ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó bá sin ọlọ́run míì (1-18)

Diutarónómì 13:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:19; Jer 27:9
  • +Di 8:2
  • +Di 6:5; 10:12; Mt 22:37

Diutarónómì 13:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2002, ojú ìwé 16-17

Diutarónómì 13:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 18:20
  • +Di 17:2, 3, 7; 1Kọ 5:13

Diutarónómì 13:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rẹ́ rẹ tó jẹ́ ẹni bí ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:4; 2Pe 2:1

Diutarónómì 13:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 1:8

Diutarónómì 13:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:20; 32:27; Nọ 25:5
  • +Di 17:2, 3, 7

Diutarónómì 13:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 20:2, 27

Diutarónómì 13:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:13; 1Ti 5:20

Diutarónómì 13:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 19:15; 1Ti 5:19

Diutarónómì 13:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:4, 5; 2Kr 28:6
  • +Ẹk 22:20

Diutarónómì 13:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí a ti fòfin dè pé ó jẹ́ ọlọ́wọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 6:18
  • +Jẹ 22:15, 17; 26:3, 4

Diutarónómì 13:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fetí sí ohùn rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:18

Àwọn míì

Diu. 13:3Ais 8:19; Jer 27:9
Diu. 13:3Di 8:2
Diu. 13:3Di 6:5; 10:12; Mt 22:37
Diu. 13:4Di 10:20
Diu. 13:5Di 18:20
Diu. 13:5Di 17:2, 3, 7; 1Kọ 5:13
Diu. 13:61Ọb 11:4; 2Pe 2:1
Diu. 13:8Ga 1:8
Diu. 13:9Ẹk 22:20; 32:27; Nọ 25:5
Diu. 13:9Di 17:2, 3, 7
Diu. 13:10Le 20:2, 27
Diu. 13:11Di 17:13; 1Ti 5:20
Diu. 13:14Di 19:15; 1Ti 5:19
Diu. 13:15Di 17:4, 5; 2Kr 28:6
Diu. 13:15Ẹk 22:20
Diu. 13:17Joṣ 6:18
Diu. 13:17Jẹ 22:15, 17; 26:3, 4
Diu. 13:18Di 6:18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 13:1-18

Diutarónómì

13 “Tí ẹnì kan bá di wòlíì tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àlá sọ tẹ́lẹ̀ láàárín rẹ, tó sì fún ọ ní àmì tàbí tó sọ ohun kan tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ fún ọ, 2 tí àmì náà tàbí ohun tó sọ fún ọ sì ṣẹ, tó wá ń sọ pé, ‘Jẹ́ ká tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì,’ àwọn ọlọ́run tí o kò mọ̀, ‘sì jẹ́ ká máa sìn wọ́n,’ 3 o ò gbọ́dọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn tàbí ti alálàá yẹn,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń dán yín wò+ kó lè mọ̀ bóyá ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 4 Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa tọ̀ lẹ́yìn, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí; òun ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.+ 5 Àmọ́ kí ẹ pa wòlíì yẹn tàbí alálàá yẹn,+ torí ó fẹ́ mú kí ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín, kó lè mú yín kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ pé kí ẹ máa rìn, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tó sì rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú. Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+

6 “Tí arákùnrin rẹ, ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí ìyàwó rẹ tí o fẹ́ràn tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́,* bá gbìyànjú láti tàn ọ́ ní ìkọ̀kọ̀ pé, ‘Jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,’+ àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀, 7 lára àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká, ì báà jẹ́ nítòsí tàbí àwọn tó jìnnà sí yín, láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà dé ìpẹ̀kun rẹ̀ kejì, 8 o ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn tàbí kí o fetí sí i,+ o ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀ tàbí kí o yọ́nú sí i, o ò sì gbọ́dọ̀ dáàbò bò ó; 9 kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pa á.+ Ọwọ́ rẹ ni kó kọ́kọ́ bà á láti pa á, lẹ́yìn náà, kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ kí wọ́n lè pa á.+ 10 O gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta pa,+ torí ó fẹ́ mú ọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú. 11 Nígbà náà, ẹ̀rù á ba gbogbo Ísírẹ́lì tí wọ́n bá gbọ́, wọn ò sì ní dán ohun tó burú bẹ́ẹ̀ wò mọ́ láàárín rẹ.+

12 “Nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o máa gbé, tí o bá gbọ́ tí wọ́n sọ pé, 13 ‘Àwọn èèyàn tí kò ní láárí ti jáde láti àárín rẹ, kí wọ́n lè yí àwọn tó ń gbé ìlú wọn pa dà, wọ́n ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,” àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀,’ 14 rí i pé o yẹ ọ̀rọ̀ náà wò, kí o ṣe ìwádìí fínnífínní, kí o sì béèrè nípa rẹ̀;+ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni wọ́n ṣe ohun ìríra yìí láàárín rẹ, 15 kí o rí i pé o fi idà pa àwọn tó ń gbé ìlú yẹn.+ Kí o fi idà pa ìlú náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ run pátápátá, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀.+ 16 Kí o wá kó gbogbo ẹrù inú rẹ̀ jọ sí àárín ojúde ìlú náà, kí o sì fi iná sun ìlú náà, àwọn ẹrù yẹn á wá di odindi ọrẹ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Àwókù ni ìlú náà máa dà títí láé. O ò gbọ́dọ̀ tún un kọ́ láé. 17 O ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tí a máa pa run,*+ kí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi lè rọ̀, kó lè ṣàánú rẹ, kó yọ́nú sí ọ, kó sì mú kí o pọ̀, bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá rẹ gẹ́lẹ́.+ 18 Kí o máa pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́, kí o lè máa ṣègbọràn sí i,* kí o lè máa ṣe ohun tó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́