Jóòbù
23 Jóòbù fèsì pé:
2 “Àní lónìí, màá fi orí kunkun ṣàròyé;*+
Okun mi ti tán torí ẹ̀dùn ọkàn mi.
3 Ká ní mo mọ ibi tí mo ti lè rí Ọlọ́run ni!+
Ǹ bá lọ sí ibùgbé rẹ̀.+
4 Màá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,
Màá sì fi gbogbo ẹnu mi gbèjà ara mi;
5 Màá fetí sí ìdáhùn tó bá fún mi,
Màá sì fọkàn sí ohun tó bá sọ fún mi.
6 Ṣé ó máa fi agbára ńlá rẹ̀ bá mi jà?
Rárá, ó dájú pé ó máa gbọ́ mi.+
7 Ibẹ̀ ni òun àti olóòótọ́ ti máa lè yanjú ọ̀rọ̀,
Adájọ́ mi sì máa dá mi láre títí láé.
8 Àmọ́ tí mo bá lọ sí ìlà oòrùn, kò sí níbẹ̀;
Mo pa dà, mi ò sì rí i.
9 Nígbà tó ń ṣiṣẹ́ lápá òsì, mi ò lè rí i;
Ó wá yí sí apá ọ̀tún, síbẹ̀ mi ò rí i.
10 Àmọ́, ó mọ ọ̀nà tí mo gbà.+
Lẹ́yìn tó bá dán mi wò, màá wá dà bíi wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́.+
11 Ẹsẹ̀ mi tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí;
Mò ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ ṣáá, mi ò sì yà kúrò níbẹ̀.+
12 Mi ò pa àṣẹ ẹnu rẹ̀ tì.
Mò ń pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́+ ju ohun tó béèrè lọ́wọ́ mi* pàápàá.
13 Tó bá ti pinnu, ta ló lè dá a dúró?+
Tó* bá fẹ́ ṣe ohun kan, ó máa ṣe é.+
14 Torí ó máa ṣe gbogbo ohun tó ti pinnu* nípa mi,
Irú nǹkan wọ̀nyí sì pọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.
15 Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi ò fi balẹ̀ nítorí rẹ̀;
Tí mo bá ronú nípa rẹ̀, ẹ̀rù á túbọ̀ bà mí.
16 Ọlọ́run ti sọ mí di ojo,
Olódùmarè sì ti mú kí ẹ̀rù bà mí.
17 Àmọ́ òkùnkùn ò tíì pa mí lẹ́nu mọ́,
Ìṣúdùdù tó bò mí lójú kò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀.