ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jékọ́bù pàdé Réṣẹ́lì (1-14)

      • Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì (15-20)

      • Jékọ́bù fẹ́ Líà àti Réṣẹ́lì (21-29)

      • Àwọn ọmọ mẹ́rin tí Líà bí fún Jékọ́bù: Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà (30-35)

Jẹ́nẹ́sísì 29:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:42, 43; Iṣe 7:2

Jẹ́nẹ́sísì 29:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:29
  • +Jẹ 24:24; 31:53

Jẹ́nẹ́sísì 29:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:19; Rut 4:11

Jẹ́nẹ́sísì 29:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “arákùnrin.”

Jẹ́nẹ́sísì 29:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:29

Jẹ́nẹ́sísì 29:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2003, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 29:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “arákùnrin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:5
  • +Jẹ 30:27, 28; 31:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2003, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 29:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Rut 4:11

Jẹ́nẹ́sísì 29:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:41

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2003, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 29:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:26; Ho 12:12

Jẹ́nẹ́sísì 29:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2020, ojú ìwé 7

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 8-9

Jẹ́nẹ́sísì 29:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:1, 2; 30:9; 46:18

Jẹ́nẹ́sísì 29:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:7, 42

Jẹ́nẹ́sísì 29:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:41

Jẹ́nẹ́sísì 29:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:22
  • +Jẹ 30:1, 3

Jẹ́nẹ́sísì 29:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 12:12

Jẹ́nẹ́sísì 29:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kórìíra.”

  • *

    Ní Héb., “ó ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:15; Rut 4:11
  • +Jẹ 30:22

Jẹ́nẹ́sísì 29:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọmọkùnrin Kan Rèé!”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:22; 37:22; 49:3, 4; Ẹk 6:14; 1Kr 5:1
  • +Jẹ 30:20; 1Sa 1:5, 6; Lk 1:24, 25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 29:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ó Ń Gbọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 34:25; 49:5; 1Kr 4:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 29:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Rọ̀ Mọ́; Fà Mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 34:25; 49:5; Ẹk 6:16; Nọ 3:12; 1Kr 6:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 29:35

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ìyìn; Ẹni Tí Ìyìn Yẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:23; 37:26; 44:18; 49:8; 1Kr 2:3; Ifi 5:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 9

Àwọn míì

Jẹ́n. 29:4Jẹ 27:42, 43; Iṣe 7:2
Jẹ́n. 29:5Jẹ 24:29
Jẹ́n. 29:5Jẹ 24:24; 31:53
Jẹ́n. 29:6Jẹ 46:19; Rut 4:11
Jẹ́n. 29:13Jẹ 24:29
Jẹ́n. 29:15Jẹ 28:5
Jẹ́n. 29:15Jẹ 30:27, 28; 31:7
Jẹ́n. 29:16Rut 4:11
Jẹ́n. 29:18Jẹ 31:41
Jẹ́n. 29:20Jẹ 30:26; Ho 12:12
Jẹ́n. 29:24Jẹ 16:1, 2; 30:9; 46:18
Jẹ́n. 29:25Jẹ 31:7, 42
Jẹ́n. 29:27Jẹ 31:41
Jẹ́n. 29:29Jẹ 35:22
Jẹ́n. 29:29Jẹ 30:1, 3
Jẹ́n. 29:30Ho 12:12
Jẹ́n. 29:31Jẹ 46:15; Rut 4:11
Jẹ́n. 29:31Jẹ 30:22
Jẹ́n. 29:32Jẹ 35:22; 37:22; 49:3, 4; Ẹk 6:14; 1Kr 5:1
Jẹ́n. 29:32Jẹ 30:20; 1Sa 1:5, 6; Lk 1:24, 25
Jẹ́n. 29:33Jẹ 34:25; 49:5; 1Kr 4:24
Jẹ́n. 29:34Jẹ 34:25; 49:5; Ẹk 6:16; Nọ 3:12; 1Kr 6:1
Jẹ́n. 29:35Jẹ 35:23; 37:26; 44:18; 49:8; 1Kr 2:3; Ifi 5:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 29:1-35

Jẹ́nẹ́sísì

29 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó sì forí lé ilẹ̀ àwọn ará Ìlà Oòrùn. 2 Ó wá rí kànga kan nínú pápá, ó sì rí agbo àgùntàn mẹ́ta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, torí wọ́n máa ń fún àwọn agbo ẹran lómi látinú kànga yẹn. Òkúta ńlá kan wà ní ẹnu kànga náà. 3 Nígbà tí gbogbo agbo ẹran náà ti kóra jọ síbẹ̀, wọ́n yí òkúta náà kúrò ní ẹnu kànga náà, wọ́n fún àwọn agbo ẹran náà lómi, wọ́n sì dá òkúta pa dà síbi tó wà, ní ẹnu kànga náà.

4 Jékọ́bù bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin èèyàn mi, ibo lẹ ti wá?” Wọ́n fèsì pé: “Háránì+ la ti wá.” 5 Ó bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ mọ Lábánì+ ọmọ ọmọ Náhórì?”+ Wọ́n fèsì pé: “A mọ̀ ọ́n.” 6 Ló bá bi wọ́n pé: “Ṣé àlàáfíà ló wà?” Wọ́n fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Réṣẹ́lì+ ọmọ rẹ̀ náà ló ń da àgùntàn bọ̀ yìí!” 7 Ló bá sọ pé: “Ọ̀sán ṣẹ̀ṣẹ̀ pọ́n ni. Kò tíì tó àkókò láti kó agbo ẹran jọ. Ẹ fún àwọn àgùntàn lómi, kí ẹ sì lọ fún wọn ní oúnjẹ.” 8 Wọ́n fèsì pé: “Wọn ò gbà wá láyè ká ṣe bẹ́ẹ̀, ó dìgbà tí a bá kó gbogbo agbo ẹran jọ, tí wọ́n sì yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga náà. Lẹ́yìn ìyẹn, a lè fún àwọn àgùntàn lómi.”

