ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Jòhánù 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Jòhánù

      • Ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí wò (1-6)

      • Ẹ mọ Ọlọ́run, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (7-21)

        • “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” (8, 16)

        • Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́ (18)

1 Jòhánù 4:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “gbogbo ẹ̀mí.”

  • *

    Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Tẹ 2:1, 2; 1Ti 4:1
  • +Ifi 22:6
  • +2Pe 2:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 6-7

    3/1/2007, ojú ìwé 5

    9/1/2004, ojú ìwé 17

1 Jòhánù 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:14; 1Kọ 12:3; Ifi 19:10

1 Jòhánù 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 2:22
  • +2Tẹ 2:7; 1Jo 2:18
  • +Iṣe 20:29, 30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2015, ojú ìwé 14

1 Jòhánù 4:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 5:4
  • +Jo 17:21
  • +Ef 2:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1991, ojú ìwé 17

1 Jòhánù 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 5:19
  • +Jo 15:19

1 Jòhánù 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 10:27
  • +Jo 8:47
  • +1Jo 4:1

1 Jòhánù 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Pe 1:22
  • +1Jo 4:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2006, ojú ìwé 21-22

1 Jòhánù 4:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:6; Mik 7:18; 1Jo 4:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 7

    Jí!,

    No. 1 2021 ojú ìwé 14

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2019 ojú ìwé 9

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2015, ojú ìwé 16

    7/1/2003, ojú ìwé 14

    6/1/2002, ojú ìwé 6

    2/1/1997, ojú ìwé 9-10

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 14-15, 236-237

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 16-17

1 Jòhánù 4:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:14
  • +Jo 3:16; Ro 5:8; 8:32; 1Jo 5:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 28

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 2 2017 ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/1997, ojú ìwé 12

    6/15/1996, ojú ìwé 6

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 15-16

1 Jòhánù 4:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ètùtù; ohun tí a fi ń tuni lójú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 5:7
  • +Ro 3:25; Heb 2:17; 9:26; 1Jo 2:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 28

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2008, ojú ìwé 27

    3/15/1999, ojú ìwé 9

    6/15/1996, ojú ìwé 6

1 Jòhánù 4:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 18:33; Jo 15:12; Ro 13:8; 1Jo 3:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 28

    Ṣọ́nà!, ojú ìwé 29

1 Jòhánù 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 33:20; Jo 1:18; 4:24; 6:46
  • +1Jo 2:5

1 Jòhánù 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 1:21; Jo 3:17; 12:47; Iṣe 5:31

1 Jòhánù 4:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 10:9
  • +1Jo 2:23, 24

1 Jòhánù 4:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:16
  • +1Jo 4:8
  • +Jo 17:21

1 Jòhánù 4:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ní ìgboyà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 4:16; 1Jo 2:28

1 Jòhánù 4:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ju ìbẹ̀rù síta.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:15
  • +1Jo 2:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2004, ojú ìwé 29

    8/1/1995, ojú ìwé 31

1 Jòhánù 4:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 4:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 46

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2015, ojú ìwé 23

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 237-239

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 5

1 Jòhánù 4:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 2:4
  • +1Jo 3:17
  • +1Jo 4:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2007, ojú ìwé 30

