ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ọlọ́run ní kí Ìsíkíẹ́lì jẹ àkájọ ìwé tó fún un (1-15)

      • Ìsíkíẹ́lì máa ṣe olùṣọ́ (16-27)

        • Tí kò bá kìlọ̀, yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ (18-21)

Ìsíkíẹ́lì 3:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jẹ ohun tí o rí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 10:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 6/2017,

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    6/2017, ojú ìwé 5

Ìsíkíẹ́lì 3:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:103; Jer 15:16; Ifi 10:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 6/2017,

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    6/2017, ojú ìwé 5

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2008, ojú ìwé 8

    7/1/2007, ojú ìwé 12

    3/15/1991, ojú ìwé 15-16

Ìsíkíẹ́lì 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jon 3:4, 5; Mt 11:21

Ìsíkíẹ́lì 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 10:16
  • +Ẹk 34:9; Jer 3:3; 5:3

Ìsíkíẹ́lì 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:18, 19; 15:20; Mik 3:8

Ìsíkíẹ́lì 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 50:7
  • +Jer 17:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/1/1991, ojú ìwé 31

Ìsíkíẹ́lì 3:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọ èèyàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:12, 14
  • +Isk 2:5

Ìsíkíẹ́lì 3:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 8:3

Ìsíkíẹ́lì 3:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 1:24
  • +Isk 10:16

Ìsíkíẹ́lì 3:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 1:3
  • +Jer 23:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2007, ojú ìwé 13

Ìsíkíẹ́lì 3:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 21:8; 62:6; Jer 6:17
  • +Ais 58:1; Isk 33:7

Ìsíkíẹ́lì 3:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọrùn rẹ ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:40; 1Ti 4:16
  • +Isk 33:4
  • +Isk 33:8

Ìsíkíẹ́lì 3:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 33:9; Iṣe 18:6; 20:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 15

Ìsíkíẹ́lì 3:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo mọ́.”

  • *

    Tàbí “ọrùn rẹ ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 18:24, 26; 33:12, 18
  • +Le 19:17; Isk 33:6; Heb 13:17

Ìsíkíẹ́lì 3:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 17:10; Isk 33:14, 15; Jem 5:19, 20

Ìsíkíẹ́lì 3:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 1:27, 28
  • +Isk 1:1

Ìsíkíẹ́lì 3:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 2:2; Da 10:19

Ìsíkíẹ́lì 3:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 66

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2003, ojú ìwé 29

Ìsíkíẹ́lì 3:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 24:27; 33:22
  • +Mt 11:15
  • +Ais 30:9

Àwọn míì

Ìsík. 3:1Ifi 10:9, 10
Ìsík. 3:3Sm 119:103; Jer 15:16; Ifi 10:9, 10
Ìsík. 3:6Jon 3:4, 5; Mt 11:21
Ìsík. 3:7Lk 10:16
Ìsík. 3:7Ẹk 34:9; Jer 3:3; 5:3
Ìsík. 3:8Jer 1:18, 19; 15:20; Mik 3:8
Ìsík. 3:9Ais 50:7
Ìsík. 3:9Jer 17:18
Ìsík. 3:112Ọb 24:12, 14
Ìsík. 3:11Isk 2:5
Ìsík. 3:12Isk 8:3
Ìsík. 3:13Isk 1:24
Ìsík. 3:13Isk 10:16
Ìsík. 3:15Isk 1:3
Ìsík. 3:15Jer 23:9
Ìsík. 3:17Ais 21:8; 62:6; Jer 6:17
Ìsík. 3:17Ais 58:1; Isk 33:7
Ìsík. 3:18Iṣe 2:40; 1Ti 4:16
Ìsík. 3:18Isk 33:4
Ìsík. 3:18Isk 33:8
Ìsík. 3:19Isk 33:9; Iṣe 18:6; 20:26
Ìsík. 3:20Isk 18:24, 26; 33:12, 18
Ìsík. 3:20Le 19:17; Isk 33:6; Heb 13:17
Ìsík. 3:21Owe 17:10; Isk 33:14, 15; Jem 5:19, 20
Ìsík. 3:23Isk 1:27, 28
Ìsík. 3:23Isk 1:1
Ìsík. 3:24Isk 2:2; Da 10:19
Ìsík. 3:27Isk 24:27; 33:22
Ìsík. 3:27Mt 11:15
Ìsík. 3:27Ais 30:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 3:1-27

Ìsíkíẹ́lì

3 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ ohun tó wà níwájú rẹ.* Jẹ àkájọ ìwé yìí, kí o sì lọ bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”+