9 Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Réṣẹ́lì kó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ dé, torí darandaran ni Réṣẹ́lì. 10 Nígbà tí Jékọ́bù rí Réṣẹ́lì ọmọ Lábánì, arákùnrin ìyá rẹ̀ àti àwọn àgùntàn Lábánì, Jékọ́bù sún mọ́ ibi kànga náà lójú ẹsẹ̀, ó yí òkúta kúrò ní ẹnu rẹ̀, ó sì fún àwọn àgùntàn Lábánì arákùnrin ìyá rẹ̀ lómi. 11 Jékọ́bù wá fi ẹnu ko Réṣẹ́lì lẹ́nu, ó ké, ó sì bú sẹ́kún. 12 Jékọ́bù sì sọ fún Réṣẹ́lì pé mọ̀lẹ́bí* bàbá rẹ̀ ni òun àti pé òun ni ọmọ Rèbékà. Réṣẹ́lì bá sáré lọ sọ fún bàbá rẹ̀.

13 Gbàrà tí Lábánì+ gbọ́ ìròyìn nípa Jékọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó sáré lọ pàdé rẹ̀. Ó gbá a mọ́ra, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sínú ilé rẹ̀. Jékọ́bù wá ń ròyìn gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ fún Lábánì. 14 Lábánì sọ fún un pé: “Ó dájú pé egungun mi àti ẹran ara mi ni ọ́.”* Torí náà, ó dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan gbáko.

15 Lábánì wá sọ fún Jékọ́bù pé: “Ṣé wàá máa bá mi ṣiṣẹ́ láìgba nǹkan kan torí o jẹ́ mọ̀lẹ́bí*+ mi ni? Sọ fún mi, kí lo fẹ́ kí n fún ọ?”+ 16 Lábánì ní ọmọbìnrin méjì. Ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Líà, àbúrò sì ń jẹ́ Réṣẹ́lì.+ 17 Ojú Líà kò fani mọ́ra, àmọ́ Réṣẹ́lì wuni, ó sì rẹwà gan-an. 18 Jékọ́bù wá nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì gidigidi, ó sì sọ pé: “Mo ṣe tán láti sìn ọ́ fún ọdún méje torí Réṣẹ́lì+ ọmọ rẹ tó jẹ́ àbúrò Líà.” 19 Lábánì fèsì pé: “Ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n fún ọ ju kí n fún ọkùnrin míì. Máa gbé lọ́dọ̀ mi.” 20 Jékọ́bù wá fi ọdún méje ṣiṣẹ́ fún Lábánì nítorí Réṣẹ́lì,+ àmọ́ bí ọjọ́ díẹ̀ ló rí lójú rẹ̀ torí ìfẹ́ tó ní fún Réṣẹ́lì.

21 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ fún Lábánì pé: “Fún mi ní ìyàwó mi torí ọjọ́ mi ti pé, kí o sì jẹ́ kí n bá a ní àṣepọ̀.” 22 Ni Lábánì bá kó gbogbo èèyàn ibẹ̀ jọ, ó sì se àsè. 23 Àmọ́ ní alẹ́, Líà ló mú lọ fún un, kó lè bá a ní àṣepọ̀. 24 Lábánì tún fún Líà ọmọ rẹ̀ ní Sílípà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, kó lè jẹ́ ìránṣẹ́+ Líà. 25 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jékọ́bù rí i pé Líà ni! Torí náà, ó sọ fún Lábánì pé: “Kí lo ṣe fún mi yìí? Ṣebí torí Réṣẹ́lì ni mo ṣe sìn ọ́? Kí ló dé tí o fi tàn mí jẹ?”+ 26 Lábánì fèsì pé: “Kì í ṣe àṣà wa níbí pé kí àbúrò lọ ilé ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n. 27 Ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú obìnrin yìí fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, màá fún ọ ní obìnrin kejì yìí tí o bá sìn mí fún ọdún méje sí i.”+ 28 Jékọ́bù ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, Lábánì fún un ní Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 29 Lábánì tún fún Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀ ní Bílíhà,+ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ kó lè di ìránṣẹ́+ Réṣẹ́lì.

30 Jékọ́bù wá bá Réṣẹ́lì pẹ̀lú ní àṣepọ̀, ó nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì ju Líà lọ, ó sì fi ọdún méje+ míì ṣiṣẹ́ fún Lábánì. 31 Nígbà tí Jèhófà rí i pé Jékọ́bù kò fẹ́ràn* Líà, ó jẹ́ kí Líà lóyún,*+ àmọ́ Réṣẹ́lì yàgàn.+ 32 Líà wá lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì.*+ Ó sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti rí ìyà+ tó ń jẹ mí, ọkọ mi á wá nífẹ̀ẹ́ mi báyìí.” 33 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti fetí sílẹ̀, ó rí i pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ mi, torí náà, ó tún fún mi ní èyí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síméónì.*+ 34 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, ọkọ mi yóò fà mọ́ mi, torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Léfì.*+ 35 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, màá yin Jèhófà.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Júdà.*+ Lẹ́yìn ìyẹn, kò bímọ mọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́