ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀ tó bà jẹ́ (1-11)

      • Ọlọ́run máa fọ́ àwọn ìṣà wáìnì (12-14)

      • Júdà alágídí máa lọ sí ìgbèkùn (15-27)

        • “Ǹjẹ́ ọmọ Kúṣì lè yí àwọ̀ rẹ̀ pa dà?” (23)

Jeremáyà 13:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Jeremáyà 13:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:19; Sef 3:11

Jeremáyà 13:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16
  • +Jer 6:28

Jeremáyà 13:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5; Di 26:18; Sm 135:4
  • +Jer 33:9
  • +Jer 6:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2017, ojú ìwé 3

Jeremáyà 13:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 29:9; 51:17; Jer 25:27

Jeremáyà 13:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:21; Isk 5:10
  • +Isk 7:4; 24:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 258

Jeremáyà 13:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 59:9

Jeremáyà 13:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn mi á.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:1
  • +Sm 100:3

Jeremáyà 13:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyáàfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:12; Jer 22:24, 26

Jeremáyà 13:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dó ti àwọn ìlú gúúsù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:64

Jeremáyà 13:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:22
  • +Isk 34:8

Jeremáyà 13:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 39:1, 2
  • +Jer 6:24; Mik 4:9

Jeremáyà 13:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:19; 16:10, 11
  • +Isk 16:37

Jeremáyà 13:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ará Etiópíà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 27:22

Jeremáyà 13:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:33; Di 28:64

Jeremáyà 13:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:32
  • +Di 32:37, 38; Ais 28:15; Jer 10:14

Jeremáyà 13:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 1:8; Isk 16:37; 23:29

Jeremáyà 13:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dójú tini.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:20; Isk 16:15
  • +Ais 65:7; Isk 6:13
  • +Isk 24:13

Àwọn míì

Jer. 13:9Le 26:19; Sef 3:11
Jer. 13:102Kr 36:15, 16
Jer. 13:10Jer 6:28
Jer. 13:11Ẹk 19:5; Di 26:18; Sm 135:4
Jer. 13:11Jer 33:9
Jer. 13:11Jer 6:17
Jer. 13:13Ais 29:9; 51:17; Jer 25:27
Jer. 13:14Jer 6:21; Isk 5:10
Jer. 13:14Isk 7:4; 24:14
Jer. 13:16Ais 59:9
Jer. 13:17Jer 9:1
Jer. 13:17Sm 100:3
Jer. 13:182Ọb 24:12; Jer 22:24, 26
Jer. 13:19Di 28:64
Jer. 13:20Jer 6:22
Jer. 13:20Isk 34:8
Jer. 13:21Ais 39:1, 2
Jer. 13:21Jer 6:24; Mik 4:9
Jer. 13:22Jer 5:19; 16:10, 11
Jer. 13:22Isk 16:37
Jer. 13:23Owe 27:22
Jer. 13:24Le 26:33; Di 28:64
Jer. 13:25Jer 2:32
Jer. 13:25Di 32:37, 38; Ais 28:15; Jer 10:14
Jer. 13:26Ida 1:8; Isk 16:37; 23:29
Jer. 13:27Jer 2:20; Isk 16:15
Jer. 13:27Ais 65:7; Isk 6:13
Jer. 13:27Isk 24:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 13:1-27

Jeremáyà

13 Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Lọ ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀,* kí o sì dè é mọ́ ìbàdí rẹ, àmọ́ má ṣe tì í bọ omi.” 2 Nítorí náà, mo ra àmùrè náà bí Jèhófà ṣe sọ, mo sì dè é mọ́ ìbàdí mi. 3 Jèhófà sì tún bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé: 4 “Mú àmùrè tí o rà, tí o dè mọ́ ìbàdí rẹ, sì dìde, lọ sí odò Yúfírétì, kí o sì fi pa mọ́ sínú pàlàpálá àpáta.” 5 Nítorí náà, mo lọ, mo sì fi pa mọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún mi.

6 Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: “Dìde, lọ sí odò Yúfírétì, kí o sì mú àmùrè tí mo pàṣẹ pé kí o fi pa mọ́ náà kúrò níbẹ̀.” 7 Torí náà, mo lọ sí odò Yúfírétì, mo walẹ̀, mo sì mú àmùrè náà ní ibi tí mo fi pa mọ́ sí, sì wò ó! àmùrè náà ti bà jẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.