    12/1/2006, ojú ìwé 27

1 Jòhánù 4:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 22:37, 39; Jo 13:34; 15:12

Àwọn míì

1 Jòh. 4:12Tẹ 2:1, 2; 1Ti 4:1
1 Jòh. 4:1Ifi 22:6
1 Jòh. 4:12Pe 2:1
1 Jòh. 4:2Jo 1:14; 1Kọ 12:3; Ifi 19:10
1 Jòh. 4:31Jo 2:22
1 Jòh. 4:32Tẹ 2:7; 1Jo 2:18
1 Jòh. 4:3Iṣe 20:29, 30
1 Jòh. 4:41Jo 5:4
1 Jòh. 4:4Jo 17:21
1 Jòh. 4:4Ef 2:2
1 Jòh. 4:51Jo 5:19
1 Jòh. 4:5Jo 15:19
1 Jòh. 4:6Jo 10:27
1 Jòh. 4:6Jo 8:47
1 Jòh. 4:61Jo 4:1
1 Jòh. 4:71Pe 1:22
1 Jòh. 4:71Jo 4:16
1 Jòh. 4:8Ẹk 34:6; Mik 7:18; 1Jo 4:19
1 Jòh. 4:9Jo 1:14
1 Jòh. 4:9Jo 3:16; Ro 5:8; 8:32; 1Jo 5:11
1 Jòh. 4:101Kọ 5:7
1 Jòh. 4:10Ro 3:25; Heb 2:17; 9:26; 1Jo 2:1, 2
1 Jòh. 4:11Mt 18:33; Jo 15:12; Ro 13:8; 1Jo 3:16
1 Jòh. 4:12Ẹk 33:20; Jo 1:18; 4:24; 6:46
1 Jòh. 4:121Jo 2:5
1 Jòh. 4:14Mt 1:21; Jo 3:17; 12:47; Iṣe 5:31
1 Jòh. 4:15Ro 10:9
1 Jòh. 4:151Jo 2:23, 24
1 Jòh. 4:16Jo 3:16
1 Jòh. 4:161Jo 4:8
1 Jòh. 4:16Jo 17:21
1 Jòh. 4:17Heb 4:16; 1Jo 2:28
1 Jòh. 4:18Ro 8:15
1 Jòh. 4:181Jo 2:5
1 Jòh. 4:191Jo 4:10
1 Jòh. 4:201Jo 2:4
1 Jòh. 4:201Jo 3:17
1 Jòh. 4:201Jo 4:12
1 Jòh. 4:21Mt 22:37, 39; Jo 13:34; 15:12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Jòhánù 4:1-21

Ìwé Kìíní Jòhánù

4 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gba gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí*+ gbọ́, àmọ́ kí ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí* wò kí ẹ lè mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá,+ torí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ló ti jáde lọ sínú ayé.+

2 Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ kan tó ní ìmísí ti wá: Gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tó bá fi hàn pé Jésù Kristi wá nínú ẹran ara jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 3 Àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tí kò bá fi hàn pé Jésù wá, kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Bákan náà, ọ̀rọ̀ yìí ni aṣòdì sí Kristi mí sí, ẹni tí ẹ gbọ́ pé ó ń bọ̀,+ ó sì ti wà ní ayé báyìí.+

4 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lẹ ti wá, ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn,+ torí ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín+ tóbi ju ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ayé.+ 5 Inú ayé ni wọ́n ti wá;+ ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ohun tó wá látinú ayé, ayé sì ń fetí sí wọn.+ 6 Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá. Ẹnikẹ́ni tó bá ti wá mọ Ọlọ́run ń fetí sí wa;+ ẹnikẹ́ni tí kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í fetí sí wa.+ Báyìí la ṣe ń fìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ní ìmísí àti ọ̀rọ̀ àṣìṣe tó ní ìmísí.+

7 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa,+ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá, gbogbo ẹni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ la ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.+ 8 Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, torí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.+ 9 Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wa nìyí, Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo+ wá sí ayé, ká lè ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.+ 10 Bí ìfẹ́ náà ṣe jẹ́ nìyí, kì í ṣe pé àwa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ kó lè jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+

11 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, tó bá jẹ́ pé bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa nìyí, àwa náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa.+ 12 Kò sí ẹni tó rí Ọlọ́run rí.+ Tí a bá túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ ara wa, Ọlọ́run ò ní fi wá sílẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ á sì di pípé nínú wa.+ 13 Èyí la fi mọ̀ pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí òun náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, torí ó ti fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀. 14 Bákan náà, àwa fúnra wa ti rí, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ wá kó lè jẹ́ olùgbàlà ayé.+ 15 Ẹnikẹ́ni tó bá gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù,+ Ọlọ́run wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni yẹn, òun náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.+ 16 A ti wá mọ̀, a sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa.+

Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,+ ẹni tó bá wà nínú ìfẹ́ ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+ 17 Báyìí la ṣe sọ ìfẹ́ di pípé nínú wa, ká lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà*+ ní ọjọ́ ìdájọ́, torí pé bí ẹni yẹn ṣe jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà jẹ́ nínú ayé yìí. 18 Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́,+ àmọ́ ìfẹ́ tó pé máa ń lé ìbẹ̀rù jáde,* torí ìbẹ̀rù máa ń ká wa lọ́wọ́ kò. Lóòótọ́, ẹni tó bá ń bẹ̀rù kò tíì di pípé nínú ìfẹ́.+ 19 A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.+

20 Tí ẹnikẹ́ni bá sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,” síbẹ̀ tó ń kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni.+ Torí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí,+ kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.+ 21 Àṣẹ tí a gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀ nìyí, pé ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́