ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ábúráhámù yóò di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè (1-8)

        • Orúkọ Ábúrámù yí pa dà sí Ábúráhámù (5)

      • Májẹ̀mú nípa ìdádọ̀dọ́ (9-14)

      • Orúkọ Sáráì yí pa dà sí Sérà (15-17)

      • Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò bí Ísákì (18-27)

Jẹ́nẹ́sísì 17:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Máa rìn níwájú mi.”

  • *

    Tàbí “aláìlábùkù.”

Jẹ́nẹ́sísì 17:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18; Sm 105:8-11
  • +Jẹ 22:17; Di 1:10; Heb 11:11, 12

Jẹ́nẹ́sísì 17:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:9-11
  • +Jẹ 13:16; Ro 4:17

Jẹ́nẹ́sísì 17:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Bàbá Ga (Di Ẹni Àgbéga).”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Bàbá Èèyàn Rẹpẹtẹ (Ogunlọ́gọ̀); Bàbá Ọ̀pọ̀ Èèyàn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 17:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 84, 87

Jẹ́nẹ́sísì 17:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 1:72, 73

Jẹ́nẹ́sísì 17:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:4; Heb 11:8, 9
  • +Di 14:2

Jẹ́nẹ́sísì 17:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Jẹ́nẹ́sísì 17:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Tàbí “kọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:4; Ro 2:29

Jẹ́nẹ́sísì 17:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọ ara yín nílà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:8; Ro 4:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2007, ojú ìwé 12-13

Jẹ́nẹ́sísì 17:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọlà.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 2:21

Jẹ́nẹ́sísì 17:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:44

Jẹ́nẹ́sísì 17:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Jẹ́nẹ́sísì 17:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Alárìíyànjiyàn.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Yóò Di Ìyá Àwọn Ọba.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 11:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 14

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 17:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 14

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 96

Jẹ́nẹ́sísì 17:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:12
  • +Ro 4:19; Heb 11:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 5 2017 ojú ìwé 14

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 84

Jẹ́nẹ́sísì 17:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:11

Jẹ́nẹ́sísì 17:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ẹ̀rín.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 1:2
  • +Jẹ 26:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 13-14

Jẹ́nẹ́sísì 17:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:10; 21:13, 18; 25:13-16; 1Kr 1:29-31

Jẹ́nẹ́sísì 17:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:3; Heb 11:8, 9
  • +Jẹ 18:10, 14; 21:1

Jẹ́nẹ́sísì 17:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó sì kọ wọ́n nílà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:13

Jẹ́nẹ́sísì 17:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:8; Ro 4:11

Jẹ́nẹ́sísì 17:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:16

Àwọn míì

Jẹ́n. 17:2Jẹ 15:18; Sm 105:8-11
Jẹ́n. 17:2Jẹ 22:17; Di 1:10; Heb 11:11, 12
Jẹ́n. 17:4Sm 105:9-11
Jẹ́n. 17:4Jẹ 13:16; Ro 4:17
Jẹ́n. 17:6Jẹ 35:10, 11
Jẹ́n. 17:7Lk 1:72, 73
Jẹ́n. 17:8Ẹk 6:4; Heb 11:8, 9
Jẹ́n. 17:8Di 14:2
Jẹ́n. 17:10Jẹ 21:4; Ro 2:29
Jẹ́n. 17:11Iṣe 7:8; Ro 4:11
Jẹ́n. 17:12Lk 2:21
Jẹ́n. 17:13Ẹk 12:44
Jẹ́n. 17:15Jẹ 11:29
Jẹ́n. 17:16Jẹ 18:10
Jẹ́n. 17:17Jẹ 18:12
Jẹ́n. 17:17Ro 4:19; Heb 11:11
Jẹ́n. 17:18Jẹ 16:11
Jẹ́n. 17:19Mt 1:2
Jẹ́n. 17:19Jẹ 26:24
Jẹ́n. 17:20Jẹ 16:10; 21:13, 18; 25:13-16; 1Kr 1:29-31
Jẹ́n. 17:21Jẹ 26:3; Heb 11:8, 9
Jẹ́n. 17:21Jẹ 18:10, 14; 21:1
Jẹ́n. 17:23Jẹ 17:13
Jẹ́n. 17:24Iṣe 7:8; Ro 4:11
Jẹ́n. 17:25Jẹ 16:16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 17:1-27

Jẹ́nẹ́sísì

17 Nígbà tí Ábúrámù pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè. Máa bá mi rìn,* kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.* 2 Màá fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá ọ dá+ múlẹ̀, màá sì mú kí o di púpọ̀ gan-an.”+

