ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Sọ́ọ̀lù yan àwọn ọmọ ogun (1-4)

      • Sọ́ọ̀lù kọjá àyè rẹ̀ (5-9)

      • Sámúẹ́lì bá Sọ́ọ̀lù wí (10-14)

      • Ísírẹ́lì kò ní àwọn ohun ìjà (15-23)

1 Sámúẹ́lì 13:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Kò sí iye ọdún náà nínú ẹ̀dà ti èdè Hébérù ayé àtijọ́.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 13:21

1 Sámúẹ́lì 13:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:1; 2Sa 1:4; 21:7
  • +Joṣ 18:28; 1Sa 10:26

1 Sámúẹ́lì 13:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:2, 3; 1Sa 9:16
  • +Joṣ 21:8, 17
  • +Ond 3:26, 27; 6:34; 2Sa 2:28

1 Sámúẹ́lì 13:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 5:9; 1Sa 11:14

1 Sámúẹ́lì 13:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 20:1
  • +Joṣ 7:2; 18:11, 12; 1Sa 14:23

1 Sámúẹ́lì 13:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yàrá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 14:11

1 Sámúẹ́lì 13:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:1, 33; Joṣ 13:24, 25

1 Sámúẹ́lì 13:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yàn.”

1 Sámúẹ́lì 13:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:22, 23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2017, ojú ìwé 17

1 Sámúẹ́lì 13:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 13:6, 8
  • +1Sa 13:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2000, ojú ìwé 13

1 Sámúẹ́lì 13:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tu Jèhófà lójú.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2000, ojú ìwé 13

1 Sámúẹ́lì 13:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:11

1 Sámúẹ́lì 13:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:28
  • +1Sa 16:1; 2Sa 7:15; Sm 78:70; Iṣe 13:22
  • +Jẹ 49:10; 2Sa 5:2; 7:8; 1Kr 28:4
  • +Owe 11:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2011, ojú ìwé 26-29

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 120-121

1 Sámúẹ́lì 13:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 13:7; 14:2

1 Sámúẹ́lì 13:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 13:3
  • +1Sa 13:2

1 Sámúẹ́lì 13:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:11

1 Sámúẹ́lì 13:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Òṣùwọ̀n àtijọ́ kan, ó wúwo tó nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta ṣékélì kan.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 75

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1713

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2005, ojú ìwé 29

1 Sámúẹ́lì 13:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 17:47, 50

1 Sámúẹ́lì 13:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwùjọ àwọn ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 13:2; 14:4, 5

Àwọn míì

1 Sám. 13:1Iṣe 13:21
1 Sám. 13:21Sa 18:1; 2Sa 1:4; 21:7
1 Sám. 13:2Joṣ 18:28; 1Sa 10:26
1 Sám. 13:3Joṣ 13:2, 3; 1Sa 9:16
1 Sám. 13:3Joṣ 21:8, 17
1 Sám. 13:3Ond 3:26, 27; 6:34; 2Sa 2:28
1 Sám. 13:4Joṣ 5:9; 1Sa 11:14
1 Sám. 13:5Di 20:1
1 Sám. 13:5Joṣ 7:2; 18:11, 12; 1Sa 14:23
1 Sám. 13:61Sa 14:11
1 Sám. 13:7Nọ 32:1, 33; Joṣ 13:24, 25
1 Sám. 13:91Sa 15:22, 23
1 Sám. 13:111Sa 13:6, 8
1 Sám. 13:111Sa 13:5
1 Sám. 13:131Sa 15:11
1 Sám. 13:141Sa 15:28
1 Sám. 13:141Sa 16:1; 2Sa 7:15; Sm 78:70; Iṣe 13:22
1 Sám. 13:14Jẹ 49:10; 2Sa 5:2; 7:8; 1Kr 28:4
1 Sám. 13:14Owe 11:2
1 Sám. 13:151Sa 13:7; 14:2
1 Sám. 13:161Sa 13:3
1 Sám. 13:161Sa 13:2
1 Sám. 13:18Joṣ 10:11
1 Sám. 13:221Sa 17:47, 50
1 Sám. 13:231Sa 13:2; 14:4, 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 13:1-23

Sámúẹ́lì Kìíní

13 Sọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni ọdún . . .* nígbà tó jọba.+ Lẹ́yìn ọdún méjì tó ti ń jọba lórí Ísírẹ́lì, 2 Sọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn látinú Ísírẹ́lì; ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) lára wọn wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù ní Míkímáṣì àti ní agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà pẹ̀lú Jónátánì+ ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì. Ó rán ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn náà lọ sí àgọ́ wọn. 3 Nígbà náà, Jónátánì bá àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì+ tó wà ní Gébà+ jà, ó ṣẹ́gun wọn, àwọn Filísínì sì gbọ́. Ni Sọ́ọ̀lù bá ní kí wọ́n fun ìwo+ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ náà, pé: “Kí gbogbo àwọn Hébérù gbọ́ o!” 4 Gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ ìròyìn pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣẹ́gun àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì, Ísírẹ́lì sì ti wá di ẹni ìkórìíra lójú àwọn Filísínì.” Torí náà, wọ́n pe àwọn èèyàn náà jọ sí Gílígálì láti tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù.+

