ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Òwe 1:1-31:31
  • Òwe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òwe
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Òwe

ÒWE

1 Òwe Sólómọ́nì,+ ọmọ Dáfídì,+ ọba Ísírẹ́lì:+

 2 Láti kọ́* ọgbọ́n+ àti ìbáwí;

Láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n;

 3 Láti gba ìbáwí+ tó ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye,

Òdodo,+ ìdájọ́ òdodo*+ àti ìdúróṣinṣin;*

 4 Láti mú kí àwọn aláìmọ̀kan ní àròjinlẹ̀;+

Láti mú kí ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti làákàyè.+

 5 Ọlọ́gbọ́n máa ń fetí sílẹ̀, á sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i;+

Olóye máa ń gba ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n+

 6 Láti lóye òwe àti ọ̀rọ̀ tó díjú,*

Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àlọ́ wọn.+

 7 Ìbẹ̀rù* Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀.+

Àwọn òmùgọ̀ ni kì í ka ọgbọ́n àti ìbáwí sí.+

 8 Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ,+

Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+

 9 Wọ́n dà bí adé ẹwà fún orí rẹ+

Àti ohun ọ̀ṣọ́ tó rẹwà fún ọrùn rẹ.+

10 Ọmọ mi, tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá fẹ́ fa ojú rẹ mọ́ra, má gbà.+

11 Tí wọ́n bá sọ pé: “Jẹ́ ká lọ.

Ká lọ lúgọ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

Àá fara pa mọ́, àá sì dúró de àwọn aláìṣẹ̀ tó máa kó sọ́wọ́ wa.

12 A máa gbé wọn mì láàyè bí Isà Òkú* ti ń ṣe,

Lódindi, bí àwọn tó ń lọ sínú kòtò.

13 Jẹ́ ká gba gbogbo ìṣúra wọn tó ṣeyebíye;

Àá fi ẹrù tí a bá gbà kún ilé wa.

14 Dara pọ̀ mọ́ wa,*

Àá sì jọ pín ohun tí a bá jí lọ́gbọọgba.”*

15 Ọmọ mi, má tẹ̀ lé wọn.

Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ jìnnà sí ọ̀nà wọn,+

16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ láti ṣe ibi;

Wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+

17 Asán ni téèyàn bá ta àwọ̀n sílẹ̀ níṣojú ẹyẹ.

18 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lúgọ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀;

Wọ́n fara pa mọ́ láti gba ẹ̀mí* àwọn ẹlòmíì.

19 Báyìí ni ọ̀nà àwọn tó ń wá èrè tí kò tọ́,

Tó máa gba ẹ̀mí* àwọn tó ń kó o jọ.+

20 Ọgbọ́n tòótọ́+ ń ké jáde ní ojú ọ̀nà.+

Ó ń gbé ohùn rẹ̀ sókè ní àwọn ojúde ìlú.+

21 Ó ké jáde ní igun* ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà.

Ní àtiwọ àwọn ẹnubodè ìlú, ó ń sọ pé:+

22 “Ìgbà wo ni ẹ̀yin aláìmọ̀kan máa jáwọ́ nínú àìmọ̀kan yín?

Ìgbà wo ni ẹ̀yin afiniṣẹ̀sín máa gbádùn fífini ṣẹ̀sín dà?

Ìgbà wo sì ni ẹ̀yin òmùgọ̀ máa kórìíra ìmọ̀ dà?+

23 Gba ìbáwí mi.*+

Nígbà náà, màá tú ẹ̀mí mi jáde fún yín;

Màá jẹ́ kí ẹ mọ àwọn ọ̀rọ̀ mi.+

24 Nítorí mò ń pè, àmọ́ ẹ ò dáhùn,

Mo na ọwọ́ mi jáde, àmọ́ kò sẹ́ni tó fiyè sí i,+

25 Ẹ kì í ka gbogbo ìmọ̀ràn mi sí

Ẹ kì í sì í gba ìbáwí mi,

26 Èmi náà á rẹ́rìn-ín nígbà tí àjálù bá dé bá yín;

Màá fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù bá dé,+

27 Nígbà tí ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù bá dé bí ìjì,

Tí àjálù yín sì dé bí ìjì líle,

Nígbà tí ìdààmú àti wàhálà bá dé bá yín.

28 Ní àkókò yẹn, wọ́n á máa pè mí, àmọ́ mi ò ní dáhùn;

Wọ́n á máa fi ìtara wá mi, àmọ́ wọn ò ní rí mi,+

29 Torí wọ́n kórìíra ìmọ̀,+

Wọn ò sì bẹ̀rù Jèhófà.+

30 Wọn ò gba ìmọ̀ràn mi;

Wọn ò ka gbogbo ìbáwí mi sí.

31 Torí náà, wọ́n á jìyà* ọ̀nà tí wọ́n yàn,+

Ìmọ̀ràn* wọn á sì yí dà lé wọn lórí.

32 Nítorí ìwà àìníjàánu àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n,

Àìka-nǹkan-sí àwọn òmùgọ̀ ni yóò sì pa wọ́n run.

33 Àmọ́ ẹni tó ń fetí sí mi á máa gbé lábẹ́ ààbò+

Ìbẹ̀rù àjálù kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu.”+

2 Ọmọ mi, tí o bá gba àwọn ọ̀rọ̀ mi

Tí o sì fi àwọn àṣẹ mi ṣe ìṣúra rẹ,+

 2 Nípa fífi etí sí ọgbọ́n+

Àti fífi ọkàn sí ìfòyemọ̀;+

 3 Bákan náà, tí o bá ké pe òye+

Tí o sì nahùn pe ìfòyemọ̀;+

 4 Tí o bá ń wá a bíi fàdákà,+

Tí o sì ń wá a kiri bí àwọn ìṣúra tó fara sin;+

 5 Nígbà náà, wàá lóye ìbẹ̀rù Jèhófà,+

Wàá sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.+

 6 Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n;+

Ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.

 7 Ó ń to ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣinṣin;

Ó jẹ́ apata fún àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́.+

 8 Ó ń pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́,

Ó sì ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin rẹ̀.+

 9 Nígbà náà, wàá lóye ohun tó jẹ́ òdodo àti ẹ̀tọ́ àti àìṣègbè,

Gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere.+

10 Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn rẹ+

Tí ìmọ̀ sì tù ọ́ lára,*+

11 Làákàyè yóò máa ṣọ́ ọ,+

Ìfòyemọ̀ yóò sì máa dáàbò bò ọ́,

12 Láti gbà ọ́ kúrò ní ọ̀nà búburú,

Kúrò lọ́wọ́ ẹni tó ń sọ ọ̀rọ̀ àyídáyidà,+

13 Kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ọ̀nà òdodo* sílẹ̀

Kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀nà òkùnkùn,+

14 Kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ìwà àìtọ́ ṣayọ̀,

Àwọn tí ìwà tó burú jáì ń múnú wọn dùn,

15 Àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́

Tí gbogbo ọ̀nà wọn sì jẹ́ békebèke.

16 Yóò dáàbò bò ọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin oníwàkiwà,*

Kúrò lọ́wọ́ ọ̀rọ̀ dídùn* obìnrin oníṣekúṣe,*+

17 Ẹni tó fi ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́* ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀+

Tó sì gbàgbé májẹ̀mú Ọlọ́run rẹ̀;

18 Nítorí ilé rẹ̀ ń rini sínú ikú,

Àwọn ọ̀nà* rẹ̀ sì lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ikú ti pa.*+

19 Kò sí ìkankan lára àwọn tó ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú rẹ̀* tó máa pa dà,

Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní pa dà sí ọ̀nà ìyè.+

20 Torí náà, máa gba ọ̀nà àwọn ẹni rere

Má sì kúrò ní ọ̀nà àwọn olódodo,+

21 Nítorí àwọn adúróṣinṣin ló máa gbé ní ayé,

Àwọn aláìlẹ́bi* ló sì máa ṣẹ́ kù sínú rẹ̀.+

22 Ní ti àwọn ẹni burúkú, a ó pa wọ́n run kúrò ní ayé,+

Ní ti àwọn oníbékebèke, a ó fà wọ́n tu kúrò nínú rẹ̀.+

3 Ọmọ mi, má gbàgbé ẹ̀kọ́* mi,

Sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́,

 2 Nítorí wọ́n á fi ọ̀pọ̀ ọjọ́

Àti ẹ̀mí gígùn pẹ̀lú àlàáfíà kún un fún ọ.+

 3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́* fi ọ́ sílẹ̀.+

So wọ́n mọ́ ọrùn rẹ;

Kọ wọ́n sí wàláà ọkàn rẹ;+

 4 Nígbà náà, wàá rí ojú rere àti òye tó jinlẹ̀ gan-an

Lójú Ọlọ́run àti èèyàn.+

 5 Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+

Má sì gbára lé òye tìrẹ.+

 6 Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ,+

Á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.+

 7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ.+

Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yẹra fún ibi.

 8 Yóò jẹ́ ìwòsàn fún ara* rẹ

Àti ìtura fún egungun rẹ.

 9 Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà,+

Pẹ̀lú àkọ́so* gbogbo irè oko rẹ;*+

10 Nígbà náà, àwọn ilé ìkẹ́rùsí rẹ á kún fọ́fọ́,+

Wáìnì tuntun á sì kún àwọn ẹkù* rẹ ní àkúnwọ́sílẹ̀.

11 Ọmọ mi, má ṣe kọ ìbáwí Jèhófà,+

Má sì kórìíra ìtọ́sọ́nà rẹ̀,+

12 Torí pé àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí,+

Bí bàbá ṣe máa ń fún ọmọ tí inú rẹ̀ dùn sí ní ìbáwí.+

13 Aláyọ̀ ni ẹni tó wá ọgbọ́n rí+

Àti ẹni tó ní òye;

14 Kéèyàn ní in sàn ju kéèyàn ní fàdákà,

Kéèyàn jèrè rẹ̀ sì sàn ju kéèyàn jèrè wúrà.+

15 Ó ṣeyebíye ju iyùn* lọ;

Kò sí ohun míì tí o fẹ́ tó ṣeé fi wé e.

16 Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;

Ọrọ̀ àti ògo sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.

17 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ gbádùn mọ́ni,

Àlàáfíà sì wà ní gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+

18 Igi ìyè ni fún àwọn tó dì í mú,

Aláyọ̀ ni a ó sì máa pe àwọn tó dì í mú ṣinṣin.+

19 Ọgbọ́n ni Jèhófà fi dá ayé.+

Òye ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in.+

20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni àwọn ibú omi fi pínyà

Tí ìkùukùu ojú sánmà sì ń mú kí ìrì sẹ̀.+

21 Ọmọ mi, máa fi wọ́n* sọ́kàn.

Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́;

22 Wọ́n á fún ọ* ní ìyè

Wọ́n á sì jẹ́ ọ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ;

23 Nígbà náà, wàá máa rìn láìséwu ní ọ̀nà rẹ,

Ẹsẹ̀ rẹ kò sì ní kọ́* ohunkóhun.+

24 Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, ẹ̀rù ò ní bà ọ́;+

Wàá sùn, oorun rẹ á sì dùn mọ́ ọ.+

25 O ò ní bẹ̀rù àjálù òjijì+

Tàbí ìjì tó ń bọ̀ lórí àwọn ẹni burúkú.+

26 Nítorí Jèhófà yóò jẹ́ ìgbọ́kànlé rẹ;+

Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kó sí pańpẹ́.+

27 Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún*+

Tó bá wà níkàáwọ́ rẹ* láti ṣe é.+

28 Má sọ fún ọmọnìkejì rẹ pé, “Máa lọ ná, tó bá dọ̀la kí o pa dà wá, màá fún ọ,”

Nígbà tí o lè fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

29 Má gbèrò ibi sí ọmọnìkejì rẹ+

Nígbà tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ pé kò séwu.

30 Má ṣe bá ẹnì kankan jà láìnídìí+

Nígbà tí kò ṣe aburú kankan sí ọ.+

31 Má ṣe jowú ẹni tó ń hùwà ipá+

Má sì yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀,

32 Nítorí Jèhófà kórìíra oníbékebèke,+

Ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.+

33 Ègún Jèhófà wà lórí ilé ẹni burúkú,+

Àmọ́, ó ń bù kún ilé àwọn olódodo.+

34 Ó ń fi àwọn afiniṣẹ̀sín ṣe ẹlẹ́yà,+

Àmọ́, ó ń ṣojú rere sí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+

35 Àwọn ọlọ́gbọ́n á jogún ọlá,

Àmọ́, ẹ̀tẹ́ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣayọ̀.+

4 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí ìbáwí bàbá;+

Ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ lè ní òye,

 2 Nítorí màá fún yín ní ìtọ́ni rere;

Ẹ má ṣe pa ẹ̀kọ́* mi tì.+

 3 Ọmọ gidi ni mo jẹ́ fún bàbá mi+

Ìyá mi sì fẹ́ràn mi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.+

 4 Bàbá mi kọ́ mi, ó sì sọ pé: “Kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wà lọ́kàn rẹ digbí.+

Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa wà láàyè.+

 5 Ní ọgbọ́n, ní òye.+

Má gbàgbé, má sì kúrò nínú ohun tí mo sọ.

 6 Má pa á tì, yóò dáàbò bò ọ́.

Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́.

 7 Ọgbọ́n ni ohun tó ṣe pàtàkì* jù lọ,+ torí náà ní ọgbọ́n,

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.+

 8 Jẹ́ kó níyì gan-an lójú rẹ, yóò sì gbé ọ ga.+

Yóò bọlá fún ọ nítorí pé o gbá a mọ́ra.+

 9 Yóò fi òdòdó ẹ̀yẹ tó fani mọ́ra sí ọ lórí;

Yóò sì dé ọ ní adé ẹwà.”

10 Ọmọ mi, fetí sílẹ̀, kí o sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi,

Ọdún tí o máa fi wà láàyè yóò sì pọ̀.+

11 Màá kọ́ ọ ní ọ̀nà ọgbọ́n;+

Màá darí rẹ ní ipa ọ̀nà òdodo.*+

12 Nígbà tí o bá ń rìn, ẹsẹ̀ rẹ kò ní kọ́lẹ̀;

Tí o bá sì ń sáré, o ò ní kọsẹ̀.

13 Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kó lọ.+

Pa á mọ́, nítorí òun ni ẹ̀mí rẹ.+

14 Má ṣe gba ọ̀nà àwọn ẹni burúkú,

Má sì rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.+

15 Yẹra fún un, má gba ibẹ̀ kọjá;+

Má gbabẹ̀, máa bá tìẹ lọ.+

16 Torí wọn ò lè sùn àfi tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa.

Wọn kì í rí oorun sùn àfi tí wọ́n bá mú kí ẹnì kan ṣubú.

17 Oúnjẹ ìwà burúkú ni wọ́n fi ń bọ́ ara wọn,

Wáìnì ìwà ipá ni wọ́n sì ń mu.

