Hábákúkù
3 Àdúrà tí wòlíì Hábákúkù fi orin arò* gbà:
2 Jèhófà, mo ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ.
Jèhófà, ohun tí o ṣe bà mí lẹ́rù.
Tún ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò wa!*
Jẹ́ ká tún rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ nígbà tiwa.*
Jọ̀ọ́, rántí fi àánú hàn nígbà wàhálà.+
Iyì rẹ̀ gba ọ̀run kan;+
Ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀.
Ìtànṣán méjì jáde láti ọwọ́ rẹ̀,
Níbi tí agbára rẹ̀ wà.
6 Ó dúró jẹ́ẹ́, ó sì mi ayé jìgìjìgì.+
Ó wo àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì mú kí wọ́n gbọ̀n rìrì.+
Ó fọ́ àwọn òkè tó ti wà tipẹ́,
Àwọn òkè àtayébáyé sì tẹrí ba.+
Òun ló ni àwọn ọ̀nà àtijọ́.
7 Mo rí wàhálà nínú àwọn àgọ́ Kúṣánì.
Àwọn aṣọ àgọ́ ilẹ̀ Mídíánì sì gbọ̀n rìrì.+
8 Jèhófà, ṣé àwọn odò ni?
Ṣé àwọn odò lò ń bínú sí?
Àbí òkun lò ń kanra mọ́?+
9 O ti yọ ọfà rẹ síta, o sì ti ṣe tán láti ta á.
Àwọn ọ̀pá* rẹ fẹ́ ṣe ohun tí o búra.* (Sélà)
O fi odò pín ayé.
10 Àwọn òkè jẹ̀rora nígbà tí wọ́n rí ọ.+
Ọ̀gbàrá òjò wọ́ kọjá.
Ibú omi pariwo.+
Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
11 Oòrùn àti òṣùpá dúró jẹ́ẹ́ níbi tí wọ́n wà lókè.+
Àwọn ọfà rẹ ń yára jáde bí ìmọ́lẹ̀.+
Ọ̀kọ̀ rẹ ń kọ mànà.
12 O fi ìkannú rin ayé já.
O fi ìbínú tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.*
13 O jáde lọ láti gba àwọn èèyàn rẹ là, kí o lè gba ẹni àmì òróró rẹ là.
O tẹ olórí* ilé àwọn ẹni burúkú rẹ́.
O wó ilé náà láti òkè* títí dé ìpìlẹ̀. (Sélà)
14 O fi àwọn ohun ìjà rẹ̀* gún àwọn jagunjagun rẹ̀ ní orí
Nígbà tí wọ́n ya bò mí bí ìjì láti tú mi ká.
Inú wọn dùn láti dúró sí ìkọ̀kọ̀ kí wọ́n lè pa ẹni tí ìyà ń jẹ run.
15 O fi àwọn ẹṣin rẹ rin òkun já,
O fi wọ́n la ibú omi kọjá.
Egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹrà;+
Ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì.
Àmọ́ mò ń fara balẹ̀ dúró de ọjọ́ wàhálà,+
Torí àwọn tó ń gbógun tì wá ni yóò dé bá.
17 Igi ọ̀pọ̀tọ́ lè má rúwé,
Àjàrà sì lè má so èso;
Tí igi ólífì kò bá tiẹ̀ so,
Tí ilẹ̀* kò sì mú èso jáde;
Tí kò bá tiẹ̀ sí agbo ẹran mọ́ nínú ọgbà ẹran,
Tí kò sì sí màlúù mọ́ ní ilé ẹran;
18 Síbẹ̀, ní tèmi, màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà;
Inú mi yóò dùn nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.+
19 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni agbára mi;+
Yóò mú kí ẹsẹ̀ mi dà bíi ti àgbọ̀nrín,
Yóò sì mú kí n rìn lórí àwọn ibi gíga.+
Sí olùdarí; pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin mi olókùn tín-ín-rín.