3 Ni Ábúrámù bá dojú bolẹ̀, Ọlọ́run tún sọ fún un pé: 4 “Wò ó! Ní tèmi, mo ti bá ọ dá májẹ̀mú,+ ó sì dájú pé wàá di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.+ 5 O ò ní jẹ́ Ábúrámù* mọ́; orúkọ rẹ yóò di Ábúráhámù,* torí màá mú kí o di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. 6 Màá mú kí o bímọ tó pọ̀ gan-an, màá mú kí o di àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba yóò sì tinú rẹ jáde.+

7 “Màá mú májẹ̀mú mi ṣẹ, tí mo bá ìwọ+ àti ọmọ* rẹ dá jálẹ̀ gbogbo ìran wọn, pé màá jẹ́ Ọlọ́run fún ọ àti fún ọmọ* rẹ. 8 Màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ ní ilẹ̀ tí o gbé nígbà tí o jẹ́ àjèjì,+ ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Kénáánì, yóò jẹ́ ohun ìní wọn títí láé, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run+ wọn.”

9 Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn. 10 Májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nìyí, òun sì ni ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò máa pa mọ́: Gbogbo ọkùnrin tó wà láàárín yín gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́.*+ 11 Kí ẹ dá adọ̀dọ́ yín,* yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú tó wà láàárín èmi àti ẹ̀yin.+ 12 Jálẹ̀ àwọn ìran yín, gbogbo ọmọkùnrin tó wà láàárín yín tó jẹ́ ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá bí nínú ilé àti ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ* yín àmọ́ tí ẹ fi owó yín rà lọ́wọ́ àjèjì. 13 Gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí ní ilé rẹ àti gbogbo ọkùnrin tí o fi owó rẹ rà gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ májẹ̀mú mi tó wà nínú ẹran ara yín gbọ́dọ̀ jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14 Tí ọkùnrin èyíkéyìí ò bá dá adọ̀dọ́ rẹ̀, kí wọ́n pa ẹni* náà, kí wọ́n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Ó ti da májẹ̀mú mi.”

15 Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní ti Sáráì*+ ìyàwó rẹ, má pè é ní Sáráì mọ́, torí Sérà* ni yóò máa jẹ́. 16 Èmi yóò bù kún un, màá sì mú kí ó+ bí ọmọkùnrin kan fún ọ; èmi yóò bù kún un, ó máa di àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ọba àwọn èèyàn yóò sì tinú rẹ̀ jáde.” 17 Ni Ábúráhámù bá dojú bolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, ó sì ń sọ lọ́kàn rẹ̀+ pé: “Ṣé ọkùnrin ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún lè di bàbá ọmọ? Ṣé Sérà, obìnrin ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún sì lè bímọ?”+

18 Ábúráhámù wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí Íṣímáẹ́lì wà láàyè níwájú rẹ!”+ 19 Ọlọ́run fèsì pé: “Ó dájú pé Sérà ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o sì sọ ọ́ ní Ísákì.*+ Màá sì fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá a dá múlẹ̀, ó máa jẹ́ májẹ̀mú ayérayé fún àtọmọdọ́mọ* rẹ̀.+ 20 Ní ti ohun tó o sọ nípa Íṣímáẹ́lì, mo ti gbọ́. Wò ó! Èmi yóò bù kún un, màá mú kó bímọ, màá sì mú kí ó di púpọ̀ gan-an. Ó máa bí ìjòyè méjìlá (12), màá sì mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.+ 21 Àmọ́, èmi yóò fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Ísákì,+ ọmọ tí Sérà máa bí fún ọ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀.”+

22 Nígbà tí Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ Ábúráhámù. 23 Ábúráhámù wá mú Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin tí wọ́n bí nínú ilé rẹ̀ àti gbogbo ẹni tó fi owó rà, gbogbo ọkùnrin inú agbo ilé Ábúráhámù, ó sì dá adọ̀dọ́ wọn* ní ọjọ́ yẹn gan-an, bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un.+ 24 Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ni Ábúráhámù nígbà tó dádọ̀dọ́.+ 25 Ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) sì ni Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ nígbà tó dádọ̀dọ́.  + 26 Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Ábúráhámù àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ dádọ̀dọ́. 27 Gbogbo ọkùnrin agbo ilé rẹ̀, gbogbo ẹni tí wọ́n bí nínú ilé náà àti ẹni tí wọ́n fi owó rà láti ọwọ́ àjèjì ló dádọ̀dọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́