18 Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀

Tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.+

19 Ọ̀nà àwọn ẹni burúkú dà bí òkùnkùn;

Wọn ò mọ ohun tó ń mú wọn kọsẹ̀.

20 Ọmọ mi, fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi;

Fetí sílẹ̀ dáadáa* sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

21 Máa fi wọ́n sọ́kàn;

Jẹ́ kí wọ́n jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ,+

22 Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tó wá wọn rí+

Wọ́n sì jẹ́ ìlera fún gbogbo ara* wọn.

23 Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ,+

Nítorí inú rẹ̀ ni àwọn ohun tó ń fúnni ní ìyè ti ń wá.

24 Mú èké ọ̀rọ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+

Sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ békebèke jìnnà sí ọ.

25 Ọ̀ọ́kán tààrà ni kí ojú rẹ máa wò,

Bẹ́ẹ̀ ni, iwájú rẹ gan-an ni kí o tẹjú* mọ́.+

26 Mú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ ń gbà jọ̀lọ̀,*+

Gbogbo ọ̀nà rẹ á sì lójú.

27 Má yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+

Má fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà búburú.

5 Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n mi.

Fetí sílẹ̀ dáadáa* sí òye mi,+

 2 Kí o bàa lè dáàbò bo làákàyè rẹ

Kí o sì fi ètè rẹ dáàbò bo ìmọ̀.+

 3 Nítorí ètè obìnrin oníwàkiwà* ń kán tótó bí afárá oyin,+

Ọ̀rọ̀* rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ.+

 4 Àmọ́, nígbẹ̀yìn ó korò bí iwọ*+

Ó sì mú bí idà olójú méjì.+

 5 Àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ikú.

Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí Isà Òkú.*

 6 Kì í ronú nípa ọ̀nà ìyè.

Ó ti ṣìnà, kò mọ ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí.

 7 Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi

Ẹ má sì kúrò nínú ohun tí mò ń sọ.

 8 Jìnnà réré sí i;

Má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀,+

 9 Kí o má bàa fi iyì rẹ fún àwọn ẹlòmíì+

Tàbí kí o fi ọ̀pọ̀ ọdún kórè ohun tó burú;+

10 Kí àwọn àjèjì má bàa fa ọrọ̀* rẹ gbẹ,+

Kí àwọn ohun tí o ṣiṣẹ́ kára fún sì lọ sí ilé àjèjì.

11 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ

Nígbà tí okun rẹ bá tán, tí ẹran ara rẹ sì gbẹ+

12 Tí o sì sọ pé: “Ẹ wo bí mo ṣe kórìíra ẹ̀kọ́ tó!

Ẹ wo bí ọkàn mi ti ṣàìka ìbáwí sí!

13 Mi ò fetí sí ohùn àwọn tó ń kọ́ mi

Mi ò sì tẹ́tí sí àwọn olùkọ́ mi.

14 Mo ti dé bèbè ìparun

Ní àárín ìjọ lápapọ̀.”*+

15 Mu omi látinú àmù rẹ

Àti omi tó ń sun* látinú kànga rẹ.+

16 Ṣé ó yẹ kí ìsun omi rẹ tú síta,

Kí ìṣàn omi rẹ sì tú sí àwọn ojúde ìlú?+

17 Jẹ́ kí wọ́n wà fún ìwọ nìkan,

Kì í ṣe fún ìwọ àti àwọn àjèjì.+

18 Kí orísun omi* rẹ ní ìbùkún,

Kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ,+

19 Abo àgbọ̀nrín tó fani mọ́ra, ewúrẹ́ rírẹwà orí òkè.+

Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ máa dá ọ lọ́rùn* nígbà gbogbo.

Kí ìfẹ́ rẹ̀ máa gbà ọ́ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+

20 Torí náà, ọmọ mi, kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí obìnrin oníwàkiwà* gbà ọ́ lọ́kàn

Tàbí tí wàá fi gbá àyà obìnrin oníṣekúṣe* mọ́ra?+

21 Nítorí àwọn ọ̀nà èèyàn wà níwájú Jèhófà;

Ó ń ṣàyẹ̀wò gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+

22 Àwọn àṣìṣe ẹni burúkú ló ń dẹkùn mú un,

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ á sì wé mọ́ ọn bí okùn.+

23 Ó máa kú nítorí kò gba ìbáwí

Á sì ṣìnà nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù.

6 Ọmọ mi, tí o bá ti ṣe onídùúró* fún ọmọnìkejì rẹ,+

Tí o bá ti bọ àjèjì lọ́wọ́,*+

 2 Tí ìlérí rẹ bá ti dẹkùn mú ọ,

Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ bá ti mú ọ,+

 3 Ohun tí wàá ṣe nìyí, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ sílẹ̀,

Nítorí o ti kó sọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ:

Lọ rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì tètè bẹ ọmọnìkejì rẹ.+

 4 Má ṣe jẹ́ kí oorun kun ojú rẹ,

Má sì jẹ́ kí ìpéǹpéjú rẹ tòògbé.

 5 Gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tó bọ́ lọ́wọ́ ọdẹ,

Àti bí ẹyẹ tó bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.

 6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;+

Kíyè sí àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì gbọ́n.

 7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, aláṣẹ tàbí alákòóso,

 8 Ó ń ṣètò oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn,+

Ó sì ń kó oúnjẹ rẹ̀ jọ nígbà ìkórè.

 9 Ìgbà wo ni ìwọ ọ̀lẹ máa dùbúlẹ̀ dà?

Ìgbà wo lo máa dìde lójú oorun rẹ?

10 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,

Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,+

11 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,

Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+

12 Ìkà àti aláìwúlò ẹ̀dá ń rìn kiri tòun ti èké ọ̀rọ̀;+

13 Bó ṣe ń ṣẹ́jú,+ bẹ́ẹ̀ ló ń fi ẹsẹ̀ sọ̀rọ̀, tó sì ń nàka.

14 Pẹ̀lú ọkàn burúkú,

Ó ń gbèrò ibi ní gbogbo ìgbà,+ ó sì ń dá awuyewuye sílẹ̀.+

15 Torí náà, àjálù rẹ̀ yóò dé lójijì;

Ojú ẹsẹ̀ ni yóò wó lulẹ̀, kò sì ní ṣeé wò sàn.+

16 Ohun mẹ́fà wà tí Jèhófà kórìíra;

Bẹ́ẹ̀ ni, ohun méje tó jẹ́ ohun ìríra fún un:*

17 Ojú ìgbéraga,+ ahọ́n èké+ àti ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+

18 Ọkàn tó ń gbèrò ìkà+ àti ẹsẹ̀ tó ń sáré tete láti ṣe ibi,

19 Ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́+

Àti ẹni tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.+

20 Ọmọ mi, pa àṣẹ bàbá rẹ mọ́,

Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+

21 So wọ́n mọ́ ọkàn rẹ nígbà gbogbo;

Dè wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.

22 Nígbà tí o bá ń rìn, á máa darí rẹ;

Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, á máa ṣọ́ ẹ;

Nígbà tí o bá sì jí, á máa bá ẹ sọ̀rọ̀.*

23 Nítorí àṣẹ jẹ́ fìtílà,+

Òfin jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+

Àwọn ẹ̀kọ́ inú ìbáwí sì ni ọ̀nà ìyè.+

24 Wọ́n máa dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ obìnrin burúkú,+

Lọ́wọ́ ahọ́n obìnrin oníṣekúṣe* tó ń sọ ọ̀rọ̀ tó fani mọ́ra.+

25 Má ṣe jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́+

Tàbí kí o jẹ́ kó fi ojú rẹ̀ tó ń fani mọ́ra mú ọ,

26 Ní tìtorí aṣẹ́wó, èèyàn á di ẹni tí kò ní ju búrẹ́dì kan ṣoṣo lọ,+

Ní ti obìnrin alágbèrè, ẹ̀mí* tó ṣeyebíye ló fi ń ṣe ìjẹ.

27 Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí àyà rẹ̀, kí ẹ̀wù rẹ̀ má sì jó?+

28 Tàbí ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyin iná, kó má sì jó o lẹ́sẹ̀?

29 Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún ẹni tó bá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀;

Kò sí ẹni tó fọwọ́ kàn án tó máa lọ láìjìyà.+

30 Àwọn èèyàn kì í pẹ̀gàn olè

Tó bá jẹ́ pé ebi tó ń pa á ló mú kó jalè kó lè tẹ́ ọkàn* rẹ̀ lọ́rùn.

31 Síbẹ̀, tí wọ́n bá rí i, á san án pa dà ní ìlọ́po méje;

Gbogbo ohun tó níye lórí nínú ilé rẹ̀ ló máa kó sílẹ̀.+

32 Ẹni tó bá bá obìnrin ṣe àgbèrè kò ní làákàyè;*

Ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń fa ìparun bá ara* rẹ̀.+

33 Ọgbẹ́ àti àbùkù ló máa gbà,+

Ìtìjú rẹ̀ kò sì ní pa rẹ́.+

34 Nítorí owú máa ń mú kí ọkọ bínú;

Kò ní ṣojú àánú nígbà tó bá ń gbẹ̀san.+

35 Kò ní gba àsandípò;*

Láìka bí ẹ̀bùn náà ṣe pọ̀ tó, kò ní tù ú lójú.

7 Ọmọ mi, pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́,

Kí o sì fi àwọn àṣẹ mi ṣe ìṣúra rẹ. +

 2 Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì wà láàyè;+

Pa ẹ̀kọ́* mi mọ́ bí ọmọlójú rẹ.

 3 So wọ́n mọ́ ìka rẹ;

Kọ wọ́n sí wàláà ọkàn rẹ. +

 4 Sọ fún ọgbọ́n pé, “Arábìnrin mi ni ọ́,”

Kí o sì pe òye ní “ìbátan mi,”

 5 Láti dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ obìnrin oníwàkiwà,*+

Lọ́wọ́ obìnrin oníṣekúṣe* àti àwọn ọ̀rọ̀ dídùn* rẹ̀.+

 6 Lójú fèrèsé* ilé mi,

Mo bojú wolẹ̀ látojú fèrèsé,*

 7 Bí mo ṣe ń wo àwọn aláìmọ̀kan,*

Mo kíyè sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò ní làákàyè* láàárín àwọn ọ̀dọ́.+

 8 Ó gba ojú ọ̀nà tó wà nítòsí ìyànà ilé obìnrin náà kọjá,

Ó sì rìn lọ sí ọ̀nà ilé obìnrin náà

 9 Ní ìrọ̀lẹ́, ní àṣálẹ́,+

Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú, tí òkùnkùn sì ń kùn.

10 Ni mo bá rí obìnrin kan tó wá pàdé rẹ̀,

Ó múra bí* aṣẹ́wó,+ ó ní ọkàn àrékérekè.

11 Ó jẹ́ aláriwo àti aláfojúdi.+

Kì í* dúró sílé.

12 Ó lè wà níta nísìnyí, àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́, á ti dé ojúde ìlú,

Kò sí oríta tí kì í dúró sí.+

13 Obìnrin náà gbá a mú, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu;

Ó fi ọ̀dájú sọ fún un pé:

14 “Mo ti rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+

Òní ni mo san àwọn ẹ̀jẹ́ mi.

15 Ìdí nìyẹn tí mo fi jáde wá pàdé rẹ,

Láti wá ọ, mo sì ti rí ọ!

16 Mo ti tẹ́ àwọn aṣọ tó dára lé ibùsùn mi,

Aṣọ ọ̀gbọ̀* aláràbarà láti Íjíbítì.+

17 Mo ti fi òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn mi.+

18 Wá, jẹ́ ká jọ ṣeré ìfẹ́ títí di àárọ̀;

Jẹ́ ká gbádùn ìfẹ́ láàárín ara wa,

19 Nítorí ọkọ mi ò sí nílé;

Ó ti rin ìrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìn.

20 Ó gbé àpò owó dání,

Kò sì ní pa dà títí di ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú.”

21 Ó fi ọ̀rọ̀ tó ń yíni lérò pa dà ṣì í lọ́nà.+

Ó fi ọ̀rọ̀ dídùn fa ojú rẹ̀ mọ́ra.

22 Lójijì, ó tẹ̀ lé obìnrin náà, bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,

Bí òmùgọ̀ tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ nínú àbà,*+

23 Títí ọfà fi gún ẹ̀dọ̀ rẹ̀ ní àgúnyọ;

Bí ẹyẹ tó kó sínú pańpẹ́, kò mọ̀ pé ẹ̀mí òun máa lọ sí i.+

24 Ní báyìí, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ mi;

Ẹ fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ.

25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀.

Má rìn gbéregbère wọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀,+

26 Nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣekú pa,+

Àwọn tó ti pa sì pọ̀ gan-an.+

27 Ilé rẹ̀ lọ sí Isà Òkú;*

Ó sọ̀ kalẹ̀ sínú yàrá ikú.

8 Ǹjẹ́ ọgbọ́n ò máa ké jáde?

Ṣé òye ò máa gbé ohùn rẹ̀ sókè?+

 2 Ní orí àwọn ibi gíga+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà,

Ó dúró ní àwọn oríta.

 3 Lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè tó wọnú ìlú,

Ní àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà,

Ó ń ké tantan pé:+

 4 “Ẹ̀yin ni mò ń pè, ẹ̀yin èèyàn;

Gbogbo yín* ni mò ń ké sí.

 5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́ àròjinlẹ̀;+

Ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ wá ọkàn òye.*

 6 Ẹ fetí sílẹ̀, torí ohun tí mò ń sọ ṣe pàtàkì,

Ètè mi ń sọ ohun tí ó tọ́;

 7 Nítorí ẹnu mi ń sọ òtítọ́ ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,

Ètè mi sì kórìíra ohun tó burú.

 8 Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

Kò sí ẹ̀tàn kankan tàbí màgòmágó nínú wọn.

 9 Gbogbo wọn tọ̀nà lójú ẹni tó lóye

Wọ́n sì tọ́ lójú àwọn tó ti wá ìmọ̀ rí.

10 Ẹ gba ìbáwí mi dípò fàdákà,

Àti ìmọ̀ dípò wúrà tó dára jù lọ,+

11 Nítorí ọgbọ́n sàn ju iyùn* lọ;

Kò sí ohun ṣíṣeyebíye míì tí a lè fi wé e.

12 Èmi ọgbọ́n, mò ń bá àròjinlẹ̀ gbé;

Mo ti wá ìmọ̀ àti làákàyè rí.+

13 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìkórìíra ohun búburú.+

Mo kórìíra ìṣefọ́nńté àti ìgbéraga+ àti ọ̀nà ibi àti ọ̀rọ̀ àyídáyidà.+

14 Mo ní ìmọ̀ràn rere àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́;+

Òye+ àti agbára+ jẹ́ tèmi.

