ONÍWÀÁSÙ
1 Àwọn ọ̀rọ̀ akónijọ,*+ ọmọ Dáfídì, ọba ní Jerúsálẹ́mù.+
2 Akónijọ sọ pé, “Asán* pátápátá gbáà!”
“Asán pátápátá gbáà! Asán ni gbogbo rẹ̀!”+
3 Èrè wo ni èèyàn rí jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀
Èyí tó ń fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run?*+
6 Ẹ̀fúùfù ń lọ sí gúúsù, ó sì ń yí lọ sí àríwá;
Yíyí ló ń yí po nígbà gbogbo; ẹ̀fúùfù ń yí po ṣáá.
7 Gbogbo odò* ló ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀ òkun kò kún.+
Ibi tí àwọn odò ti ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n ń pa dà sí, kí wọ́n tún lè ṣàn jáde.+
8 Ohun gbogbo ló ń kó àárẹ̀ báni;
Kódà, ó kọjá ohun téèyàn lè sọ.
Ìran kì í sú ojú;
Bẹ́ẹ̀ ni etí kì í kọ gbígbọ́.
10 Ṣé ohun kan wà tí a lè sọ pé: “Wò ó, tuntun ni”?
Ó ti wà tipẹ́tipẹ́;
Ó ti wà ṣáájú àkókò wa.
11 Kò sí ẹni tó ń rántí àwọn èèyàn ayé àtijọ́;
Kò sì sí ẹni tó máa rántí àwọn tó ń bọ̀;
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó máa wá nígbà tó bá yá kò ní rántí àwọn náà.+
12 Èmi, akónijọ, ló ti ń jọba lórí Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù.+ 13 Mo fi ọgbọ́n+ ṣe ìwádìí àti àyẹ̀wò ohun gbogbo tí a ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,+ ìyẹn iṣẹ́ tó ń tánni lókun tí Ọlọ́run fún ọmọ aráyé tó ń mú kí ọwọ́ wọn dí.
14 Mo rí gbogbo iṣẹ́ tí a ṣe lábẹ́ ọ̀run,*
Sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo.*+
15 Ohun tó ti wọ́, a kò lè mú un tọ́,
Ohun tí kò sì sí, a kò lè kà á.
16 Nígbà náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Wò ó! Mo ti ní ọgbọ́n tó pọ̀ gan-an ju ẹnikẹ́ni tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ọkàn mi sì ti kó ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tó pọ̀ gan-an jọ.” 17 Mo fi ọkàn mi sí mímọ ọgbọ́n àti mímọ ìwà wèrè* àti mímọ ìwà ẹ̀gọ̀,+ èyí pẹ̀lú jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
18 Nítorí ọ̀pọ̀ ọgbọ́n máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ wá,
Tó fi jẹ́ pé ẹni tó ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ ń fi ìrora kún ìrora.+
2 Nígbà náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Wá, jẹ́ kí n dán ìgbádùn* wò, kí n sì rí ohun rere tó máa tibẹ̀ wá.” Àmọ́ wò ó! asán ni èyí pẹ̀lú.
2 Mo sọ nípa ẹ̀rín pé, “Wèrè ni!”
Àti nípa ìgbádùn* pé, “Kí ni ìwúlò rẹ̀?”
3 Mo mu wáìnì,+ kí n lè fi ọkàn mi ṣèwádìí, àmọ́ ní gbogbo àkókò yìí mi ò sọ ọgbọ́n mi nù; kódà, mo fara mọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ kí n lè rí ohun tó dáa jù lọ fún ọmọ aráyé láti máa ṣe láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n máa lò lábẹ́ ọ̀run. 4 Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá.+ Mo kọ́ àwọn ilé fún ara mi;+ mo gbin àwọn ọgbà àjàrà fún ara mi.+ 5 Mo ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn àti ọgbà ìtura fún ara mi, mo sì gbin oríṣiríṣi igi eléso sínú wọn. 6 Mo ṣe àwọn adágún omi fún ara mi, láti máa fi bomi rin ọgbà* tí àwọn igi tó léwé dáadáa wà. 7 Mo ní àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin,+ mo sì ní àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n bí ní agbo ilé mi.* Mo tún ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn, ìyẹn màlúù àti agbo ẹran,+ tó pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù. 8 Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi,+ ìṣúra* àwọn ọba àti ti àwọn ìpínlẹ̀.+ Mo kó àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin jọ fún ara mi, títí kan ohun tó ń múnú ọmọ aráyé dùn gidigidi, ìyẹn obìnrin, àní ọ̀pọ̀ obìnrin.* 9 Torí náà, mo dẹni ńlá, mo sì ga ju gbogbo àwọn tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.+ Bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.
10 Mi ò fi ohunkóhun tí mo fẹ́* du ara mi.+ Kò sí irú ìgbádùn* tí ọkàn mi fẹ́ tí mi ò fún un, torí ọkàn mi ń yọ̀ nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi, èyí sì ni èrè* mi nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi.+ 11 Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti ṣe àti gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti sapá láti ṣe yọrí,+ mo rí i pé asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo;*+ kò sí ohun gidi kan* lábẹ́ ọ̀run.*+
12 Mo wá fiyè sí ọgbọ́n àti ìwà wèrè àti ìwà ẹ̀gọ̀.+ (Kí ni ẹni tó máa wá lẹ́yìn ọba lè ṣe? Ohun tí àwọn èèyàn ti ṣe tẹ́lẹ̀ ni.) 13 Mo rí i pé àǹfààní wà nínú ọgbọ́n ju ìwà ẹ̀gọ̀ lọ,+ bí àǹfààní ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀ ju òkùnkùn lọ.
