ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Àsọtẹ́lẹ̀ tí Áhíjà sọ sórí Jèróbóámù (1-20)

      • Rèhóbóámù ṣàkóso lórí Júdà (21-31)

        • Ṣíṣákì ya wọ Jerúsálẹ́mù (25, 26)

1 Àwọn Ọba 14:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:30, 31

1 Àwọn Ọba 14:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.

1 Àwọn Ọba 14:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:1; 1Sa 4:3

1 Àwọn Ọba 14:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Báyìí-báyìí ni kí o sọ fún un.”

1 Àwọn Ọba 14:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:30, 31; 12:20

1 Àwọn Ọba 14:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:16
  • +1Ọb 15:5; Iṣe 13:22

1 Àwọn Ọba 14:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 27:15; 2Kr 11:15
  • +Ne 9:26; Sm 50:17

1 Àwọn Ọba 14:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ké gbogbo ọkùnrin ilé Jèróbóámù kúrò.”

  • *

    Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:25-29

1 Àwọn Ọba 14:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 244

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2010, ojú ìwé 29

    7/1/2005, ojú ìwé 31

    4/1/1995, ojú ìwé 12

1 Àwọn Ọba 14:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ké.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:25-29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 133-134

1 Àwọn Ọba 14:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, koríko etí omi.

  • *

    Ìyẹn, odò Yúfírétì.

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:7-9; 29:28; Joṣ 23:15; 2Ọb 17:6
  • +Di 28:64; 2Ọb 15:29; 18:11
  • +Di 12:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 133-134

1 Àwọn Ọba 14:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:28-30; 13:33, 34

1 Àwọn Ọba 14:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 12:15; 13:3

1 Àwọn Ọba 14:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Àwọn ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 13:20
  • +1Ọb 15:25

1 Àwọn Ọba 14:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 78:68; 132:13
  • +Ẹk 20:24; Di 12:5, 6; 1Ọb 8:16, 17
  • +1Ọb 11:1; 2Kr 12:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2011, ojú ìwé 10

1 Àwọn Ọba 14:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:7; 2Kr 12:1
  • +Ais 65:2

1 Àwọn Ọba 14:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:1
  • +Ais 65:7
  • +Di 12:2, 3; Ais 57:5; Jer 2:20; Ho 4:13

1 Àwọn Ọba 14:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:17, 18; 1Ọb 15:11, 12; 22:46; 2Ọb 23:7; Ho 4:14

1 Àwọn Ọba 14:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:40
  • +2Kr 12:2-4

1 Àwọn Ọba 14:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:51; 15:18; 2Ọb 18:14, 15; 24:12, 13
  • +1Ọb 10:16, 17; 2Kr 12:9-11

1 Àwọn Ọba 14:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn sárésáré.”

1 Àwọn Ọba 14:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 27:24; 2Kr 12:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2009, ojú ìwé 32

1 Àwọn Ọba 14:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:6

1 Àwọn Ọba 14:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tí wọ́n tún ń pè ní Ábíjà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:43
  • +1Ọb 11:1; 2Kr 12:13
  • +1Kr 3:10; Mt 1:7