15 Ipasẹ̀ mi ni àwọn ọba ń ṣàkóso,

Tí àwọn aláṣẹ sì ń pàṣẹ òdodo.+

16 Ipasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣàkóso,

Tí àwọn èèyàn pàtàkì sì ń fi òdodo ṣèdájọ́.

17 Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi,

Àwọn tó sì ń wá mi yóò rí mi.+

18 Ọrọ̀ àti ògo wà lọ́dọ̀ mi,

Ọlá tó wà pẹ́ títí* àti òdodo.

19 Èso mi sàn ju wúrà lọ, àní wúrà tí a yọ́ mọ́,

Ohun tí mo sì ń mú jáde sàn ju fàdákà tó dára jù lọ.+

20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,

Ní àárín àwọn ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo;

21 Mo fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi ní ogún tó ṣeyebíye,

Mo sì mú kí ilé ìkẹ́rùsí wọn kún.

22 Jèhófà ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀nà rẹ̀,+

Àkọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà láéláé.+

23 Láti ayébáyé* ni a ti gbé mi kalẹ̀,+

Láti ìbẹ̀rẹ̀, ṣáájú kí ayé tó wà.+

24 Nígbà tí kò sí àwọn ibú omi,+ a mú mi jáde,*

Nígbà tí kò sí àwọn ìsun omi tó kún dẹ́múdẹ́mú.

25 Kí a tó fìdí àwọn òkè ńlá kalẹ̀,

Ṣáájú àwọn òkè kéékèèké, a ti mú mi jáde,

26 Nígbà tí kò tíì dá ayé àti àwọn pápá rẹ̀

Tàbí erùpẹ̀ ilẹ̀ tó kọ́kọ́ wà.

27 Nígbà tó dá ọ̀run,+ mo wà níbẹ̀;

Nígbà tó fi ààlà* sí orí omi,+

28 Nígbà tó ṣe àwọsánmà sókè,*

Nígbà tó dá àwọn ìsun ibú omi,

29 Nígbà tó pàṣẹ fún òkun

Pé kí omi rẹ̀ má kọjá àṣẹ tó pa fún un,+

Nígbà tó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,*

30 Nígbà náà, mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.+

Èmi ni àrídunnú rẹ̀+ lójoojúmọ́;

Inú mi sì ń dùn níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà;+

31 Inú mi ń dùn nítorí ayé tí ó dá fún èèyàn láti máa gbé,

Mo sì fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn* lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.

32 Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi;

Bẹ́ẹ̀ ni, aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́.

33 Ẹ fetí sí ìbáwí+ kí ẹ sì gbọ́n,

Ẹ má ṣe pa á tì láé.

34 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fetí sí mi

Tó ń jí wá sẹ́nu* ọ̀nà mi lójoojúmọ́,

Tó ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn mi;

35 Nítorí ẹni tó bá rí mi yóò rí ìyè,+

Yóò sì rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.

36 Àmọ́ ẹni tó bá pa mí tì, ara* rẹ̀ ló ń ṣe,

Àwọn tó sì kórìíra mi fẹ́ràn ikú.”+

9 Ọgbọ́n tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀;

Ó ti gbẹ́ òpó rẹ̀ méjèèje.

 2 Ó ti ṣètò gbogbo ẹran rẹ̀;*

Ó ti po wáìnì rẹ̀;

Ó sì ti tẹ́ tábìlì rẹ̀.

 3 Ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde

Láti ké jáde látorí àwọn ibi gíga ìlú pé:+

 4 “Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.”

Ó sọ fún àwọn tí kò ní làákàyè* pé:

 5 “Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ mi

Kí ẹ sì mu nínú wáìnì tí mo ti pò.

 6 Ẹ fi àìmọ̀kan yín* sílẹ̀, kí ẹ lè wà láàyè;+

Kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà òye nìṣó.”+

 7 Ẹni tó bá ń tọ́ afiniṣẹ̀sín sọ́nà ń wá àbùkù,+

Ẹni tó bá sì ń bá ẹni burúkú wí yóò rí ìbànújẹ́.

 8 Má ṣe bá afiniṣẹ̀sín wí, torí á kórìíra rẹ.+

Bá ọlọ́gbọ́n wí, yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+

 9 Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóò sì gbọ́n sí i. +

Kọ́ olódodo, yóò sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.

10 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,+

Ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ+ sì ni òye.

11 Ọgbọ́n yóò jẹ́ kí ọjọ́ ayé rẹ di púpọ̀,+

Yóò sì fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.

12 Tí o bá gbọ́n, o gbọ́n fún àǹfààní ara rẹ,

Àmọ́ tí o bá ya afiniṣẹ̀sín, ìwọ nìkan lo máa jìyà rẹ̀.

13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo.+

Òpè ni, kò sì mọ nǹkan kan rárá.

14 Ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀

Lórí ìjókòó ní àwọn ibi gíga ìlú,+

15 Ó ń pe àwọn tó ń kọjá lọ,

Àwọn tó ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn, pé:

16 “Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.”

Ó sọ fún àwọn tí kò ní làákàyè* pé:+

17 “Omi tí a jí gbé máa ń dùn,

Oúnjẹ tí a sì jẹ ní ìkọ̀kọ̀ máa ń gbádùn mọ́ni.”+

18 Àmọ́ wọn kò mọ̀ pé àwọn tí ikú ti pa* wà níbẹ̀,

Àti pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ Isà Òkú.*+

10 Òwe Sólómọ́nì.+

Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+

Àmọ́ òmùgọ̀ ọmọ ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìyá rẹ̀.

 2 Àwọn ìṣúra téèyàn fi ìwà ìkà kó jọ kò ní ṣe é láǹfààní,

Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+

 3 Jèhófà ò ní jẹ́ kí ebi pa olódodo,*+

Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ẹni burúkú tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́.

 4 Ọwọ́ tó dilẹ̀ ń sọni di òtòṣì,+

Àmọ́ ọwọ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára ń sọni di ọlọ́rọ̀.+

 5 Ọmọ tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń kó irè oko jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,

Àmọ́ ọmọ tó ń dójú tini ń sùn fọnfọn nígbà ìkórè.+

 6 Ìbùkún wà lórí olódodo,+

Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.

 7 Ìrántí* olódodo yẹ fún ìbùkún,+

Àmọ́ orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.+

 8 Ọlọ́gbọ́n ọkàn yóò gba ẹ̀kọ́,*+

Àmọ́ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+

 9 Ẹni tó ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò,+

Àmọ́ àṣírí ẹni tó ń sọ ọ̀nà ara rẹ̀ di wíwọ́ yóò tú.+

10 Ẹni tó ń dínjú ń fa ẹ̀dùn ọkàn,+

Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+

11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,+

Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.+

12 Ìkórìíra ló ń dá awuyewuye sílẹ̀,

Àmọ́ ìfẹ́ máa ń bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.+

13 Ọgbọ́n wà ní ètè olóye,+

Àmọ́ ọ̀pá wà fún ẹ̀yìn ẹni tí kò ní làákàyè.*+

14 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń fi ìmọ̀ ṣe ìṣúra,+

Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń fa ìparun.+

15 Ohun ìní* ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀.

Ipò òṣì àwọn aláìní ni ìparun wọn.+

16 Iṣẹ́ olódodo ń yọrí sí ìyè;

Àmọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹni burúkú ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.+

17 Ẹni tó ń gba ìbáwí jẹ́* ipa ọ̀nà ìyè fún àwọn èèyàn,

Àmọ́ ẹni tó ń kọ ìbáwí ń kó àwọn èèyàn ṣìnà.

18 Ẹni tó ń bo ìkórìíra rẹ̀ mọ́ra ń parọ́,+

Ẹni tó sì ń tan ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́* ká jẹ́ òmùgọ̀.

19 Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe ò ní ṣàì wáyé,+

Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ á máa fi ọgbọ́n hùwà.+

20 Ahọ́n olódodo dà bíi fàdákà tó dára jù lọ,+

Àmọ́ ọkàn ẹni burúkú kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan.

21 Ẹnu olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn,*+

Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ ń kú nítorí wọn kò ní làákàyè.+

22 Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀,+

Kì í sì í fi ìrora* kún un.

23 Híhùwà àìnítìjú dà bí eré lójú òmùgọ̀,

Àmọ́ ọgbọ́n wà fún ẹni tó ní òye.+

24 Ohun tí ẹni burúkú ń bẹ̀rù yóò ṣẹlẹ̀ sí i;

Àmọ́ a ó ṣe ohun tí ọkàn àwọn olódodo fẹ́ fún wọn.+

25 Nígbà tí ẹ̀fúùfù bá fẹ́ kọjá, ẹni burúkú kò ní sí mọ́,+

Àmọ́ olódodo jẹ́ ìpìlẹ̀ títí láé.+

26 Bí ọtí kíkan ṣe ń ṣe eyín àti bí èéfín ṣe ń ṣe ojú,

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ṣe rí sí ẹni tó rán an níṣẹ́.*

27 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú kí ẹ̀mí ẹni gùn,+

Àmọ́ ọdún àwọn ẹni burúkú ni a ó gé kúrú.+

28 Ìfojúsọ́nà* àwọn olódodo ń mú ayọ̀ wá,+

Àmọ́ ìrètí àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+

29 Ọ̀nà Jèhófà jẹ́ ibi ààbò fún aláìlẹ́bi,+

Àmọ́ ìparun ló jẹ́ fún àwọn aṣebi.+

30 Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn olódodo ṣubú,+

Àmọ́ àwọn ẹni burúkú ò ní gbé ilẹ̀ ayé mọ́.+

31 Ẹnu olódodo ń mú* ọgbọ́n jáde,

Àmọ́, ahọ́n àyídáyidà ni a ó gé kúrò.

32 Ètè olódodo mọ ohun tó tọ́ láti sọ,

Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú jẹ́ ẹ̀tàn.

11 Òṣùwọ̀n èké* jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,

Àmọ́ ìwọ̀n* tí ó pé máa ń mú inú rẹ̀ dùn.+

 2 Tí ìkọjá àyè bá dé, àbùkù á tẹ̀ lé e,+

Àmọ́ ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.+

 3 Ìwà títọ́ àwọn adúróṣinṣin ló ń tọ́ wọn sọ́nà,+

Àmọ́ ẹ̀tàn àwọn oníbékebèke ni yóò pa wọ́n run.+

 4 Ọrọ̀* kò ní ṣeni láǹfààní ní ọjọ́ ìbínú ńlá,+

Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+

 5 Òdodo aláìlẹ́bi ń mú kí ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́,

Àmọ́ ẹni burúkú á ṣubú nítorí ìwà burúkú rẹ̀.+

 6 Òdodo àwọn adúróṣinṣin ni yóò gbà wọ́n,+

Àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn oníbékebèke ni yóò dẹkùn mú wọn.+

 7 Nígbà tí ẹni burúkú bá kú, ìrètí rẹ̀ á ṣègbé;

Ohun tó sì ń retí pé òun á fi agbára òun ṣe yóò ṣègbé pẹ̀lú.+

 8 A gba olódodo lọ́wọ́ wàhálà,

Ẹni burúkú sì bọ́ síbẹ̀ dípò rẹ̀.+

 9 Ẹnu ni apẹ̀yìndà* fi ń fa ìparun bá ọmọnìkejì rẹ̀,

Àmọ́ ìmọ̀ ló ń gba àwọn olódodo sílẹ̀.+

10 Ìwà rere àwọn olódodo ń mú kí ìlú yọ̀,

Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá ṣègbé, igbe ìdùnnú á ta.+

11 Nítorí ìbùkún àwọn adúróṣinṣin, ìlú á ní ìgbéga,+

Àmọ́ ẹnu àwọn ẹni burúkú á wó o lulẹ̀.+

12 Ẹni tí kò ní làákàyè* ń kórìíra* ọmọnìkejì rẹ̀,

Àmọ́ ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń dákẹ́.+

13 Abanijẹ́ ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kiri,+

Àmọ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán* máa ń pa àṣírí mọ́.*

14 Nígbà tí kò bá sí ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n, àwọn èèyàn á ṣubú,

Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* àṣeyọrí* á wà.+

15 Ẹni tó bá ṣe onídùúró* fún àjèjì yóò rí láburú,+

Àmọ́ ẹni tó bá yẹra fún* bíbọ ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́ yóò rí ààbò.

16 Obìnrin onínúure* ń gba ògo,+

Àmọ́ àwọn ìkà èèyàn ń gbẹ́sẹ̀ lé ọrọ̀.

17 Ẹni tó ń ṣoore* ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní,*+

Àmọ́ ìkà èèyàn ń fa wàhálà* bá ara rẹ̀.+

18 Ẹni burúkú ń jẹ èrè asán,+

Àmọ́ ẹni tó ń gbin òdodo ń jẹ èrè gidi.+

19 Ẹni tó dúró gbọn-in lórí òdodo máa rí ìyè,+

Àmọ́ ẹni tó ń lépa ohun búburú á rí ikú he.

20 Àwọn tí ọkàn wọn burú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+

Àmọ́ àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́ ń mú inú rẹ̀ dùn.+

21 Jẹ́ kó dá ọ lójú pé:* Ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,+

Àmọ́ àwọn ọmọ olódodo yóò yè bọ́.

22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀

Ni obìnrin tó rẹwà àmọ́ tí kì í lo làákàyè.

23 Ìfẹ́ ọkàn àwọn olódodo ń yọrí sí ire,+

Àmọ́ ohun tí àwọn ẹni burúkú ń retí máa ń yọrí sí ìbínú ńlá.

24 Ẹnì kan wà tó ń fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀,* ó sì ń ní sí i;+

Ẹnì kan sì wà tó ń fawọ́ ohun tó yẹ kó fúnni sẹ́yìn, àmọ́ ó di aláìní.+

25 Ẹni* tó bá lawọ́ máa láásìkí,*+

Ẹni tó bá sì ń mára tu àwọn míì,* ara máa tu òun náà.+

26 Àwọn èèyàn á gégùn-ún fún ẹni tó bá kó oúnjẹ pa mọ́,

Àmọ́ wọ́n á súre fún ẹni tó bá ń tà á.

27 Ẹni tó ń wá bó ṣe máa ṣe rere lójú méjèèjì ń wá ojú rere,+

Àmọ́ ẹni tó bá ń wá ibi, ó dájú pé ibi ló máa wá sórí rẹ̀.+

28 Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀ máa ṣubú,+

Àmọ́ olódodo máa rú yọ bí ewé tútù.+

29 Ẹni tó bá ń fa wàhálà* bá agbo ilé rẹ̀ á jogún òfo,*+

Òmùgọ̀ èèyàn ló sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ ọlọ́gbọ́n.

