ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Émọ́sì 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Émọ́sì

      • Ìdájọ́ Ọlọ́run kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ (1-10)

      • Ọlọ́run á gbé àtíbàbà Dáfídì dìde (11-15)

Émọ́sì 9:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:1; Isk 1:27, 28
  • +Emọ 2:14

Émọ́sì 9:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 18

Émọ́sì 9:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:24

Émọ́sì 9:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:33
  • +Di 28:63, 65

Émọ́sì 9:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ayé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 1:4
  • +Ho 4:3
  • +Emọ 8:8

Émọ́sì 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 36:27, 28; Sm 135:7
  • +Ẹk 3:15; Emọ 4:13; 5:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2009, ojú ìwé 16-17

Émọ́sì 9:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:51
  • +Jer 47:4
  • +2Ọb 16:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    2/1/1995, ojú ìwé 31

Émọ́sì 9:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 13:34; 2Ọb 18:11
  • +Jer 30:11

Émọ́sì 9:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:33; Di 28:64

Émọ́sì 9:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àgọ́; ahéré.”

  • *

    Tàbí “wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 9:6, 7; 16:5; Jer 23:5; Isk 37:24, 25; Sek 12:8; Lk 1:31-33
  • +2Sa 7:11; Iṣe 15:16-18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2013, ojú ìwé 8-9

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 109

Émọ́sì 9:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:18; Ais 11:14; Ọbd 18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2012, ojú ìwé 6

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 109

Émọ́sì 9:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “máa yọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:5; Ho 2:22
  • +Joẹ 3:18
  • +Ais 35:1; 55:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 18-19

Émọ́sì 9:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 3:1; Jer 30:3; Isk 39:25
  • +Ais 61:4; Isk 36:33
  • +Ais 65:21, 22; Isk 28:25, 26
  • +Ais 62:8, 9; Mik 4:4

Émọ́sì 9:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 60:21; Isk 34:27, 28; 37:25

Àwọn míì

Émọ́sì 9:1Ais 6:1; Isk 1:27, 28
Émọ́sì 9:1Emọ 2:14
Émọ́sì 9:3Jer 23:24
Émọ́sì 9:4Le 26:33
Émọ́sì 9:4Di 28:63, 65
Émọ́sì 9:5Mik 1:4
Émọ́sì 9:5Ho 4:3
Émọ́sì 9:5Emọ 8:8
Émọ́sì 9:6Job 36:27, 28; Sm 135:7
Émọ́sì 9:6Ẹk 3:15; Emọ 4:13; 5:8
Émọ́sì 9:7Ẹk 12:51
Émọ́sì 9:7Jer 47:4
Émọ́sì 9:72Ọb 16:9
Émọ́sì 9:81Ọb 13:34; 2Ọb 18:11
Émọ́sì 9:8Jer 30:11
Émọ́sì 9:9Le 26:33; Di 28:64
Émọ́sì 9:11Ais 9:6, 7; 16:5; Jer 23:5; Isk 37:24, 25; Sek 12:8; Lk 1:31-33
Émọ́sì 9:112Sa 7:11; Iṣe 15:16-18
Émọ́sì 9:12Nọ 24:18; Ais 11:14; Ọbd 18, 19
Émọ́sì 9:13Le 26:5; Ho 2:22
Émọ́sì 9:13Joẹ 3:18
Émọ́sì 9:13Ais 35:1; 55:12
Émọ́sì 9:14Ẹsr 3:1; Jer 30:3; Isk 39:25
Émọ́sì 9:14Ais 61:4; Isk 36:33
Émọ́sì 9:14Ais 65:21, 22; Isk 28:25, 26
Émọ́sì 9:14Ais 62:8, 9; Mik 4:4
Émọ́sì 9:15Ais 60:21; Isk 34:27, 28; 37:25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Émọ́sì 9:1-15

Émọ́sì

9 Mo rí i tí Jèhófà+ dúró lókè pẹpẹ, ó sì sọ pé: “Lu orí òpó, àwọn ibi àbáwọlé á sì mì jìgìjìgì. Gé orí wọn kúrò, màá sì fi idà pa èyí tó gbẹ̀yìn lára wọn. Kò sí ẹnì kankan lára wọn tó máa lè sá lọ tàbí tó máa sá àsálà.+

 2 Bí wọ́n bá walẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,*

Ibẹ̀ ni ọwọ́ mi á ti tẹ̀ wọ́n;

Bí wọ́n bá sì gòkè lọ sí ọ̀run,

Ibẹ̀ ni màá ti fà wọ́n sọ̀ kalẹ̀.