Àwọn míì

1 Ọba 14:21Ọb 11:30, 31
1 Ọba 14:4Joṣ 18:1; 1Sa 4:3
1 Ọba 14:71Ọb 11:30, 31; 12:20
1 Ọba 14:81Ọb 12:16
1 Ọba 14:81Ọb 15:5; Iṣe 13:22
1 Ọba 14:9Di 27:15; 2Kr 11:15
1 Ọba 14:9Ne 9:26; Sm 50:17
1 Ọba 14:101Ọb 15:25-29
1 Ọba 14:141Ọb 15:25-29
1 Ọba 14:15Di 8:7-9; 29:28; Joṣ 23:15; 2Ọb 17:6
1 Ọba 14:15Di 28:64; 2Ọb 15:29; 18:11
1 Ọba 14:15Di 12:3
1 Ọba 14:161Ọb 12:28-30; 13:33, 34
1 Ọba 14:192Kr 12:15; 13:3
1 Ọba 14:202Kr 13:20
1 Ọba 14:201Ọb 15:25
1 Ọba 14:21Sm 78:68; 132:13
1 Ọba 14:21Ẹk 20:24; Di 12:5, 6; 1Ọb 8:16, 17
1 Ọba 14:211Ọb 11:1; 2Kr 12:13
1 Ọba 14:221Ọb 11:7; 2Kr 12:1
1 Ọba 14:22Ais 65:2
1 Ọba 14:23Le 26:1
1 Ọba 14:23Ais 65:7
1 Ọba 14:23Di 12:2, 3; Ais 57:5; Jer 2:20; Ho 4:13
1 Ọba 14:24Di 23:17, 18; 1Ọb 15:11, 12; 22:46; 2Ọb 23:7; Ho 4:14
1 Ọba 14:251Ọb 11:40
1 Ọba 14:252Kr 12:2-4
1 Ọba 14:261Ọb 7:51; 15:18; 2Ọb 18:14, 15; 24:12, 13
1 Ọba 14:261Ọb 10:16, 17; 2Kr 12:9-11
1 Ọba 14:291Kr 27:24; 2Kr 12:15
1 Ọba 14:301Ọb 15:6
1 Ọba 14:311Ọb 11:43
1 Ọba 14:311Ọb 11:1; 2Kr 12:13
1 Ọba 14:311Kr 3:10; Mt 1:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 14:1-31

Àwọn Ọba Kìíní

14 Ní àkókò yẹn, Ábíjà ọmọkùnrin Jèróbóámù ń ṣàìsàn. 2 Torí náà, Jèróbóámù sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, dìde, yí ìmúra rẹ pa dà kí wọ́n má bàa mọ̀ pé ìyàwó Jèróbóámù ni ọ́, kí o sì lọ sí Ṣílò. Wò ó! Wòlíì Áhíjà wà níbẹ̀. Òun ni ó sọ nípa mi pé màá di ọba lórí àwọn èèyàn yìí.+ 3 Mú búrẹ́dì mẹ́wàá dání àti kéèkì tí a bu nǹkan wọ́n àti ṣágo* oyin, kí o sì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó máa sọ ohun tí á ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”

4 Ìyàwó Jèróbóámù ṣe ohun tí ọkọ rẹ̀ sọ. Ó dìde, ó lọ sí Ṣílò,+ ó sì wá sí ilé Áhíjà. Ojú Áhíjà là sílẹ̀, àmọ́ kò ríran mọ́ nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.

5 Àmọ́ Jèhófà ti sọ fún Áhíjà pé: “Wò ó, ìyàwó Jèróbóámù ń bọ̀ wá wádìí nípa ọmọ rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ, torí pé ọmọ náà ń ṣàìsàn. Màá sọ fún ọ, ohun tí o máa sọ fún un.* Tí ó bá dé, kò ní jẹ́ kí o dá òun mọ̀.”

6 Bí Áhíjà ṣe gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó ń bọ̀ lẹ́nu ọ̀nà, ó sọ pé: “Wọlé, ìyàwó Jèróbóámù. Kí ló dé tí o fi ṣe bíi pé ẹlòmíràn ni ọ́? Iṣẹ́ tó lágbára kan wà tí Ọlọ́run ní kí n jẹ́ fún ọ. 7 Lọ sọ fún Jèróbóámù pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Mo gbé ọ dìde láti àárín àwọn èèyàn rẹ, kí n lè sọ ọ́ di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 8 Lẹ́yìn náà, mo fa ìjọba ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fún ọ.+ Àmọ́, o kò ṣe bí ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ẹni tí ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ó sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, tí ó ṣe kìkì ohun tí ó tọ́ lójú mi.+ 9 Ohun tí o ṣe burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ, o ṣe ọlọ́run míì fún ara rẹ àti àwọn ère onírin* láti mú mi bínú,+ o sì kẹ̀yìn sí mi.+ 10 Nítorí ohun tí o ṣe yìí, màá mú àjálù bá ilé Jèróbóámù, màá pa gbogbo ọkùnrin* ilé Jèróbóámù rẹ́,* títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì, màá sì gbá ilé Jèróbóámù+ dà nù, bí ìgbà tí èèyàn gbá ìgbẹ́ ẹran kúrò láìku nǹkan kan! 11 Èèyàn Jèróbóámù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni ajá yóò jẹ; èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ, nítorí Jèhófà ti sọ ọ́.”’

