́n. 22:16Heb 6:13, 14
Jẹ́n. 22:16Jo 3:16; Ro 8:32; Heb 11:17
Jẹ́n. 22:17Jẹ 13:14, 16; 15:1, 5; Iṣe 3:25
Jẹ́n. 22:17Sm 2:8; Da 2:44
Jẹ́n. 22:18Jẹ 3:15; Ro 9:7; Ga 3:16
Jẹ́n. 22:18Ga 3:8
Jẹ́n. 22:19Jẹ 21:31
Jẹ́n. 22:20Jẹ 11:26, 29
Jẹ́n. 22:22Jẹ 25:20
Jẹ́n. 22:23Jẹ 24:15; Ro 9:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 22:1-24

Jẹ́nẹ́sísì

22 Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò,+ ó ní: “Ábúráhámù!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí!” 2 Ó wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, mú ọmọ rẹ, ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi,+ ìyẹn Ísákì,+ kí o sì lọ sí ilẹ̀ Moráyà,+ kí o fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí màá fi hàn ọ́.”

3 Torí náà, Ábúráhámù jí ní àárọ̀ kùtù, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀,* ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dání pẹ̀lú Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó la igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó gbéra, ó sì lọ síbi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un. 4 Ní ọjọ́ kẹta, Ábúráhámù gbójú sókè, ó sì rí ibẹ̀ ní ọ̀ọ́kán. 5 Ábúráhámù wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níbí, àmọ́ èmi àti ọmọ náà máa lọ síbẹ̀ yẹn láti jọ́sìn, a ó sì pa dà wá bá yín.”

6 Ábúráhámù wá gbé igi tó fẹ́ fi dáná ẹbọ sísun náà, ó sì gbé e ru Ísákì ọmọ rẹ̀. Ó mú iná àti ọ̀bẹ* dání, àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ. 7 Ísákì wá sọ fún Ábúráhámù bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí, ọmọ mi!” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Iná àti igi rèé, àmọ́ ibo ni àgùntàn tí a máa fi rú ẹbọ sísun wà?” 8 Ábúráhámù fèsì pé: “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa pèsè àgùntàn tí a máa fi rú ẹbọ sísun.”+ Àwọn méjèèjì sì jọ ń rìn lọ.

9 Níkẹyìn, wọ́n dé ibi tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un, Ábúráhámù wá mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì to igi sórí rẹ̀. Ó de Ísákì ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó sì gbé e sórí igi tó wà lórí pẹpẹ náà.+ 10 Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ* kó lè pa ọmọ+ rẹ̀. 11 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà pè é láti ọ̀run, ó sì sọ pé: “Ábúráhámù, Ábúráhámù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 12 Ó sì sọ pé: “Má pa ọmọ náà, má sì ṣe ohunkóhun sí i, torí mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, torí o ò kọ̀ láti fún mi+ ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní.” 13 Ni Ábúráhámù bá wòkè, ó sì rí àgbò kan ní ọ̀ọ́kán tí ìwo rẹ̀ há sínú igbó. Ábúráhámù lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. 14 Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Jèhófà-jirè.* Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ọ́ títí dòní pé: “Orí òkè Jèhófà ni a ó ti pèsè.”+

15 Áńgẹ́lì Jèhófà tún pe Ábúráhámù lẹ́ẹ̀kejì láti ọ̀run, 16 ó sọ pé: “‘Mo fi ara mi búra pé torí ohun tí o ṣe yìí,’ ni Jèhófà+ wí, ‘tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ, ọ̀kan ṣoṣo+ tí o ní, 17 ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti iyanrìn etí òkun,+ ọmọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 18 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ*+ rẹ torí pé o fetí sí ohùn+ mi.’”

19 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n gbéra, wọ́n sì jọ pa dà sí Bíá-ṣébà;+ Ábúráhámù sì ń gbé ní Bíá-ṣébà.

20 Lẹ́yìn èyí, wọ́n ròyìn fún Ábúráhámù pé: “Mílíkà náà ti bí àwọn ọmọ fún Náhórì arákùnrin+ rẹ: 21 Úsì ni àkọ́bí rẹ̀, Búsì ni àbúrò àti Kémúélì bàbá Árámù, 22 Késédì, Hásò, Pílídáṣì, Jídíláfù àti Bẹ́túẹ́lì.”+ 23 Bẹ́túẹ́lì bí Rèbékà.+ Àwọn mẹ́jọ yìí ni Mílíkà bí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù. 24 Wáhàrì* rẹ̀ tó ń jẹ́ Réúmà náà bímọ: Tébà, Gáhámù, Táháṣì àti Máákà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́