ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì (1-6)

      • Ábúráhámù kú (7-11)

      • Àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì (12-18)

      • Wọ́n bí Jékọ́bù àti Ísọ̀ (19-26)

      • Ísọ̀ ta ogún ìbí rẹ̀ (27-34)

Jẹ́nẹ́sísì 25:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2023,

Jẹ́nẹ́sísì 25:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:28; Ẹk 2:15; Nọ 31:2; Ond 6:2
  • +1Kr 1:32, 33

Jẹ́nẹ́sísì 25:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:36

Jẹ́nẹ́sísì 25:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:14

Jẹ́nẹ́sísì 25:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2010, ojú ìwé 13

Jẹ́nẹ́sísì 25:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2016, ojú ìwé 7-8

Jẹ́nẹ́sísì 25:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 23:8, 9; 49:29, 30

Jẹ́nẹ́sísì 25:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 23:2, 19

Jẹ́nẹ́sísì 25:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:19; 26:12-14
  • +Jẹ 16:14

Jẹ́nẹ́sísì 25:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:10, 11
  • +Ga 4:24

Jẹ́nẹ́sísì 25:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:2, 3; Ais 60:7
  • +Sm 120:5; Jer 49:28; Isk 27:21
  • +1Kr 1:29-31

Jẹ́nẹ́sísì 25:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àgọ́ olódi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:20

Jẹ́nẹ́sísì 25:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Jẹ́nẹ́sísì 25:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Kò sí àlàáfíà láàárín àwọn àtàwọn arákùnrin wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:7
  • +Jẹ 16:7, 8
  • +Jẹ 16:11, 12

Jẹ́nẹ́sísì 25:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 22:2; Mt 1:1, 2

Jẹ́nẹ́sísì 25:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 22:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1695

Jẹ́nẹ́sísì 25:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 9:10

Jẹ́nẹ́sísì 25:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 139:15
  • +Jẹ 36:31; Nọ 20:14
  • +Jẹ 27:29, 30; Di 2:4
  • +2Sa 8:14; Mal 1:2, 3; Ro 9:10-13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2004, ojú ìwé 28

    10/15/2003, ojú ìwé 29

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 90-91

Jẹ́nẹ́sísì 25:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Onírun Lára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:11
  • +Jẹ 27:32; 36:9; Mal 1:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 14

Jẹ́nẹ́sísì 25:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Di Gìgísẹ̀ Mú; Ẹni Tó Gba Ipò Onípò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 12:3
  • +Jẹ 27:36

Jẹ́nẹ́sísì 25:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:3, 5
  • +Heb 11:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2013, ojú ìwé 27

    10/15/2003, ojú ìwé 28

Jẹ́nẹ́sísì 25:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:6, 7, 46

Jẹ́nẹ́sísì 25:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fún mi ní díẹ̀ nínú.”

  • *

    Ní Héb., “pupa yìí, pupa yìí gangan.”

  • *

    Tàbí “ebi ń pa mí gan-an.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Pupa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2002, ojú ìwé 11

Jẹ́nẹ́sísì 25:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 21:16, 17

Jẹ́nẹ́sísì 25:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 12:16

Àwọn míì

Jẹ́n. 25:2Jẹ 37:28; Ẹk 2:15; Nọ 31:2; Ond 6:2
Jẹ́n. 25:21Kr 1:32, 33
Jẹ́n. 25:5Jẹ 24:36
Jẹ́n. 25:6Jẹ 21:14
Jẹ́n. 25:9Jẹ 23:8, 9; 49:29, 30
Jẹ́n. 25:10Jẹ 23:2, 19
Jẹ́n. 25:11Jẹ 17:19; 26:12-14
Jẹ́n. 25:11Jẹ 16:14
Jẹ́n. 25:12Jẹ 16:10, 11
Jẹ́n. 25:12Ga 4:24
Jẹ́n. 25:13Jẹ 36:2, 3; Ais 60:7
Jẹ́n. 25:13Sm 120:5; Jer 49:28; Isk 27:21
Jẹ́n. 25:131Kr 1:29-31
Jẹ́n. 25:16Jẹ 17:20
Jẹ́n. 25:181Sa 15:7
Jẹ́n. 25:18Jẹ 16:7, 8
Jẹ́n. 25:18Jẹ 16:11, 12
Jẹ́n. 25:19Jẹ 22:2; Mt 1:1, 2
Jẹ́n. 25:20Jẹ 22:23
Jẹ́n. 25:22Ro 9:10
Jẹ́n. 25:23Sm 139:15
Jẹ́n. 25:23Jẹ 36:31; Nọ 20:14
Jẹ́n. 25:23Jẹ 27:29, 30; Di 2:4
Jẹ́n. 25:232Sa 8:14; Mal 1:2, 3; Ro 9:10-13
Jẹ́n. 25:25Jẹ 27:11
Jẹ́n. 25:25Jẹ 27:32; 36:9; Mal 1:3
Jẹ́n. 25:26Ho 12:3
Jẹ́n. 25:26Jẹ 27:36
Jẹ́n. 25:27Jẹ 27:3, 5
Jẹ́n. 25:27Heb 11:9
Jẹ́n. 25:28Jẹ 27:6, 7, 46
Jẹ́n. 25:30Jẹ 36:1
Jẹ́n. 25:31Di 21:16, 17
Jẹ́n. 25:33Heb 12:16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 25:1-34

Jẹ́nẹ́sísì

25 Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì, Kétúrà ni orúkọ rẹ̀. 2 Nígbà tó yá, ó bí Símíránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì,+ Íṣíbákì àti Ṣúáhì.+

3 Jókíṣánì bí Ṣébà àti Dédánì.

Àwọn ọmọ Dédánì ni Áṣúrímù, Létúṣímù àti Léúmímù.

