ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì di ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì (1-5)

      • Wọ́n gba Jerúsálẹ́mù (6-16)

        • Síónì, Ìlú Dáfídì (7)

      • Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì (17-25)

2 Sámúẹ́lì 5:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Egungun àti ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 2:1, 11; 1Kr 12:23
  • +1Kr 11:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2005, ojú ìwé 17

2 Sámúẹ́lì 5:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìwọ lò ń mú Ísírẹ́lì jáde tí o sì ń mú un wọlé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:13; 25:28
  • +Jẹ 49:10; 1Sa 16:1; 25:30; 2Sa 6:21; 7:8; 1Kr 28:4; Sm 78:71

2 Sámúẹ́lì 5:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:17
  • +1Sa 16:13; 2Sa 2:4; Iṣe 13:22

2 Sámúẹ́lì 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:26, 27

2 Sámúẹ́lì 5:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 14:18

2 Sámúẹ́lì 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:23; Joṣ 15:63; Ond 1:8, 21
  • +1Kr 11:4-6

2 Sámúẹ́lì 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:10; Ne 12:37

2 Sámúẹ́lì 5:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn Dáfídì.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/1997, ojú ìwé 9-10

2 Sámúẹ́lì 5:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ó.”

  • *

    Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 9:15, 24; 11:27; 2Kr 32:5
  • +1Kr 11:7-9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1709

2 Sámúẹ́lì 5:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:13; 2Sa 3:1
  • +1Sa 17:45

2 Sámúẹ́lì 5:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:1, 8
  • +2Kr 2:3
  • +2Sa 7:2; 1Kr 14:1, 2

2 Sámúẹ́lì 5:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:16; Sm 41:11; 89:21
  • +Sm 89:27
  • +1Ọb 10:9; 2Kr 2:11

2 Sámúẹ́lì 5:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:16
  • +1Kr 3:5-9; 14:3-7

2 Sámúẹ́lì 5:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 3:23, 31
  • +2Sa 12:24

2 Sámúẹ́lì 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:3
  • +Sm 2:2
  • +1Sa 22:1, 5; 24:22; 2Sa 23:14; 1Kr 14:8

2 Sámúẹ́lì 5:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:8, 12; 1Kr 11:15; 14:9

2 Sámúẹ́lì 5:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 27:21
  • +1Kr 14:10-12

2 Sámúẹ́lì 5:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọ̀gá Àwọn Tó Ń Ya Luni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 22:41
  • +Ais 28:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1991, ojú ìwé 20-21

2 Sámúẹ́lì 5:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:8, 12; 1Kr 11:15; 14:13-17

2 Sámúẹ́lì 5:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1991, ojú ìwé 21

2 Sámúẹ́lì 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:7
  • +Joṣ 18:21, 24
  • +Joṣ 16:10

Àwọn míì

2 Sám. 5:12Sa 2:1, 11; 1Kr 12:23
2 Sám. 5:11Kr 11:1-3
2 Sám. 5:21Sa 18:13; 25:28
2 Sám. 5:2Jẹ 49:10; 1Sa 16:1; 25:30; 2Sa 6:21; 7:8; 1Kr 28:4; Sm 78:71
2 Sám. 5:32Ọb 11:17
2 Sám. 5:31Sa 16:13; 2Sa 2:4; Iṣe 13:22
2 Sám. 5:41Kr 29:26, 27
2 Sám. 5:5Jẹ 14:18
2 Sám. 5:6Ẹk 23:23; Joṣ 15:63; Ond 1:8, 21
2 Sám. 5:61Kr 11:4-6
2 Sám. 5:71Ọb 2:10; Ne 12:37
2 Sám. 5:91Ọb 9:15, 24; 11:27; 2Kr 32:5
2 Sám. 5:91Kr 11:7-9
2 Sám. 5:101Sa 16:13; 2Sa 3:1
2 Sám. 5:101Sa 17:45
2 Sám. 5:111Ọb 5:1, 8
2 Sám. 5:112Kr 2:3
2 Sám. 5:112Sa 7:2; 1Kr 14:1, 2
2 Sám. 5:122Sa 7:16; Sm 41:11; 89:21
2 Sám. 5:12Sm 89:27
2 Sám. 5:121Ọb 10:9; 2Kr 2:11
2 Sám. 5:132Sa 15:16
2 Sám. 5:131Kr 3:5-9; 14:3-7
2 Sám. 5:14Lk 3:23, 31
2 Sám. 5:142Sa 12:24
2 Sám. 5:172Sa 5:3
2 Sám. 5:17Sm 2:2
2 Sám. 5:171Sa 22:1, 5; 24:22; 2Sa 23:14; 1Kr 14:8
2 Sám. 5:18Joṣ 15:8, 12; 1Kr 11:15; 14:9
2 Sám. 5:19Nọ 27:21
2 Sám. 5:191Kr 14:10-12
2 Sám. 5:202Sa 22:41
2 Sám. 5:20Ais 28:21
2 Sám. 5:22Joṣ 15:8, 12; 1Kr 11:15; 14:13-17
2 Sám. 5:25Le 26:7
2 Sám. 5:25Joṣ 18:21, 24
2 Sám. 5:25Joṣ 16:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 5:1-25

