ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ìrònúpìwàdà ń mú ìbùkún wá (1-4)

      • Àjálù yóò wá láti àríwá (5-18)

      • Àjálù tó ń bọ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jeremáyà (19-31)

Jeremáyà 4:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 3:22; Joẹ 2:12, 13

Jeremáyà 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 65:16

Jeremáyà 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 10:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 9

Jeremáyà 4:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dá ara yín ládọ̀dọ́.”

  • *

    Tàbí “dádọ̀dọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:25, 26
  • +Ida 4:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 9-10

    3/15/2007, ojú ìwé 9

Jeremáyà 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:1
  • +Jer 35:11

Jeremáyà 4:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:14; 21:7; 25:9

Jeremáyà 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:1; 25:1; Jer 5:6; 50:17
  • +Isk 26:7
  • +Ais 5:9; 6:11; Jer 2:15; 9:11

Jeremáyà 4:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

  • *

    Tàbí “Ẹ lu àyà yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:26

Jeremáyà 4:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọba kì yóò ní ìgboyà.”

  • *

    Tàbí “Àwọn ìjòyè kì yóò ní ìgboyà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:5
  • +Ais 29:9, 10

Jeremáyà 4:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “nígbà tí idà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 14:9
  • +Jer 6:13, 14; 14:13; 23:16, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 9

Jeremáyà 4:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ọ̀rọ̀ ewì tó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí àánú tàbí ìgbatẹnirò bíi pé èèyàn ni wọ́n.

Jeremáyà 4:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:26, 28
  • +Di 28:49, 50; Ida 4:19; Hab 1:8

Jeremáyà 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:16; Isk 18:31

Jeremáyà 4:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 8:16

Jeremáyà 4:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Àwọn olùṣọ́,” ìyẹn, àwọn tó ń ṣọ́ ìlú kan, kí wọ́n lè mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n gbéjà kò ó.

Jeremáyà 4:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:1, 2
  • +Ais 63:10; Isk 2:3

Jeremáyà 4:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 107:17

Jeremáyà 4:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ìfun mi.”

  • *

    Ní Héb., “Ògiri ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ariwo ogun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:15, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 155-156, 182-183

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/1/1994, ojú ìwé 12

Jeremáyà 4:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 10:20

Jeremáyà 4:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:1

Jeremáyà 4:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọlọ́gbọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:6; Jer 5:21

Jeremáyà 4:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:10
  • +Ais 5:30; Joẹ 2:31

Jeremáyà 4:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:25

Jeremáyà 4:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:3

Jeremáyà 4:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 29:22, 23

Jeremáyà 4:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:32; 2Kr 36:20, 21; Ais 6:11; Jer 10:22; Isk 33:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 109

Jeremáyà 4:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 24:4; Joẹ 1:10
  • +Ais 5:30; Joẹ 2:30, 31
  • +2Ọb 23:26; Isk 24:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 109

Jeremáyà 4:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:4
  • +Ais 2:19

Jeremáyà 4:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lẹ́ẹ̀dì.”

  • *

    Tàbí “wọ́n ń lépa ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 23:22, 26
  • +Ida 1:2

Jeremáyà 4:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 1:17

Àwọn míì

Jer. 4:1Jer 3:22; Joẹ 2:12, 13
Jer. 4:2Ais 65:16
Jer. 4:3Ho 10:12
Jer. 4:4Jer 9:25, 26
Jer. 4:4Ida 4:11
Jer. 4:5Jer 6:1
Jer. 4:5Jer 35:11
Jer. 4:6Jer 1:14; 21:7; 25:9
Jer. 4:72Ọb 24:1; 25:1; Jer 5:6; 50:17
Jer. 4:7Isk 26:7
Jer. 4:7Ais 5:9; 6:11; Jer 2:15; 9:11
Jer. 4:8Jer 6:26
Jer. 4:92Ọb 25:5
Jer. 4:9Ais 29:9, 10
Jer. 4:10Isk 14:9
Jer. 4:10Jer 6:13, 14; 14:13; 23:16, 17
Jer. 4:13Ais 5:26, 28
Jer. 4:13Di 28:49, 50; Ida 4:19; Hab 1:8
Jer. 4:14Ais 1:16; Isk 18:31
Jer. 4:15Jer 8:16
Jer. 4:172Ọb 25:1, 2
Jer. 4:17Ais 63:10; Isk 2:3
Jer. 4:18Sm 107:17
Jer. 4:19Sef 1:15, 16
Jer. 4:20Jer 10:20
Jer. 4:21Jer 6:1
Jer. 4:22Di 32:6; Jer 5:21
Jer. 4:23Jer 9:10
Jer. 4:23Ais 5:30; Joẹ 2:31
Jer. 4:24Ais 5:25
Jer. 4:25Sef 1:3
Jer. 4:26Di 29:22, 23
Jer. 4:27Le 26:32; 2Kr 36:20, 21; Ais 6:11; Jer 10:22; Isk 33:28
Jer. 4:28Ais 24:4; Joẹ 1:10
Jer. 4:28Ais 5:30; Joẹ 2:30, 31
Jer. 4:282Ọb 23:26; Isk 24:14
Jer. 4:292Ọb 25:4
Jer. 4:29Ais 2:19
Jer. 4:30Isk 23:22, 26
Jer. 4:30Ida 1:2
Jer. 4:31Ida 1:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 4:1-31