4 Àwọn ọmọ Mídíánì ni Eéfà, Éférì, Hánókù, Ábíídà àti Élídáà.

Ọmọ Kétúrà ni gbogbo wọn.

5 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fún Ísákì  + ní gbogbo ohun tó ní, 6 àmọ́ Ábúráhámù fún àwọn ọmọ tí àwọn wáhàrì* rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn. Nígbà tó ṣì wà láàyè, ó ní kí wọ́n máa lọ sí apá ìlà oòrùn kúrò lọ́dọ̀ Ísákì ọmọ+ rẹ̀, sí ilẹ̀ Ìlà Oòrùn. 7 Ọjọ́ ayé Ábúráhámù jẹ́ ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án (175). 8 Ábúráhámù mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, ó darúgbó, ayé rẹ̀ sì dára, wọ́n wá kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 9 Ísákì àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ sin ín sí ihò Mákípẹ́là lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Sóhárì, ọmọ Hétì, tó wà níwájú Mámúrè,+ 10 ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hétì. Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù sí, pẹ̀lú Sérà+ ìyàwó rẹ̀. 11 Lẹ́yìn tí Ábúráhámù kú, Ọlọ́run ṣì ń bù kún Ísákì+ ọmọ rẹ̀, Ísákì sì ń gbé nítòsí Bia-laháí-róì.+

12 Ìtàn Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Ábúráhámù nìyí, ẹni tí Hágárì+ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Sérà bí fún Ábúráhámù.

13 Orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì nìyí, orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí wọ́n ti wá: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì ni Nébáótì,+ lẹ́yìn náà ó bí Kídárì,+ Ádíbéélì, Míbúsámù,+ 14 Míṣímà, Dúmà, Máásà, 15 Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà. 16 Àwọn yìí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì, orúkọ wọn sì nìyí, gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé àti ibùdó* wọn, wọ́n jẹ́ ìjòyè méjìlá (12) ní àwọn agbo ilé+ wọn. 17 Ọjọ́ ayé Íṣímáẹ́lì jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógóje (137). Ó mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, wọ́n kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 18 Wọ́n tẹ̀ dó sí Háfílà+ nítòsí Ṣúrì,+ tó sún mọ́ Íjíbítì, títí lọ dé Ásíríà. Wọ́n sì ń gbé nítòsí gbogbo àwọn arákùnrin+ wọn.*

19 Ìtàn Ísákì ọmọ Ábúráhámù+ nìyí.

Ábúráhámù bí Ísákì. 20 Ẹni ogójì (40) ọdún ni Ísákì nígbà tó fẹ́ Rèbékà, ọmọ Bẹ́túẹ́lì+ ará Arémíà ní ilẹ̀ Padani-árámù, òun ni arábìnrin Lábánì ará Arémíà. 21 Ísákì sì ń bẹ Jèhófà nítorí ìyàwó rẹ̀, torí pé ó yàgàn; Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sì lóyún. 22 Àwọn ọmọ inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn+ jà, débi tó fi sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé bó ṣe máa ń rí nìyí, ǹjẹ́ kò ní sàn kí n kú?” Torí náà, ó wádìí lọ́wọ́ Jèhófà. 23 Jèhófà sì sọ fún un pé: “Orílẹ̀-èdè méjì ló wà nínú ikùn+ rẹ, èèyàn méjì tó yàtọ̀ síra máa tinú rẹ+ jáde; orílẹ̀-èdè kan máa lágbára ju ìkejì+ lọ, ẹ̀gbọ́n sì máa sin àbúrò.”+

24 Nígbà tí àsìkò tó máa bímọ tó, wò ó! ìbejì ló wà ní inú rẹ̀. 25 Èyí àkọ́kọ́ sì jáde, ó pupa látòkè délẹ̀, ó dà bí aṣọ onírun,+ torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísọ̀.*+ 26 Lẹ́yìn náà, àbúrò rẹ̀ jáde, ó sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú, torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.*+ Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Ísákì nígbà tí Rèbékà bí àwọn ọmọ náà.

27 Bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Ísọ̀ di ọdẹ+ tó já fáfá, inú igbó ló sábà máa ń lọ, àmọ́ Jékọ́bù jẹ́ aláìlẹ́bi, inú àgọ́+ ló máa ń wà. 28 Ísákì nífẹ̀ẹ́ Ísọ̀ torí ó máa ń fún un ní ẹran ìgbẹ́ jẹ, àmọ́ Rèbékà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù.+ 29 Lọ́jọ́ kan, Jékọ́bù ń se ọbẹ̀ nígbà tí Ísọ̀ dé láti oko ọdẹ, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. 30 Torí náà Ísọ̀ sọ fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀ọ́, sáré fún mi lára* ọbẹ̀ pupa tí ò ń sè yẹn,* torí ó ti rẹ̀ mí!”* Ìdí nìyẹn tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹ́ Édómù.*+ 31 Jékọ́bù wá fèsì pé: “Kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+ fún mi!” 32 Ísọ̀ dá a lóhùn pé: “Èmi tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú! Kí ni ogún ìbí fẹ́ dà fún mi?” 33 Jékọ́bù sọ pé: “Kọ́kọ́ búra fún mi!” Ló bá búra fún un, ó sì ta ogún ìbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù.+ 34 Jékọ́bù wá fún Ísọ̀ ní búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ó jẹ, ó sì mu. Ó dìde, ó sì ń lọ. Bí Ísọ̀ ṣe fi hàn pé òun ò mọyì ogún ìbí rẹ̀ nìyẹn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́