ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 32
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Àwọn áńgẹ́lì pàdé Jékọ́bù (1, 2)

      • Jékọ́bù múra láti pàdé Ísọ̀ (3-23)

      • Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì (24-32)

        • Orúkọ Jékọ́bù yí pa dà di Ísírẹ́lì (28)

Jẹ́nẹ́sísì 32:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Àgọ́ Méjì.”

Jẹ́nẹ́sísì 32:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “pápá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:39; 36:8; Di 2:5; Joṣ 24:4
  • +Jẹ 25:30

Jẹ́nẹ́sísì 32:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbé bí àjèjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:41

Jẹ́nẹ́sísì 32:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:43; 33:11

Jẹ́nẹ́sísì 32:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 33:1, 2

Jẹ́nẹ́sísì 32:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:41; 32:11

Jẹ́nẹ́sísì 32:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:3, 13

Jẹ́nẹ́sísì 32:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:15; Sm 100:5
  • +Jẹ 28:10; 30:43; 32:7

Jẹ́nẹ́sísì 32:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:4
  • +Jẹ 27:41

Jẹ́nẹ́sísì 32:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:14; 46:2, 3; Ẹk 1:7; 32:13; Iṣe 7:17

Jẹ́nẹ́sísì 32:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 33:10

Jẹ́nẹ́sísì 32:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:43

Jẹ́nẹ́sísì 32:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 33:8

Jẹ́nẹ́sísì 32:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 43:11; 1Sa 25:18

Jẹ́nẹ́sísì 32:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:30; Rut 4:11
  • +Jẹ 30:3, 9
  • +Di 3:16; Joṣ 12:2; Ond 11:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 7

Jẹ́nẹ́sísì 32:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àfonífojì.”

Jẹ́nẹ́sísì 32:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 12:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2003, ojú ìwé 25

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 7

Jẹ́nẹ́sísì 32:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:31, 32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 4/2020, ojú ìwé 2

Jẹ́nẹ́sísì 32:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 12:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2002, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 32:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Bá Ọlọ́run Wọ̀jà” (“Ẹni Tó Rọ̀ Mọ́ Ọlọ́run”) tàbí “Ọlọ́run Wọ̀jà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:10
  • +Ho 12:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2003, ojú ìwé 25

Jẹ́nẹ́sísì 32:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:17, 18

Jẹ́nẹ́sísì 32:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ojú Ọlọ́run.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:25
  • +Jẹ 16:7, 13; Ond 6:22; Jo 1:18

Jẹ́nẹ́sísì 32:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Péníélì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:25

Jẹ́nẹ́sísì 32:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fọ́nrán iṣan tó wà níbi itan.”

Àwọn míì

Jẹ́n. 32:3Jẹ 27:39; 36:8; Di 2:5; Joṣ 24:4
Jẹ́n. 32:3Jẹ 25:30
Jẹ́n. 32:4Jẹ 31:41
Jẹ́n. 32:5Jẹ 30:43; 33:11
Jẹ́n. 32:6Jẹ 33:1, 2
Jẹ́n. 32:7Jẹ 27:41; 32:11
Jẹ́n. 32:9Jẹ 31:3, 13
Jẹ́n. 32:10Jẹ 28:15; Sm 100:5
Jẹ́n. 32:10Jẹ 28:10; 30:43; 32:7
Jẹ́n. 32:11Sm 34:4
Jẹ́n. 32:11Jẹ 27:41
Jẹ́n. 32:12Jẹ 28:14; 46:2, 3; Ẹk 1:7; 32:13; Iṣe 7:17
Jẹ́n. 32:13Jẹ 33:10
Jẹ́n. 32:15Jẹ 30:43
Jẹ́n. 32:18Jẹ 33:8
Jẹ́n. 32:20Jẹ 43:11; 1Sa 25:18
Jẹ́n. 32:22Jẹ 29:30; Rut 4:11
Jẹ́n. 32:22Jẹ 30:3, 9
Jẹ́n. 32:22Di 3:16; Joṣ 12:2; Ond 11:13
Jẹ́n. 32:24Ho 12:3
Jẹ́n. 32:25Jẹ 32:31, 32
Jẹ́n. 32:26Ho 12:4
Jẹ́n. 32:28Jẹ 35:10
Jẹ́n. 32:28Ho 12:3
Jẹ́n. 32:29Ond 13:17, 18
Jẹ́n. 32:301Ọb 12:25
Jẹ́n. 32:30Jẹ 16:7, 13; Ond 6:22; Jo 1:18
Jẹ́n. 32:31Jẹ 32:25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 32:1-32

Jẹ́nẹ́sísì

32 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù ń bá tirẹ̀ lọ, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀. 2 Gbàrà tí Jékọ́bù rí wọn, ó sọ pé: “Àgọ́ Ọlọ́run nìyí!” Torí náà, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Máhánáímù.*

3 Nígbà náà, Jékọ́bù ní kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ilẹ̀ Séírì,+ ní agbègbè* Édómù,+ 4 ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Ísọ̀ olúwa mi nìyí, ‘Ohun tí Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ sọ nìyí: “Ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbé* lọ́dọ̀ Lábánì títí di báyìí.+ 5 Mo ti ní àwọn akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin,+ mo sì ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi láti fi èyí tó o létí, kí n lè rí ojúure rẹ.”’”