8 Nígbà náà, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀: 9 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ọ̀nà kan náà ni màá gbà ba ògo Júdà àti ògo ńlá Jerúsálẹ́mù jẹ́.+ 10 Àwọn èèyàn búburú yìí, tí kò ṣègbọràn sí ohùn mi,+ àwọn alágídí tó ń ṣe ohun tí ọkàn wọn ń sọ,+ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, tí wọ́n ń sìn wọ́n, tí wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn, àwọn náà yóò dà bí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun mọ́.’ 11 ‘Nítorí bí àmùrè ṣe ń lẹ̀ mọ́ ìbàdí èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà lẹ̀ mọ́ mi,’ ni Jèhófà wí, ‘kí wọ́n lè di èèyàn kan,+ orúkọ kan,+ ìyìn kan àti ohun ẹlẹ́wà fún mi. Ṣùgbọ́n wọn kò ṣègbọràn.’+

12 “Kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ pọn wáìnì kún inú gbogbo ìṣà ńlá.”’ Wọ́n á fèsì pé, ‘Ṣé a ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí a pọn wáìnì kún inú gbogbo ìṣà ńlá ni?’ 13 Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, màá rọ gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà yó,+ látorí àwọn ọba tó ń jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì dórí àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 14 Màá gbé wọn kọ lu ara wọn, àwọn bàbá àti àwọn ọmọ,” ni Jèhófà wí.+ “Mi ò ní yọ́nú sí wọn tàbí kí n bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní ṣàánú wọn. Kò sì sí ohun tó máa dá mi dúró láti pa wọ́n run.”’+

15 Ẹ gbọ́, ẹ sì fetí sílẹ̀.

Ẹ má ṣe gbéra ga, torí Jèhófà ti sọ̀rọ̀.

16 Ẹ fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run yín

Kí ó tó mú òkùnkùn wá

Kí ẹ sì tó fẹsẹ̀ kọ lórí àwọn òkè nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú.

Ẹ ó máa retí ìmọ́lẹ̀,

Àmọ́ òkùnkùn biribiri ló máa mú wá;

Yóò sọ ọ́ di ìṣúdùdù tó kàmàmà.+

17 Bí ẹ kò bá sì fetí sílẹ̀,

Màá* sunkún ní ìkọ̀kọ̀ torí ìgbéraga yín.

Màá da omijé púpọ̀, omi á sì dà lójú mi,+

Nítorí wọ́n ti kó agbo Jèhófà+ lọ sí oko ẹrú.

18 Sọ fún ọba àti ìyá ọba*+ pé, ‘Ẹ jókòó sí ibi tó rẹlẹ̀,

Nítorí adé ẹwà yín máa já bọ́ lórí yín.’

19 A ti ti àwọn ìlú gúúsù pa,* kò sì sẹ́ni tó máa ṣí wọn.

A ti kó gbogbo èèyàn Júdà lọ sí ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ti kó lọ pátápátá.+

20 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tó ń bọ̀ láti àríwá.+

Ibo ni agbo ẹran tí wọ́n fún ọ wà, àwọn àgùntàn rẹ tó lẹ́wà?+

21 Kí lo máa sọ nígbà tí ìyà rẹ bá dé

Látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tí o ní láti ìbẹ̀rẹ̀?+

Ǹjẹ́ irú ìrora tí obìnrin máa ń ní nígbà ìbímọ kò ní bá ọ?+

22 Nígbà tí o bá sì sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?’+

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó pọ̀ ni wọ́n ṣe ká aṣọ rẹ sókè +

Tí wọ́n sì fìyà jẹ gìgísẹ̀ rẹ.

23 Ǹjẹ́ ọmọ Kúṣì* lè yí àwọ̀ rẹ̀ pa dà, àbí ṣé àmọ̀tẹ́kùn lè yí àmì ara rẹ̀ pa dà?+

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ẹ lè ṣe rere,

Ẹ̀yin tí wọ́n ti kọ́ láti máa ṣe búburú.

24 Nítorí náà, màá fọ́n wọn ká bíi pòròpórò tí ẹ̀fúùfù láti aṣálẹ̀ ń gbá lọ.+

25 Ìpín rẹ nìyí, ìpín tí mo wọ̀n fún ọ,” ni Jèhófà wí,

“Nítorí pé o ti gbàgbé mi,+ o sì ń gba irọ́ gbọ́.+

26 Nítorí náà, màá ká aṣọ rẹ sókè bò ọ́ lójú,

Wọ́n á sì rí ìtìjú rẹ,+

27 Ìwà àgbèrè rẹ + àti bí o ṣe ń yán bí ẹṣin tó fẹ́ gùn,

Ìṣekúṣe rẹ tó ń ríni lára.*

Lórí àwọn òkè àti ní pápá,

Mo ti rí ìwà ẹ̀gbin rẹ.+

O gbé, ìwọ Jerúsálẹ́mù!

Títí dìgbà wo lo fi máa jẹ́ aláìmọ́?”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́