Jeremáyà

4 “Bí o bá máa pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì,” ni Jèhófà wí,

“Bí o bá máa pa dà sọ́dọ̀ mi

Kí o mú òrìṣà ẹ̀gbin rẹ kúrò níwájú mi,

Nígbà náà, ìwọ kò ní jẹ́ ìsáǹsá.+

 2 Bí o bá ń ṣe òtítọ́ àti òdodo pẹ̀lú ẹ̀tọ́, bí o ti ń búra pé,

‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’

Nígbà náà, àwọn orílẹ̀-èdè á gba ìbùkún látọ̀dọ̀ rẹ̀,

Wọ́n á sì máa ṣògo nínú rẹ̀.”+

3 Ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn ọkùnrin Júdà àti fún Jerúsálẹ́mù nìyí:

“Ẹ tú ilẹ̀ tó dáa fún ọ̀gbìn,

Ẹ má sì máa fúnrúgbìn sáàárín ẹ̀gún.+

 4 Ẹ kọ ara yín nílà* fún Jèhófà,

Ẹ sì kọlà fún* ọkàn yín,+

Ẹ̀yin èèyàn Júdà àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù,

Kí ìbínú mi má bàa ru jáde bí iná

Kí ó sì máa jó, tí kò fi ní sí ẹni tó lè pa á,

Nítorí ìwà ibi yín.”+

 5 Ẹ kéde rẹ̀ ní Júdà, ẹ sì polongo rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.

Ẹ kígbe, kí ẹ sì fun ìwo jákèjádò ilẹ̀ náà.+

Ẹ gbóhùn sókè, kí ẹ sì sọ pé: “Ẹ kóra jọ,

Ẹ sì jẹ́ kí a sá wọ àwọn ìlú olódi.+

 6 Ẹ gbé àmì kan dúró* tó ń tọ́ka sí Síónì.

Ẹ wá ibi ààbò, ẹ má sì dúró tẹtẹrẹ,”

Nítorí mò ń mú àjálù bọ̀ láti àríwá,+ yóò sì jẹ́ ìparun tó bùáyà.

 7 Ó yọ jáde láti inú igbó bíi kìnnìún;+

Ẹni tó ń pa àwọn orílẹ̀-èdè run ti jáde.+

Ó ti jáde kúrò ní àyè rẹ̀ kí ó lè sọ ilẹ̀ rẹ di ohun àríbẹ̀rù.

Àwọn ìlú rẹ yóò di àwókù tí kò ní sí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ mọ́.+

 8 Torí náà, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+

Ẹ ṣọ̀fọ̀,* kí ẹ sì pohùn réré ẹkún,

Nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná kò tíì kúrò lórí wa.

 9 “Ní ọjọ́ náà, ọkàn ọba á domi,”*+ ni Jèhófà wí

“Àti ọkàn àwọn ìjòyè;*

Ẹ̀rù á ba àwọn àlùfáà, kàyéfì á sì ṣe àwọn wòlíì.”+

10 Ni mo bá sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! O ti tan àwọn èèyàn yìí+ àti Jerúsálẹ́mù jẹ pátápátá, o sọ pé, ‘Ẹ máa ní àlàáfíà,’+ nígbà tó jẹ́ pé idà ló wà lọ́rùn wa.”*

11 Nígbà yẹn, a ó sọ fún àwọn èèyàn yìí àti Jerúsálẹ́mù pé:

“Ẹ̀fúùfù gbígbóná láti orí àwọn òkè tó wà ní aṣálẹ̀ tí kò sí ohunkóhun tó hù lórí wọn

Ló máa gbá ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi lọ;

Kì í ṣe pé ó máa wá fẹ́ ọkà tàbí pàǹtírí.

12 Èmi ni mo sọ pé kí ẹ̀fúùfù líle fẹ́ wá láti orí àwọn òkè.

Ní báyìí, màá kéde ìdájọ́ lé wọn lórí.