2 Torí náà, mo la ẹnu mi, ó sì fún mi ní àkájọ ìwé náà pé kí n jẹ ẹ́. 3 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ àkájọ ìwé tí mo fún ọ yìí, kí o sì jẹ ẹ́ yó.” Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.+

4 Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, lọ sí ilé Ísírẹ́lì, kí o sì jíṣẹ́ mi fún wọn. 5 Torí kì í ṣe àwọn èèyàn tó ń sọ èdè tó ṣòroó lóye tàbí tí èdè wọn ṣàjèjì ni mò ń rán ọ sí, bí kò ṣe ilé Ísírẹ́lì. 6 Kì í ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń sọ èdè tó ṣòroó lóye tàbí tí èdè wọn ṣàjèjì ni mò ń rán ọ sí. Ká ní àwọn ni mo rán ọ sí ni, wọ́n á gbọ́.+ 7 Àmọ́ ilé Ísírẹ́lì ò ní tẹ́tí sí ọ torí wọn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.+ Olórí kunkun àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+ 8 Wò ó! Mo ti mú kí ojú rẹ le bí ojú wọn, mo sì mú kí iwájú orí rẹ le bí iwájú orí wọn.+ 9 Mo ti mú kí iwájú orí rẹ dà bíi dáyámọ́ǹdì, ó le ju akọ òkúta lọ.+ Má bẹ̀rù wọn, má sì jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́,+ torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.”

10 Ó ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ, ó ní: “Ọmọ èèyàn, fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fún ọ, kí o sì fi í sọ́kàn. 11 Lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ* tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn,+ kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀. Yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’”+

12 Ẹ̀mí kan wá ń gbé mi lọ,+ mo sì gbọ́ ìró ohùn kan tó ń rọ́ gììrì lẹ́yìn mi pé: “Ẹ yin Jèhófà lógo láti àyè rẹ̀.” 13 Mo sì gbọ́ ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà bí wọ́n ṣe ń kanra wọn+ àti ìró àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn+ àti ìró ìrọ́gìrì tó rinlẹ̀. 14 Ẹ̀mí náà gbé mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi lọ. Inú mi bà jẹ́, inú sì ń bí mi bí mo ṣe ń lọ, ọwọ́ Jèhófà wà lára mi lọ́nà tó lágbára. 15 Mo wá lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Tẹli-ábíbù, tí wọ́n ń gbé lẹ́bàá odò Kébárì,+ mo sì dúró síbi tí wọ́n ń gbé; mò ń wò suu,+ mo wà lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ méje.

16 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, Jèhófà sọ fún mi pé:

17 “Ọmọ èèyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì,+ nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kí o bá mi kìlọ̀ fún wọn.+ 18 Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ó dájú pé wàá kú,’ àmọ́ tí ìwọ kò kìlọ̀ fún un, tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ kó lè wà láàyè,+ yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí pé ó jẹ́ ẹni burúkú,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.*+ 19 Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú tí kò sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi àti ìwà burúkú rẹ̀, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+ 20 Àmọ́ tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,* èmi yóò fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, yóò sì kú.+ Tí ìwọ kò bá kìlọ̀ fún un, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, mi ò sì ní rántí iṣẹ́ òdodo tó ti ṣe, àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.*+ 21 Àmọ́ tí o bá ti kìlọ̀ fún olódodo náà pé kó má ṣe dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, ó dájú pé ó máa wà láàyè torí o ti kìlọ̀ fún un,+ ìwọ náà yóò sì gba ẹ̀mí* rẹ là.”

22 Ọwọ́ Jèhófà wá sára mi níbẹ̀, ó sì sọ fún mi pé: “Dìde, lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀.” 23 Torí náà mo dìde, mo sì lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wò ó! ògo Jèhófà wà níbẹ̀,+ bí ògo tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì,+ mo sì dojú bolẹ̀. 24 Ẹ̀mí wá wọ inú mi, ó sì mú mi dìde dúró,+ ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sì sọ fún mi pé:

“Lọ ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ. 25 Ní ti ìwọ, ọmọ èèyàn, wọn yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa kúrò láàárín wọn. 26 Màá sì mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ, o ò ní lè sọ̀rọ̀, o ò sì ní lè bá wọn wí, torí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 27 Àmọ́ tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, màá mú kí o sọ̀rọ̀, o sì gbọ́dọ̀ sọ fún wọn pé,+ ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí.’ Kí ẹni tó ń gbọ́ máa gbọ́,+ kí ẹni tí kò bá fẹ́ gbọ́ má sì gbọ́, nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́