11 Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti ṣe àti gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti sapá láti ṣe yọrí,+ mo rí i pé asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo;*+ kò sí ohun gidi kan* lábẹ́ ọ̀run.*+
27 Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun,+ èyí tí Ọmọ èèyàn máa fún yín; torí pé Baba, ìyẹn Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ti gbé èdìdì ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ lé ẹni yìí.”+