ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Jèhóádà dá sí ọ̀rọ̀ náà; wọ́n fi Jèhóáṣì jọba (1-11)

      • Wọ́n pa Ataláyà (12-15)

      • Àwọn àtúnṣe tí Jèhóádà ṣe (16-21)

2 Kíróníkà 23:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dá májẹ̀mú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:4

2 Kíróníkà 23:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 8:14

2 Kíróníkà 23:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:3
  • +2Sa 7:8, 12; 1Ọb 2:4; 9:5; Sm 89:20, 29

2 Kíróníkà 23:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:3
  • +2Ọb 11:5-8; 1Kr 9:22-25; 26:1

2 Kíróníkà 23:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:1
  • +1Ọb 7:12

2 Kíróníkà 23:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 23:28, 32

2 Kíróníkà 23:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “nígbà tó bá wọlé àti nígbà tó bá jáde.”

2 Kíróníkà 23:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:9-12
  • +1Kr 24:1; 26:1

2 Kíróníkà 23:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.

  • *

    Tàbí “apata ribiti.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:4
  • +2Sa 8:7
  • +1Kr 26:26, 27; 2Kr 5:1

2 Kíróníkà 23:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọṣẹ́.”

2 Kíróníkà 23:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dáyádémà.”

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé tí Òfin Ọlọ́run wà nínú rẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:2
  • +Di 17:18
  • +1Sa 10:1, 24

2 Kíróníkà 23:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:13-16

2 Kíróníkà 23:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “òpó rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “fi àmì darí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 23:1
  • +1Ọb 1:39, 40

2 Kíróníkà 23:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

2 Kíróníkà 23:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:17, 18; 2Kr 34:1, 31

2 Kíróníkà 23:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:27, 28
  • +Di 12:3; 2Kr 34:1, 4
  • +Di 13:5; 1Ọb 18:40

2 Kíróníkà 23:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láti ọwọ́ Dáfídì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 23:6, 30, 31
  • +Ẹk 29:38; Nọ 28:2

2 Kíróníkà 23:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 9:26; 26:1, 13

2 Kíróníkà 23:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:9
  • +1Ọb 7:7
  • +2Ọb 11:19, 20

2 Kíróníkà 23:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi idà pa.”

Àwọn míì

2 Kíró. 23:12Ọb 11:4
2 Kíró. 23:22Kr 8:14
2 Kíró. 23:32Sa 5:3
2 Kíró. 23:32Sa 7:8, 12; 1Ọb 2:4; 9:5; Sm 89:20, 29
2 Kíró. 23:41Kr 24:3
2 Kíró. 23:42Ọb 11:5-8; 1Kr 9:22-25; 26:1
2 Kíró. 23:51Ọb 7:1
2 Kíró. 23:51Ọb 7:12
2 Kíró. 23:61Kr 23:28, 32
2 Kíró. 23:82Ọb 11:9-12
2 Kíró. 23:81Kr 24:1; 26:1
2 Kíró. 23:92Ọb 11:4
2 Kíró. 23:92Sa 8:7
2 Kíró. 23:91Kr 26:26, 27; 2Kr 5:1
2 Kíró. 23:112Ọb 11:2
2 Kíró. 23:11Di 17:18
2 Kíró. 23:111Sa 10:1, 24
2 Kíró. 23:122Ọb 11:13-16
2 Kíró. 23:132Kr 23:1
2 Kíró. 23:131Ọb 1:39, 40
2 Kíró. 23:162Ọb 11:17, 18; 2Kr 34:1, 31
2 Kíró. 23:172Ọb 10:27, 28
2 Kíró. 23:17Di 12:3; 2Kr 34:1, 4
2 Kíró. 23:17Di 13:5; 1Ọb 18:40
2 Kíró. 23:181Kr 23:6, 30, 31
2 Kíró. 23:18Ẹk 29:38; Nọ 28:2
2 Kíró. 23:191Kr 9:26; 26:1, 13
2 Kíró. 23:202Ọb 11:9
2 Kíró. 23:201Ọb 7:7
2 Kíró. 23:202Ọb 11:19, 20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 23:1-21

Kíróníkà Kejì

23 Ní ọdún keje, Jèhóádà gbé ìgbésẹ̀ akin, ó sì bá àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ṣe àdéhùn,*+ àwọn ni: Asaráyà ọmọ Jéróhámù, Íṣímáẹ́lì ọmọ Jèhóhánánì, Asaráyà ọmọ Óbédì, Maaseáyà ọmọ Ádáyà àti Élíṣáfátì ọmọ Síkírì. 2 Nígbà náà, wọ́n lọ káàkiri Júdà, wọ́n sì kó àwọn ọmọ Léfì+ jọ látinú gbogbo àwọn ìlú Júdà àti àwọn olórí àwọn agbo ilé ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n dé sí Jerúsálẹ́mù, 3 gbogbo ìjọ náà bá ọba dá májẹ̀mú+ nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́, lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé:

