ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gálátíà 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà

      • Òmìnira Kristẹni (1-15)

      • Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí (16-26)

        • Àwọn iṣẹ́ ti ara (19-21)

        • Èso ti ẹ̀mí (22, 23)

Gálátíà 5:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 16:13; Flp 4:1
  • +Iṣe 15:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/1998, ojú ìwé 13

    3/15/1992, ojú ìwé 15, 19

Gálátíà 5:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 6:12

Gálátíà 5:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 2:25; Ga 3:10

Gálátíà 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 3:20

Gálátíà 5:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkọlà.”

  • *

    Tàbí “àìkọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 7:19; Ga 6:15; Kol 3:10, 11

Gálátíà 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 9:24; Ga 3:3

Gálátíà 5:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 5:6; 15:33; 2Ti 2:16-18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1992, ojú ìwé 20

Gálátíà 5:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 17:20, 21
  • +Ga 1:7

Gálátíà 5:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkọlà.”

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 1:23

Gálátíà 5:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “di ìwẹ̀fà,” kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí kò kúnjú ìwọ̀n láti tẹ̀ lé òfin tí wọ́n fọwọ́ sí.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1992, ojú ìwé 20

Gálátíà 5:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Pe 2:16
  • +1Kọ 9:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2010, ojú ìwé 27

    2/15/2010, ojú ìwé 11

    3/15/1992, ojú ìwé 20

Gálátíà 5:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “kó gbogbo Òfin jọ sínú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:18; Mt 7:12; 22:39; Ro 13:8, 9; Jem 2:8

Gálátíà 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 3:14
  • +Jem 4:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2000, ojú ìwé 26-27

Gálátíà 5:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:5, 13
  • +Ro 6:12; 1Pe 2:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2010, ojú ìwé 15-18

    7/15/2007, ojú ìwé 21-25

    3/15/1992, ojú ìwé 20

Gálátíà 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 7:15, 19, 23

Gálátíà 5:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1992, ojú ìwé 20

Gálátíà 5:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 5:9; Ef 5:3; Kol 3:5; Ifi 2:20
  • +Mk 7:21, 22; Ef 4:19; 2Pe 2:2; Jud 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1704

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2012, ojú ìwé 31

    5/15/2008, ojú ìwé 27

    7/15/2006, ojú ìwé 29-31

    8/1/2001, ojú ìwé 15-16

    3/15/1992, ojú ìwé 20-21

Gálátíà 5:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “iṣẹ́ oṣó; lílo oògùn olóró.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:26, 31; Di 18:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    6/8/1997, ojú ìwé 20

Gálátíà 5:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 21:20, 21; Ais 5:11
  • +1Pe 4:3
  • +1Kọ 6:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 43

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2000, ojú ìwé 19-20

    Jí!,

    6/8/1996, ojú ìwé 14-15

Gálátíà 5:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìpamọ́ra.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 5:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2020, ojú ìwé 17

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2004, ojú ìwé 6

    8/1/2001, ojú ìwé 15-16

    10/1/1994, ojú ìwé 13

Gálátíà 5:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2020, ojú ìwé 17

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2004, ojú ìwé 6

Gálátíà 5:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 6:6

Gálátíà 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:4

Gálátíà 5:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 2:3
  • +Onw 4:4; 1Kọ 4:7; Ga 6:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2021, ojú ìwé 15-16

    Jí!,

    11/8/1996, ojú ìwé 30

Àwọn míì

Gál. 5:11Kọ 16:13; Flp 4:1
Gál. 5:1Iṣe 15:10
Gál. 5:2Ga 6:12
Gál. 5:3Ro 2:25; Ga 3:10
Gál. 5:4Ro 3:20
Gál. 5:61Kọ 7:19; Ga 6:15; Kol 3:10, 11
Gál. 5:71Kọ 9:24; Ga 3:3
Gál. 5:91Kọ 5:6; 15:33; 2Ti 2:16-18
Gál. 5:10Jo 17:20, 21
Gál. 5:10Ga 1:7
Gál. 5:111Kọ 1:23
Gál. 5:131Pe 2:16
Gál. 5:131Kọ 9:19
Gál. 5:14Le 19:18; Mt 7:12; 22:39; Ro 13:8, 9; Jem 2:8
Gál. 5:15Jem 3:14
Gál. 5:15Jem 4:1, 2
Gál. 5:16Ro 8:5, 13
Gál. 5:16Ro 6:12; 1Pe 2:11
Gál. 5:17Ro 7:15, 19, 23
Gál. 5:191Kọ 5:9; Ef 5:3; Kol 3:5; Ifi 2:20
Gál. 5:19Mk 7:21, 22; Ef 4:19; 2Pe 2:2; Jud 4
Gál. 5:20Le 19:26, 31; Di 18:10, 11
Gál. 5:21Di 21:20, 21; Ais 5:11
Gál. 5:211Pe 4:3
Gál. 5:211Kọ 6:9, 10
Gál. 5:22Ef 5:9
Gál. 5:23Jem 3:17
Gál. 5:24Ro 6:6
Gál. 5:25Ro 8:4
Gál. 5:26Flp 2:3
Gál. 5:26Onw 4:4; 1Kọ 4:7; Ga 6:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Gálátíà 5:1-26