13 Wò ó! Ọ̀tá yóò wá bí òjò tó ṣú,

Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ á sì wá bí ìjì.+

Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju ẹyẹ idì lọ.+

A gbé, torí pé a ti di ahoro!

14 Wẹ ìwà burúkú kúrò lọ́kàn rẹ, kí o lè rí ìgbàlà, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+

Ìgbà wo lo máa tó mú èrò burúkú kúrò lọ́kàn rẹ?

15 Nítorí ohùn kan ròyìn láti Dánì,+

Ó sì kéde àjálù láti àwọn òkè Éfúrémù.

16 Ẹ ròyìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ròyìn rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè;

Ẹ kéde rẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù.”

“Àwọn ẹ̀ṣọ́* ń bọ̀ láti ilẹ̀ tó jìnnà,

Wọ́n á sì gbé ohùn wọn sókè sí àwọn ìlú Júdà.

17 Wọ́n yí Jerúsálẹ́mù ká bí ìgbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá ń ṣọ́ pápá gbalasa,+

Nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”+ ni Jèhófà wí.

18 “Ọ̀nà rẹ àti ìṣe rẹ á yí dà lé ọ lórí.+

Wo bí àjálù rẹ á ti korò tó!

Nítorí ó ti dé inú ọkàn rẹ.”

19 Ìrora mi pọ̀,* ìrora mi pọ̀!

Ọkàn mi* gbọgbẹ́.

Àyà mi ń lù kìkì.

Mi ò lè dákẹ́,

Nítorí mo* ti gbọ́ ìró ìwo

Àti ìró ogun.*+

20 Àjálù lórí àjálù ni ìròyìn tí à ń gbọ́,

Nítorí pé wọ́n ti pa gbogbo ilẹ̀ náà run.

Lójijì, wọ́n pa àgọ́ mi run,

Ní ìṣẹ́jú kan, wọ́n pa aṣọ àgọ́ mi run.+

21 Ìgbà wo ni mi ò ní rí àmì* mọ́,

Tí mi ò sì ní máa gbọ́ ìró ìwo?+

22 “Nítorí àwọn èèyàn mi gọ̀;+

Wọn ò kà mí sí.

Ọmọ tí kò gbọ́n ni wọ́n, wọn ò sì lóye.

Ọ̀jáfáfá* ni wọ́n nínú ìwà ibi,

Àmọ́, wọn ò mọ bí a ti ń ṣe rere.”

23 Mo rí ilẹ̀ náà, sì wò ó! ó ṣófo, ó sì dahoro.+

Mo bojú wo ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí mọ́.+

24 Mo rí àwọn òkè ńlá, sì wò ó! wọ́n ń mì tìtì,

Àwọn òkè kéékèèké sì ń mì.+

25 Mo wò ó, kíyè sí i! kò sí èèyàn kankan níbẹ̀,

Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti fò lọ.+

26 Mo wò ó, kíyè sí i! ọgbà eléso ti di aginjù,

Gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ ti wó lulẹ̀.+

Nítorí Jèhófà ni,

Torí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò ni.

27 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Gbogbo ilẹ̀ náà á di ahoro,+

Àmọ́ mi ò ní pa á run pátápátá.

28 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà máa ṣọ̀fọ̀,+

Àwọn ọ̀run á sì ṣókùnkùn.+

Torí pé mo ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pinnu,

Mi ò ní pèrò dà,* bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò ní yí pa dà.+

29 Nítorí ìró àwọn agẹṣin àti àwọn tafàtafà,

Gbogbo ìlú sá lọ.+

Wọ́n wọnú igbó,

Wọ́n sì gun àwọn àpáta.+

Gbogbo ìlú ni wọ́n ti fi sílẹ̀,

Kò sì sí èèyàn kankan tó ń gbé inú wọn.”

30 Ní báyìí tí o ti di ahoro, kí lo máa ṣe?

O ti máa ń wọ aṣọ rírẹ̀dòdò tẹ́lẹ̀,

O ti máa ń fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe ara rẹ lóge,

O sì ti máa ń fi tìróò* sọ ojú rẹ di ńlá.

Àmọ́ lásán lo ṣe ara rẹ lóge,+

Àwọn tí ìfẹ́ rẹ ti kó sí lórí ti pa ọ́ tì;

Ní báyìí wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe gba ẹ̀mí rẹ.*+

31 Nítorí mo gbọ́ ohùn kan tó dà bíi ti obìnrin tó ń ṣàìsàn,

Ìdààmú bíi ti obìnrin tó ń rọbí àkọ́bí ọmọ rẹ̀,

Ohùn ọmọbìnrin Síónì tó ń mí gúlegúle.

Bó ṣe tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó ń sọ pé:+

“Mo gbé, àárẹ̀ ti mú mi* nítorí àwọn apààyàn!”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́