30 Èso olódodo jẹ́ igi ìyè,+

Ẹni tó bá sì ń jèrè ọkàn* jẹ́ ọlọ́gbọ́n.+

31 Tó bá jẹ́ pé ẹ̀san wà fún olódodo lóòótọ́,

Mélòómélòó ni ti ẹni burúkú àti ẹlẹ́ṣẹ̀!+

12 Ẹni tó bá fẹ́ràn ẹ̀kọ́ fẹ́ràn ìmọ̀,+

Àmọ́ ẹni tó bá kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìnírònú.*+

 2 Ẹni rere ń rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà,

Àmọ́ Ó ń dá ẹni tó ń gbèrò ìkà lẹ́bi.+

 3 Ìwà burúkú kì í jẹ́ kéèyàn fìdí múlẹ̀,+

Àmọ́ kò sí ohun tó lè fa olódodo tu.

 4 Aya tó dáńgájíá jẹ́ adé fún ọkọ rẹ̀,+

Àmọ́ adójútini aya dà bí ìjẹrà nínú egungun ọkọ rẹ̀.+

 5 Ìrònú àwọn olódodo máa ń tọ́,

Àmọ́ ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú.

 6 Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú dà bíi lílúgọ láti ṣekú pani,*+

Àmọ́ ẹnu àwọn adúróṣinṣin ń gbà wọ́n sílẹ̀.+

 7 Nígbà tí a bá bi àwọn ẹni burúkú ṣubú, wọn ò ní sí mọ́,

Àmọ́ ilé àwọn olódodo yóò dúró digbí.+

 8 Èèyàn á gba ìyìn nítorí ọgbọ́n tó ń jáde lẹ́nu rẹ̀,+

Àmọ́ ẹ̀gàn ló máa bá ọlọ́kàn ẹ̀tàn.+

 9 Ó sàn kí a gbéni ga díẹ̀, kéèyàn sì ní ìránṣẹ́

Ju kí èèyàn máa yin ara rẹ̀, kó má sì ní oúnjẹ.*+

10 Olódodo ń tọ́jú ẹran* ọ̀sìn rẹ̀,+

Àmọ́ tí ẹni burúkú bá tiẹ̀ ṣàánú, ìkà ló máa já sí.

11 Ẹni tó ń ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò jẹun tẹ́rùn,+

Àmọ́ ẹni tó ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí kò ní làákàyè.*

12 Ẹni burúkú ń jowú ohun tí àwọn ẹni burúkú míì dẹkùn mú,

Àmọ́ àwọn olódodo dà bí igi tí gbòǹgbò rẹ̀ jinlẹ̀ tó ń méso jáde.

13 Ọ̀rọ̀ burúkú tó ń jáde lẹ́nu ẹni ibi ló ń dẹkùn mú un,+

Àmọ́ olódodo ń bọ́ lọ́wọ́ wàhálà.

14 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa ń fi ohun rere tẹ́ ẹ lọ́rùn,+

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì san èrè fún un.

15 Ọ̀nà òmùgọ̀ tọ́ ní ojú ara rẹ̀,+

Àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń gba ìmọ̀ràn.*+

16 Òmùgọ̀ máa ń fi ìbínú rẹ̀ hàn lójú ẹsẹ̀,*+

Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gbójú fo* àbùkù tí wọ́n fi kàn án.

17 Ẹni tó ń fòótọ́ jẹ́rìí máa ń sọ òtítọ́,*

Àmọ́ ẹlẹ́rìí èké máa ń sọ ẹ̀tàn.

18 Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni,

Àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.+

19 Ètè tó ń sọ òtítọ́ máa wà títí láé,+

Àmọ́ ahọ́n tó ń parọ́ kò ní tọ́jọ́.+

20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tó ń gbèrò ibi,

Àmọ́ àwọn tó ń mú kí àlàáfíà wà* máa ní ayọ̀.+

21 Kò sí jàǹbá tó máa ṣe olódodo,+

Àmọ́ ọ̀pọ̀ àjálù ló máa dé bá àwọn ẹni burúkú.+

22 Ètè tó ń parọ́ jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+

Àmọ́ àwọn tó ń fi òtítọ́ hùwà ń mú inú rẹ̀ dùn.

23 Aláròjinlẹ̀ máa ń fi ohun tó mọ̀ pa mọ́,

Àmọ́ ọkàn òmùgọ̀ máa ń tú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ jáde.+

24 Ọwọ́ àwọn tó ń ṣíṣẹ́ kára yóò ṣàkóso,+

Àmọ́ ọwọ́ tó dilẹ̀ yóò wà fún iṣẹ́ àfipáṣe.+

25 Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì,*+

Àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.+

26 Olódodo ń ṣàyẹ̀wò ibi ìjẹko rẹ̀,

Àmọ́ ọ̀nà àwọn ẹni burúkú ń kó wọn ṣìnà.

27 Ọ̀lẹ kò lè sáré lé ẹran tó fẹ́ pa,+

Àmọ́ iṣẹ́ àṣekára ni ìṣúra èèyàn.

28 Ipa ọ̀nà òdodo ń yọrí sí ìyè;+

Kò sí ikú ní ipa ọ̀nà rẹ̀.

13 Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń gba ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀,+

Àmọ́ ẹlẹ́gàn kì í fetí sí ìbáwí.*+

 2 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa jẹ́ kó rí ohun rere gbà,+

Àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn oníbékebèke máa ń jẹ́ kí wọ́n hùwà ipá.

 3 Ẹni tó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀* ń dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tó ń la ẹnu rẹ̀ gbàgà yóò pa run.+

 4 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ọ̀lẹ ń fẹ́, síbẹ̀ kò* ní nǹkan kan,+

Àmọ́ ẹni* tó ń ṣiṣẹ́ kára yóò ní ànító.*+

 5 Olódodo kórìíra irọ́,+

Àmọ́ ìwà ẹni burúkú ń fa ìtìjú àti àbùkù.

 6 Òdodo ń dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+

Àmọ́ ìwà burúkú máa ń dojú ẹlẹ́ṣẹ̀ dé.

 7 Ẹnì kan wà tó ń ṣe bíi pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀ kò ní nǹkan kan;+

Ẹlòmíì sì wà tó ń ṣe bíi pé aláìní lòun, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ.

 8 Ọrọ̀ ni ọlọ́rọ̀ fi ń ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà,+

Àmọ́ ẹnikẹ́ni kì í halẹ̀ mọ́ aláìní.*+

 9 Ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo mọ́lẹ̀ rekete,*+

Àmọ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.+

10 Wàhálà ni ìkọjá àyè máa ń dá sílẹ̀,+

Àmọ́ ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.*+

11 Ọrọ̀ tí èèyàn fi ìkánjú kó jọ* kì í pẹ́ tán,+

Àmọ́ ọrọ̀ tí èèyàn ń kó jọ díẹ̀díẹ̀* á máa pọ̀ sí i.

12 Ìrètí* pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn,+

Àmọ́ nígbà tí ìfẹ́ ọkàn ẹni bá ṣẹ, igi ìyè ni.+

13 Ẹni tí kò bá ka ìtọ́ni* sí á jìyà rẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tó bá bọ̀wọ̀ fún àṣẹ yóò gba èrè rẹ̀.+

14 Ẹ̀kọ́* ọlọgbọ́n jẹ́ orísun ìyè+

Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú.

15 Ìjìnlẹ̀ òye ń mú kéèyàn jèrè ojú rere,

Àmọ́ ọ̀nà àwọn oníbékebèke korò.

16 Aláròjinlẹ̀ máa ń fi ìmọ̀ hùwà,+

Àmọ́ òmùgọ̀ máa ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+

17 Òjíṣẹ́ burúkú máa ń kó sínú ìjàngbọ̀n,+

Àmọ́ aṣojú tó jẹ́ olóòótọ́ ń mú ìwòsàn wá.+

18 Ẹni tí kò bá ka ìbáwí sí á di òtòṣì, á sì kan àbùkù,

Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìtọ́sọ́nà* ni a ó gbé ga.+

19 Nígbà tí ìfẹ́ ọkàn ẹni bá ṣẹ, ó máa ń dùn mọ́ni,*+

Àmọ́ òmùgọ̀ kì í fẹ́ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.+

20 Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,+

Àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.+

21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+

Àmọ́ aásìkí ni èrè àwọn olódodo.+

22 Ẹni rere máa ń fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,

Àmọ́ ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó kó jọ fún àwọn olódodo.+

23 Ọ̀pọ̀ oúnjẹ ló ń jáde látinú oko tí àwọn aláìní dá,

Àmọ́ àìsí ìdájọ́ òdodo lè gbá a* lọ.

24 Ẹni tó bá fa ọ̀pá* sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa ń bá a wí dáadáa.*+

25 Olódodo ń jẹ àjẹtẹ́rùn,*+

Àmọ́ inú àwọn ẹni burúkú ṣófo.+

14 Ọlọ́gbọ́n obìnrin ń kọ́ ilé rẹ̀,+

Àmọ́ òmùgọ̀ obìnrin á fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya tirẹ̀ lulẹ̀.

 2 Ẹni tó ń rìn nínú ìdúróṣinṣin ń bẹ̀rù Jèhófà,

Àmọ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́* ń tàbùkù sí I.

 3 Pàṣán ìgbéraga wà ní ẹnu òmùgọ̀,

Àmọ́ ètè àwọn ọlọ́gbọ́n yóò dáàbò bò wọ́n.

 4 Tí kò bá sí ẹran ọ̀sìn,* ibùjẹ ẹran á mọ́ tónítóní,

Àmọ́ agbára akọ màlúù máa ń mú kí ìkórè pọ̀.

 5 Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ olóòótọ́ kì í parọ́,

Àmọ́ ẹlẹ́rìí èké kò lè ṣe kó má parọ́.+

 6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n, kò sì rí i,

Àmọ́ ìmọ̀ máa ń wá sọ́dọ̀ àwọn olóye pẹ̀lú ìrọ̀rùn.+

 7 Jìnnà sí òmùgọ̀ èèyàn,

Torí o ò ní rí ìmọ̀ ní ẹnu rẹ̀.+

 8 Ọgbọ́n ni aláròjinlẹ̀ fi ń lóye ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí,

Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń ṣì wọ́n lọ́nà.*+

 9 Òmùgọ̀ ló ń da ẹ̀bi rẹ̀* sáwàdà,+

Àmọ́ àwọn adúróṣinṣin máa ń fẹ́ láti pa dà wà níṣọ̀kan.*

10 Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀,*

Àjèjì kò sì lè pín nínú ayọ̀ rẹ̀.

11 Ilé àwọn ẹni burúkú máa pa run,+

Àmọ́ àgọ́ àwọn adúróṣinṣin máa gbilẹ̀.

12 Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,+

Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+

13 Èèyàn lè máa rẹ́rìn-ín, síbẹ̀ kí ọkàn rẹ̀ máa jẹ̀rora,

Ìdùnnú sì lè di ìbànújẹ́.

14 Aláìṣòótọ́ máa gba èrè àwọn ọ̀nà rẹ̀,+

Àmọ́ èèyàn rere máa gba èrè ìwà rẹ̀.+

15 Aláìmọ̀kan* máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́,

Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.+

16 Ọlọ́gbọ́n máa ń ṣọ́ra, ó sì ń yẹra fún ìwà burúkú,

Àmọ́ òmùgọ̀ kì í kíyè sára,* ó sì máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù.

17 Ẹni tó bá tètè ń bínú máa ń hùwà òmùgọ̀,+

Àmọ́ ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò* ni aráyé ń kórìíra.

18 Aláìmọ̀kan* yóò jogún ìwà òmùgọ̀,

Àmọ́ a ó fi ìmọ̀ dé àwọn aláròjinlẹ̀ ládé.+

19 Àwọn èèyàn búburú yóò tẹrí ba níwájú àwọn ẹni rere,

Àwọn èèyàn burúkú yóò sì tẹrí ba ní ẹnubodè àwọn olódodo.

20 Àwọn tó sún mọ́ tálákà pàápàá máa ń kórìíra rẹ̀,+

Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá olówó ṣọ̀rẹ́.+

21 Ẹni tó bá ń fojú àbùkù wo ọmọnìkejì rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,

Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣàánú aláìní jẹ́ aláyọ̀.+

22 Àwọn tó ń gbèrò ibi máa ṣìnà.

Àmọ́ àwọn tó ti pinnu láti máa ṣe rere máa rí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́.+

23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè,

Àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ń yọrí sí àìní.+

24 Adé àwọn ọlọ́gbọ́n ni ọrọ̀ wọn;

Àmọ́ ìwà àwọn òmùgọ̀ jẹ́ kìkì ẹ̀gọ̀.+

25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ ń gba ẹ̀mí* là,

Àmọ́ ẹlẹ́tàn kò lè ṣe kó má parọ́.

26 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa ń fọkàn ẹni balẹ̀ pẹ̀sẹ̀,+

Yóò sì jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.+

27 Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ orísun ìyè,

Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú.

28 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni ògo ọba,+

Àmọ́ alákòóso tí kò ní àwọn tó ń jọba lé lórí ti ṣubú.

29 Ẹni tí kì í tètè bínú ní ìjìnlẹ̀ òye,+

Àmọ́ ẹni tí kò ní sùúrù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+

30 Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun,*

Àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.+

31 Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì ń gan Ẹni tó dá a,+

Àmọ́ ẹni tó ń ṣàánú tálákà ń yìn Ín lógo.+

32 Ìwà ibi ẹni burúkú ló máa gbé e ṣubú,

Àmọ́ olódodo máa rí ààbò nítorí ìwà títọ́ rẹ̀.+

33 Inú ọkàn olóye ni ọgbọ́n fìdí kalẹ̀ sí,+

Àmọ́ àárín àwọn òmùgọ̀ ló ti máa ń fi ara rẹ̀ hàn.

34 Òdodo máa ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,+

Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ máa ń kó ìtìjú bá orílẹ̀-èdè.

35 Inú ọba máa ń dùn sí ìránṣẹ́ tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye,+

Àmọ́ inú rẹ̀ máa ń ru sí èyí tó ń hùwà ìtìjú.+

15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́* máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀,+

Àmọ́ ọ̀rọ̀ líle* ń ru ìbínú sókè.+

 2 Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere,+

Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń tú ọ̀rọ̀ ẹ̀gọ̀ jáde.

