ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 138
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

      • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ga, ó ń ṣìkẹ́ èèyàn

        • ‘O dáhùn àdúrà mi’ (3)

        • ‘Bí mo tiẹ̀ wà nínú ewu, o gbà mí sílẹ̀’ (7)

Sáàmù 138:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Láìfi ti àwọn ọlọ́run mìíràn pè, màá kọrin sí ọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 9:1

Sáàmù 138:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibi mímọ́ rẹ.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “o ti gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ ìwọ fúnra rẹ lọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 3:3; 1Kr 16:1; Sm 28:2
  • +Jo 17:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2006, ojú ìwé 19

    9/1/2006, ojú ìwé 16

Sáàmù 138:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 18:6
  • +Sm 29:11; Ais 12:2; 41:10

Sáàmù 138:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 102:15; Ais 60:3

Sáàmù 138:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:10, 11

Sáàmù 138:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 2:8; Sm 113:6-8; Ais 57:15
  • +Jem 4:6; 1Pe 5:5

Sáàmù 138:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 71:20

Sáàmù 138:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 103:17
  • +Job 14:15; Sm 71:18

Àwọn míì

Sm 138:1Sm 9:1
Sm 138:21Sa 3:3; 1Kr 16:1; Sm 28:2
Sm 138:2Jo 17:6
Sm 138:3Sm 18:6
Sm 138:3Sm 29:11; Ais 12:2; 41:10
Sm 138:4Sm 102:15; Ais 60:3
Sm 138:51Ọb 8:10, 11
Sm 138:61Sa 2:8; Sm 113:6-8; Ais 57:15
Sm 138:6Jem 4:6; 1Pe 5:5
Sm 138:7Sm 71:20
Sm 138:8Sm 103:17
Sm 138:8Job 14:15; Sm 71:18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù 138:1-8

Sáàmù

Ti Dáfídì.

138 Màá fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́.+

Níṣojú àwọn ọlọ́run mìíràn,

Màá kọ orin ìyìn.*

2 Màá forí balẹ̀ ní ìdojúkọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ,*+

Màá sì yin orúkọ rẹ,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ.

Torí o ti gbé ọ̀rọ̀ rẹ àti orúkọ rẹ ga ju gbogbo nǹkan míì lọ.*

3 Ní ọjọ́ tí mo pè, o dá mi lóhùn;+

O mú kí n* nígboyà, o sì mú kí n lágbára.+

4 Gbogbo ọba ayé yóò yìn ọ́, Jèhófà,+

Nítorí wọ́n á ti gbọ́ àwọn ìlérí tí o ṣe.

5 Wọ́n á máa fi àwọn ọ̀nà Jèhófà kọrin,

Nítorí pé ògo Jèhófà pọ̀.+

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ga, ó ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀,+

Àmọ́, ó jìnnà sí àwọn agbéraga.+

7 Bí mo bá tiẹ̀ ń rìn nínú ewu, wàá dá ẹ̀mí mi sí.+

O na ọwọ́ rẹ sórí àwọn ọ̀tá mi tó ń bínú;

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò gbà mí là.

8 Jèhófà yóò mú gbogbo ohun tó ní lọ́kàn fún mi ṣẹ.

Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí láé;+

Má ṣe pa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́