ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Ámónì (1-7)

      • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Móábù (8-11)

      • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Édómù (12-14)

      • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Filísíà (15-17)

Ìsíkíẹ́lì 25:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 19:36, 38
  • +Jer 49:1; Emọ 1:13; Sef 2:9

Ìsíkíẹ́lì 25:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àgọ́ olódi.”

Ìsíkíẹ́lì 25:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:26; Isk 21:20

Ìsíkíẹ́lì 25:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 2:15
  • +Sef 2:8

Ìsíkíẹ́lì 25:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:2; Emọ 1:14

Ìsíkíẹ́lì 25:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 15:1; Jer 48:1; Emọ 2:1
  • +Di 2:4

Ìsíkíẹ́lì 25:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”

  • *

    Tàbí “lọ́ṣọ̀ọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:37, 38; Joṣ 13:15, 19

Ìsíkíẹ́lì 25:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 25:4
  • +Isk 21:28, 32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 74

Ìsíkíẹ́lì 25:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 74

Ìsíkíẹ́lì 25:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 28:17; Sm 137:7; Ida 4:22; Emọ 1:11; Ọbd 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 74

Ìsíkíẹ́lì 25:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 1:4
  • +Jer 49:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2017, ojú ìwé 4

Ìsíkíẹ́lì 25:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 11:14; 63:1
  • +Na 1:2

Ìsíkíẹ́lì 25:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Bí àwọn Filísínì ṣe rẹró sínú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 28:18; Ais 9:11, 12; 14:29; Jer 47:1; Joẹ 3:4-6; Emọ 1:6

Ìsíkíẹ́lì 25:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:17, 20; Sef 2:4
  • +Sef 2:5
  • +Jer 47:4

Ìsíkíẹ́lì 25:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 81

Àwọn míì

Ìsík. 25:2Jẹ 19:36, 38
Ìsík. 25:2Jer 49:1; Emọ 1:13; Sef 2:9
Ìsík. 25:52Sa 12:26; Isk 21:20
Ìsík. 25:6Ida 2:15
Ìsík. 25:6Sef 2:8
Ìsík. 25:7Jer 49:2; Emọ 1:14
Ìsík. 25:8Ais 15:1; Jer 48:1; Emọ 2:1
Ìsík. 25:8Di 2:4
Ìsík. 25:9Nọ 32:37, 38; Joṣ 13:15, 19
Ìsík. 25:10Isk 25:4
Ìsík. 25:10Isk 21:28, 32
Ìsík. 25:11Jer 48:1
Ìsík. 25:122Kr 28:17; Sm 137:7; Ida 4:22; Emọ 1:11; Ọbd 10
Ìsík. 25:13Mal 1:4
Ìsík. 25:13Jer 49:7, 8
Ìsík. 25:14Ais 11:14; 63:1
Ìsík. 25:14Na 1:2
Ìsík. 25:152Kr 28:18; Ais 9:11, 12; 14:29; Jer 47:1; Joẹ 3:4-6; Emọ 1:6
Ìsík. 25:16Jer 25:17, 20; Sef 2:4
Ìsík. 25:16Sef 2:5
Ìsík. 25:16Jer 47:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 25:1-17

Ìsíkíẹ́lì

25 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn.+ 3 Kí o sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Torí ẹ sọ pé ‘Àháà!’ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì di ahoro àti nígbà tí ilé Júdà lọ sí ìgbèkùn, 4 torí náà, èmi yóò mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn tẹ̀ ọ́, wàá sì di ohun ìní wọn. Wọ́n á kọ́ àwọn ibùdó* wọn sínú rẹ, wọ́n á sì pàgọ́ wọn sáàárín rẹ. Wọ́n á jẹ èso rẹ, wọ́n á sì mu wàrà rẹ. 5 Èmi yóò sọ Rábà+ di ibi tí àwọn ràkúnmí á ti máa jẹko, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì di ibi ìsinmi agbo ẹran; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”

6 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí ẹ pàtẹ́wọ́,+ tí ẹ fẹsẹ̀ kilẹ̀, tí ẹ* sì ń yọ̀ bí ẹ ṣe ń fi ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe irú ẹlẹ́yà yìí,+ 7 torí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ yín, kí n lè mú kí àwọn orílẹ̀-èdè kó ẹrù yín lọ. Màá pa yín rẹ́ láàárín àwọn èèyàn, màá sì pa yín run ní àwọn ilẹ̀ náà.+ Màá pa yín rẹ́, ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’

8 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí Móábù+ àti Séírì + sọ pé: “Wò ó! Ilé Júdà dà bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù,” 9 èmi yóò mú kó rọrùn láti gbógun ti àwọn ìlú tó wà ní ẹ̀gbẹ́* Móábù, ní ààlà rẹ̀. Àwọn ló rẹwà* jù ní ilẹ̀ náà, Bẹti-jẹ́ṣímótì, Baali-méónì, títí dé Kiriátáímù.+ 10 Màá mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn+ tẹ òun àti àwọn ọmọ Ámónì, yóò sì di ohun ìní wọn, kí a má bàa rántí àwọn ọmọ Ámónì mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 11 Èmi yóò ṣèdájọ́ ní Móábù,+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’

12 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+ 13 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+ 14 ‘Màá lo àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì láti gbẹ̀san lára Édómù.+ Wọ́n á mú ìbínú mi àti ìrunú mi wá sórí Édómù, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ló ń gbẹ̀san lára wọn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’

15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èrò ìkà tó wà lọ́kàn àwọn Filísínì* ti mú kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san kí wọ́n sì pani run, torí wọn ò yéé kórìíra.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ àwọn Filísínì,+ màá pa àwọn Kérétì rẹ́,+ màá sì run àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn tó ń gbé ní etí òkun.+ 17 Màá gbẹ̀san lára wọn lọ́nà tó lé kenkà, màá fi ìbínú jẹ wọ́n níyà, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn.”’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́