ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Àwọn ọmọ Ọlọ́run fẹ́ ìyàwó ní ayé (1-3)

      • Wọ́n bí àwọn Néfílímù (4)

      • Ìwà búburú èèyàn ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ (5-8)

      • Ọlọ́run ní kí Nóà kan áàkì (9-16)

      • Ọlọ́run kéde pé Ìkún Omi ń bọ̀ (17-22)

Jẹ́nẹ́sísì 6:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 1:6; 38:7; 2Pe 2:4; Jud 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2013, ojú ìwé 22

    4/15/2010, ojú ìwé 20

    6/1/2008, ojú ìwé 5

    6/1/2007, ojú ìwé 4-5

    4/15/2000, ojú ìwé 27

    6/15/1997, ojú ìwé 15-16

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 68-69

Jẹ́nẹ́sísì 6:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “torí ohun tí ẹran ara ń fẹ́ ló ń ṣe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:4; 1Pe 3:20
  • +2Pe 3:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2012, ojú ìwé 22-23

    12/15/2010, ojú ìwé 30-31

    12/15/2003, ojú ìwé 15

    11/1/2001, ojú ìwé 9-10

    8/15/1999, ojú ìwé 16

    9/15/1998, ojú ìwé 10-11

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 69-70

Jẹ́nẹ́sísì 6:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àwọn Abiniṣubú,” ìyẹn, àwọn tó ń gbé èèyàn ṣubú. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 12

    6/15/2013, ojú ìwé 22

    4/1/2013, ojú ìwé 12-13

    6/1/2008, ojú ìwé 5

    6/1/2007, ojú ìwé 5

    11/15/2001, ojú ìwé 28-29

    4/15/2000, ojú ìwé 27-28

    6/15/1997, ojú ìwé 15-16

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 18

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 70

Jẹ́nẹ́sísì 6:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:21; Jer 17:9; Mt 15:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 71

Jẹ́nẹ́sísì 6:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Jèhófà kẹ́dùn.”

  • *

    Tàbí “ó sì dùn ún dọ́kàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 78:40, 41

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 5

    1/1/2004, ojú ìwé 29

    4/15/1998, ojú ìwé 7

    7/1/1992, ojú ìwé 9

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 71

Jẹ́nẹ́sísì 6:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/1998, ojú ìwé 7

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 71

Jẹ́nẹ́sísì 6:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìlábùkù.”

  • *

    Ní Héb., “àwọn ìran rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:1; Isk 14:14; Heb 11:7
  • +2Pe 2:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2017 ojú ìwé 11

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2013, ojú ìwé 12

    6/1/2008, ojú ìwé 5-6

    9/1/2005, ojú ìwé 18-20

    11/15/2001, ojú ìwé 29

    12/15/1998, ojú ìwé 30

    11/15/1998, ojú ìwé 10

    9/15/1998, ojú ìwé 23

    6/1/1998, ojú ìwé 9

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 17

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 68

Jẹ́nẹ́sísì 6:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 5:32

Jẹ́nẹ́sísì 6:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2013, ojú ìwé 5

    12/15/2003, ojú ìwé 16-17

Jẹ́nẹ́sísì 6:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo èèyàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 11:18
  • +Mt 24:37-39; 2Pe 2:5

Jẹ́nẹ́sísì 6:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:4

Jẹ́nẹ́sísì 6:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn igi góférì,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ igi sípírẹ́sì.

  • *

    Ní Héb., “àpótí ńlá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:7
  • +Jẹ 14:10; Ẹk 2:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    11/8/2003, ojú ìwé 3

Jẹ́nẹ́sísì 6:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    2/8/1997, ojú ìwé 27

Jẹ́nẹ́sísì 6:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

  • *

    Lédè Hébérù, tsoʹhar. Yàtọ̀ sí fèrèsé tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọlé, tsoʹhar tún lè tọ́ka sí àjà tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ kan, tó sì dagun.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:16

Jẹ́nẹ́sísì 6:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èémí ìyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:7; 7:6, 11
  • +Jẹ 7:21; Sm 104:29; Mt 24:39; 2Pe 2:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/1998, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 6:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 13-14

Jẹ́nẹ́sísì 6:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:17
  • +Jẹ 7:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 13-14

Jẹ́nẹ́sísì 6:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:14, 15

Jẹ́nẹ́sísì 6:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:29, 30

Jẹ́nẹ́sísì 6:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:16; Heb 11:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2004, ojú ìwé 30