14 Ojú ọlọ́gbọ́n wà ní orí rẹ̀;*+ àmọ́ òmùgọ̀ ń rìn nínú òkùnkùn.+ Mo sì wá rí i pé ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ 15 Lẹ́yìn náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ló máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà.”+ Kí wá ni èrè ọgbọ́n tí mo gbọ́n ní àgbọ́njù? Mo sì sọ lọ́kàn mi pé: “Asán ni èyí pẹ̀lú.” 16 Nítorí a kì í rántí ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀ títí lọ.+ Bó pẹ́ bó yá, a ò ní rántí ẹnikẹ́ni mọ́. Báwo sì ni ọlọ́gbọ́n ṣe máa kú? Á kú pẹ̀lú àwọn òmùgọ̀.+
17 Ayé wá sú mi,+ nítorí gbogbo ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run* ló ń kó ìdààmú báni lójú tèmi, torí asán ni gbogbo rẹ̀,+ ìmúlẹ̀mófo.*+ 18 Mo wá kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,*+ torí mo gbọ́dọ̀ fi í sílẹ̀ fún ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi.+ 19 Ta ló sì mọ̀ bóyá ó máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀?+ Síbẹ̀, òun ni yóò máa darí gbogbo ohun tí mo ti fi akitiyan àti ọgbọ́n kó jọ lábẹ́ ọ̀run.* Asán ni èyí pẹ̀lú. 20 Torí náà, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo fi gbogbo agbára mi ṣe lábẹ́ ọ̀run.* 21 Nítorí èèyàn lè fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti òye ṣiṣẹ́ ní àṣekára, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ fi èrè rẹ̀* sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́ fún un.+ Asán ni èyí pẹ̀lú àti àdánù* ńlá.
22 Kí tiẹ̀ ni èrè tí èèyàn rí jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ àti gbogbo bó ṣe ń wù ú* láti ṣiṣẹ́ kára lábẹ́ ọ̀run?*+ 23 Torí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ ń mú ìrora àti ìjákulẹ̀ bá a,+ kódà kì í rí oorun sùn lóru.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.
24 Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì gbádùn* iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.+ Èyí pẹ̀lú ni mo ti rí pé ó wá láti ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ 25 àbí ta ló ń jẹ, tó sì ń mu ohun tó dáa ju tèmi lọ?+
26 Ọlọ́run ń fún ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ìdùnnú,+ àmọ́ ó ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní iṣẹ́ kíkó jọ àti ṣíṣà jọ kí wọ́n lè fún ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo* sì ni.
3 Ohun gbogbo ni àkókò wà fún,
Àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́ lábẹ́ ọ̀run:
2 Ìgbà bíbímọ àti ìgbà kíkú;
Ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn tu;
3 Ìgbà pípa àti ìgbà wíwòsàn;
Ìgbà wíwólulẹ̀ àti ìgbà kíkọ́;
4 Ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín;
Ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà jíjó;*
5 Ìgbà jíju òkúta sọ nù àti ìgbà kíkó òkúta jọ;
Ìgbà gbígbánimọ́ra àti ìgbà téèyàn ò ní gbáni mọ́ra;
6 Ìgbà wíwá àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọ nù;
Ìgbà fífi pa mọ́ àti ìgbà jíjù sọ nù;
8 Ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra;+
Ìgbà ogun àti ìgbà àlàáfíà.
9 Kí ni èrè tí òṣìṣẹ́ rí jẹ látinú gbogbo ìsapá rẹ̀?+ 10 Mo ti rí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún ọmọ aráyé láti mú kí ọwọ́ wọn dí. 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.
12 Mo ti wá rí i pé kò sí ohun tó dáa fún wọn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ayé wọn,+ 13 àti pé kí kálukú máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.+
14 Mo ti wá mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe máa wà títí láé. Kò sí nǹkan kan tí a máa fi kún un, kò sì sí nǹkan kan tí a máa yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe é bẹ́ẹ̀ kí àwọn èèyàn lè máa bẹ̀rù rẹ̀.+
15 Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí, ohun tó sì ń bọ̀ ti wà tẹ́lẹ̀;+ àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ń wá ohun tí a ti lépa.*
16 Mo tún ti rí i lábẹ́ ọ̀run* pé: Ìwà burúkú ti rọ́pò ìdájọ́ òdodo, ìwà burúkú sì ti rọ́pò òdodo.+ 17 Torí náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ẹni burúkú,+ nítorí àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́ àti gbogbo akitiyan.”
18 Mo tún sọ nípa àwọn ọmọ aráyé lọ́kàn mi pé Ọlọ́run tòótọ́ máa dán wọn wò, á sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé bí ẹranko ni wọ́n rí, 19 nítorí pé ohun* kan wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn, ohun kan sì wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko; ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ Bí ọ̀kan ṣe ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní.+ Torí náà, èèyàn kò lọ́lá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni ohun gbogbo. 20 Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ.+ Inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá,+ inú erùpẹ̀ sì ni gbogbo wọn ń pa dà sí.+ 21 Ta ló mọ̀ bóyá ẹ̀mí èèyàn ń lọ sí òkè tàbí ẹ̀mí ẹranko ń lọ sí ilẹ̀?+ 22 Mo sì rí i pé kò sí ohun tó dáa fún èèyàn ju pé kó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀,+ nítorí ìyẹn ni èrè* rẹ̀; torí ta ló lè mú kó rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti lọ?+
4 Mo tún fiyè sí gbogbo ìwà ìnilára tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.* Mo rí omijé àwọn tí wọ́n ń ni lára, kò sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú.+ Agbára wà lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára, kò sì sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú. 2 Mo bá àwọn tó ti kú yọ̀ dípò àwọn tó ṣì wà láàyè.+ 3 Ẹni tó sàn ju àwọn méjèèjì lọ ni ẹni tí wọn ò tíì bí,+ tí kò tíì rí ohun tó ń kó ìdààmú báni tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+
4 Mo ti rí bí ìdíje+ ṣe ń mú kí àwọn èèyàn máa sapá,* kí wọ́n sì máa fòye ṣiṣẹ́; asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*
5 Òmùgọ̀ ká ọwọ́ gbera, bẹ́ẹ̀ ló ń rù sí i.*+
6 Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.*+
7 Mo fiyè sí àpẹẹrẹ ohun míì tó jẹ́ asán lábẹ́ ọ̀run:* 8 Ọkùnrin kan wà tó dá wà, kò ní ẹnì kejì; kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ará, àmọ́ iṣẹ́ àṣekára tó ń ṣe kò lópin. Ojú rẹ̀ kò kúrò nínú kíkó ọrọ̀ jọ.+ Àmọ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bi ara rẹ̀ pé, ‘Ta ni mò ń tìtorí rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára tí mo sì ń fi àwọn ohun rere du ara mi’?+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ó sì jẹ́ iṣẹ́ tó ń tánni lókun.+
9 Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ,+ nítorí pé wọ́n ní èrè* fún iṣẹ́ àṣekára wọn. 10 Torí tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé e* dìde. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó ṣubú tí kò sí ẹni tó máa gbé e dìde?