 3 Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo,

Ó ń ṣọ́ ẹni burúkú àti ẹni rere.+

 4 Ahọ́n pẹ̀lẹ́* jẹ́ igi ìyè,+

Àmọ́ ọ̀rọ̀ békebèke máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.*

 5 Òmùgọ̀ kì í ka ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀ sí,+

Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gba ìbáwí.*+

 6 Ọ̀pọ̀ ìṣúra ló wà nínú ilé olódodo,

Àmọ́ èso* ẹni burúkú máa ń fa wàhálà bá a.+

 7 Ètè ọlọ́gbọ́n máa ń tan ìmọ̀ kálẹ̀,+

Àmọ́ ọkàn àwọn òmùgọ̀ kì í ṣe bẹ́ẹ̀.+

 8 Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+

Àmọ́ àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Rẹ̀ dùn.+

 9 Jèhófà kórìíra ọ̀nà ẹni burúkú,+

Àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń wá òdodo.+

10 Ìbáwí dà bí ohun tí kò dára* lójú ẹni tó ń ṣìnà,+

Ẹni tó bá sì kórìíra ìbáwí á kú.+

11 Isà Òkú* àti ibi ìparun* ṣí sílẹ̀ gbayawu lójú Jèhófà.+

Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ọkàn èèyàn!+

12 Ẹlẹ́gàn kì í fẹ́ràn ẹni tó ń tọ́ ọ sọ́nà.*+

Kì í fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọlọ́gbọ́n.+

13 Inú dídùn ló ń mórí yá,

Àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.+

14 Ọkàn tó ní òye máa ń wá ìmọ̀,+

Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣe oúnjẹ jẹ.*+

15 Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ,+

Àmọ́ ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn* máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.+

16 Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀, kó sì bẹ̀rù Jèhófà+

Ju kó ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ pẹ̀lú àníyàn.*+

17 Oúnjẹ tí a fi nǹkan ọ̀gbìn sè níbi tí ìfẹ́ wà+

Sàn ju akọ màlúù àbọ́sanra* níbi tí ìkórìíra wà.+

18 Onínúfùfù máa ń dá wàhálà sílẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tí kì í tètè bínú máa ń mú kí ìjà rọlẹ̀.+

19 Ọ̀nà ọ̀lẹ dà bí igbó ẹ̀gún,+

Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin dà bí ọ̀nà tó tẹ́jú.+

20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+

Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń kórìíra ìyá rẹ̀.+

21 Ẹni tí kò ní làákàyè* máa ń fi ìwà òmùgọ̀ ṣayọ̀,+

Àmọ́ ẹni tó ní òye máa ń rìn lọ tààrà.+

22 Láìsí ìfinúkonú,* èrò á dasán,

Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* àṣeyọrí á wà.+

23 Inú èèyàn máa ń dùn tí ìdáhùn rẹ̀ bá tọ̀nà,*+

Ọ̀rọ̀ tó bá sì bọ́ sí àkókò mà dára o!+

24 Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń tọ ọ̀nà ìyè tó lọ sókè,+

Kí ó lè yẹra fún Isà Òkú* nísàlẹ̀.+

25 Jèhófà máa ya ilé àwọn agbéraga lulẹ̀,+

Àmọ́ kò ní jẹ́ kí wọ́n sún ààlà opó sẹ́yìn.+

26 Jèhófà kórìíra èrò àwọn ẹni ibi,+

Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára mọ́ lójú Rẹ̀.+

27 Ẹni tó ń jẹ èrè tí kò tọ́ ń fa wàhálà* bá agbo ilé rẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò máa wà láàyè.+

28 Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn,*+

Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú máa ń tú ọ̀rọ̀ burúkú jáde.

29 Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,

Àmọ́ ó máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olódodo.+

30 Ojú tó ń dán* máa ń mú ọkàn yọ̀;

Ìròyìn tó dára máa ń mú kí egungun lágbára.*+

31 Ẹni tó ń fetí sí ìbáwí tó ń fúnni ní ìyè,

Àárín àwọn ọlọ́gbọ́n ló ń gbé.+

32 Ẹni tó bá ń kọ ìbáwí kórìíra ẹ̀mí* rẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìbáwí ní òye.*+

33 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń kọ́ni lọ́gbọ́n,+

Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+

16 Èèyàn lè gbèrò ohun kan lọ́kàn ara rẹ̀,*

Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáhùn rẹ̀* ti máa wá.+

 2 Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́* lójú ara rẹ̀,+

Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn.*+

 3 Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́,*+

Ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.

 4 Jèhófà ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́,

Kódà láti pa ẹni burúkú run ní ọjọ́ àjálù.+

 5 Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.+

Ó dájú* pé wọn ò ní lọ láìjìyà.

 6 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+

Ìbẹ̀rù Jèhófà sì máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.+

 7 Tí inú Jèhófà bá dùn sí ọ̀nà èèyàn,

Ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.+

 8 Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀ àmọ́ kó jẹ́ olóòótọ́+

Ju kéèyàn fi èrú kó èrè púpọ̀ jọ.+

 9 Èèyàn lè ro bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe máa rí lọ́kàn rẹ̀,

Àmọ́ Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ rẹ̀.+

10 Ìpinnu tó ní ìmísí* ló yẹ kó máa wà lẹ́nu ọba;+

Kò gbọ́dọ̀ dá ẹjọ́ lọ́nà tí kò tọ́.+

11 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé ti wá;

Gbogbo òkúta ìwọ̀n tó wà nínú àpò jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

12 Àwọn ọba kórìíra ìwà burúkú,+

Nítorí òdodo ló ń fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ gbọn-in.+

13 Ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́ ìdùnnú àwọn ọba.

Wọ́n fẹ́ràn ẹni tó bá ń sọ òótọ́.+

14 Ìbínú ọba dà bí òjíṣẹ́ ikú,+

Àmọ́ ọlọ́gbọ́n ló ń tù ú lójú.*+

15 Ẹni tó bá rí ojú rere ọba, ayé onítọ̀hún á ládùn;

Ojú rere rẹ̀ dà bíi ṣíṣú òjò ìgbà ìrúwé.+

16 Ó mà sàn kéèyàn ní ọgbọ́n ju kó ní wúrà o!+

Ó sì dára kéèyàn ní òye ju kó ní fàdákà.+

17 Láti yẹra fún ohun búburú ni ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin.

Ẹni tó bá ń ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀ ń dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀.+

18 Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun,

Ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.+

19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀* láàárín àwọn oníwà pẹ̀lẹ́+

Ju kéèyàn pín nínú ẹrù tí àwọn agbéraga kó.

20 Ẹni tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀ràn yóò ṣàṣeyọrí,*

Aláyọ̀ sì ni ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

21 Ẹni tó ní ọkàn ọgbọ́n ni a ó pè ní olóye,+

Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ rere* ń yíni lérò pa dà.+

22 Ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ kànga ìyè fún àwọn tó ni ín,

Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń bá wọn wí.

23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń fún ẹnu rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye+

Ó sì ń fi ìyíniléròpadà kún ọ̀rọ̀ rẹ̀.

24 Ọ̀rọ̀ dídùn jẹ́ afárá oyin,

Ó dùn mọ́ ọkàn,* ó sì ń wo egungun sàn.+

25 Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,

Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+

26 Ikùn* lébìrà ló ń mú kó ṣiṣẹ́ kára,

Ebi tó ń pa á* sì ń mú kó tẹpá mọ́ṣẹ́.+

27 Èèyàn tí kò ní láárí máa ń hú ohun tí kò dáa jáde;+

Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí iná tó ń jóni.+

28 Oníwàhálà* máa ń dá ìyapa sílẹ̀,+

Abanijẹ́ sì máa ń tú àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.+

29 Oníwà ipá máa ń tan ọmọnìkejì rẹ̀

Á sì kó o ṣìnà.

30 Bó ṣe ń ṣẹ́jú ló ń gbèrò ibi.

Ó fún ètè rẹ̀ pọ̀ bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ibi.

31 Ewú orí jẹ́ adé ẹwà*+

Nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.+

32 Ẹni tí kì í tètè bínú+ sàn ju akíkanjú ọkùnrin,

Ẹni tó sì ń kápá ìbínú rẹ̀* sàn ju ẹni tó ṣẹ́gun ìlú.+

33 Orí itan ni à ń ṣẹ́ kèké lé,+

Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìpinnu tí ó bá ṣe ti wá.+

17 Òkèlè* gbígbẹ níbi tí àlàáfíà wà*+

Sàn ju ilé àsè* rẹpẹtẹ tí ìjà wà.+

 2 Ìránṣẹ́ tó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò di ọ̀gá lórí ọmọ tó ń hùwà ìtìjú,

Yóò sì pín nínú ogún bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ.

 3 Ìkòkò tí wọ́n fi ń yọ́ nǹkan mọ́ wà fún fàdákà, iná ìléru sì wà fún wúrà,+

Àmọ́ Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò ọkàn.+

 4 Ẹni burúkú máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń dunni,

Ẹlẹ́tàn sì ń fetí sí ahọ́n tó ń bani jẹ́.+

 5 Ẹni tó bá ń fi aláìní ṣẹ̀sín ń gan Ẹni tó dá a,+

Ẹni tó bá sì ń yọ̀ nítorí àjálù tó bá ẹlòmíì kò ní lọ láìjìyà.+

 6 Àwọn ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,

Ògo àwọn ọmọkùnrin* sì ni bàbá* wọn.

 7 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ́* kò yẹ òmùgọ̀.+

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ èké kò yẹ alákòóso!*+

 8 Ẹ̀bùn dà bí òkúta iyebíye* lójú ẹni tó ni ín;+

Ibi gbogbo tí ẹni náà bá yíjú sí ni yóò ti mú kó máa ṣàṣeyọrí.+

 9 Ẹni tó bá ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini* ń wá ìfẹ́,+

Àmọ́ ẹni tó bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ṣáá ń tú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.+

10 Ìbáwí tí a fún olóye máa ń ṣe é láǹfààní púpọ̀+

Ju lílu òmùgọ̀ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.+

11 Kìkì ọ̀tẹ̀ ni ẹni búburú máa ń wá,

Àmọ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ ìkà ni wọn yóò rán sí i láti fìyà jẹ ẹ́.+

12 Ó sàn kéèyàn pàdé bíárì tó ṣòfò ọmọ

Ju kéèyàn pàdé ẹni tó jẹ́ òmùgọ̀ nínú ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀. +

13 Tí ẹnikẹ́ni bá ń fi búburú san rere,

Ohun búburú kò ní kúrò ní ilé rẹ̀.+

14 Ìbẹ̀rẹ̀ ìjà dà bí ìgbà téèyàn ṣí ibú omi sílẹ̀;*

Kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.+

15 Ẹni tó bá dá ẹni burúkú láre àti ẹni tó dá olódodo lẹ́bi+

Àwọn méjèèjì jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú Jèhófà.

16 Àǹfààní wo ló jẹ́ fún òmùgọ̀ pé ó rí ọ̀nà láti ní ọgbọ́n

Nígbà tí kò ní làákàyè?*+

17 Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo,+

Ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.+

18 Ẹni tí kò ní làákàyè* ló máa ń bọ ọwọ́, tí á sì tún gbà tọkàntọkàn

Láti ṣe onídùúró* níwájú ọmọnìkejì rẹ̀.+

19 Ẹni tó bá fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀.+

Ẹni tó bá mú kí àbáwọlé rẹ̀ ga sókè ń wá ìparun.+

20 Ẹni tí ọkàn rẹ̀ burú kò ní ṣàṣeyọrí,*+

Ẹni tó bá sì ń sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yóò ṣubú sínú ìparun.

21 Ẹni tó bá bí òmùgọ̀ ọmọ yóò ní ẹ̀dùn ọkàn;

Bàbá ọmọ tí kò nírònú kì í sì í láyọ̀.+

22 Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara,*+

Àmọ́ ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.*+

23 Èèyàn burúkú yóò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀*

Láti yí ìdájọ́ po.+

24 Ọgbọ́n wà ní ọ̀gangan iwájú olóye,

Àmọ́ ojú àwọn òmùgọ̀ ń rìn gbéregbère títí dé ìkángun ayé.+

25 Òmùgọ̀ ọmọ ń fa ìbànújẹ́ fún bàbá rẹ̀

Ó sì ń fa ọgbẹ́ ọkàn* fún ìyá tó bí i.+

26 Kò dára láti fìyà jẹ* olódodo,

Kò sì tọ́ láti na àwọn èèyàn pàtàkì.

27 Ẹni tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ,+

Ẹni tó sì ní òye kì í gbaná jẹ.*+

28 Kódà òmùgọ̀ tó bá dákẹ́, a ó kà á sí ọlọ́gbọ́n,

Ẹni tó bá sì pa ètè rẹ̀ dé, a ó kà á sí olóye.

18 Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ ń wá ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀;

Gbogbo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ni yóò máa kọ̀.*

 2 Inú òmùgọ̀ kì í dùn sí òye;

Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń tú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde.+

 3 Nígbà tí ẹni burúkú bá dé, ìkórìíra náà á dé,

Ìtìjú ló sì máa ń bá àbùkù rìn.+

 4 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn dà bí odò tó jìn.+

Orísun ọgbọ́n dà bí odò tó ń ṣàn.

 5 Kò dáa kí a ṣe ojúsàájú sí ẹni burúkú+

Tàbí kí a fi ẹ̀tọ́ olódodo dù ú.+

 6 Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ máa ń dá ìjà sílẹ̀,+

Ẹnu rẹ̀ sì máa ń mú kí wọ́n lù ú.+

 7 Ẹnu òmùgọ̀ ni ìparun rẹ̀,+

Ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ẹ̀mí* rẹ̀.

 8 Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn;*+

Tí a gbé mì sínú ikùn lọ́hùn-ún.+

 9 Ẹni tó bá ya ọ̀lẹ nídìí iṣẹ́ rẹ̀,

Ọmọ ìyá ẹni tó ń fa ìparun ni.+

10 Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára.+

Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.*+

11 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀;

Lọ́kàn rẹ̀, ó dà bí ògiri tó ń dáàbò boni.+

12 Ọkàn gíga ló ń ṣáájú ìṣubú,+

Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+

13 Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀,

Ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.+

14 Ẹ̀mí èèyàn lè mú kó fara da àìsàn,+

Àmọ́, ta ló lè fara da ẹ̀mí tí ìdààmú bá?*+

15 Ọkàn ẹni tó ní òye ń gba ìmọ̀,+

Etí ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gbọ́ ìmọ̀.

16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tó fúnni;+

Ó ń jẹ́ kó dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni ńlá.

17 Ẹni tó bá kọ́kọ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ ló ń dà bíi pé ó jàre,+

Títí ẹnì kejì fi wá, tó sì bi í ní ìbéèrè.*+

18 Ṣíṣẹ́ kèké máa ń parí awuyewuye+

Ó sì ń làjà* láàárín àwọn alágbára tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀.

19 Ọmọ ìyá tí a ṣẹ̀, ó le ju ìlú olódi lọ,+

Àwọn ìjà kan sì wà tó dà bí ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè ilé gogoro tó láàbò.+

20 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa ń fi ohun rere tẹ́ ikùn rẹ̀ lọ́rùn;+

Yóò rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ohun tí ẹnu rẹ̀ sọ.

21 Ahọ́n ní agbára láti fa ikú tàbí ìyè;+

Àwọn tó bá fẹ́ràn láti máa lò ó yóò jẹ èrè rẹ̀.+

22 Ẹni tó bá rí aya rere fẹ́ ti rí ohun rere,+

Ó sì rí ojú rere* Jèhófà.+

23 Aláìní máa ń bẹ̀bẹ̀ tó bá ń sọ̀rọ̀,

Àmọ́ ọlọ́rọ̀ máa ń dáhùn lọ́nà líle.

