ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 31
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ló dájú, kì í ṣe ti èèyàn (1-9)

        • Ẹran ara ni àwọn ẹṣin Íjíbítì (3)

Àìsáyà 31:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn agẹṣin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:2
  • +Di 17:15, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 317-318

Àìsáyà 31:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:6, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 319-320

Àìsáyà 31:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 33:17; Owe 21:31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 320-321

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 28-29

Àìsáyà 31:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 321-323

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1996, ojú ìwé 32

Àìsáyà 31:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:11, 12; Sm 91:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 323

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1996, ojú ìwé 32

Àìsáyà 31:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 55:7; Joẹ 2:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 323-325

Àìsáyà 31:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 325-327

Àìsáyà 31:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:35; 2Kr 32:21; Ais 37:36

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 327-328

Àìsáyà 31:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “iná.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 328

Àwọn míì

Àìsá. 31:1Ais 30:2
Àìsá. 31:1Di 17:15, 16
Àìsá. 31:2Isk 29:6, 7
Àìsá. 31:3Sm 33:17; Owe 21:31
Àìsá. 31:5Di 32:11, 12; Sm 91:4
Àìsá. 31:6Ais 55:7; Joẹ 2:12
Àìsá. 31:82Ọb 19:35; 2Kr 32:21; Ais 37:36
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 31:1-9

Àìsáyà

31 Ó mà ṣe fún àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì o,+

Tí wọ́n gbójú lé ẹṣin,+

Tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ogun, torí pé wọ́n pọ̀,

Àti àwọn ẹṣin ogun,* torí pé wọ́n lágbára.

Wọn ò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,

Wọn ò sì wá Jèhófà.

 2 Àmọ́ òun náà gbọ́n, ó sì máa mú àjálù wá,

Kò sì ní kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ.

Ó máa dìde sí ilé àwọn tó ń ṣe ohun tó burú

Àti sí àwọn tó ń ran aṣebi lọ́wọ́.+

 3 Àmọ́ èèyàn lásán ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì í ṣe Ọlọ́run;

Ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn ní, wọn kì í ṣe ẹ̀mí.+

Tí Jèhófà bá na ọwọ́ rẹ̀,

Ẹnikẹ́ni tó bá ranni lọ́wọ́ máa kọsẹ̀,

Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá sì ràn lọ́wọ́ máa ṣubú;

Gbogbo wọn máa ṣègbé lẹ́ẹ̀kan náà.

 4 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:

“Bí kìnnìún, ìyẹn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ṣe ń kùn lórí ẹran tó pa,

Nígbà tí a pe odindi àwùjọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn sí i,

Tí ohùn wọn ò dẹ́rù bà á,

Tí gìrìgìrì wọn ò sì kó jìnnìjìnnì bá a,

Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa sọ̀ kalẹ̀ wá ja ogun

Lórí Òkè Síónì àti lórí òkè kékeré rẹ̀.

 5 Bí àwọn ẹyẹ tó ń já ṣòòrò wálẹ̀, ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ṣe máa gbèjà Jerúsálẹ́mù.+

Ó máa gbèjà rẹ̀, ó sì máa gbà á là.

Ó máa dá a sí, ó sì máa gbà á sílẹ̀.”

6 “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ Ẹni tí ẹ fi àfojúdi ṣọ̀tẹ̀ sí, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì.+ 7 Torí pé ní ọjọ́ yẹn, kálukú máa kọ àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí, tó fi fàdákà ṣe àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò wúlò, tó fi wúrà ṣe, èyí tí ẹ fi ọwọ́ ara yín ṣe, tó sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

 8 Ará Ásíríà máa tipa idà tí kì í ṣe ti èèyàn ṣubú;

Idà tí kì í ṣe ti aráyé ló sì máa jẹ ẹ́ run.+

Ó máa sá lọ nítorí idà,

Wọ́n sì máa fipá kó àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́.

 9 Àpáta rẹ̀ máa kọjá lọ torí ìbẹ̀rù tó bò ó,

Jìnnìjìnnì sì máa bá àwọn ìjòyè rẹ̀ torí òpó tí a fi ṣe àmì,” ni Jèhófà wí,

Ẹni tí ìmọ́lẹ̀* rẹ̀ wà ní Síónì, tí iná ìléru rẹ̀ sì wà ní Jerúsálẹ́mù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́