11 Bákan náà, tí àwọn méjì bá dùbúlẹ̀ pa pọ̀, ara wọn á móoru, àmọ́ báwo ni ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè móoru? 12 Ẹnì kan lè borí ẹni tó dá wà, àmọ́ àwọn méjì tó wà pa pọ̀ lè kojú rẹ̀. Okùn onífọ́nrán mẹ́ta kò ṣeé tètè* fà já.
13 Ọmọdé tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n sàn ju àgbàlagbà ọba tó jẹ́ òmùgọ̀,+ tí làákàyè rẹ̀ kò tó láti gba ìkìlọ̀ mọ́.+ 14 Nítorí inú ẹ̀wọ̀n ló* ti jáde lọ di ọba,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà tí ẹni yẹn ń ṣàkóso lọ́wọ́ ni wọ́n bí i ní aláìní.+ 15 Mo kíyè sí gbogbo àwọn alààyè tó ń rìn káàkiri lábẹ́ ọ̀run,* mo tún kíyè sí bí nǹkan ṣe rí fún ọmọ tó wá gba ipò ọba náà. 16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ń tì í lẹ́yìn kò lóǹkà, inú àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn kò ní dùn sí i.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*
5 Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́;+ ó sàn kéèyàn wá fetí sílẹ̀+ ju kó mú ẹbọ wá bí àwọn òmùgọ̀ ti ń ṣe,+ nítorí wọn ò mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dáa.
2 Má ṣe yánu sọ̀rọ̀ tàbí kí ọkàn rẹ sọ̀rọ̀ láìronú níwájú Ọlọ́run tòótọ́,+ nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà ní ọ̀run àmọ́ ìwọ wà ní ayé. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.+ 3 Nítorí ọ̀pọ̀ iṣẹ́* máa ń mú kí èèyàn lá àlá,+ àpọ̀jù ọ̀rọ̀+ sì máa ń mú kí àwọn òmùgọ̀ máa wí ìrégbè. 4 Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má fi falẹ̀, san án,+ nítorí inú rẹ̀ kì í dùn sí àwọn òmùgọ̀.+ Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.+ 5 Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.+ 6 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ* dẹ́ṣẹ̀,+ má sì sọ níwájú áńgẹ́lì* pé àṣìṣe ni.+ Kí nìdí tí wàá fi mú Ọlọ́run tòótọ́ bínú nítorí ohun tí o sọ, tí á sì pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run?+ 7 Nítorí bí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣe ń mú kí èèyàn lá àlá,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ púpọ̀ ṣe ń já sí asán. Àmọ́, Ọlọ́run tòótọ́ ni kí o bẹ̀rù.+
8 Tí o bá rí i tí wọ́n ń ni àwọn aláìní lára tàbí tí wọ́n ń tẹ ìdájọ́ òdodo àti òtítọ́ lójú ní agbègbè rẹ, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu.+ Torí ẹnì kan wà tó ń ṣọ́ ẹni tó wà nípò gíga, ẹni yẹn sì ga jù ú lọ, síbẹ̀ àwọn míì tún wà tó ga jù wọ́n lọ.
9 Bákan náà, wọ́n pín èrè ilẹ̀ náà láàárín ara wọn; kódà inú oko ni oúnjẹ ọba ti ń wá.+
10 Fàdákà kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.+
11 Nígbà tí ohun rere bá pọ̀ sí i, àwọn tó ń jẹ ẹ́ á pọ̀ sí i.+ Àǹfààní wo ló sì jẹ́ fún ẹni tó ní in ju pé kó máa fi ojú rẹ̀ wò ó?+
12 Oorun ẹni tó ń sìn máa ń dùn, bóyá oúnjẹ díẹ̀ ló jẹ tàbí púpọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ọlọ́rọ̀ ní kì í jẹ́ kó rí oorun sùn.