24 Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà,+

Àmọ́ ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.+

19 Ó sàn kéèyàn jẹ́ aláìní àmọ́ kó máa rìn nínú ìwà títọ́+

Ju kéèyàn jẹ́ òmùgọ̀ kó sì máa parọ́.+

 2 Kò dára kí èèyàn* wà láìní ìmọ̀,+

Ẹ̀ṣẹ̀ sì ni kéèyàn máa fi wàdùwàdù ṣe nǹkan.*

 3 Ìwà òmùgọ̀ èèyàn ló ń lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po,

Tí ọkàn rẹ̀ fi ń bínú gidigidi sí Jèhófà.

 4 Ọrọ̀ ń mú kéèyàn ní ọ̀rẹ́ púpọ̀,

Àmọ́ ọ̀rẹ́ tálákà pàápàá yóò fi í sílẹ̀.+

 5 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,+

Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ kò ní yè bọ́.+

 6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ojú rere èèyàn pàtàkì,*

Gbogbo èèyàn ló sì ń bá ẹni tó ń fúnni lẹ́bùn ṣọ̀rẹ́.

 7 Gbogbo ọmọ ìyá tálákà máa ń kórìíra rẹ̀;+

Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó pa á tì!+

Ó ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ wọn ṣáá, àmọ́ kò sẹ́ni tó dá a lóhùn.

 8 Ẹni tó ní làákàyè* fẹ́ràn ara* rẹ̀.+

Ẹni tó fi òye ṣe ìṣúra yóò ṣàṣeyọrí.*+

 9 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,

Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ yóò ṣègbé.+

10 Kò yẹ kí òmùgọ̀ máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ;

Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí ìránṣẹ́ máa ṣe olórí àwọn ìjòyè!+

11 Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀,+

Ẹwà ló sì jẹ́ fún un pé kó gbójú fo* àṣìṣe.*+

12 Ìrunú ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn,+

Àmọ́ ojú rere rẹ̀ dà bí ìrì lára ewéko.

13 Òmùgọ̀ ọmọ ń fa àjálù bá bàbá rẹ̀,+

Oníjà* aya sì dà bí òrùlé tó ń jò ṣáá.+

14 Ọ̀dọ̀ àwọn baba ni a ti ń jogún ilé àti ọrọ̀,

Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti ń wá.+

15 Ìwà ọ̀lẹ máa ń fa oorun àsùnwọra,

Ebi yóò sì pa ẹni* tó ń ṣe ìmẹ́lẹ́.+

16 Ẹni tó ń pa àṣẹ mọ́ ń pa ẹ̀mí* rẹ̀ mọ́;+

Ẹni tí kì í kíyè sí ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.+

17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

18 Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà,+

Kí o má bàa jẹ̀bi* ikú rẹ̀.+

19 Onínúfùfù yóò jìyà ìwà rẹ̀;

Tí o bá gbà á sílẹ̀, wàá tún ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra.+

20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí,+

Kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.+

21 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn ń gbèrò nínú ọkàn rẹ̀,

Àmọ́ ìmọ̀ràn* Jèhófà ni yóò borí.+

22 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ẹwà èèyàn;+

Ó sì sàn kéèyàn jẹ́ aláìní ju kí ó jẹ́ òpùrọ́.

23 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń yọrí sí ìyè;+

Ẹni tó bá ní in yóò sun oorun àsùnwọra, láìsí aburú kankan.+

24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,

Àmọ́ kò wulẹ̀ janpata láti gbé e pa dà sí ẹnu.+

25 Gbá afiniṣẹ̀sín,+ kí aláìmọ̀kan lè ní àròjinlẹ̀,+

Sì bá olóye wí, kí ìmọ̀ rẹ̀ lè pọ̀ sí i.+

26 Ẹni tó ṣe àìdáa sí bàbá rẹ̀ tó sì lé ìyá rẹ̀ lọ

Jẹ́ ọmọ tó ń fa ìtìjú àti àbùkù.+

27 Ọmọ mi, tí o bá ṣíwọ́ fífi etí sí ìbáwí,

Wàá yà kúrò ní ọ̀nà ìmọ̀.

28 Ẹlẹ́rìí tí kò ní láárí ń fi ìdájọ́ òdodo ṣẹ̀sín,+

Ẹnu èèyàn burúkú sì ń gbé ibi mì.+

29 Ìdájọ́ ń dúró de àwọn afiniṣẹ̀sín,+

Ẹgba sì ń dúró de ẹ̀yìn àwọn òmùgọ̀.+

20 Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì,+ aláriwo ni ọtí;+

Ẹni tó bá sì tipasẹ̀ wọn ṣìnà kò gbọ́n.+

 2 Ẹ̀rù* tó wà lára ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn;+

Ẹnikẹ́ni tó bá mú un bínú ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu.+

 3 Ògo ló jẹ́ fún èèyàn láti yẹra fún ìjà,+

Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ jẹ́ aríjàgbá.+

 4 Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù,

Tó bá dìgbà ìkórè, á máa tọrọ torí pé kò ní nǹkan kan.*+

 5 Èrò* ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn,

Àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.

 6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,

Àmọ́ ibo la ti lè rí olóòótọ́ èèyàn?

 7 Olódodo ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀.+

Aláyọ̀ ni àwọn ọmọ* tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀.+

 8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ láti dájọ́,+

Ó máa ń fi ojú rẹ̀ yẹ ọ̀ràn wò kí ó lè mú gbogbo ìwà ibi kúrò.+

 9 Ta ló lè sọ pé: “Mo ti wẹ ọkàn mi mọ́;+

Mo ti mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi”?+

10 Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n èké*

Àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà.+

11 Èèyàn lè fi ìṣe ọmọdé* pàápàá dá a mọ̀,

Bóyá ìwà rẹ̀ mọ́, tí ó sì tọ́.+

12 Etí tí a fi ń gbọ́ràn àti ojú tí a fi ń ríran

Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+

13 Má ṣe nífẹ̀ẹ́ oorun, torí wàá di aláìní.+

La ojú rẹ, wàá sì máa jẹ àjẹtẹ́rùn.+

14 “Èyí ò dáa, tọ̀hún ò dáa!” ni ẹni tó ń rajà ń sọ;

Lẹ́yìn náà, ó bá tirẹ̀ lọ, ó sì ń yangàn.+

15 Wúrà wà, ọ̀pọ̀ iyùn* sì wà,

Àmọ́ ètè ìmọ̀ jẹ́ ohun tó ṣeyebíye.+

16 Gba ẹ̀wù ẹni tó bá ṣe onídùúró fún àjèjì;+

Tó bá sì jẹ́ pé obìnrin àjèjì* ló ṣe é fún, gba ohun tó fi ṣe ìdúró lọ́wọ́ rẹ̀.+

17 Oúnjẹ tí a fi èrú kó jọ máa ń dùn lẹ́nu èèyàn,

Àmọ́ tó bá yá, òkúta ni yóò kún ẹnu rẹ̀.+

18 Ìmọ̀ràn* máa ń jẹ́ kí ohun téèyàn fẹ́ ṣe yọrí sí rere,*+

Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n sì ni kí o fi ja ogun rẹ.+

19 Abanijẹ́ ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kiri;+

Má ṣe bá ẹni tó fẹ́ràn láti máa ṣòfófó* kẹ́gbẹ́.

20 Ẹni tó bá bú bàbá àti ìyá rẹ̀,

Fìtílà rẹ̀ yóò kú nígbà tí òkùnkùn bá ṣú.+

21 Ogún téèyàn bá fi ojúkòkòrò gbà níbẹ̀rẹ̀

Kì í ní ìbùkún lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+

22 Má ṣe sọ pé: “Màá fi búburú san búburú!”+

Ní ìrètí nínú Jèhófà,+ yóò sì gbà ọ́ là.+

23 Jèhófà kórìíra ìwọ̀n èké,*

Òṣùwọ̀n èké kò sì dára.

24 Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ èèyàn;+

Báwo ni èèyàn ṣe lè lóye ọ̀nà ara rẹ̀?*

25 Ìdẹkùn ni téèyàn bá sọ láìronú pé, “Mímọ́!”+

Lẹ́yìn náà, kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú lórí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́.+

26 Ọlọ́gbọ́n ọba máa ń yọ àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀+

Á sì wa àgbá kẹ̀kẹ́ ìpakà kọjá lórí wọn.+

27 Èémí èèyàn jẹ́ fìtílà Jèhófà,

Ó ń ṣàyẹ̀wò inú rẹ̀ lọ́hùn-ún.

28 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ ń dáàbò bo ọba;+

Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sì ń jẹ́ kó pẹ́ lórí ìtẹ́ rẹ̀.+

29 Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn,+

Iyì àwọn arúgbó sì ni ewú orí wọn.+

30 Ọgbẹ́ àti egbò máa ń fọ* ibi dà nù,+

Lílù sì ń fọ inú èèyàn lọ́hùn-ún mọ́.

21 Ọkàn ọba dà bí odò ní ọwọ́ Jèhófà.+

Ibi tí Ó bá fẹ́ ló ń darí rẹ̀ sí.+

 2 Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́ lójú ara rẹ̀,+

Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn.*+

 3 Kí èèyàn ṣe ohun tó dára tí ó sì tọ́

Máa ń mú inú Jèhófà dùn ju ẹbọ lọ.+

 4 Ojú ìgbéraga àti ọkàn gíga

Ni fìtílà tó ń darí àwọn ẹni burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ sì ni.+

 5 Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere,*+

Àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.+

 6 Láti fi ahọ́n èké kó ìṣúra jọ

Dà bí ìkùukùu tó ń pòórá, ìdẹkùn ikú ni.*+

 7 Ìwà ipá àwọn ẹni burúkú yóò gbá wọn dà nù,+

Torí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.

 8 Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,

Àmọ́ iṣẹ́ aláìlẹ́bi máa ń tọ́.+

 9 Ó sàn láti máa gbé ní igun òrùlé

Ju kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* gbé inú ilé kan náà.+

10 Ohun tí kò dáa ló máa ń wu ẹni* burúkú;+

Kì í ṣàánú ọmọnìkejì rẹ̀.+

11 Nígbà tí wọ́n bá fìyà jẹ afiniṣẹ̀sín, aláìmọ̀kan á kọ́gbọ́n,

Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá sì rí ìjìnlẹ̀ òye, á ní ìmọ̀.*+

12 Ọlọ́run Olódodo máa ń kíyè sí ilé ẹni burúkú;

Ó ń dojú àwọn ẹni burúkú dé kí wọ́n lè pa run.+

13 Ẹni tó bá di etí rẹ̀ sí igbe aláìní

Òun fúnra rẹ̀ yóò pè, a kò sì ní dá a lóhùn.+

14 Ẹ̀bùn tí a fúnni ní ìkọ̀kọ̀ ń mú ìbínú rọlẹ̀,+

Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a sì fúnni ní bòókẹ́lẹ́* ń mú ìbínú gbígbóná rọlẹ̀.

15 Inú olódodo máa ń dùn láti ṣe ohun tó bá ẹ̀tọ́ mu,+

Àmọ́ ó ṣòro gan-an fún àwọn tó ń hùwà burúkú.

16 Ẹni tó bá fi ọ̀nà ìjìnlẹ̀ òye sílẹ̀

Á sinmi pẹ̀lú àwọn tí ikú ti pa.*+

17 Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàájì* yóò di aláìní;+

Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró kò ní lówó lọ́wọ́.

18 Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo,

A ó sì mú oníbékebèke dípò adúróṣinṣin.+

19 Ó sàn láti máa gbé ní aginjù

Ju kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* àti oníkanra gbé.+

20 Ìṣúra tó ṣeyebíye àti òróró máa ń wà ní ilé ọlọ́gbọ́n,+

Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń fi ohun tó ní ṣòfò.*+

21 Ẹni tó bá ń wá òdodo àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀

Yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.+

22 Ọlọ́gbọ́n lè gun* ìlú àwọn alágbára

Kí ó sì mú agbára tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé balẹ̀.+

23 Ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu àti ahọ́n rẹ̀

Ń pa ara* rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́ wàhálà.+

24 Agbéraga tó ń fọ́nnu tó sì ń kọjá àyè rẹ̀

Là ń pe ẹni tó ń fi wàdùwàdù ṣe nǹkan láìbìkítà.+

25 Ohun tó ń wu ọ̀lẹ ló máa pa á,

Nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.+

26 Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ló ń ṣojúkòkòrò,

Àmọ́ olódodo ń fúnni láìfawọ́ nǹkan kan sẹ́yìn.+

27 Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra.+

Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kó mú un wá pẹ̀lú èrò ibi!*

28 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé,+

Àmọ́ ẹ̀rí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ yóò fìdí múlẹ̀.*

29 Èèyàn burúkú máa ń lo ògbójú,+

Àmọ́ adúróṣinṣin ni ọ̀nà rẹ̀ dájú.*+

30 Kò sí ọgbọ́n tàbí òye tàbí ìmọ̀ràn tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.+

31 Èèyàn lè ṣètò ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,+

Àmọ́ ti Jèhófà ni ìgbàlà.+

22 Orúkọ rere* ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀;+

Kéèyàn níyì* sàn ju fàdákà àti wúrà.

 2 Ohun tí ọlọ́rọ̀ àti aláìní fi jọra* ni pé:

Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+

 3 Ọlọ́gbọ́n* rí ewu, ó sì fara pa mọ́,

Àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.*

 4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà

Ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.+

 5 Ẹ̀gún àti pańpẹ́ wà ní ọ̀nà onímàgòmágó,

Àmọ́ ẹni tí ẹ̀mí* rẹ̀ bá jọ lójú yóò jìnnà réré sí wọn.+

 6 Tọ́ ọmọdé* ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀;+

Kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.+

 7 Ọlọ́rọ̀ ń ṣàkóso àwọn aláìní,

Ẹni tó yá nǹkan sì ni ẹrú ẹni tó yá a ní nǹkan.+

 8 Ẹni tó bá gbin àìṣòdodo yóò ká àjálù,+

Ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò sì ṣègbé.+

 9 Ọ̀làwọ́* yóò gba ìbùkún,

Nítorí ó ń fún aláìní lára oúnjẹ rẹ̀.+

10 Lé afiniṣẹ̀sín lọ,

Ìjà á tán nílẹ̀;

Àríyànjiyàn* àti àbùkù á sì dópin.

11 Ẹni tó fẹ́ràn ọkàn tó mọ́, tó sì lọ́rọ̀ rere lẹ́nu,

Yóò di ọ̀rẹ́ ọba.+

12 Ojú Jèhófà ń ṣọ́ ìmọ̀,

Àmọ́ Ó ń dojú ọ̀rọ̀ oníbékebèke dé.+

13 Ọ̀lẹ ń sọ pé: “Kìnnìún wà níta!

Àárín gbàgede ìlú ló máa pa mí sí!”+

14 Kòtò jíjìn ni ẹnu obìnrin oníwàkiwà.*+

Ẹni tí Jèhófà dá lẹ́bi yóò já sínú rẹ̀.

