ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt ojú ìwé 910-911
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Oníwàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Lílò Tí Jehofa Ń Lo “Ìwà-òmùgọ̀” Lati Gba Awọn Wọnni Ti Wọn Gbagbọ Là
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Jèhófà Fẹ́ Kó O Ní Ọgbọ́n Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

ONÍWÀÁSÙ

OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

  • 1

    • Asán ni ohun gbogbo (1-11)

      • Ayé wà títí láé (4)

      • Àwọn ohun tó ń yí po ní ayé (5-7)

      • Kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn (9)

    • Ó níbi tí ọgbọ́n èèyàn mọ (12-18)

      • Ìmúlẹ̀mófo (14)

  • 2

    • Àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí Sólómọ́nì ṣe (1-11)

    • Ó níbi tí ọgbọ́n èèyàn wúlò dé (12-16)

    • Asán tó wà nínú iṣẹ́ àṣekára (17-23)

    • Máa jẹ, máa mu, kí o sì gbádùn iṣẹ́ rẹ (24-26)

  • 3

    • Ohun gbogbo ni àkókò wà fún (1-8)

    • Ká gbádùn ayé, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni (9-15)

      • Ayérayé wà ní ọkàn èèyàn (11)

    • Òdodo ni Ọlọ́run fi ń ṣe ìdájọ́ gbogbo èèyàn (16, 17)

    • Bí èèyàn ṣe ń kú náà ni ẹranko ń kú (18-22)

      • Gbogbo wọn á pa dà sí erùpẹ̀ (20)

  • 4

    • Ìnilára burú ju ikú lọ (1-3)

    • Ojú tó yẹ ká fi wo iṣẹ́ (4-6)

    • Iyì ọ̀rẹ́ (7-12)

      • Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ (9)

    • Ìgbésí ayé alákòóso lè jẹ́ asán (13-16)

  • 5

    • Wá síwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ìbẹ̀rù tó yẹ (1-7)

    • Àwọn tó ga ju àwọn tó wà nípò gíga ń ṣọ́ wọn (8, 9)

    • Asán tó wà nínú ọrọ̀ (10-20)

      • Owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ owó (10)

      • Oorun òṣìṣẹ́ máa ń dùn (12)

  • 6

    • Ọ̀pọ̀ ohun ìní láìsí ìgbádùn (1-6)

    • Gbádùn ohun tí o ní nísinsìnyí (7-12)

  • 7

    • Orúkọ rere àti ọjọ́ ikú (1-4)

    • Ìbáwí tí ọlọ́gbọ́n fúnni (5-7)

    • Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ (8-10)

    • Àǹfààní ọgbọ́n (11, 12)

    • Ọjọ́ rere àti ọjọ́ burúkú (13-15)

    • Yẹra fún àṣejù (16-22)

    • Àwọn ohun tí akónijọ kíyè sí (23-29)

  • 8

    • Lábẹ́ àkóso èèyàn aláìpé (1-17)

      • Pa àṣẹ ọba mọ́ (2-4)

      • Ìjọba èèyàn ń pani lára (9)

      • Nígbà tí a kò bá tètè mú ìdájọ́ ṣẹ (11)

      • Máa jẹ, máa mu, kí o sì máa yọ̀ (15)

  • 9

    • Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn gbogbo wọn (1-3)

    • Gbádùn ayé rẹ bí ikú tiẹ̀ máa dé (4-12)

      • Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan (5)

      • Èèyàn ò lè ṣe nǹkan kan nínú Isà Òkú (10)

      • Ìgbà àti èèṣì (11)

    • Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń mọyì ọgbọ́n (13-18)

  • 10

    • Ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ń ba ọgbọ́n jẹ́ (1)

    • Ewu tó wà nínú àìmọṣẹ́ (2-11)

    • Ohun búburú tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òmùgọ̀ (12-15)

    • Ìwà òmùgọ̀ àwọn alákòóso (16-20)

      • Ẹyẹ lè tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ (20)

  • 11

    • Lo àǹfààní tí o ní (1-8)

      • Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi (1)

      • Fún irúgbìn láti àárọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ (6)

    • Gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ lọ́nà tó yẹ (9, 10)

  • 12

    • Rántí Ẹlẹ́dàá kí ọjọ́ ogbó tó dé (1-8)

    • Ìparí ọ̀rọ̀ akónijọ (9-14)

      • Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù (11)

      • Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ (13)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́