ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Ẹlikénà àti àwọn ìyàwó rẹ̀ (1-8)

      • Hánà tó jẹ́ àgàn gbàdúrà kó lè rọ́mọ bí (9-18)

      • Ó bí Sámúẹ́lì, ó sì fi í fún Jèhófà (19-28)

1 Sámúẹ́lì 1:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti Rámà, ó jẹ́ ará Súfì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:19; 7:15, 17
  • +Joṣ 16:5
  • +1Kr 6:22, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1998, ojú ìwé 16

1 Sámúẹ́lì 1:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 15

1 Sámúẹ́lì 1:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “forí balẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:14; 34:23; Di 12:5, 6; Joṣ 18:1; Ond 21:19; Lk 2:41
  • +1Sa 2:12, 22; 4:17
  • +Nọ 3:10; Di 33:10; Mal 2:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 51, 54

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 14-15

    3/15/2007, ojú ìwé 15

    3/1/1998, ojú ìwé 16

1 Sámúẹ́lì 1:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:15

1 Sámúẹ́lì 1:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ti sé ilé ọmọ Hánà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 52

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 15

1 Sámúẹ́lì 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 15

1 Sámúẹ́lì 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:16; 1Sa 2:18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 15

1 Sámúẹ́lì 1:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lọ́kàn jẹ́?”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 52-54

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 14-15

    3/15/2007, ojú ìwé 15-16

    3/15/2005, ojú ìwé 22

1 Sámúẹ́lì 1:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:8; 1Sa 3:3; 2Sa 7:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 15

1 Sámúẹ́lì 1:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn Hánà gbọgbẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 55:22; 65:2

1 Sámúẹ́lì 1:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:22
  • +Nọ 6:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 4-5

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 57

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 17

    3/15/2007, ojú ìwé 16

1 Sámúẹ́lì 1:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 55

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 16

    2/1/2001, ojú ìwé 20

1 Sámúẹ́lì 1:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Obìnrin tí ìnira ńlá bá ẹ̀mí rẹ̀ ni mí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 42:6; 62:8; 142:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 16

    2/1/2001, ojú ìwé 20-21

1 Sámúẹ́lì 1:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2001, ojú ìwé 20-21

1 Sámúẹ́lì 1:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:11

1 Sámúẹ́lì 1:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 55-56

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 16, 18

    3/15/2007, ojú ìwé 16

1 Sámúẹ́lì 1:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rántí rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:1
  • +1Sa 1:11; Sm 66:19; Owe 15:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 16

1 Sámúẹ́lì 1:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tó yá.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Orúkọ Ọlọ́run.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 5:29; 41:51; Ẹk 2:21, 22; Mt 1:21

1 Sámúẹ́lì 1:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:3

1 Sámúẹ́lì 1:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:16
  • +1Sa 1:11; 2:11; 2Kr 31:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 16

1 Sámúẹ́lì 1:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ohun tó bá dára ní ojú rẹ.”

1 Sámúẹ́lì 1:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.

  • *

    Ó dà bíi jọ́ọ̀gì omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 15:8-10
  • +Joṣ 18:1

1 Sámúẹ́lì 1:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Bí ọkàn rẹ ti wà láàyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:15

1 Sámúẹ́lì 1:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 1:11, 17; Sm 66:19

1 Sámúẹ́lì 1:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣe kedere pé Ẹlikénà ló ń tọ́ka sí.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 5

Àwọn míì

1 Sám. 1:11Sa 1:19; 7:15, 17
1 Sám. 1:1Joṣ 16:5
1 Sám. 1:11Kr 6:22, 27
1 Sám. 1:3Ẹk 23:14; 34:23; Di 12:5, 6; Joṣ 18:1; Ond 21:19; Lk 2:41
1 Sám. 1:31Sa 2:12, 22; 4:17
1 Sám. 1:3Nọ 3:10; Di 33:10; Mal 2:7
1 Sám. 1:4Le 7:15
1 Sám. 1:7Di 16:16; 1Sa 2:18, 19
1 Sám. 1:9Ẹk 25:8; 1Sa 3:3; 2Sa 7:2
1 Sám. 1:10Sm 55:22; 65:2
1 Sám. 1:11Jẹ 30:22
1 Sám. 1:11Nọ 6:5
1 Sám. 1:15Sm 42:6; 62:8; 142:2
1 Sám. 1:171Sa 1:11
1 Sám. 1:191Sa 1:1
1 Sám. 1:191Sa 1:11; Sm 66:19; Owe 15:29
1 Sám. 1:20Jẹ 5:29; 41:51; Ẹk 2:21, 22; Mt 1:21
1 Sám. 1:211Sa 1:3
1 Sám. 1:22Di 16:16
1 Sám. 1:221Sa 1:11; 2:11; 2Kr 31:16
1 Sám. 1:24Nọ 15:8-10
1 Sám. 1:24Joṣ 18:1
1 Sám. 1:261Sa 1:15
1 Sám. 1:271Sa 1:11, 17; Sm 66:19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 1:1-28

Sámúẹ́lì Kìíní

1 Ọkùnrin kan wà, ó wá láti ìlú Ramataimu-sófíímù*+ ní agbègbè olókè Éfúrémù,+ orúkọ rẹ̀ ni Ẹlikénà,+ ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíhù, ọmọ Tóhù, ọmọ Súfì, ó jẹ́ ará Éfúrémù. 2 Ó ní ìyàwó méjì, ọ̀kan ń jẹ́ Hánà, èkejì sì ń jẹ́ Pẹ̀nínà. Pẹ̀nínà bí àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò bímọ. 3 Lọ́dọọdún, ọkùnrin yẹn máa ń lọ láti ìlú rẹ̀ sí Ṣílò+ láti jọ́sìn,* kó sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ibẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì+ ti ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+

