Jóòbù
16 Jóòbù fèsì pé:
2 “Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan báyìí rí.
Olùtùnú tó ń dani láàmú ni gbogbo yín!+
3 Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ asán* lópin ni?
Kí ló ń bí ẹ nínú tí o fi ń fèsì báyìí?
4 Èmi náà lè sọ̀rọ̀ bíi tiyín.
Ká ní ẹ̀yin lẹ wà ní ipò tí mo wà,*
Mo lè sọ̀rọ̀ sí yín, tó máa mú kí ẹ ronú,
Mo sì lè mi orí sí yín.+
6 Tí mo bá sọ̀rọ̀, kò dín ìrora mi kù,+
Tí mo bá sì dákẹ́, mélòó ló máa dín kù nínú ìrora mi?
8 O tún gbá mi mú, ó sì ti jẹ́rìí sí i,
Débi pé ara mi tó rù kan eegun dìde, ó sì jẹ́rìí níṣojú mi.
9 Ìbínú rẹ̀ ti fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ń dì mí sínú.+
Ó ń wa eyín pọ̀ sí mi.
Ọ̀tá mi ń fi ojú rẹ̀ gún mi lára.+
10 Wọ́n ti la ẹnu wọn gbàù sí mi,+
Tẹ̀gàntẹ̀gàn ni wọ́n sì gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,
Wọ́n kóra jọ rẹpẹtẹ láti ta kò mí.+
11 Ọlọ́run fi mí lé àwọn ọ̀dọ́kùnrin lọ́wọ́,
Ó sì tì mí sọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.+
12 Wàhálà kankan ò bá mi, àmọ́ ó fọ́ mi sí wẹ́wẹ́;+
Ó rá mi mú ní ẹ̀yìn ọrùn, ó sì fọ́ mi túútúú;
Èmi ló dájú sọ.
14 Ó ń dá ihò sí mi lára, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn;
Ó pa kuuru mọ́ mi bíi jagunjagun.
16 Ojú mi ti pọ́n torí mò ń sunkún,+
Òkùnkùn biribiri* sì wà ní ìpéǹpéjú mi,
17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ mi ò hùwà ipá kankan,
Àdúrà mi sì mọ́.
18 Ìwọ ilẹ̀, má bo ẹ̀jẹ̀ mi!+
Má sì jẹ́ kí igbe mi rí ibi ìsinmi kankan!
19 Kódà ní báyìí, ẹlẹ́rìí mi wà ní ọ̀run;
Ẹni tó lè jẹ́rìí sí mi wà ní ibi tó ga.
21 Kí ẹnì kan gbọ́ ẹjọ́ èèyàn àti Ọlọ́run
Bí èèyàn ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan àti ẹnì kejì rẹ̀.+