Ìsíkíẹ́lì
26 Ní ọdún kọkànlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, torí pé Tírè ti sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé,+ ‘Àháà! Wọ́n ti fọ́ ilẹ̀kùn àwọn èèyàn náà!+ Gbogbo nǹkan á di tèmi, màá sì wá di ọlọ́rọ̀ torí ó ti di ahoro báyìí’; 3 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Màá bá ọ jà, ìwọ Tírè, màá sì gbé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dìde sí ọ, bí òkun ṣe ń gbé ìgbì rẹ̀ dìde. 4 Wọ́n á run ògiri Tírè, wọ́n á wó àwọn ilé gogoro rẹ̀,+ màá ha iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ kúrò, màá sì sọ ọ́ di àpáta lásán tó ń dán. 5 Yóò di ibi tí wọ́n ń sá àwọ̀n sí láàárín òkun.’+
“‘Torí èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kó o ní ẹrù. 6 Idà ni yóò pa àwọn agbègbè* tó wà ní ìgbèríko rẹ̀ run, àwọn èèyàn á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
7 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì gbéjà ko Tírè láti àríwá;+ ọba àwọn ọba ni,+ pẹ̀lú àwọn ẹṣin,+ kẹ̀kẹ́ ogun,+ àwọn tó ń gẹṣin àti ọ̀pọ̀ ọmọ ogun.* 8 Yóò fi idà pa àwọn agbègbè tó wà ní ìgbèríko rẹ run, yóò mọ odi láti gbéjà kò ọ́, yóò mọ òkìtì láti dó tì ọ́, yóò sì fi apata ńlá bá ọ jà. 9 Yóò fi igi* tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri kọ lu ògiri rẹ, yóò sì fi àáké* wó àwọn ilé gogoro rẹ. 10 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ débi pé wọ́n á fi eruku bò ọ́, ìró àwọn tó ń gẹṣin, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ àti kẹ̀kẹ́ ogun yóò mú kí àwọn ògiri rẹ mì tìtì nígbà tó bá gba àwọn ẹnubodè rẹ wọlé, bí ìgbà táwọn èèyàn ń rọ́ wọ ìlú tí ògiri rẹ̀ ti wó. 11 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò fi pátákò wọn tẹ gbogbo ojú ọ̀nà rẹ mọ́lẹ̀;+ yóò fi idà pa àwọn èèyàn rẹ, àwọn òpó ńláńlá rẹ yóò sì wó lulẹ̀. 12 Wọ́n á kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ, wọ́n á kó àwọn ọjà rẹ bí ẹrù ogun,+ wọ́n á ya àwọn ògiri rẹ lulẹ̀, wọ́n á wó àwọn ilé rẹ tó rẹwà; wọ́n á wá da àwọn òkúta rẹ, àwọn iṣẹ́ tí o fi igi ṣe àti iyẹ̀pẹ̀ rẹ sínú omi.’
13 “‘Màá fòpin sí ariwo orin yín, wọn ò sì ní gbọ́ ìró àwọn háàpù rẹ mọ́.+ 14 Màá sọ ọ́ di àpáta lásán tó ń dán àti ibi tí wọ́n ti ń sá àwọ̀n.+ Wọn ò ní tún ọ kọ́ láé, torí èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún Tírè nìyí: ‘Tí ìró ìṣubú rẹ bá dún, tí àwọn tó ń kú lọ* ń kérora, tí wọ́n pa ọ̀pọ̀ láàárín rẹ, ǹjẹ́ àwọn erékùṣù ò ní mì jìgìjìgì?+ 16 Gbogbo àwọn olórí* òkun yóò sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n á bọ́ aṣọ* wọn, títí kan èyí tí wọ́n kó iṣẹ́ sí, jìnnìjìnnì á sì bò wọ́n.* Wọ́n á jókòó sílẹ̀, wọ́n á máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, wọ́n á sì máa wò ọ́ tìyanutìyanu.+ 17 Wọ́n á kọ orin arò*+ torí rẹ, wọ́n á sì sọ fún ọ pé:
“Wo bí o ti ṣègbé,+ ìwọ tí àwọn tó wá láti òkun ń gbé inú rẹ̀, ìwọ ìlú tí wọ́n ń yìn;
Ìwọ àti àwọn* tó ń gbé inú rẹ jẹ́ alágbára lórí òkun,+
Ẹ sì ń dẹ́rù ba gbogbo àwọn tó ń gbé ayé!
18 Àwọn erékùṣù yóò gbọ̀n rìrì ní ọjọ́ tí o bá ṣubú,
Ìdààmú yóò bá àwọn erékùṣù òkun ní ọjọ́ tí o bá lọ.”’+
19 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ahoro, bí àwọn ìlú tí ẹnikẹ́ni kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi ya lù ọ́, tí omi tó ń ru gùdù sì bò ọ́ mọ́lẹ̀,+ 20 màá mú ìwọ àti àwọn tó ń bá ọ lọ sínú kòtò* lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni àtijọ́; màá sì mú kí o máa gbé níbi tó rẹlẹ̀ jù lọ, bí àwọn ibi àtijọ́ tó ti di ahoro, pẹ̀lú àwọn tó ń lọ sínú kòtò,+ kí ẹnì kankan má bàa gbé inú rẹ. Màá sì wá ṣe ilẹ̀ alààyè lógo.*
21 “‘Màá mú kí jìnnìjìnnì bá ọ lójijì, ìwọ kò sì ní sí mọ́.+ Wọ́n á wá ọ àmọ́ wọn ò ní rí ọ mọ́ láé,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”