Jóòbù
20 Sófárì+ ọmọ Náámà fèsì pé:
2 “Ìdí nìyí tí àwọn èrò tó ń dà mí láàmú fi mú kí n fèsì,
Nítorí ìdààmú tó bá mi.
3 Mo ti gbọ́ ìbáwí tí o fi bú mi;
Òye mi* sì mú kí n fèsì.
4 Ó dájú pé o gbọ́dọ̀ ti mọ èyí tipẹ́,
Torí ó ti wà bẹ́ẹ̀ látìgbà tí èèyàn* ti wà ní ayé,+
5 Pé igbe ayọ̀ ẹni burúkú kì í pẹ́
Àti pé ìgbà díẹ̀ ni inú ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* fi máa ń dùn.+
6 Bí títóbi rẹ̀ tiẹ̀ ga dé ọ̀run,
Tí orí rẹ̀ sì kan sánmà,
7 Ó máa ṣègbé títí láé bí ìgbẹ́ òun fúnra rẹ̀;
Àwọn tó ti ń rí i máa sọ pé, ‘Ibo ló wà?’
8 Ó máa fò lọ bí àlá, wọn ò sì ní rí i;
A máa lé e lọ, bí ìran òru.
9 Ojú tó fìgbà kan rí i kò ní rí i mọ́,
Àyè rẹ̀ ò sì ní rí i mọ́.+
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá ojúure lọ́dọ̀ aláìní,
Ọwọ́ ara rẹ̀ sì máa dá ọrọ̀ rẹ̀ pa dà.+
11 Okun ìgbà èwe kún inú àwọn egungun rẹ̀,
Àmọ́, ó* máa bá a dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀ lásán.
12 Tí ohun tó burú bá dùn lẹ́nu rẹ̀,
Tó bá fi pa mọ́ sábẹ́ ahọ́n rẹ̀,
13 Tó bá ń gbádùn rẹ̀, tí kò sì gbé e mì,
Àmọ́ tó ṣì fi í sẹ́nu,
14 Oúnjẹ rẹ̀ máa kan nínú rẹ̀;
Ó máa dà bí oró* ṣèbé nínú rẹ̀.
15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, àmọ́ ó máa pọ̀ ọ́;
Ọlọ́run máa kó o jáde nínú ikùn rẹ̀.
16 Ó máa fa oró ṣèbé mu;
Eyín* paramọ́lẹ̀ máa pa á.
17 Kò ní rí odò tó ń ṣàn láé,
Ọ̀gbàrá oyin àti bọ́tà.
19 Torí ó ti tẹ aláìní rẹ́, ó sì pa á tì;
Ó ti gba ilé tí kò kọ́.
20 Àmọ́ kò ní ní àlàáfíà rárá nínú ara rẹ̀;
Ọrọ̀ rẹ̀ kò ní gbà á sílẹ̀.
21 Ohunkóhun ò ní ṣẹ́ kù fún un láti jẹ;
Ìdí nìyẹn tí aásìkí rẹ̀ kò fi ní tọ́jọ́.
22 Tí ọrọ̀ rẹ̀ bá pọ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àníyàn máa gbà á lọ́kàn;
Gbogbo agbára ni àjálù máa fi kọ lù ú.
24 Tó bá ń sá fún àwọn ohun ìjà irin,
Àwọn ọfà tí wọ́n fi ọrun bàbà ta máa gún un.
26 Òkùnkùn biribiri ń dúró de àwọn ìṣúra rẹ̀;
Iná tí ẹnì kankan ò fẹ́ atẹ́gùn sí máa jẹ ẹ́ run;
Àjálù máa bá ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù nínú àgọ́ rẹ̀.
27 Ọ̀run máa tú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ síta;
Ayé máa dìde sí i.
28 Àkúnya omi máa gbé ilé rẹ̀ lọ;
Ọ̀gbàrá máa pọ̀ gan-an ní ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.*
29 Èyí ni ìpín ẹni burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,
Ogún tí Ọlọ́run ti pín fún un.”