4 Lọ́jọ́ kan tí Ẹlikénà rúbọ, ó pín lára ẹran tó fi rúbọ fún Pẹ̀nínà ìyàwó rẹ̀ àti gbogbo ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀,+ 5 ṣùgbọ́n ó fún Hánà ní ìpín kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, torí pé Hánà ló fẹ́ràn jù, àmọ́ Jèhófà kò tíì fún Hánà ní ọmọ.* 6 Yàtọ̀ síyẹn, orogún rẹ̀ ń pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i nítorí pé Jèhófà kò tíì fún un ní ọmọ. 7 Ohun tó máa ń ṣe nìyẹn lọ́dọọdún, nígbàkigbà tí Hánà bá lọ sí ilé Jèhófà,+ orogún rẹ̀ máa ń pẹ̀gàn rẹ̀ débi pé ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun. 8 Àmọ́ Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Hánà, kí ló ń pa ẹ́ lẹ́kún, kí ló dé tó ò jẹun, kí ló ń bà ẹ́ nínú jẹ́?* Ṣé mi ò sàn ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ fún ọ ni?”

9 Nígbà náà, Hánà dìde lẹ́yìn tí wọ́n ti parí jíjẹ àti mímu ní Ṣílò. Ní àkókò yẹn, àlùfáà Élì jókòó lórí ìjókòó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì*+ Jèhófà. 10 Inú Hánà bà jẹ́* gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sì ń sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. 11 Ó wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, tí o bá bojú wo ìnira tó dé bá ìránṣẹ́ rẹ, tí o rántí mi, tí o kò gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ, tí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọmọ ọkùnrin,+ ṣe ni màá fi fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kan orí rẹ̀.”+

12 Ní gbogbo àkókò tó fi ń gbàdúrà níwájú Jèhófà, Élì ń wo ẹnu rẹ̀. 13 Hánà ń gbàdúrà nínú ọkàn rẹ̀, ètè rẹ̀ nìkan ló ń mì, a kò sì gbọ́ ohùn rẹ̀. Torí náà, Élì rò pé ó mutí yó ni. 14 Élì sọ fún un pé: “Ìgbà wo ni ọtí máa tó dá lójú rẹ? Má mutí mọ́.” 15 Ni Hánà bá dáhùn pé: “Kò rí bẹ́ẹ̀, olúwa mi! Ìdààmú ńlá ló bá mi;* kì í ṣe pé mo mu wáìnì tàbí ọtí kankan, ohun tó wà lọ́kàn mi ni mò ń tú jáde níwájú Jèhófà.+ 16 Má rò pé obìnrin tí kò ní láárí ni ìránṣẹ́ rẹ, àdúrà ni mò ń gbà títí di báyìí nítorí ìrora àti ìdààmú ńlá tó dé bá mi.” 17 Ni Élì bá dáhùn pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fún ọ ní ohun tí o béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”+ 18 Hánà fèsì pé: “Kí ìránṣẹ́ rẹ rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ.” Obìnrin náà sì bá tirẹ̀ lọ, ó jẹun, kò sì kárí sọ mọ́.

19 Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n forí balẹ̀ níwájú Jèhófà, wọ́n sì pa dà sí ilé wọn ní Rámà.+ Ẹlikénà ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Hánà ìyàwó rẹ̀, Jèhófà sì ṣíjú àánú wò ó.*+ 20 Láàárín ọdún kan,* Hánà lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ+ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì,* torí ó sọ pé, “ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè rẹ̀.”

21 Nígbà tó yá, Ẹlikénà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ lọ láti rú ẹbọ ọdọọdún sí Jèhófà,+ kí ó sì mú ọrẹ tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ wá. 22 Àmọ́ Hánà kò lọ,+ torí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Gbàrà tí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọdékùnrin náà, màá mú un wá, á fara hàn níwájú Jèhófà, á sì máa gbé ibẹ̀ láti ìgbà náà lọ.”+ 23 Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí o bá mọ̀ pé ó dára jù* ni kí o ṣe. Dúró sí ilé títí wàá fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí Jèhófà jẹ́ kó rí bí o ṣe sọ.” Torí náà, obìnrin náà dúró sí ilé, ó sì ń tọ́jú ọmọ rẹ̀ títí ó fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.

24 Gbàrà tó gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, ó mú un lọ sí Ṣílò pẹ̀lú akọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta àti ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n eéfà* kan àti ìṣà* wáìnì+ ńlá kan. Ó wá sí ilé Jèhófà ní Ṣílò,+ ó sì mú ọmọdékùnrin náà dání. 25 Wọ́n pa akọ màlúù náà, wọ́n sì mú ọmọdékùnrin náà wá sọ́dọ̀ Élì. 26 Hánà wá sọ fún Élì pé: “Jọ̀ọ́, olúwa mi! Bí o ti wà láàyè,* olúwa mi, èmi ni obìnrin tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ ní ibí yìí láti gbàdúrà sí Jèhófà.+ 27 Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀, Jèhófà sì fún mi ní ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+ 28 Èmi náà sì wá láti fi í fún Jèhófà. Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ló máa fi jẹ́ ti Jèhófà.”

Ọkùnrin náà* sì forí balẹ̀ níbẹ̀ fún Jèhófà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́