6 Nígbà tó yá, àwọn ìránṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ Jékọ́bù, wọ́n sì sọ fún un pé: “A rí Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ, ó sì ti ń bọ̀ wá pàdé rẹ+ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.” 7 Ẹ̀rù wá ba Jékọ́bù gan-an, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀.+ Torí náà, ó pín àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ àtàwọn agbo ẹran, àwọn màlúù àtàwọn ràkúnmí, ó pín wọn sí ọ̀nà méjì. 8 Ó ní: “Bí Ísọ̀ bá gbéjà ko apá kan, apá kejì á lè sá lọ.”

9 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ pé: “Ọlọ́run Ábúráhámù bàbá mi àti Ọlọ́run Ísákì bàbá mi, Jèhófà, ìwọ tí ò ń sọ fún mi pé, ‘Pa dà sí ilẹ̀ rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, màá sì ṣe dáadáa sí ọ,’+ 10 ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn àti bí o ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí ìránṣẹ́+ rẹ kò tọ́ sí mi, mi ò ní ju ọ̀pá kan ṣoṣo nígbà tí mo sọdá odò Jọ́dánì, àmọ́ mo ti wá di àgọ́ méjì+ báyìí. 11 Mo bẹ̀ ọ́,+ gbà mí lọ́wọ́ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi, torí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, ó lè wá gbógun ja èmi+ àti àwọn ọmọ mi pẹ̀lú àwọn ìyá wọn. 12 O sì ti sọ pé: ‘Ó dájú pé màá ṣe dáadáa sí ọ, màá sì mú kí àtọmọdọ́mọ* rẹ pọ̀ bí iyanrìn òkun, débi pé wọn ò ní lè kà wọ́n.’”+

13 Ó wá sun ibẹ̀ mọ́jú. Ó sì mú ẹ̀bùn fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀ látinú àwọn ohun ìní rẹ̀: 14 igba (200) abo ewúrẹ́, ogún (20) òbúkọ, igba (200) abo àgùntàn, ogún (20) àgbò, 15 ọgbọ̀n (30) ràkúnmí tó ń tọ́mọ, ogójì (40) màlúù, akọ màlúù mẹ́wàá, ogún (20) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ mẹ́wàá tó ti dàgbà dáadáa.

16 Ó fà wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, agbo ẹran kan tẹ̀ lé òmíràn, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ sọdá, kí ẹ máa lọ níwájú mi, kí ẹ sì fi àyè sílẹ̀ láàárín agbo ẹran kan àti èyí tó tẹ̀ lé e.” 17 Ó tún pàṣẹ fún èyí tó ṣáájú pé: “Tí Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi bá pàdé rẹ, tó sì bi ọ́ pé, ‘Ta ni ọ̀gá rẹ, ibo lò ń lọ, ta ló sì ni àwọn ohun tó wà níwájú rẹ yìí?’ 18 kí o sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ni. Ẹ̀bùn yìí ló fi ránṣẹ́ sí Ísọ̀+ olúwa mi. Wò ó! Òun náà ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” 19 Ó sì pàṣẹ fún ẹnì kejì, ẹnì kẹta àti gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé agbo ẹran pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Ísọ̀ nìyẹn tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20 Kí ẹ tún sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” Torí ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Tí mo bá kọ́kọ́ fi ẹ̀bùn ránṣẹ́,+ tí mo fi wá ojúure rẹ̀, tí mo bá wá rí òun fúnra rẹ̀, bóyá ó lè tẹ́wọ́ gbà mí.’ 21 Wọ́n sì kó àwọn ẹ̀bùn náà sọdá ṣáájú rẹ̀, àmọ́ inú àgọ́ ni òun sùn.

22 Lóru ọjọ́ yẹn, ó dìde, ó mú àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì,+ àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ rẹ̀ méjèèjì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kànlá (11) tí wọ́n ṣì kéré, wọ́n sì gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò Jábókù+ sọdá. 23 Ó kó gbogbo wọn, ó mú wọn sọdá odò,* ó sì kó gbogbo ohun míì tó ní kọjá.

24 Níkẹyìn, ó ṣẹ́ ku Jékọ́bù nìkan. Ọkùnrin kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jìjàkadì títí ilẹ̀ fi mọ́.+ 25 Nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun ò borí, ó fọwọ́ kan egungun ìbàdí rẹ̀; egungun ìbàdí Jékọ́bù sì yẹ̀ nígbà tó ń bá a jìjàkadì.+ 26 Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé: “Jẹ́ kí n máa lọ, torí ilẹ̀ ti ń mọ́.” Àmọ́ ó fèsì pé: “Mi ò ní jẹ́ kí o lọ, àfi tí o bá súre fún mi.”+ 27 Ó wá bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Jékọ́bù.” 28 Ó wá sọ fún un pé: “O ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì*+ ni wàá máa jẹ́, torí o ti bá Ọlọ́run + àti èèyàn wọ̀jà, o sì ti wá borí.” 29 Ni Jékọ́bù bá sọ pé: “Jọ̀ọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Àmọ́ ó fèsì pé: “Kí nìdí tí o fi ń béèrè orúkọ mi?”+ Ó sì súre fún un níbẹ̀. 30 Torí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ ó dá ẹ̀mí* mi sí.”+

31 Oòrùn wá yọ ní gbàrà tó kọjá Pénúélì,* àmọ́ ó ń tiro torí ohun tó ṣe ìbàdí+ rẹ̀. 32 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé títí dòní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í jẹ iṣan tó wà níbi itan* ní oríkèé egungun ìbàdí, torí ó fọwọ́ kan iṣan tó wà níbi itan ní oríkèé egungun ìbàdí Jékọ́bù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́