Sí Àwọn Ará Gálátíà

5 Kristi ti dá wa sílẹ̀ ká lè ní irú òmìnira yìí. Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in,+ ẹ má sì tọrùn bọ àjàgà ẹrú mọ́.+

2 Ẹ wò ó! Èmi, Pọ́ọ̀lù, ń sọ fún yín pé tí ẹ bá dádọ̀dọ́,* Kristi ò ní ṣe yín láǹfààní kankan.+ 3 Mo tún jẹ́rìí sí i pé dandan ni fún gbogbo ẹni tó bá dádọ̀dọ́* láti pa gbogbo Òfin mọ́.+ 4 Ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ kí a pè yín ní olódodo nípasẹ̀ òfin;+ ẹ ti yà kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. 5 Ní tiwa, nínú ẹ̀mí, à ń dúró de òdodo tí à ń retí lójú méjèèjì, èyí tó ń wá látinú ìgbàgbọ́. 6 Torí nínú Kristi Jésù, ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́* kò ṣàǹfààní,+ ìgbàgbọ́ tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ ló ṣàǹfààní.

7 Ẹ ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀.+ Ta ló dí yín lọ́wọ́ kí ẹ má ṣègbọràn sí òtítọ́ mọ́? 8 Irú èrò tí wọ́n fi yí yín lọ́kàn pa dà yìí kò wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó ń pè yín. 9 Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú.+ 10 Ọkàn mi balẹ̀ pé ẹ̀yin tí ẹ wà nínú Olúwa+ kò ní ronú lọ́nà míì; àmọ́, ẹni tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ ẹnì yòówù kó jẹ́, yóò gba ìdájọ́ tó tọ́ sí i. 11 Ní tèmi, ẹ̀yin ará, tí mo bá ṣì ń wàásù ìdádọ̀dọ́,* kí ló dé tí wọ́n tún ń ṣe inúnibíni sí mi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, òpó igi oró*+ kì í ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ mọ́ fún àwọn tó ń ta kò mí. 12 Ó wù mí kí àwọn tó fẹ́ da àárín yín rú tẹ ara wọn lọ́dàá.*

13 Ẹ̀yin ará, a pè yín kí ẹ lè ní òmìnira; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí láti máa ṣe ìfẹ́ ti ara,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú kí ẹ sin ara yín bí ẹrú.+ 14 Nítorí a ti mú gbogbo Òfin ṣẹ nínú* àṣẹ kan ṣoṣo, tó sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 15 Tí ẹ bá wá ń bu ara yín jẹ, tí ẹ sì ń fa ara yín ya,+ ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín run.+

16 Àmọ́ mo sọ pé, Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí,+ ẹ kò sì ní ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.+ 17 Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́, ẹ̀mí sì lòdì sí ara; àwọn méjèèjì ta ko ara wọn, ìdí nìyẹn tí ẹ kò fi lè ṣe ohun tí ẹ fẹ́ ṣe.+ 18 Yàtọ̀ síyẹn, tí ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.

19 Àwọn iṣẹ́ ti ara hàn kedere, àwọn sì ni ìṣekúṣe,*+ ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú,*+ 20 ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò,*+ ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, 21 ìlara, ìmutíyó,+ àwọn àríyá aláriwo àti irú àwọn nǹkan yìí.+ Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú nípa àwọn nǹkan yìí, lọ́nà kan náà tí mo gbà kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀, pé àwọn tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+

22 Àmọ́, èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù,* inú rere, ìwà rere,+ ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.+ Kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí. 24 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó jẹ́ ti Kristi Jésù ti kan ẹran ara mọ́gi* pẹ̀lú ohun tí ẹran ara ń fẹ́ àti ohun tó ń wù ú.+

25 Tí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò nípa ẹ̀mí.+ 26 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga,+ kí a má ṣe máa bá ara wa díje,+ kí a má sì máa jowú ara wa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́