“Ẹ wò ó! Ọmọ ọba yóò jọba, bí Jèhófà ti ṣèlérí nípa àwọn ọmọ Dáfídì.+ 4 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ìdá mẹ́ta lára àwọn àlùfáà àti lára àwọn ọmọ Léfì tó máa wà lẹ́nu iṣẹ́+ ní Sábáàtì máa jẹ́ aṣọ́nà;+ 5 ìdá mẹ́ta míì máa wà ní ilé* ọba,+ ìdá mẹ́ta tó kù á wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn náà á sì wà ní àwọn àgbàlá ilé Jèhófà.+ 6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọ ilé Jèhófà àfi àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣe ìránṣẹ́.+ Àwọn yìí lè wọlé torí pé àwùjọ mímọ́ ni wọ́n, gbogbo àwọn èèyàn náà yóò sì máa ṣe ojúṣe wọn fún Jèhófà. 7 Àwọn ọmọ Léfì gbọ́dọ̀ yí ọba ká, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá wọlé. Kí ẹ sì dúró ti ọba níbikíbi tó bá lọ.”*

8 Àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Júdà ṣe ohun tí àlùfáà Jèhóádà pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. Nítorí náà, kálukú mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì pẹ̀lú àwọn tí kò sí lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì,+ torí pé àlùfáà Jèhóádà kò tíì ní kí àwọn àwùjọ náà+ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn. 9 Lẹ́yìn náà, àlùfáà Jèhóádà fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ní àwọn ọ̀kọ̀ àti asà* àti apata* tó jẹ́ ti Ọba Dáfídì,+ tó wà nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 10 Ó wá fi gbogbo àwọn èèyàn náà sí ibi tí wọ́n máa wà, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà* rẹ̀ lọ́wọ́, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé náà, gbogbo wọn yí ọba ká. 11 Nígbà náà, wọ́n mú ọmọ ọba+ jáde, wọ́n sì fi adé* dé e, wọ́n fi Ẹ̀rí*+ sí i lórí, wọ́n fi jọba, Jèhóádà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì fòróró yàn án. Wọ́n sọ pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”+

12 Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ìró àwọn èèyàn tó ń sáré tí wọ́n sì ń yin ọba, ní kíá, ó lọ bá àwọn tó wà ní ilé Jèhófà.+ 13 Ó wá rí ọba níbẹ̀ tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó* ní ibi àbáwọlé. Àwọn ìjòyè + àti àwọn tó ń fun kàkàkí wà lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀,+ wọ́n sì ń fun kàkàkí, àwọn akọrin tí ohun ìkọrin wà lọ́wọ́ wọn ló sì ń darí* orin ìyìn náà. Ni Ataláyà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kígbe pé: “Ọ̀tẹ̀ rèé o! Ọ̀tẹ̀ rèé o!” 14 Àmọ́ àlùfáà Jèhóádà kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún jáde, àwọn tí a yàn ṣe olórí ọmọ ogun, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mú un kúrò láàárín àwọn ọmọ ogun, tí ẹnikẹ́ni bá sì tẹ̀ lé e, kí ẹ fi idà pa á!” Nítorí àlùfáà ti sọ pé: “Ẹ má ṣe pa á ní ilé Jèhófà.” 15 Torí náà, wọ́n mú un, nígbà tó sì dé ibi àbáwọlé Ẹnubodè Ẹṣin tó wà ní ilé* ọba, wọ́n pa á níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

16 Lẹ́yìn náà, Jèhóádà dá májẹ̀mú láàárín òun àti gbogbo àwọn èèyàn náà àti ọba pé àwọn á máa jẹ́ èèyàn Jèhófà nìṣó.+ 17 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn náà wá sí ilé* Báálì, wọ́n sì wó o lulẹ̀,+ wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ rẹ̀ àti àwọn ère rẹ̀ túútúú,+ wọ́n sì pa Mátánì àlùfáà Báálì+ níwájú àwọn pẹpẹ náà. 18 Jèhóádà wá fi iṣẹ́ àbójútó ilé Jèhófà sí ìkáwọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí Dáfídì yàn sí àwọn àwùjọ tó ń bójú tó ilé Jèhófà láti máa rú àwọn ẹbọ sísun Jèhófà+ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè,+ pẹ̀lú ayọ̀ àti orin, bí Dáfídì ṣe sọ.* 19 Ó tún fi àwọn aṣọ́bodè+ sí àwọn ẹnubodè ilé Jèhófà kí aláìmọ́ èyíkéyìí má bàa wọlé. 20 Ó wá kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn èèyàn pàtàkì, àwọn alákòóso àti gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, ó sì mú ọba wá láti ilé Jèhófà. Wọ́n gba ẹnubodè apá òkè wá sí ilé* ọba, wọ́n sì mú ọba jókòó sórí ìtẹ́+ ìjọba. + 21 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀, ìlú náà sì tòrò, nítorí pé wọ́n ti pa* Ataláyà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́