ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Jèhóáhásì di ọba Ísírẹ́lì (1-9)

      • Jèhóáṣì di ọba Ísírẹ́lì (10-13)

      • Èlíṣà dán ìtara Jèhóáṣì wò (14-19)

      • Ikú Èlíṣà; egungun rẹ̀ jí ọkùnrin kan dìde (20, 21)

      • Àsọtẹ́lẹ̀ tí Èlíṣà sọ kẹ́yìn ṣẹ (22-25)

2 Àwọn Ọba 13:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:2, 21
  • +2Ọb 8:26; 9:27
  • +2Ọb 10:30, 35

2 Àwọn Ọba 13:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:28-30; 13:33; 14:16

2 Àwọn Ọba 13:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 12:29
  • +Le 26:14, 17
  • +1Ọb 19:17; 2Ọb 8:12
  • +2Ọb 13:24

2 Àwọn Ọba 13:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tu Jèhófà lójú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:7; Ond 10:16; 2Ọb 14:26, 27

2 Àwọn Ọba 13:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ní àlàáfíà àti ààbò.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:27

2 Àwọn Ọba 13:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Inú rẹ̀ ló ti ń rìn.”

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:29; 17:21
  • +Di 7:5; 1Ọb 14:15; 16:33

2 Àwọn Ọba 13:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:12; 10:32
  • +Emọ 1:3

2 Àwọn Ọba 13:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:35

2 Àwọn Ọba 13:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 14:1

2 Àwọn Ọba 13:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Inú ẹ̀ṣẹ̀ náà ló ti ń rìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:29

2 Àwọn Ọba 13:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 14:8, 13

2 Àwọn Ọba 13:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 14:28
  • +2Ọb 10:35; 13:9

2 Àwọn Ọba 13:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:16
  • +2Ọb 2:11, 12

2 Àwọn Ọba 13:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

  • *

    Tàbí “ìgbàlà.”

  • *

    Tàbí “ìgbàlà.”

  • *

    Tàbí “borí Síríà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 29:1; 1Ọb 20:26

2 Àwọn Ọba 13:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 13:25

2 Àwọn Ọba 13:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akónilẹ́rù.”

  • *

    Ní Héb., “nígbà tí ọdún ń wọlé dé,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìrúwé.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 1:1; 24:2

2 Àwọn Ọba 13:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akónilẹ́rù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:44; Heb 11:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2017, ojú ìwé 5

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2005, ojú ìwé 11

    11/15/1991, ojú ìwé 5

2 Àwọn Ọba 13:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:15
  • +2Ọb 8:12; 10:32

2 Àwọn Ọba 13:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 14:26, 27
  • +Jẹ 13:14-16
  • +Jẹ 26:3
  • +Jẹ 28:13; Sm 105:8; Mik 7:20

2 Àwọn Ọba 13:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣẹ́gun rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 13:19

Àwọn míì

2 Ọba 13:12Ọb 11:2, 21
2 Ọba 13:12Ọb 8:26; 9:27
2 Ọba 13:12Ọb 10:30, 35
2 Ọba 13:21Ọb 12:28-30; 13:33; 14:16
2 Ọba 13:3Heb 12:29
2 Ọba 13:3Le 26:14, 17
2 Ọba 13:31Ọb 19:17; 2Ọb 8:12
2 Ọba 13:32Ọb 13:24
2 Ọba 13:4Ẹk 3:7; Ond 10:16; 2Ọb 14:26, 27
2 Ọba 13:5Ne 9:27
2 Ọba 13:62Ọb 10:29; 17:21
2 Ọba 13:6Di 7:5; 1Ọb 14:15; 16:33
2 Ọba 13:72Ọb 8:12; 10:32
2 Ọba 13:7Emọ 1:3
2 Ọba 13:92Ọb 10:35
2 Ọba 13:102Ọb 14:1
2 Ọba 13:112Ọb 10:29
2 Ọba 13:122Ọb 14:8, 13
2 Ọba 13:132Ọb 14:28
2 Ọba 13:132Ọb 10:35; 13:9
2 Ọba 13:141Ọb 19:16
2 Ọba 13:142Ọb 2:11, 12
2 Ọba 13:171Sa 29:1; 1Ọb 20:26
2 Ọba 13:192Ọb 13:25
2 Ọba 13:202Ọb 1:1; 24:2
2 Ọba 13:21Jo 11:44; Heb 11:35
2 Ọba 13:221Ọb 19:15
2 Ọba 13:222Ọb 8:12; 10:32
2 Ọba 13:232Ọb 14:26, 27
2 Ọba 13:23Jẹ 13:14-16
2 Ọba 13:23Jẹ 26:3
2 Ọba 13:23Jẹ 28:13; Sm 105:8; Mik 7:20
2 Ọba 13:252Ọb 13:19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 13:1-25

Àwọn Ọba Kejì

13 Ní ọdún kẹtàlélógún Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà+ ọba Júdà, Jèhóáhásì ọmọ Jéhù+ di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ló sì fi ṣàkóso. 2 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, kò sì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Kò ṣíwọ́ nínú rẹ̀. 3 Torí náà, ìbínú Jèhófà+ ru sí Ísírẹ́lì,+ ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ Hásáẹ́lì+ ọba Síríà àti Bẹni-hádádì+ ọmọ Hásáẹ́lì ní gbogbo ìgbà náà.

