Jóòbù
8 Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì+ wá fèsì pé:
2 “Ìgbà wo lo ò ní sọ̀rọ̀ báyìí mọ́?+
Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dà bí ìjì tó le!
3 Ṣé Ọlọ́run máa yí ìdájọ́ po ni,
Àbí Olódùmarè máa yí òdodo po?
4 Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ ti ṣẹ̀ ẹ́,
Ó jẹ́ kí wọ́n jìyà ìwà ọ̀tẹ̀ wọn;*
5 Àmọ́ tí o bá lè yíjú sí Ọlọ́run,+
Kí o sì bẹ Olódùmarè pé kó ṣojúure sí ọ,
6 Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lo mọ́, tí o sì jẹ́ olódodo,+
Ó máa fetí sí ọ,*
Ó sì máa dá ọ pa dà sí ibi tó tọ́ sí ọ.
7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ rẹ kéré,
Ọjọ́ iwájú rẹ máa dára gan-an.+
8 Jọ̀ọ́, béèrè lọ́wọ́ ìran àtijọ́,
Kí o sì fiyè sí àwọn ohun tí àwọn bàbá wọn rí.+
9 Torí ọmọ àná lásán ni wá, a ò sì mọ nǹkan kan,
Torí pé òjìji ni àwọn ọjọ́ ayé wa.
10 Ṣé wọn ò ní kọ́ ọ ni,
Kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n mọ̀ fún ọ?*
11 Ṣé òrépèté lè dàgbà níbi tí kò sí irà?
Ṣé esùsú* lè dàgbà láìsí omi?
12 Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rú yọ, tí wọn ò tíì já a,
Ó máa gbẹ dà nù ṣáájú gbogbo ewéko yòókù.
13 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó gbàgbé Ọlọ́run nìyẹn,*
Torí ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* máa ṣègbé,
14 Ẹni tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ já sí asán,
Tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ ò sì lágbára, àfi bí òwú* aláǹtakùn.
15 Ó máa fara ti ilé rẹ̀, àmọ́ kò ní lè dúró;
Ó máa fẹ́ dì í mú, àmọ́ kò ní wà pẹ́.
16 Ó dà bí ewéko tútù nínú oòrùn,
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gbalẹ̀ nínú ọgbà.+
17 Gbòǹgbò rẹ̀ lọ́ mọ́ra láàárín òkúta tí wọ́n kó jọ pelemọ;
Ó ń wá ilé láàárín àwọn òkúta.*
18 Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà á tu* kúrò níbi tó wà,
Ibẹ̀ máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì máa sọ fún un pé, ‘Mi ò rí ọ rí.’+
20 Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní kọ àwọn olóòótọ́* sílẹ̀;
Kò sì ní ti àwọn ẹni ibi lẹ́yìn,*
21 Torí ó ṣì máa fi ẹ̀rín kún ẹnu rẹ,
Ó sì máa mú kí ètè rẹ kígbe ayọ̀.
22 Ìtìjú máa bo àwọn tó kórìíra rẹ,
Àgọ́ àwọn ẹni burúkú ò sì ní sí mọ́.”