    12/15/1995, ojú ìwé 11-12

    Ayọ, ojú ìwé 177

Àwọn míì

Jẹ́n. 6:2Job 1:6; 38:7; 2Pe 2:4; Jud 6
Jẹ́n. 6:3Jẹ 7:4; 1Pe 3:20
Jẹ́n. 6:32Pe 3:9
Jẹ́n. 6:5Jẹ 8:21; Jer 17:9; Mt 15:19
Jẹ́n. 6:6Sm 78:40, 41
Jẹ́n. 6:9Jẹ 7:1; Isk 14:14; Heb 11:7
Jẹ́n. 6:92Pe 2:5
Jẹ́n. 6:10Jẹ 5:32
Jẹ́n. 6:12Ifi 11:18
Jẹ́n. 6:12Mt 24:37-39; 2Pe 2:5
Jẹ́n. 6:13Jẹ 7:4
Jẹ́n. 6:14Heb 11:7
Jẹ́n. 6:14Jẹ 14:10; Ẹk 2:3
Jẹ́n. 6:16Jẹ 7:16
Jẹ́n. 6:17Jẹ 1:7; 7:6, 11
Jẹ́n. 6:17Jẹ 7:21; Sm 104:29; Mt 24:39; 2Pe 2:5
Jẹ́n. 6:18Jẹ 7:13
Jẹ́n. 6:19Jẹ 8:17
Jẹ́n. 6:19Jẹ 7:2
Jẹ́n. 6:20Jẹ 7:14, 15
Jẹ́n. 6:21Jẹ 1:29, 30
Jẹ́n. 6:22Ẹk 40:16; Heb 11:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 6:1-22

Jẹ́nẹ́sísì

6 Nígbà tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí àwọn ọmọbìnrin, 2 àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin èèyàn rẹwà. Wọ́n sì ń fi gbogbo ẹni tó wù wọ́n ṣe aya. 3 Jèhófà wá sọ pé: “Ẹ̀mí mi ò ní gba èèyàn láyè títí láé,+ torí ẹlẹ́ran ara ni.* Torí náà, ọgọ́fà (120) ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”+

4 Àwọn Néfílímù* wà ní ayé nígbà yẹn àti lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń bá àwọn ọmọbìnrin èèyàn lò pọ̀, wọ́n sì bí àwọn ọmọ fún wọn. Àwọn ni alágbára ayé ìgbà yẹn, àwọn ọkùnrin olókìkí.

5 Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+ 6 Ó dun Jèhófà* pé òun dá èèyàn sáyé, ọkàn rẹ̀ sì bà jẹ́.*+ 7 Torí náà, Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò run àwọn èèyàn tí mo ti dá kúrò lórí ilẹ̀, èèyàn àti ẹran ọ̀sìn, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, torí ó dùn mí pé mo dá wọn.” 8 Àmọ́ Nóà rí ojúure Jèhófà.

9 Ìtàn Nóà nìyí.

Olódodo ni Nóà.+ Ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi* láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.* Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. 10 Nígbà tó yá, Nóà bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì.+ 11 Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́, ìwà ipá sì kún ayé. 12 Ọlọ́run wo ayé, àní ó ti bà jẹ́;+ ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara* ń hù ní ayé.+

13 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: “Mo ti pinnu pé màá run gbogbo ẹlẹ́ran ara, torí wọ́n ti fi ìwà ipá kún ayé, torí náà, màá pa wọ́n run pẹ̀lú ayé.+ 14 Ìwọ fi igi olóje*+ ṣe áàkì* fún ara rẹ. Kí o ṣe àwọn yàrá sínú áàkì náà, kí o sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì+ bo inú àti ìta rẹ̀. 15 Bí o ṣe máa ṣe é nìyí: Kí áàkì náà gùn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ìgbọ̀nwọ́,* kó fẹ̀ tó àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, kó sì ga tó ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. 16 Kí o ṣe fèrèsé* tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọ* inú áàkì náà, kó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan láti òkè. Kí o ṣe ẹnu ọ̀nà áàkì náà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ kí o sì jẹ́ kó ní àjà kìíní, àjà kejì àti àjà kẹta.

17 “Ní tèmi, màá mú kí ìkún omi  + bo ayé kí n lè run gbogbo ẹran ara tó ní ẹ̀mí* lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ohun tó wà ní ayé ló máa pa run.+ 18 Mo sì ń bá ọ dá májẹ̀mú, kí o wọ inú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó rẹ pẹ̀lú ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 19 Kí o mú méjì-méjì lára gbogbo oríṣiríṣi ohun alààyè+ wọnú áàkì náà, kí ẹ lè jọ wà láàyè. Kí o mú wọn ní akọ àti abo;+ 20 àwọn ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀ ní irú tiwọn, méjì-méjì ni kí o mú wọn wọlé sọ́dọ̀ rẹ kí wọ́n lè wà láàyè.+ 21 Ní tìrẹ, kí o kó oríṣiríṣi oúnjẹ+ jọ, kí o sì gbé wọn dání, òun ni ìwọ àti àwọn ẹran náà á máa jẹ.”

22 Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́