13 Àdánù* ńlá kan wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run:* ọrọ̀ tí àwọn ọlọ́rọ̀ kó pa mọ́ fún ìpalára ara wọn. 14 Àwọn ọrọ̀ yẹn ṣègbé nítorí òwò* àṣedànù, nígbà tó sì bímọ, kò ní ohun ìní kankan lọ́wọ́ mọ́.+
15 Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+
16 Èyí pẹ̀lú jẹ́ àdánù* ńlá: Bí ẹni náà ṣe wá gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa lọ; èrè wo ló sì wà fún ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lórí asán?+ 17 Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ ló ń jẹun nínú òkùnkùn pẹ̀lú ìbànújẹ́ ńlá àti àìsàn àti ìbínú.+
18 Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+ 19 Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ bá fún ẹnì kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní,+ tó sì jẹ́ kó lè gbádùn wọn, kí ẹni náà gba èrè* rẹ̀ kó sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.+ 20 Torí bóyá ló fi máa mọ̀* pé ọjọ́ ayé òun ń lọ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí ayọ̀ gbà á lọ́kàn.+
6 Àdánù* míì wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run,* ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn: 2 Ọlọ́run tòótọ́ fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní àti ògo, tí kò fi ṣaláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́; síbẹ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kò jẹ́ kó gbádùn àwọn ohun náà, àmọ́ ó jẹ́ kí àlejò gbádùn wọn. Asán ni èyí àti ìpọ́njú tó lágbára. 3 Tí ọkùnrin kan bá bímọ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, tó lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé, tó sì darúgbó, síbẹ̀ tí* kò gbádùn àwọn ohun rere tó ní kó tó wọnú sàréè,* ohun tí màá sọ ni pé ọmọ tí wọ́n bí ní òkú sàn jù ú lọ.+ 4 Torí pé ẹni yìí wá lásán, ó sì lọ nínú òkùnkùn, òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀. 5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rí oòrùn, kò sì mọ nǹkan kan, ó ṣì sàn* ju ẹni ìṣáájú lọ.+ 6 Kí làǹfààní kéèyàn gbé ẹgbẹ̀rún ọdún láyé ní ìlọ́po méjì, àmọ́ kó má gbádùn nǹkan kan? Torí pé ibì kan náà ni gbogbo èèyàn ń lọ.+
7 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára téèyàn ń ṣe, torí kó lè rí nǹkan fi sẹ́nu ni;+ síbẹ̀ kì í* yó. 8 Nítorí àǹfààní wo ni ọlọ́gbọ́n ní lórí òmùgọ̀?+ Tàbí àǹfààní kí ló jẹ́ fún aláìní pé ó mọ bí èèyàn ṣe ń tọ́jú ara rẹ̀?* 9 Ó sàn kéèyàn máa gbádùn ohun tí ojú rẹ̀ rí ju kó máa dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́.* Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*
10 Ohunkóhun tó bá wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a ti mọ ohun tí èèyàn jẹ́; kò sì lè bá ẹni tó lágbára jù ú lọ jiyàn.* 11 Bí ọ̀rọ̀* bá ṣe pọ̀ náà ni asán á ṣe pọ̀, àǹfààní wo sì ni èèyàn máa rí nínú wọn? 12 Ta ló mọ ohun tó dára jù lọ fún èèyàn láti fi ayé rẹ̀ ṣe láàárín ọjọ́ díẹ̀ tó máa fi gbé ìgbé ayé asán, èyí tó máa kọjá lọ bí òjìji?+ Àbí ta ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* fún èèyàn lẹ́yìn tó bá ti lọ?
7 Orúkọ rere* sàn ju òróró dáradára,+ ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ. 2 Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àsè,+ torí pé ìyẹn ni òpin gbogbo èèyàn, ó sì yẹ kí àwọn alààyè fi sọ́kàn. 3 Ìbànújẹ́ sàn ju ẹ̀rín lọ,+ torí ojú tó fà ro ń mú kí ọkàn túbọ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa.+ 4 Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, àmọ́ ilé ìdùnnú* ni ọkàn òmùgọ̀ wà.+
5 Ó sàn kéèyàn fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n+ ju kéèyàn máa gbọ́ orin àwọn òmùgọ̀. 6 Torí pé bí ẹ̀gún tó ń jó lábẹ́ ìkòkò ṣe máa ń ta pàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí;+ asán sì ni èyí pẹ̀lú. 7 Ìnilára lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bíi wèrè, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì ń sọ ọkàn dìdàkudà.+
8 Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ. Ó sàn kéèyàn ní sùúrù ju pé kéèyàn ní ẹ̀mí ìgbéraga.+ 9 Má ṣe máa yára* bínú,+ torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.*+
10 Má sọ pé, “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?” torí pé kì í ṣe ọgbọ́n ló mú kí o béèrè bẹ́ẹ̀.+
11 Ọgbọ́n pẹ̀lú ogún jẹ́ ohun tó dáa, ó sì jẹ́ àǹfààní fún àwọn tó ń rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.* 12 Nítorí ọgbọ́n jẹ́ ààbò+ bí owó ṣe jẹ́ ààbò,+ àmọ́ àǹfààní ìmọ̀ ni pé: Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.+
13 Kíyè sí iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ta ló lè mú kí ohun tó ṣe ní wíwọ́ tọ́?+ 14 Ní ọjọ́ tí nǹkan bá dáa, jẹ́ kó hàn lójú rẹ,+ àmọ́ ní ọjọ́ àjálù, fiyè sí i pé Ọlọ́run ti ṣe àkọ́kọ́ àti èkejì,+ kí aráyé má bàa lè sọ ní pàtó* ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́jọ́ iwájú.+
15 Ohun gbogbo ni mo ti rí ní gbogbo ìgbé ayé asán mi,+ látorí olódodo tó ṣègbé nínú òdodo rẹ̀,+ dórí ẹni burúkú tó pẹ́ láyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà burúkú ló ń hù.+
16 Má ṣe òdodo àṣelékè,+ bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe gbọ́n ní àgbọ́njù.+ Àbí o fẹ́ pa ara rẹ ni?+ 17 Má sọ ìwà burúkú dàṣà, má sì ya òmùgọ̀.+ Ṣé ó yẹ kí o kú láìtọ́jọ́ ni?+ 18 Ó sàn kéèyàn gba ìkìlọ̀ àkọ́kọ́, kó má sì jẹ́ kí èkejì bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́;+ nítorí ẹni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run yóò pa méjèèjì mọ́.