5 Àwọn Filísínì pẹ̀lú kóra jọ láti bá Ísírẹ́lì jà, wọ́n ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) agẹṣin àti àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n jáde lọ, wọ́n sì tẹ̀ dó sí Míkímáṣì ní ìlà oòrùn Bẹti-áfénì.+ 6 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì rí i pé àwọn ti wọ ìjàngbọ̀n, torí pé ọwọ́ ọ̀tá le mọ́ wọn; ni àwọn èèyàn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í fara pa mọ́ sínú ihò àpáta,+ sínú kòtò, sínú pàlàpálá àpáta, ihò* abẹ́lẹ̀ àti àwọn kòtò omi. 7 Àwọn Hébérù kan tiẹ̀ sọdá Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì.+ Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ṣì wà ní Gílígálì, jìnnìjìnnì sì ti bá gbogbo àwọn èèyàn tó ń tẹ̀ lé e. 8 Ọjọ́ méje ló fi ń dúró títí di àkókò tí Sámúẹ́lì dá,* àmọ́ Sámúẹ́lì kò wá sí Gílígálì, àwọn èèyàn sì ń tú ká mọ́ Sọ́ọ̀lù lórí. 9 Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ gbé ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Ó sì rú ẹbọ sísun náà.+

10 Àmọ́ gbàrà tó rú ẹbọ sísun náà tán, Sámúẹ́lì dé. Sọ́ọ̀lù bá jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀. 11 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Kí lo ṣe yìí?” Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo rí i pé àwọn èèyàn ti ń fi mí sílẹ̀,+ ìwọ náà ò sì dé ní àkókò tí o dá, àwọn Filísínì sì ń kóra jọ ní Míkímáṣì.+ 12 Ni mo bá sọ fún ara mi pé, ‘Àwọn Filísínì máa wá gbéjà kò mí ní Gílígálì, mi ò sì tíì wá ojú rere Jèhófà.’* Ìdí nìyẹn tí mo fi rí i pé ó pọn dandan kí n rú ẹbọ sísun náà.”

13 Ni Sámúẹ́lì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìwà òmùgọ̀ lo hù. O ò ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa fún ọ.+ Ká ní o ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé. 14 Àmọ́ ní báyìí, ìjọba rẹ kò ní pẹ́.+ Jèhófà máa wá ọkùnrin kan tí ọkàn rẹ̀ fẹ́,+ Jèhófà sì máa yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn rẹ̀,+ nítorí pé o ò ṣègbọràn sí ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ.”+

15 Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì dìde, ó sì bá tiẹ̀ lọ láti Gílígálì sí Gíbíà ti Bẹ́ńjámínì, Sọ́ọ̀lù sì ka àwọn èèyàn náà; àwọn tó ṣẹ́ kù sọ́dọ̀ rẹ̀ tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin.+ 16 Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù sọ́dọ̀ wọn ń gbé ní Gébà+ ti Bẹ́ńjámínì, àwọn Filísínì sì ti pàgọ́ sí Míkímáṣì.+ 17 Agbo àwọn akónilẹ́rù máa ń jáde ogun láti ibùdó àwọn Filísínì ní àwùjọ mẹ́ta. Àwùjọ kan á yíjú sí ojú ọ̀nà tó lọ sí Ọ́fírà, sí ilẹ̀ Ṣúálì; 18 àwùjọ kejì á yíjú sí ojú ọ̀nà Bẹti-hórónì;+ àwùjọ kẹta á sì yíjú sí ojú ọ̀nà tó lọ sí ààlà tó dojú kọ àfonífojì Sébóímù, lápá aginjù.

19 Ní àkókò yẹn, kò sí alágbẹ̀dẹ kankan ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn Filísínì ti sọ pé: “Kí àwọn Hébérù má bàa rọ idà tàbí ọ̀kọ̀.” 20 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti lọ sọ́dọ̀ àwọn Filísínì kí wọ́n lè pọ́n abẹ ohun ìtúlẹ̀ wọn, jígà wọn, àáké wọn tàbí dòjé wọn. 21 Iye tí wọ́n fi ń pọ́n ohun èlò kọ̀ọ̀kan jẹ́ píìmù* kan tí wọ́n bá fẹ́ pọ́n àwọn abẹ ìtúlẹ̀, jígà, àwọn ohun èlò eléyín mẹ́ta, àáké tàbí tí wọ́n bá fẹ́ de ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù pinpin. 22 Ní ọjọ́ ogun, kò sí idà tàbí ọ̀kọ̀ lọ́wọ́ ìkankan lára àwọn tó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì;+ Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ nìkan ló ní àwọn ohun ìjà.

23 Lákòókò yẹn, àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì* ti jáde lọ sí ọ̀nà àfonífojì tóóró tó wà ní Míkímáṣì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́