15 Ọkàn ọmọdé* ni ìwà òmùgọ̀ dì sí,+

Àmọ́ ọ̀pá ìbáwí yóò mú un jìnnà sí i.+

16 Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì láti túbọ̀ kó ọrọ̀ jọ+

Àti ẹni tó ń fún ọlọ́rọ̀ lẹ́bùn

Yóò di aláìní.

17 Fetí sílẹ̀ kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n,+

Kí o lè fi ọkàn rẹ sí ìmọ̀ mi,+

18 Nítorí ó dára pé kí o pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,+

Kí gbogbo wọn lè máa wà ní ètè rẹ nígbà gbogbo.+

19 Kí o lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

Ni mo ṣe ń fún ọ ní ìmọ̀ lónìí.

20 Ǹjẹ́ mi ò ti kọ̀wé sí ọ,

Láti fún ọ ní ìmọ̀ràn àti ìmọ̀,

21 Láti kọ́ ọ ní ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òótọ́ tó sì ṣe é gbára lé,

Kí o lè pa dà lọ jẹ́ iṣẹ́ tó péye fún ẹni tó rán ọ?

22 Má ja tálákà lólè torí pé kò ní lọ́wọ́,+

Má sì fojú aláìní gbolẹ̀ ní ẹnubodè,+

23 Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò gba ẹjọ́ wọn rò+

Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tó lù wọ́n ní jìbìtì.

24 Má ṣe bá onínúfùfù kẹ́gbẹ́,

Má sì bá ẹni tó máa ń tètè bínú da nǹkan pọ̀,

25 Kí o má bàa kọ́ àwọn ọ̀nà rẹ̀,

Kí o sì kó ara* rẹ sínú ìdẹkùn.+

26 Má ṣe wà lára àwọn tó ń bọ ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́,

Tí wọ́n ń ṣe onídùúró fún ẹni tó ń yá owó.+

27 Tí o kò bá rí i san,

Wọ́n á gba ibùsùn rẹ kúrò lábẹ́ rẹ!

28 Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìn

Èyí tí àwọn baba ńlá rẹ pa.+

29 Ǹjẹ́ o ti rí ọkùnrin tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀?

Yóò dúró níwájú àwọn ọba;+

Kò ní dúró níwájú àwọn èèyàn yẹpẹrẹ.

23 Nígbà tí o bá jókòó láti bá ọba jẹun,

Fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó wà níwájú rẹ;

 2 Fi ọ̀bẹ sí ara rẹ lọ́fun*

Tó bá jẹ́ pé oúnjẹ púpọ̀ lo máa ń jẹ.*

 3 Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ aládùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú,

Torí oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

 4 Má fi wàhálà pa ara rẹ torí kí o lè kó ọrọ̀ jọ.+

Fara balẹ̀ kí o sì lo òye.*

 5 Nígbà tí o bá bojú wò ó, kò ní sí níbẹ̀,+

Torí ó dájú pé ó máa hu ìyẹ́ bí ẹyẹ idì, á sì fò lọ sójú ọ̀run.+

 6 Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tó ń ṣahun;*

Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ aládùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú.

 7 Nítorí ó dà bí ẹni tó ń ṣe àkọsílẹ̀.*

Ó ń sọ fún ọ pé, “máa jẹ, máa mu,” àmọ́ kò dénú rẹ̀.*

 8 Wàá pọ àwọn òkèlè tí o ti gbé mì

Àwọn ọ̀rọ̀ ti o fi yìn ín á sì di àsọdànù.

 9 Má ṣe sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,+

Nítorí kò ní ka ọgbọ́n tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ sí.+

10 Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìn,+

Má sì wọnú ilẹ̀ àwọn aláìníbaba.

11 Nítorí Olùgbèjà* wọn lágbára;

Yóò pè ọ́ lẹ́jọ́ nítorí wọn.+

12 Fi ọkàn sí ìbáwí

Kí o sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

13 Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn fún ọmọdé.*+

Tí o bá fi ọ̀pá nà án, kò ní kú.

14 Fi ọ̀pá nà án,

Kí o lè gbà á* lọ́wọ́ Isà Òkú.*

15 Ọmọ mi, tí ọkàn rẹ bá gbọ́n,

Ọkàn tèmi náà á yọ̀.+

16 Inú mi* á dùn dé ìsàlẹ̀ ikùn

Nígbà tí ètè rẹ bá sọ ohun tí ó tọ́.

17 Kí ọkàn rẹ má ṣe jowú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+

Àmọ́ kí o máa bẹ̀rù Jèhófà láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+

18 Ìgbà náà ni ọjọ́ ọ̀la rẹ á dára+

Ìrètí rẹ kò sì ní pa rẹ́.

19 Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,

Darí ọkàn rẹ lọ́nà tí ó tọ́.

20 Má ṣe wà lára àwọn tó ń mu wáìnì lámujù,+

Tàbí àwọn tó ń jẹ ẹran ní àjẹkì,+

21 Nítorí ọ̀mùtí àti alájẹkì yóò di òtòṣì,+

Ìtòògbé yóò sì sọni di alákìísà.

22 Fetí sí bàbá rẹ tó bí ọ lọ́mọ,

Má sì pa ìyá rẹ tì torí pé ó ti darúgbó.+

23 Ra* òtítọ́, má sì tà á láé,+

Bákan náà, ra ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.+

24 Bàbá olódodo yóò máa láyọ̀;

Ẹni tó bá sì bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóò yọ̀.

25 Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò máa yọ̀,

Inú ìyá tó bí ọ yóò sì máa dùn.

26 Ọmọ mi, fi ọkàn rẹ fún mi,

Kí ojú rẹ sì fẹ́ràn àwọn ọ̀nà mi.+

27 Nítorí pé kòtò jíjìn ni aṣẹ́wó,

Kànga tóóró sì ni obìnrin oníṣekúṣe.*+

28 Ó máa ń lúgọ deni bí ọlọ́ṣà;+

Ó ń mú kí àwọn ọkùnrin aláìṣòótọ́ pọ̀ sí i.

29 Ta ló ni ìyà? Ta ló ni àìnírọ̀rùn?

Ta ló ni ìjà? Ta ló ni àròyé?

Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú tó ń ṣe bàìbàì?*

30 Àwọn tó ń pẹ́ nídìí wáìnì ni;+

Àwọn tó ń wá àdàlù wáìnì kàn.*

31 Má ṣe wo àwọ̀ pupa wáìnì

Bó ṣe ń ta wíríwírí nínú ife, tó sì ń lọ tìnrín,

32 Torí níkẹyìn, á buni ṣán bí ejò,

Á sì tu oró jáde bíi paramọ́lẹ̀.

33 Ojú rẹ yóò rí àwọn ohun àjèjì,

Ọkàn rẹ yóò sì sọ àwọn ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.+

34 Wàá dà bí ẹni tó dùbúlẹ̀ sí àárín òkun,

Bí ẹni tó dùbúlẹ̀ sí orí òpó ọkọ̀ òkun.

35 Wàá sọ pé: “Wọ́n lù mí, àmọ́ mi ò mọ̀ ọ́n lára.*

Wọ́n nà mí, àmọ́ mi ò mọ̀.

Ìgbà wo ni màá jí?+

Ẹ fún mi lọ́tí sí i.”*

24 Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi,

Má sì jẹ́ kó máa wù ọ́ láti bá wọn kẹ́gbẹ́,+

 2 Nítorí ìwà ipá ni ọkàn wọn ń rò,

Ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìjàngbọ̀n.

 3 Ọgbọ́n la fi ń gbé ilé* ró,+

Òye sì la fi ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

 4 Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ yóò fi kún fún

Onírúurú ìṣúra tó ṣeyebíye tó sì fani mọ́ra.+

 5 Ẹni tó gbọ́n jẹ́ alágbára,+

Ìmọ̀ sì ni èèyàn fi ń mú kí agbára rẹ̀ pọ̀ sí i.

 6 Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n ni kí o fi ja ogun rẹ,+

Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* ìṣẹ́gun* á wà.+

 7 Ọgbọ́n tòótọ́ ga ju ohun tí ọwọ́ òmùgọ̀ lè tẹ̀;+

Kò* ní ohun kankan láti sọ ní ẹnubodè ìlú.

 8 Ẹnikẹ́ni tó bá ń gbèrò ibi,

Ọ̀gá elétekéte la ó máa pè é.+

 9 Èrò tí kò mọ́gbọ́n dání* máa ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀,

Àwọn èèyàn sì máa ń kórìíra afiniṣẹ̀sín.+

10 Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà,*

Agbára rẹ ò ní tó nǹkan.

11 Gba àwọn tí wọ́n fẹ́ lọ pa sílẹ̀,

Sì fa àwọn tó ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sí ibi pípa sẹ́yìn.+

12 Tí o bá sọ pé: “Ṣebí a ò mọ̀ nípa rẹ̀,”

Ṣé Ẹni tó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn* kò mọ̀ ni?+

Bẹ́ẹ̀ ni, Ẹni tó ń wò ọ́* máa mọ̀

Yóò sì san ẹnì kọ̀ọ̀kan lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.+

13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí ó dára;

Oyin inú afárá sì ń dùn lẹ́nu.

14 Lọ́nà kan náà, mọ̀ pé ọgbọ́n dára fún ọ.*+

Tí o bá wá a rí, ọjọ́ ọ̀la rẹ á dára

Ìrètí rẹ kò sì ní pa rẹ́.+

15 Má ṣe lúgọ sí tòsí ilé olódodo láti ṣe é níbi;

Má ṣe ba ibi ìsinmi rẹ̀ jẹ́.

16 Nítorí olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde,+

Àmọ́ àjálù yóò mú kí ẹni burúkú ṣubú pátápátá.+

17 Tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má ṣe dunnú,

Tó bá sì kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ yọ̀;+

18 Nítorí Jèhófà yóò rí i, á sì bí i nínú,

Á sì yí ìbínú rẹ̀ kúrò lórí rẹ̀.*+

19 Má ṣe kanra* nítorí àwọn aṣebi;

Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi.

20 Nítorí ọjọ́ ọ̀la ẹni ibi kò lè dáa;+

Fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.+

21 Ọmọ mi, bẹ̀rù Jèhófà àti ọba.+

Má sì bá àwọn oníyapa* kẹ́gbẹ́.+

22 Nítorí àjálù wọn yóò dé lójijì.+

Ta ló mọ ìparun tí àwọn méjèèjì* máa mú bá wọn?+

23 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tún jẹ́ ti àwọn ọlọ́gbọ́n:

Kò dára láti máa ṣe ojúsàájú nínú ìdájọ́.+

24 Ẹni tó bá ń sọ fún ẹni burúkú pé, “Olódodo ni ọ́,”+

Àwọn èèyàn yóò gégùn-ún fún un, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì dá a lẹ́bi.

25 Àmọ́ yóò dáa fún àwọn tó ń bá a wí;+

Òjò ìbùkún ohun rere yóò rọ̀ sórí wọn.+

26 Àwọn èèyàn yóò fi ẹnu ko ètè ẹni tó ń fi òótọ́ inú fèsì.*+

27 Múra iṣẹ́ tí o máa ṣe lóde sílẹ̀, kí o sì wá gbogbo nǹkan sílẹ̀ ní pápá;

Lẹ́yìn náà, kọ́ ilé* rẹ.

28 Má ṣe ta ko ọmọnìkejì rẹ láìnídìí.+

Má ṣe fi ètè rẹ tanni jẹ.+

29 Má sọ pé: “Bó ṣe ṣe sí mi ni màá ṣe sí i pa dà;

Màá san ohun tó ṣe pa dà fún un.”*+

30 Mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ oko ọ̀lẹ,+

Lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹni tí kò ní làákàyè.*

31 Mo rí i pé igbó ti kún bò ó;

Èsìsì ti bo ilẹ̀ rẹ̀,

Ògiri olókùúta rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀.+

32 Mo kíyè sí i, mo sì fi í sọ́kàn;

Mo rí i, mo sì kọ́ ẹ̀kọ́* yìí:

33 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,

Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,

34 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,

Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+

25 Àwọn òwe míì tí Sólómọ́nì pa,+ èyí tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà+ ọba Júdà dà kọ* nìyí:

 2 Ògo Ọlọ́run ni láti pa ọ̀rọ̀ mọ́ ní àṣírí,+

Ògo àwọn ọba sì ni láti wádìí ọ̀rọ̀ kínníkínní.

 3 Bí ọ̀run ṣe ga, tí ilẹ̀ sì jìn,

Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn àwọn ọba jẹ́ ohun àwámáridìí.

 4 Yọ́ ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà,

Á sì mọ́ pátápátá.+

 5 Mú ẹni burúkú kúrò níwájú ọba,

Ìtẹ́ rẹ̀ yóò sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo.+

 6 Má bọlá fún ara rẹ níwájú ọba,+

Má sì jókòó ní àyè àwọn ẹni ńlá,+

 7 Nítorí ó sàn kó sọ fún ọ pé, “Máa bọ̀ níbí,”

Ju pé kó kàn ọ́ lábùkù níwájú àwọn èèyàn pàtàkì.+

 8 Má fi ìkánjú gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́,

Àbí kí lo máa ṣe tí ọmọnìkejì rẹ bá kàn ọ́ lábùkù?+

 9 Ro ẹjọ́ rẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ,+

Àmọ́ má sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tí o gbọ́,*+

10 Kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ má bàa kó ìtìjú bá ọ,

Ọ̀rọ̀ burúkú* tí o tàn kálẹ̀ kò sì ní ṣeé kó pa dà.

11 Bí àwọn èso ápù oníwúrà tó wà nínú abọ́* fàdákà

Ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.+

12 Bíi yẹtí wúrà àti ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi wúrà tó dára ṣe

Ni ọlọ́gbọ́n tó ń báni wí jẹ́ ní etí ẹni tó ń gbọ́ràn.+

13 Bí ìtutù yìnyín ní ọjọ́ ìkórè

Ni òjíṣẹ́ olóòótọ́ jẹ́ fún àwọn tó rán an,

Nítorí ó ń mára tu ọ̀gá rẹ̀.*+

14 Bí òjò tó ṣú, tó sì ń fẹ́ atẹ́gùn àmọ́ tí kò rọ̀

Ni ọkùnrin tó ń fọ́nnu lórí ẹ̀bùn tí kò ní fúnni.*+

15 Sùúrù la fi ń yí aláṣẹ lọ́kàn pa dà,

Ahọ́n pẹ̀lẹ́* sì lè fọ́ egungun.+

16 Tí o bá rí oyin, èyí tí o nílò nìkan ni kí o jẹ,

Torí tí o bá jẹ ẹ́ ní àjẹjù, o lè bì í.+

17 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣe lemọ́lemọ́ ní ilé ọmọnìkejì rẹ,

Kí ọ̀rọ̀ rẹ má bàa sú u, kó sì kórìíra rẹ.