19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n lágbára ju akíkanjú ọkùnrin mẹ́wàá tó ń ṣọ́ ìlú.+ 20 Nítorí kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.+
21 Bákan náà, má ṣe máa fọkàn sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn bá sọ;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè gbọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ń bú* ọ; 22 torí o mọ̀ lọ́kàn rẹ dáadáa pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti bú àwọn míì.+
23 Gbogbo èyí ni mo ti fi ọgbọ́n dán wò, mo sì sọ pé: “Màá di ọlọ́gbọ́n.” Àmọ́, ó kọjá agbára mi. 24 Ohun tó ti wà, ọwọ́ ò lè tó o, ó sì jinlẹ̀ gidigidi. Ta ló lè lóye rẹ̀?+ 25 Mo darí ọkàn mi kí n lè mọ̀, kí n lè wádìí, kí n sì lè wá ọgbọ́n àti ohun tó ń fa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, mo sì darí rẹ̀ kí n lè lóye aburú tó wà nínú ìwà ẹ̀gọ̀ àti àìlọ́gbọ́n tó wà nínú ìwà wèrè.+ 26 Mo wá rí i pé: Ohun tó korò ju ikú lọ ni obìnrin tó dà bí àwọ̀n ọlọ́dẹ, tí ọkàn rẹ̀ dà bí àwọ̀n ńlá, tí ọwọ́ rẹ̀ sì dà bíi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ á bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀,+ àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ á kó sọ́wọ́ rẹ̀.+
27 Akónijọ+ sọ pé, “Wò ó! èyí ni mo ti rí. Mo gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan kí n lè mọ ibi tí màá parí èrò sí, 28 àmọ́ mi* ò tíì rí ohun tí mò ń fi ìgbà gbogbo wá. Mo rí ọkùnrin kan* nínú ẹgbẹ̀rún, àmọ́ mi ò tíì rí obìnrin kan nínú wọn. 29 Èyí nìkan ṣoṣo ni mo ti rí pé: Ọlọ́run tòótọ́ dá aráyé ní adúróṣinṣin,+ àmọ́ wọ́n ti wá ọ̀pọ̀ ètekéte.”+
8 Ta ló dà bí ọlọ́gbọ́n? Ta ló mọ ojútùú ìṣòro?* Ọgbọ́n tí èèyàn ní máa ń mú kí ojú rẹ̀ dán, ó sì máa ń mú kí ojú rẹ̀ tó le rọ̀.
2 Mo ní: “Pa àṣẹ ọba mọ́+ nítorí o ti búra níwájú Ọlọ́run.+ 3 Má ṣe yára kúrò níwájú rẹ̀.+ Má ṣe lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó burú;+ torí ohun tó bá wù ú ló lè ṣe, 4 nítorí ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé;+ ta ló sì lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’”
5 Ẹni tó ń pa àṣẹ mọ́ kò ní rí ibi,+ ọkàn ọlọ́gbọ́n á sì mọ àkókò àti ọ̀nà tó yẹ láti gbà ṣe nǹkan.*+ 6 Gbogbo ọ̀ràn ló ní àkókò àti ọ̀nà tó yẹ kéèyàn gbà ṣe é,*+ torí wàhálà aráyé pọ̀ gan-an. 7 Nítorí kò sẹ́ni tó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ta ló lè sọ bó ṣe máa ṣẹlẹ̀ fún un?
8 Bí kò ṣe sí èèyàn tó lágbára lórí ẹ̀mí* tàbí tó lè dá ẹ̀mí dúró, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó lágbára lórí ọjọ́ ikú.+ Bí ẹnikẹ́ni kò ṣe lè dá ara rẹ̀ sílẹ̀ lójú ogun, bẹ́ẹ̀ ni ìwà burúkú kò ní jẹ́ kí àwọn tó ń hù ú yè bọ́.*
9 Gbogbo èyí ni mo ti rí, mo sì fọkàn sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,* ní àkókò tí èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára* rẹ̀.+ 10 Mo tún rí i tí wọ́n ń sìnkú àwọn ẹni burúkú, àwọn tó máa ń wọlé, tí wọ́n sì ń jáde ní ibi mímọ́, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi gbàgbé wọn ní ìlú tí wọ́n ti hu irú ìwà yìí.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.
11 Nítorí pé a kò tètè mú ìdájọ́ ṣẹ lórí ìwà burúkú,+ ọkàn àwọn èèyàn le gbagidi láti ṣe búburú.+ 12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lè ṣe búburú ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, kó sì pẹ́ láyé, síbẹ̀ mo mọ̀ pé ó máa dára fún àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.+ 13 Àmọ́ kò ní dára fún ẹni burúkú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò lè mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ tó dà bí òjìji gùn,+ nítorí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.
14 Ohun kan wà tó jẹ́ asán* tó ń ṣẹlẹ̀ láyé: Àwọn olódodo wà tí aráyé ń hùwà sí bíi pé wọ́n ti ṣe ibi,+ àwọn ẹni burúkú sì wà tí aráyé ń hùwà sí bíi pé wọ́n ti ṣe rere.+ Mo sọ pé asán ni èyí pẹ̀lú.
15 Nítorí náà, ìmọ̀ràn mi ni pé kéèyàn máa yọ̀,+ torí kò sí ohun tó dára fún èèyàn lábẹ́ ọ̀run* ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì máa yọ̀; kí inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe ń ṣiṣẹ́ àṣekára ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un lábẹ́ ọ̀run.
