Àkọsílẹ̀ Máàkù
16 Torí náà, nígbà tí Sábáàtì+ ti kọjá, Màríà Magidalénì, Màríà+ ìyá Jémíìsì àti Sàlómẹ̀ ra àwọn èròjà tó ń ta sánsán kí wọ́n lè wá fi pa á lára.+ 2 Ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, nígbà tí oòrùn ti yọ, wọ́n wá síbi ibojì* náà.+ 3 Wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Ta ló máa bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ọ̀nà ibojì náà?” 4 Àmọ́ nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta náà kúrò, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó tóbi gan-an.+ 5 Nígbà tí wọ́n wọnú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ó wọ aṣọ funfun, ẹnu sì yà wọ́n. 6 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kó yà yín lẹ́nu.+ Jésù ará Násárẹ́tì tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ̀ ń wá. A ti jí i dìde.+ Kò sí níbí. Ẹ wò ó, ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.+ 7 Àmọ́ ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti Pétérù pé, ‘Ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín.+ Ẹ máa rí i níbẹ̀, bó ṣe sọ fún yín.’”+ 8 Torí náà, nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, jìnnìjìnnì bò wọ́n, wọn ò sì mọ ohun tí wọn ì bá ṣe. Wọn ò bá ẹnì kankan sọ nǹkan kan, torí ẹ̀rù ń bà wọ́n.*+