4 Nígbà tó yá, Jèhóáhásì bẹ Jèhófà fún ojú rere,* Jèhófà sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ torí pé ó ti rí ìnira tí ọba Síríà mú bá Ísírẹ́lì.+ 5 Jèhófà wá fún Ísírẹ́lì ní olùgbàlà+ kan tó máa gbà wọ́n lọ́wọ́ Síríà, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa gbé nínú ilé wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.* 6 (Síbẹ̀, wọn kò jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ilé Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí nìṣó,* òpó òrìṣà*+ ṣì wà ní ìdúró ní Samáríà.) 7 Àádọ́ta (50) agẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́wàá pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn ló ṣẹ́ kù fún Jèhóáhásì, torí pé ọba Síríà ti run wọ́n,+ ó sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ bí erùpẹ̀ ibi ìpakà.+

8 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóáhásì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 9 Níkẹyìn, Jèhóáhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà;+ Jèhóáṣì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

10 Ní ọdún kẹtàdínlógójì Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni ó sì fi ṣàkóso. 11 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Ó ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà nìṣó.*

12 Ní ti ìtàn Jèhóáṣì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀ àti bí ó ṣe bá Amasááyà ọba Júdà+ jà, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 13 Níkẹyìn, Jèhóáṣì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, Jèróbóámù*+ wá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Wọ́n sì sin Jèhóáṣì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì.+

14 Nígbà tí ara Èlíṣà+ kò yá, tó sì jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe é yìí ló máa yọrí sí ikú rẹ̀, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì wá bá a, ó sì ń sunkún bó ṣe gbá a mọ́ra, ó sọ pé: “Bàbá mi, bàbá mi! Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ísírẹ́lì àti àwọn agẹṣin rẹ̀!”+ 15 Èlíṣà bá sọ fún un pé: “Mú ọrun àti àwọn ọfà.” Torí náà, ó mú ọrun àti àwọn ọfà. 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Fi ọwọ́ rẹ di ọrun náà mú.” Torí náà, ó dì í mú, lẹ́yìn náà Èlíṣà gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba. 17 Ó wá sọ pé: “Ṣí fèrèsé* tó dojú kọ ìlà oòrùn.” Torí náà, ó ṣí i. Èlíṣà sọ pé: “Ta á!” Nítorí náà, ó ta á. Ló bá sọ pé: “Ọfà ìṣẹ́gun* Jèhófà, ọfà ìṣẹ́gun* lórí Síríà! Wàá ṣá Síríà balẹ̀* ní Áfékì+ títí wàá fi pa á run.”

18 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kó àwọn ọfà náà,” ó sì kó wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Fi wọ́n na ilẹ̀.” Nítorí náà, ó fi wọ́n na ilẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta, ló bá dáwọ́ dúró. 19 Ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ bá bínú sí i, ó sì sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀márùn-ún tàbí ẹ̀ẹ̀mẹ́fà ló yẹ kí o fi wọ́n na ilẹ̀! Ká ní o ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ì bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣá Síríà balẹ̀ títí wàá fi pa á run, àmọ́ ní báyìí, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré lo máa ṣá Síríà balẹ̀.”+

20 Lẹ́yìn ìyẹn, Èlíṣà kú, wọ́n sì sin ín. Àwọn jàǹdùkú* ará Móábù+ máa ń wá sí ilẹ̀ náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún.* 21 Lọ́jọ́ kan, bí àwọn kan ṣe fẹ́ máa sin òkú ọkùnrin kan, wọ́n rí àwọn jàǹdùkú* náà, wọ́n bá sáré ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà, wọ́n sì sá lọ. Nígbà tí òkú ọkùnrin náà fara kan egungun Èlíṣà, ó jí dìde,+ ó sì dìde dúró.

22 Hásáẹ́lì+ ọba Síríà ń ni Ísírẹ́lì lára+ ní gbogbo ọjọ́ Jèhóáhásì. 23 Àmọ́, Jèhófà ṣíjú àánú wò wọ́n, ó ṣojú rere sí wọn,+ ó sì bójú tó wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù.+ Kò fẹ́ pa wọ́n run, kò sì ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀ títí di òní yìí. 24 Nígbà tí Hásáẹ́lì ọba Síríà kú, Bẹni-hádádì ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. 25 Nígbà náà, Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì gba àwọn ìlú pa dà lọ́wọ́ Bẹni-hádádì ọmọ Hásáẹ́lì, ìyẹn àwọn ìlú tí Hásáẹ́lì gbà lọ́wọ́ Jèhóáhásì bàbá rẹ̀ lójú ogun. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Jèhóáṣì ṣá a balẹ̀,*+ ó sì gba àwọn ìlú Ísírẹ́lì pa dà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́