12 “Ní báyìí, gbéra; máa lọ sí ilé rẹ. Bí o bá ṣe wọ ìlú náà, ọmọ náà máa kú. 13 Gbogbo Ísírẹ́lì á ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n á sì sin ín, torí òun nìkan ni wọ́n máa sin sínú sàréè lára àwọn ará ilé Jèróbóámù, nítorí pé òun nìkan ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì rí ohun rere nínú rẹ̀ ní ilé Jèróbóámù. 14 Jèhófà yóò gbé ọba kan dìde fún ara rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, tí ó máa mú* ilé Jèróbóámù+ kúrò láti ọjọ́ náà lọ, kódà ó lè jẹ́ nísinsìnyí. 15 Jèhófà yóò kọ lu Ísírẹ́lì, á sì dà bí esùsú* tó ń mì lòólòó lójú omi, yóò fa Ísírẹ́lì tu kúrò lórí ilẹ̀ dáradára yìí tó fún àwọn baba ńlá wọn,+ yóò sì tú wọn ká kọjá Odò,*+ nítorí wọ́n ṣe àwọn òpó òrìṣà,*+ tí wọ́n sì ń mú Jèhófà bínú. 16 Yóò pa Ísírẹ́lì tì nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá àti èyí tó mú kí Ísírẹ́lì dá.”+

17 Ni ìyàwó Jèróbóámù bá dìde, ó bọ́ sọ́nà, ó sì dé Tírísà. Bí ó ṣe ń dé ibi àbáwọlé, ọmọ náà kú. 18 Torí náà, wọ́n sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gba ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì Áhíjà sọ.

19 Ní ti ìyókù ìtàn Jèróbóámù, bí ó ṣe jagun+ àti bí ó ṣe ṣàkóso, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì. 20 Gbogbo ọdún* tí Jèróbóámù fi jọba jẹ́ ọdún méjìlélógún (22), lẹ́yìn náà, ó sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Nádábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

21 Ní àkókò yẹn, Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ti di ọba ní Júdà. Ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Rèhóbóámù nígbà tó di ọba, ó sì fi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Jèhófà yàn+ nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ sí.+ Orúkọ ìyá Rèhóbóámù ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. 22 Júdà ń ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ wọ́n fi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá mú un bínú ju bí àwọn baba ńlá wọn ṣe mú un bínú lọ.+ 23 Àwọn náà ń kọ́ ibi gíga àti àwọn ọwọ̀n òrìṣà pẹ̀lú àwọn òpó òrìṣà*+ fún ara wọn sórí gbogbo òkè+ àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+ 24 Àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì tún wà ní ilẹ̀ náà.+ Ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ni àwọn náà ń ṣe.

25 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba.+ Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan gbogbo apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 27 Nítorí náà, Ọba Rèhóbóámù ṣe àwọn apata bàbà láti fi rọ́pò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí ẹ̀ṣọ́* tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba. 28 Nígbàkigbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé àwọn apata náà, lẹ́yìn náà, wọ́n á dá wọn pa dà sí yàrá ẹ̀ṣọ́.

29 Ní ti ìyókù ìtàn Rèhóbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ 30 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+ 31 Níkẹyìn, Rèhóbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. Ábíjámù*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́