 3 Bí wọ́n bá fara pa mọ́ sórí òkè Kámẹ́lì,

Ibẹ̀ ni màá ti wá wọn kàn, màá sì mú wọn.+

Bí wọ́n bá sì fara pa mọ́ kúrò ní ojú mi ní ìsàlẹ̀ òkun,

Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún ejò, á sì bù wọ́n ṣán.

 4 Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lọ sí oko ẹrú,

Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún idà, yóò sì pa wọ́n;+

Màá dájú sọ wọ́n, kì í ṣe fún ire, bí kò ṣe fún ibi.+

 5 Nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni tó fọwọ́ kan ilẹ̀ náà,*

Kí ó lè yọ́,+ kí gbogbo àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀;+

Gbogbo rẹ̀ á ru sókè bí odò Náílì,

Á sì rọlẹ̀ bí odò Náílì Íjíbítì.+

 6 ‘Ẹni tó ṣe àwọn àtẹ̀gùn Rẹ̀ lọ sí ọ̀run,

Tó sì dá àwọn nǹkan sí òkè ayé;

Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkun,

Kí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+

Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.’+

 7 ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe bí àwọn ọmọ Kúṣì lẹ jẹ́ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí.

‘Ṣé mi ò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+

Àti àwọn Filísínì kúrò ní Kírétè+ àti Síríà kúrò ní Kírì?’+

 8 ‘Wò ó! Ojú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára ìjọba tó ń dẹ́ṣẹ̀,

Á sì pa á rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀.+

Ṣùgbọ́n, mi ò ní pa gbogbo ilé Jékọ́bù rẹ́,’+ ni Jèhófà wí.

 9 ‘Wò ó! Mò ń pàṣẹ,

Màá mi ilé Ísírẹ́lì jìgìjìgì láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+

Bí èèyàn ṣe ń mi ajọ̀ jìgìjìgì,

Tí òkúta róbótó kankan kò sì ní bọ́ sílẹ̀.

10 Idà ni yóò pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó wà nínú àwọn èèyàn mi,

Àwọn tó ń sọ pé, “Àjálù kò ní sún mọ́ wa tàbí kó dé ọ̀dọ̀ wa.”’

11 ‘Ní ọjọ́ yẹn, màá gbé àtíbàbà* Dáfídì+ tó ti wó dìde,

Màá sì tún àwọn àlàfo rẹ̀* ṣe,

Màá tún àwókù rẹ̀ kọ́;

Màá tún un kọ́, á sì rí bíi ti tẹ́lẹ̀,+

12 Kí wọ́n lè gba ohun tó ṣẹ́ kù nínú Édómù,+

Àti ohun tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a fi orúkọ mi pè,’ ni Jèhófà, ẹni tó ń ṣe nǹkan yìí wí.

13 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí,

‘Nígbà tí atúlẹ̀ máa lé olùkórè bá,

Tí ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ èso àjàrà á sì lé ẹni tó gbé irúgbìn bá;+

Tí wáìnì dídùn á máa kán tótó láti ara àwọn òkè ńlá,+

Tí á sì máa ṣàn jáde* lára gbogbo àwọn òkè kéékèèké.+

14 Màá kó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn pa dà,+

Wọ́n á tún àwọn ìlú tó ti di ahoro kọ́, wọ́n á sì máa gbé inú wọn;+

Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n á sì mu wáìnì wọn,+

Wọ́n á ṣe ọgbà, wọ́n á sì jẹ èso wọn.’+

15 ‘Màá gbìn wọ́n sórí ilẹ̀ wọn,

A kò sì ní fà wọ́n tu mọ́

Kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́