16 Mo fi ọkàn mi sí mímọ ọgbọ́n àti sí rírí gbogbo ohun* tó ń lọ nínú ayé,+ kódà mi ò fojú ba oorun* ní ọ̀sán tàbí ní òru. 17 Mo wá wo gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì rí i pé aráyé kò lè lóye ohun tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.*+ Bó ti wù kí aráyé sapá tó, kò lè yé wọn. Kódà, tí wọ́n bá sọ pé ọgbọ́n àwọn gbé e láti mọ̀ ọ́n, wọn ò lè lóye rẹ̀ ní ti gidi.+
9 Nítorí náà, mo fọkàn sí gbogbo èyí, mo sì gbà pé ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni àwọn olódodo àti àwọn ọlọ́gbọ́n wà pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.+ Àwọn èèyàn kò mọ ìfẹ́ àti ìkórìíra tó ti wà ṣáájú wọn. 2 Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn* gbogbo wọn,+ àti olódodo àti ẹni burúkú,+ ẹni rere pẹ̀lú ẹni tó mọ́ àti ẹni tí ò mọ́, àwọn tó ń rúbọ àti àwọn tí kì í rúbọ. Ìkan náà ni ẹni rere àti ẹlẹ́ṣẹ̀; bákan náà ni ẹni tó búra rí pẹ̀lú ẹni tó ń bẹ̀rù láti búra. 3 Ohun kan ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* tó ń kó ìdààmú báni: Nítorí ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn,+ aburú ló kún ọkàn àwọn ọmọ èèyàn; ìwà wèrè wà lọ́kàn wọn ní ọjọ́ ayé wọn, lẹ́yìn náà wọ́n á kú!*
4 Ìrètí wà fún ẹni tó bá ṣì wà láàyè, nítorí ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.+ 5 Nítorí àwọn alààyè mọ̀* pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè* kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+ 6 Bákan náà, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn pẹ̀lú owú wọn ti ṣègbé, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ nínú ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+
7 Máa lọ, máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, kí o sì máa fi ìdùnnú mu wáìnì rẹ,+ nítorí inú Ọlọ́run tòótọ́ ti dùn sí àwọn iṣẹ́ rẹ.+ 8 Kí aṣọ rẹ máa funfun* ní gbogbo ìgbà, kí o sì máa fi òróró pa orí rẹ.+ 9 Máa gbádùn ayé rẹ pẹ̀lú aya rẹ ọ̀wọ́n+ ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, tí Ó fún ọ lábẹ́ ọ̀run,* ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, torí ìyẹn ni ìpín rẹ nígbèésí ayé àti nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ, èyí tí ò ń fi gbogbo agbára rẹ ṣe lábẹ́ ọ̀run.+ 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ.
11 Mo tún ti rí nǹkan míì lábẹ́ ọ̀run,* pé ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́gbọ́n kì í fìgbà gbogbo rí oúnjẹ jẹ, ìgbà gbogbo kọ́ sì ni àwọn olórí pípé máa ń ní ọrọ̀,+ bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí,+ nítorí ìgbà àti èèṣì* ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. 12 Èèyàn kò mọ ìgbà tirẹ̀.+ Bí ẹja ṣe ń kó sínú àwọ̀n ikú, tí àwọn ẹyẹ sì ń kó sínú pańpẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èèyàn ṣe ń kó sínú ìdẹkùn ní àkókò àjálù, nígbà tó bá dé bá wọn lójijì.
13 Mo tún kíyè sí nǹkan kan nípa ọgbọ́n lábẹ́ ọ̀run,* ó sì wú mi lórí: 14 Ìlú kékeré kan wà tí èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí; ọba alágbára kan wá gbéjà kò ó, ó yí i ká, ó sì ṣe àwọn nǹkan ńlá tí á fi gbógun ti ìlú náà. 15 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó ní ọgbọ́n, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ gba ìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sẹ́ni tó rántí ọkùnrin aláìní náà.+ 16 Mo wá sọ fún ara mi pé: ‘Ọgbọ́n sàn ju agbára lọ;+ síbẹ̀ àwọn èèyàn kì í ka ọgbọ́n aláìní sí, wọn kì í sì í ṣe ohun tó bá sọ.’+
17 Ó sàn kéèyàn tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ọlọ́gbọ́n sọ ju kéèyàn máa fetí sí ariwo ẹni tó ń ṣàkóso láàárín àwọn òmùgọ̀.
18 Ọgbọ́n sàn ju àwọn ohun ìjà ogun lọ, àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ṣoṣo lè ba ọ̀pọ̀ ohun rere jẹ́.+
10 Bí òkú eṣinṣin ṣe ń ba òróró ẹni tó ń ṣe lọ́fínńdà jẹ́, tí á sì máa rùn, bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń ba ọgbọ́n àti ògo jẹ́.+
2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí ó tọ́,* àmọ́ ọkàn òmùgọ̀ máa ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí kò tọ́.*+ 3 Ibikíbi tí òmùgọ̀ bá rìn sí, kò ní lo làákàyè,*+ ó sì máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé òmùgọ̀ ni òun.+
4 Tí inú* alákòóso bá ru sí ọ, má ṣe kúrò níbi tí o wà,+ torí pé ìwà pẹ̀lẹ́ ń pẹ̀tù sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.+
5 Ohun kan wà tó ń kó ìdààmú báni tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run,* àṣìṣe tí àwọn tí agbára wà lọ́wọ́ wọn ń ṣe:+ 6 Àwọn òmùgọ̀ ló ń wà ní ọ̀pọ̀ ipò gíga, àmọ́ àwọn tó dáńgájíá* kì í kúrò ní ipò tó rẹlẹ̀.
7 Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àmọ́ tí àwọn olórí ń fẹsẹ̀ rìn bí ìránṣẹ́.+
8 Ẹni tó ń gbẹ́ kòtò lè já sínú rẹ̀;+ ẹni tó sì ń wó ògiri olókùúta, ejò lè bù ú ṣán.
9 Ẹni tó ń gbẹ́ òkúta, òkúta náà lè ṣe é léṣe, ẹni tó sì ń la gẹdú, gẹdú náà lè ṣe é ní jàǹbá.*
10 Tí irinṣẹ́ kan kò bá mú, tí ẹni tó fẹ́ lò ó kò sì pọ́n ọn, ó máa ní láti lo agbára tó pọ̀ gan-an. Àmọ́ ọgbọ́n ń mú kéèyàn ṣe àṣeyọrí.