Sámúẹ́lì Kejì

5 Nígbà tó yá, gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì,+ wọ́n sì sọ pé: “Wò ó! Ẹ̀jẹ̀* kan náà ni wá.+ 2 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba wa, ìwọ lò ń kó Ísírẹ́lì jáde ogun.*+ Jèhófà sì sọ fún ọ pé: ‘Ìwọ ni wàá máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, wàá sì di aṣáájú Ísírẹ́lì.’”+ 3 Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Ọba Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú+ ní Hébúrónì níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.+

4 Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Dáfídì nígbà tí ó di ọba, ogójì (40) ọdún+ ló sì fi ṣàkóso. 5 Ọdún méje àti oṣù mẹ́fà ló fi jọba lórí Júdà ní Hébúrónì, ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ọba àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jáde lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ gbéjà ko àwọn ará Jébúsì+ tó ń gbé ilẹ̀ náà. Wọ́n pẹ̀gàn Dáfídì pé: “O ò ní wọ ibí yìí! Kódà àwọn afọ́jú àti àwọn arọ ló máa lé ọ dà nù.” Èrò wọn ni pé, ‘Dáfídì ò ní wọ ibí yìí.’+ 7 Síbẹ̀, Dáfídì gba ibi ààbò Síónì, èyí tó wá di Ìlú Dáfídì.+ 8 Nítorí náà, Dáfídì sọ lọ́jọ́ yẹn pé: “Kí àwọn tó máa lọ gbéjà ko àwọn ará Jébúsì gba ibi ihò omi wọlé láti pa ‘àwọn arọ àti àwọn afọ́jú,’ tí Dáfídì* kórìíra!” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ pé: “Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kò ní wọlé.” 9 Nígbà náà, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibi ààbò, wọ́n* sì pe ibẹ̀ ní Ìlú Dáfídì; Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé yí ká orí Òkìtì*+ àti láwọn ibòmíì nínú ìlú.+ 10 Bí agbára Dáfídì ṣe ń pọ̀ sí i+ nìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+

11 Hírámù+ ọba Tírè rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó kó igi kédárì  + ránṣẹ́, ó tún rán àwọn oníṣẹ́ igi àti àwọn oníṣẹ́ òkúta tó ń mọ ògiri sí Dáfídì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé* fún Dáfídì.+ 12 Dáfídì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì+ àti pé ó ti gbé ìjọba òun ga+ nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀ Ísírẹ́lì.+

13 Dáfídì fẹ́ àwọn wáhàrì*+ àti àwọn ìyàwó míì ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí ó dé láti Hébúrónì, wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i fún Dáfídì.+ 14 Orúkọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún un ní Jerúsálẹ́mù nìyí: Ṣámúà, Ṣóbábù, Nátánì,+ Sólómọ́nì,+ 15 Íbárì, Élíṣúà, Néfégì, Jáfíà, 16 Élíṣámà, Élíádà àti Élífélétì.

17 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ pé wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ gbogbo àwọn Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì.+ Bí Dáfídì ṣe gbọ́ báyìí, ó lọ sí ibi ààbò.+ 18 Ìgbà náà ni àwọn Filísínì wọlé wá, wọ́n sì dúró káàkiri ní Àfonífojì* Réfáímù.+ 19 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lọ gbéjà ko àwọn Filísínì? Ṣé wàá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Ni Jèhófà bá sọ fún Dáfídì pé: “Lọ, torí ó dájú pé màá fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.”+ 20 Torí náà, Dáfídì wá sí Baali-pérásímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀. Ni ó bá sọ pé: “Jèhófà ti ya lu àwọn ọ̀tá mi+ níwájú mi, bí ìgbà tí omi bá ya lu nǹkan.” Ìdí nìyẹn tí ó fi pe ibẹ̀ ní Baali-pérásímù.*+ 21 Àwọn Filísínì fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn lọ.

22 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá, wọ́n sì dúró káàkiri Àfonífojì* Réfáímù.+ 23 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, àmọ́ Ó sọ pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà. 24 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o gbé ìgbésẹ̀ ní kíá, nítorí Jèhófà yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.” 25 Torí náà, Dáfídì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́, ó sì pa àwọn Filísínì+ láti Gébà+ títí dé Gésérì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́