11 Tí ejò bá buni ṣán kí wọ́n tó tù ú lójú, kí làǹfààní atujú tó gbówọ́.*
12 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n ń mú ire wá,+ àmọ́ ètè òmùgọ̀ ń fa ìparun rẹ̀.+ 13 Ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ jáde lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀,+ èyí tó sì sọ gbẹ̀yìn jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè tó ń ṣekú pani. 14 Síbẹ̀, ńṣe ni òmùgọ̀ á máa sọ̀rọ̀ lọ.+
Èèyàn ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀; ta ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un?+
15 Iṣẹ́ àṣekára òmùgọ̀ ń tán an lókun, torí kò tiẹ̀ mọ bó ṣe máa rí ọ̀nà tó máa gbà lọ sínú ìlú.
16 Ẹ wo bó ṣe máa burú tó fún ilẹ̀ kan tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọdékùnrin,+ tí àwọn ìjòyè rẹ̀ sì máa ń bẹ̀rẹ̀ àsè wọn ní àárọ̀! 17 Ẹ wo bó ṣe máa jẹ́ ohun ayọ̀ tó fún ilẹ̀ náà, tí ọba rẹ̀ bá jẹ́ ọmọ èèyàn pàtàkì, tí àwọn ìjòyè rẹ̀ sì ń jẹun ní àkókò tí ó tọ́ kí wọ́n lè lágbára, kì í ṣe kí wọ́n lè mutí yó!+
18 Ìwà ọ̀lẹ tó lé kenkà ló ń mú kí igi àjà tẹ̀, ọwọ́ tó dilẹ̀ sì ló ń mú kí ilé jò.+
19 Oúnjẹ* wà fún ẹ̀rín, wáìnì sì ń mú kí èèyàn gbádùn ayé;+ àmọ́ owó la fi ń ṣe ohun gbogbo tí a nílò.+
20 Kódà nínú èrò rẹ,* má ṣe bú* ọba,+ má sì bú olówó nínú yàrá rẹ; torí pé ẹyẹ kan* lè gbé ọ̀rọ̀* náà tàbí kí ohun tó ní ìyẹ́ tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ.
11 Fọ́n* oúnjẹ rẹ sí ojú omi,+ torí pé lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, wàá tún rí i.+ 2 Pín in fún àwọn méje tàbí mẹ́jọ pàápàá,+ nítorí o kò mọ àjálù tó máa dé bá ayé.
3 Tí òjò bá ṣú lójú ọ̀run, á rọ̀ sórí ilẹ̀; tí igi kan bá sì ṣubú sí gúúsù tàbí sí àríwá, ibi tí igi náà ṣubú sí, ibẹ̀ ló máa wà.
4 Ẹni tó bá ń wojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn; ẹni tó bá sì ń wo ṣíṣú òjò kò ní kórè.+
5 Bí o ò ṣe mọ bí ẹ̀mí ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú egungun ọmọ tó wà nínú* aboyún,+ bẹ́ẹ̀ lo ò ṣe mọ iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó ń ṣe ohun gbogbo.+
6 Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́;+ nítorí o ò mọ èyí tó máa ṣe dáadáa, bóyá èyí tàbí ìyẹn, ó sì lè jẹ́ àwọn méjèèjì ló máa ṣe dáadáa.
7 Ìmọ́lẹ̀ dùn, ó sì dára kí ojú rí oòrùn. 8 Tí èèyàn bá lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé, kí ó gbádùn gbogbo rẹ̀.+ Àmọ́, ó yẹ kó máa rántí pé àwọn ọjọ́ òkùnkùn lè pọ̀, asán sì ni gbogbo ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.+
9 Máa yọ̀, ìwọ ọ̀dọ́kùnrin, nígbà tí o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa yọ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ. Máa ṣe ohun tí ọkàn rẹ bá sọ, sì máa lọ síbi tí ojú rẹ bá darí rẹ sí; ṣùgbọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ máa dá ọ lẹ́jọ́* lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+ 10 Nítorí náà, mú àwọn ohun tó ń kó ìdààmú báni kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì gbá àwọn ohun tó ń ṣeni léṣe dà nù ní ara* rẹ, torí pé asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀dọ́.+
12 Nítorí náà, rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ,+ kí àwọn ọjọ́ wàhálà* tó dé,+ kí àwọn ọdún náà tó dé nígbà tí wàá sọ pé: “Wọn ò mú inú mi dùn”; 2 kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,+ tí ojú ọ̀run á sì tún ṣú lẹ́yìn tí òjò ti rọ̀;* 3 ní ọjọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́* ilé ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,* tí àwọn ọkùnrin alágbára sì tẹ̀, tí àwọn obìnrin tó ń lọ nǹkan dáwọ́ dúró nítorí pé wọn ò pọ̀ mọ́, tí àwọn ọmọge tó ń wo ìta lójú fèrèsé* sì rí i pé òkùnkùn ṣú;+ 4 nígbà tí àwọn ilẹ̀kùn tó jáde sí ojú ọ̀nà ti wà ní títì, nígbà tí ìró ọlọ ti lọ sílẹ̀, nígbà tí èèyàn á jí nítorí ìró ẹyẹ, tí ohùn gbogbo àwọn ọmọbìnrin tó ń kọrin kò sì dún sókè mọ́.+ 5 Bákan náà, èèyàn á máa bẹ̀rù ibi tó ga, ẹ̀rù á sì wà lójú ọ̀nà. Igi álímọ́ńdì ń yọ ìtànná,+ tata ń wọ́ ara rẹ̀ lọ, àgbáyun kápérì sì bẹ́, torí pé èèyàn ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé,+ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ sì ń rìn kiri ní ojú ọ̀nà;+ 6 kí okùn fàdákà tó yọ, kí àwo wúrà tó fọ́ sí wẹ́wẹ́, kí ìṣà tó wà níbi ìsun omi tó fọ́, kí kẹ̀kẹ́ ìfami tó wà níbi kòtò omi tó kán. 7 Nígbà náà, erùpẹ̀ á pa dà sí ilẹ̀,+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀mí* á sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fúnni.+
8 “Asán* pátápátá gbáà!” ni akónijọ+ wí. “Asán ni gbogbo rẹ̀.”+
9 Kì í ṣe pé akónijọ di ọlọ́gbọ́n nìkan ni, ó tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó mọ̀,+ ó ronú jinlẹ̀, ó sì wádìí fínnífínní, kí ó lè kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ.*+ 10 Akónijọ wá bó ṣe máa rí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára,+ kó sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́.
11 Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù,+ àkójọ ọ̀rọ̀ wọn sì dà bí ìṣó tó wọlé ṣinṣin; ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni wọ́n ti wá. 12 Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan yìí, ọmọ mi, ṣọ́ra: Kò sí òpin nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, fífi àkókò tó pọ̀ jù kà wọ́n sì ń kó àárẹ̀ bá ara.+
13 Òpin ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́,+ kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe èèyàn.+ 14 Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lórí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, títí kan gbogbo ohun tó fara pa mọ́, bóyá ó dára tàbí ó burú.+
Tàbí “apenijọ.”
Tàbí “Òtúbáńtẹ́.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn?”
Ní Héb.,“dúró.”
Tàbí “tan ìmọ́lẹ̀.”
Tàbí “sáré tete.”
Tàbí “odò ìgbà òtútù; odò abágbàrìn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “ìwà òmùgọ̀ tó burú jáì.”
Tàbí “ìdùnnú.”
Tàbí “ìdùnnú.”
Tàbí “igbó.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ilé.”
Tàbí “dúkìá tó jẹ́ ti.”
Tàbí “ọmọge, àní àwọn ọmọge.”
Ní Héb., “tí ojú mi béèrè.”
Tàbí “ìdùnnú.”
Tàbí “ìpín.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “ohun tó ṣàǹfààní.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “Ọlọ́gbọ́n la ojú rẹ̀ sílẹ̀.”
Tàbí “àtúbọ̀tán.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “gbogbo rẹ̀.”
Tàbí “àjálù.”
Ní Héb., “bí ọkàn rẹ̀ ṣe ń sapá.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ rí ohun rere nínú.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Ní Héb., “fífò sókè; títa pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.”
Tàbí “létòlétò; lọ́nà tó yẹ; lọ́nà tó bá a mu.”
Tàbí kó jẹ́, “ohun tó ti kọjá lọ.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “àtúbọ̀tán.”
Tàbí “ìpín.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “ṣiṣẹ́ kára.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Ní Héb., “ó ń jẹ ẹran ara rẹ̀.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “èrè púpọ̀.”
Ìyẹn, alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.
Tàbí “kò rọrùn láti.”
Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ọlọ́gbọ́n ọmọ náà.
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “àníyàn.”
Ní Héb., “ara rẹ.”
Tàbí “òjíṣẹ́.”
Tàbí “Àjálù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “iṣẹ́.”
Tàbí “àjálù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “ìpín.”
Tàbí “ìpín.”
Tàbí “rántí.”
Tàbí “Àjálù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “kí ibojì tó jẹ́ tirẹ̀.”
Ní Héb., “ní ìsinmi.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀ kì í.”
Ní Héb., “máa rìn níwájú àwọn alààyè.”
Tàbí “kí ọkàn rẹ̀ máa rìn káàkiri.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “gbèjà ara rẹ̀ níwájú ẹni tó lágbára jù ú lọ.”
Tàbí kó jẹ́, “nǹkan.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “Orúkọ.”
Tàbí “ìgbádùn.”
Ní Héb., “kánjú ní ẹ̀mí láti.”
Tàbí kó jẹ́, “ìbínú ni àmì àwọn òmùgọ̀.”
Ìyẹn, àwọn tó wà láàyè.
Tàbí “ṣàwárí.”
Ní Héb., “ṣépè fún.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkùnrin kan tó jẹ́ adúróṣinṣin.”
Tàbí “ìtúmọ̀ ọ̀ràn.”
Tàbí “ìdájọ́.”
Tàbí “ìdájọ́.”
Tàbí “èémí; afẹ́fẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “ìwà burúkú kò lè gba ẹni burúkú sílẹ̀.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “ìṣeléṣe; àdánù.”
Tàbí “tó ń tojú súni.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “iṣẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn èèyàn ò sùn.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “Àtúbọ̀tán kan náà ló wà fún.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “àtúbọ̀tán.”
Ní Héb., “lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ àwọn òkú yá!”
Tàbí “mọ̀ dáadáa.”
Tàbí “owó iṣẹ́.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ìyẹn, aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn tó fi hàn pé inú èèyàn ń dùn, kì í ṣe aṣọ ọ̀fọ̀.
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Ní Héb., “wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.”
Ní Héb., “wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.”
Ní Héb., “ọkàn á kù fún un.”
Ní Héb., “ẹ̀mí; èémí.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “àwọn ọlọ́rọ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “yẹ kó ṣọ́ra pẹ̀lú rẹ̀.”
Ní Héb., “ẹni tó láṣẹ ní ahọ́n.”
Ní Héb., “Búrẹ́dì.”
Tàbí kó jẹ́, “lórí ibùsùn rẹ.”
Tàbí “ṣépè fún.”
Ní Héb., “ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run.”
Tàbí “iṣẹ́.”
Tàbí “Da.”
Ní Héb., “egungun tó wà nínú ilé ọlẹ̀.”
Tàbí “pè ọ́ wá jíhìn.”
Ní Héb., “ẹran ara.”
Tàbí “àjálù.”
Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú òjò tó ń rọ̀.”
Tàbí “àwọn olùtọ́jú.”
Tàbí “wárìrì.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “ohun tó mú kí ẹ̀dá wà láàyè.”
Tàbí “Òtúbáńtẹ́.”
Tàbí “to ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ lẹ́sẹẹsẹ.”