18 Bíi kùmọ̀ ogun àti idà àti ọfà tó mú

Ni ẹni tó ń jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ̀.+

19 Bí eyín tó ká tàbí ẹsẹ̀ tó ń gbò yèpéyèpé

Ni ìgbọ́kànlé téèyàn ní nínú ẹni tí kò ṣe é fọkàn tán* lásìkò wàhálà.

20 Bí ẹni tó bọ́ aṣọ lọ́jọ́ òtútù

Àti bí ọtí kíkan tí wọ́n dà sórí sódà*

Ni ẹni tó ń kọrin fún ọkàn tí ìbànújẹ́ bá.+

21 Tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ,* fún un ní oúnjẹ jẹ;

Tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu,+

22 Torí ṣe ni wàá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí,*+

Jèhófà yóò sì san èrè fún ọ.

23 Ẹ̀fúùfù láti àríwá ń mú kí òjò rọ̀,

Ahọ́n tó ń ṣòfófó sì ń mú kí ojú fà ro.+

24 Ó sàn láti máa gbé ní igun òrùlé

Ju kéèyàn máa bá aya tó jẹ́ oníjà* gbé inú ilé kan náà.+

25 Bí omi tútù lára ẹni* tí àárẹ̀ mú

Ni ìròyìn rere láti ilẹ̀ tó jìnnà.+

26 Bí ìsun omi tó rú àti kànga tó ti bà jẹ́

Ni olódodo tó gbà fún* ẹni burúkú.

27 Kò dára láti jẹ oyin ní àjẹjù,+

Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ògo kankan nínú kéèyàn máa wá ògo ara rẹ̀.+

28 Bí ìlú tí a ya wọ̀, tí kò ní ògiri,

Ni ẹni tí kò lè kápá ìbínú* rẹ̀.+

26 Bíi yìnyín nígbà ẹ̀ẹ̀rùn àti òjò nígbà ìkórè,

Bẹ́ẹ̀ ni ògo kò yẹ òmùgọ̀.+

 2 Bí ẹyẹ kì í ṣeé fò láìnídìí, tí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ kì í sì í ṣàdédé fò,

Bẹ́ẹ̀ ni ègún kì í dédé wá láìsí ìdí kan pàtó.*

 3 Pàṣán wà fún ẹṣin, ìjánu wà fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,+

Ọ̀pá sì wà fún ẹ̀yìn àwọn òmùgọ̀.+

 4 Má ṣe fún òmùgọ̀ lésì gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀,

Kí o má bàa fi ara rẹ sí ipò rẹ̀.*

 5 Fún òmùgọ̀ lésì gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,

Kó má bàa rò pé òun gbọ́n.+

 6 Bí ẹni tó dá ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀, tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe*

Ni ẹni tó fa ọ̀ràn lé òmùgọ̀ lọ́wọ́.

 7 Bí ẹsẹ̀ arọ tó ṣe jọwọrọ,*

Bẹ́ẹ̀ ni òwe rí lẹ́nu àwọn òmùgọ̀.+

 8 Bí ẹni ń so òkúta mọ́ kànnàkànnà

Ni téèyàn bá ń fi ògo fún òmùgọ̀.+

 9 Bíi koríko ẹlẹ́gùn-ún tó dé ọwọ́ ọ̀mùtí,

Bẹ́ẹ̀ ni òwe rí lẹ́nu àwọn òmùgọ̀.

10 Bíi tafàtafà tó ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti rí léṣe,*

Ni ẹni tó gbéṣẹ́ fún òmùgọ̀ tàbí àwọn tó ń kọjá lọ.

11 Bí ajá tó pa dà sídìí èébì rẹ̀,

Bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ ṣe ń tún ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀ hù.+

12 Ṣe o ti rí ẹni tó rò pé òun gbọ́n?+

Ìrètí wà fún òmùgọ̀ jù ú lọ.

13 Ọ̀lẹ ń sọ pé: “Ọmọ kìnnìún wà lójú ọ̀nà,

Kìnnìún wà ní gbàgede ìlú!”+

14 Ilẹ̀kùn ń yí lórí ìkọ́* rẹ̀,

Ọ̀lẹ náà ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.+

15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,

Àmọ́, ó rẹ̀ ẹ́ débi pé kò lè gbé e pa dà sẹ́nu.+

16 Ọ̀lẹ rò pé òun gbọ́n

Ju àwọn méje tó lè fèsì tó mọ́gbọ́n dání.

17 Bí ẹni tó gbá etí ajá mú

Ni ẹni tó ń kọjá lọ, tínú sì ń bí lórí* ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.+

18 Bíi wèrè tó ń ta ohun ọṣẹ́ oníná, ọfà àti ikú*

19 Ni ẹni tó tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ, tó wá sọ pé, “Eré ni mò ń ṣe!”+

20 Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú,

Níbi tí kò bá sì sí abanijẹ́, ìjà á tán.+

21 Bí èédú ṣe wà fún ẹyin iná, tí igi sì wà fún iná,

Bẹ́ẹ̀ ni alárìíyànjiyàn ṣe máa ń dá ìjà sílẹ̀.+

22 Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn;*

Tí a gbé mì sínú ikùn lọ́hùn-ún.+

23 Bíi fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́ tó bo àfọ́kù ìkòkò

Ni ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tó ń jáde látinú* ọkàn búburú.+

24 Ẹni tó kórìíra ẹlòmíì máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu bò ó mọ́lẹ̀,

Àmọ́ ẹ̀tàn ló fi sínú.

25 Bó tilẹ̀ ń sọ ohun rere, má gbà á gbọ́,

Nítorí ohun ìríra méje ló wà lọ́kàn rẹ̀.*

26 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ẹ̀tàn bo ìkórìíra rẹ̀ mọ́lẹ̀,

A ó tú ìwà burúkú rẹ̀ síta nínú ìjọ.

27 Ẹni tó gbẹ́ kòtò yóò já sínú rẹ̀,

Ẹni tó bá sì yí òkúta kúrò, òkúta náà yóò pa dà sórí rẹ̀.+

28 Ẹni tó ní ahọ́n èké kórìíra àwọn tó fi ń bà jẹ́,

Ẹnu tó ń pọ́nni sì ń fa ìparun.+

27 Má ṣe máa fọ́nnu nípa ọ̀la,

Torí o ò mọ bí ọ̀la ṣe máa rí.*+

 2 Ẹlòmíì* ni kó yìn ọ́, kì í ṣe ẹnu tìrẹ;

Àwọn míì* ni kó ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ.+

 3 Òkúta wúwo, iyanrìn sì tẹ̀wọ̀n,

Àmọ́ ìbínú tí òmùgọ̀ máa ń fà wúwo ju àwọn méjèèjì lọ.+

 4 Ìrunú jẹ́ ìwà ìkà, ìbínú sì dà bí àkúnya omi,

Àmọ́ ta ló lè dúró níwájú owú?+

 5 Ìbáwí tí a fúnni níta sàn ju ìfẹ́ tí a fi pa mọ́ lọ.+

 6 Àwọn ọgbẹ́ tí ọ̀rẹ́ dá síni lára jẹ́ ìṣòtítọ́,+

Àmọ́ ìfẹnukonu ọ̀tá pọ̀ rẹpẹtẹ.*

 7 Ẹni* tó bá ti yó kì í ka oyin inú afárá sí,*

Àmọ́ ní ti ẹni* tí ebi ń pa, ohun tó korò pàápàá á dùn lẹ́nu rẹ̀.

 8 Bí ẹyẹ tó ṣìnà* ìtẹ́ rẹ̀

Ni ẹni tó ṣìnà ilé rẹ̀ rí.

 9 Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀;

Bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.+

10 Má fi ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ọ̀rẹ́ bàbá rẹ sílẹ̀,

Má sì wọ ilé ọmọ ìyá rẹ ní ọjọ́ àjálù rẹ;

Aládùúgbò tó wà nítòsí sàn ju ọmọ ìyá tó jìnnà réré.+

11 Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn mi yọ̀,+

Kí n lè fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi lésì.+

12 Ọlọ́gbọ́n* rí ewu, ó sì fara pa mọ́,+

Àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.*

13 Gba ẹ̀wù ẹni tó bá ṣe onídùúró fún àjèjì;

Tó bá sì jẹ́ pé obìnrin àjèjì* ló ṣe é fún, gba ohun tó fi ṣe ìdúró lọ́wọ́ rẹ̀.+

14 Tí ẹnì kan bá ń fi ohùn tó ròkè súre fún ọmọnìkejì rẹ̀ láàárọ̀ kùtù,

Ńṣe ni àwọn èèyàn máa sọ pé ó ń gégùn-ún.

15 Aya tó jẹ́ oníjà* dà bí òrùlé tó ń jò ṣùrùṣùrù lọ́jọ́ tí òjò ń rọ̀.+

16 Ẹni tó bá lè kápá rẹ̀ lè kápá ẹ̀fúùfù,

Á sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ di òróró mú.

17 Bí irin ṣe ń pọ́n irin,

Bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n* ọ̀rẹ́ rẹ̀.+

18 Ẹni tó bá ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èso rẹ̀,+

Ẹni tó bá sì ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ògo.+

19 Bí omi ṣe ń fi ìrísí ojú hàn,

Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn èèyàn ń fi ti ẹlòmíì hàn.

20 Isà Òkú àti ibi ìparun* kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,+

Bẹ́ẹ̀ ni ojú èèyàn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.

21 Bí ìkòkò tí wọ́n fi ń yọ́ nǹkan mọ́ ṣe wà fún fàdákà, tí iná ìléru sì wà fún wúrà,+

Bẹ́ẹ̀ ni ìyìn tí ẹnì kan gbà ṣe ń dán an wò.*

22 Kódà tí o bá fi ọmọ odó gún òmùgọ̀

Bí ọkà tí a ti pa nínú odó,

Ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀ kò ní fi í sílẹ̀.

23 Ó yẹ kí o mọ bí agbo ẹran rẹ ṣe rí ní àmọ̀dunjú.

Tọ́jú* àwọn àgùntàn rẹ dáadáa,+

24 Nítorí ọrọ̀ kì í wà títí láé,+

Bẹ́ẹ̀ ni adé* kì í wà jálẹ̀ gbogbo ìran.

25 Bí koríko tútù ṣe ń pa rẹ́, tí koríko tuntun ń fara hàn,

Bẹ́ẹ̀ ni à ń kó àwọn ewéko orí òkè wálé.

26 Àwọn ọmọ àgbò ń pèsè aṣọ rẹ,

Àwọn òbúkọ sì ń pèsè owó pápá.

27 Wàrà ewúrẹ́ tí ó pọ̀ tó yóò sì wà láti bọ́ ìwọ

Àti agbo ilé rẹ àti láti gbé ẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ ró.

28 Ẹni burúkú ń sá nígbà tí ẹnì kankan kò lé e,

Àmọ́ olódodo láyà bíi kìnnìún.*+

 2 Tí ẹ̀ṣẹ̀* bá wà ní ilẹ̀ kan, olórí ibẹ̀ kì í pẹ́ kí òmíì tó jẹ,+

Àmọ́ nípasẹ̀ ẹnì kan tó ní òye àti ìmọ̀, olórí* yóò pẹ́ lórí ìtẹ́.+

 3 Tálákà tó ń lu aláìní ní jìbìtì,+

Ó dà bí òjò tó ń gbá gbogbo oúnjẹ lọ.

 4 Àwọn tó ń pa òfin tì máa ń yin àwọn ẹni burúkú,

Àmọ́ àwọn tó ń pa òfin mọ́ máa ń bínú sí wọn.+

 5 Àwọn ẹni ibi kò lè lóye ìdájọ́ òdodo,

Àmọ́ àwọn tó ń wá Jèhófà ń lóye ohun gbogbo.+

 6 Aláìní tó ń rìn nínú ìwà títọ́

Sàn ju olówó tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́ lọ.+

 7 Ọmọ tó lóye máa ń pa òfin mọ́,

Àmọ́ ẹni tó ń bá àwọn alájẹkì kẹ́gbẹ́ ń dójú ti bàbá rẹ̀.+

 8 Ẹni tó ń gba èlé+ àti èlé gọbọi láti mú kí ọrọ̀ rẹ̀ pọ̀

Ń kó o jọ fún ẹni tó ń ṣàánú aláìní.+

 9 Ẹni tí kì í fetí sí òfin,

Àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìríra.+

10 Ẹni tó bá ń ṣi adúróṣinṣin lọ́nà láti ṣe búburú máa já sínú kòtò òun fúnra rẹ̀,+

Àmọ́ àwọn aláìlẹ́bi máa jogún ohun rere.+

11 Ọlọ́rọ̀ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,+

Àmọ́ aláìní tó ní òye lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+

12 Nígbà tí olódodo bá borí, ìdùnnú á ṣubú layọ̀,

Àmọ́ nígbà tí agbára bá dọ́wọ́ ẹni burúkú, àwọn èèyàn á lọ fara pa mọ́.+

13 Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí,+

Àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.+

14 Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń kíyè sára* nígbà gbogbo,

Àmọ́ ẹni tó bá ń sé ọkàn rẹ̀ le yóò ṣubú sínú ìyọnu.+

15 Bíi kìnnìún tó ń kùn àti bíárì tó ń kù gììrì mọ́ nǹkan

Ni ìkà èèyàn tó ń ṣàkóso àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+

16 Aṣáájú tí kò lóye máa ń ṣi agbára lò,+

Àmọ́ ẹni tó kórìíra èrè tí kò tọ́ yóò mú ẹ̀mí ara rẹ̀ gùn.+

17 Ẹni tí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá wọ̀ lọ́rùn torí pé ó gba ẹ̀mí èèyàn* yóò máa sá títí á fi wọnú sàréè.*+

Kí ẹnì kankan má ṣe dì í mú.

18 Ẹni tó bá ń rìn láìlẹ́bi ni a ó gbà là,+

Àmọ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́ yóò ṣubú lójijì.+

19 Ẹni tó bá ń ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ tó pọ̀,

Àmọ́ ẹni tó ń lé àwọn ohun tí kò ní láárí yóò di òtòṣì paraku.+

20 Olóòótọ́ èèyàn yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún,+

Àmọ́ ọwọ́ ẹni tó ń kánjú láti di olówó kò lè mọ́.+

21 Kò dáa kéèyàn máa ṣe ojúsàájú;+

Àmọ́ èèyàn lè ṣe ohun tí kò tọ́ nítorí búrẹ́dì tí kò tó nǹkan.

22 Onílara* èèyàn ń wá bó ṣe máa di olówó,

Kò mọ̀ pé òṣì máa ta òun.

23 Ẹni tó bá ń báni wí+ yóò rí ojú rere níkẹyìn+

Ju ẹni tó ń fi ahọ́n rẹ̀ pọ́nni.

24 Ẹni tó bá ja bàbá àti ìyá rẹ̀ lólè tó sì ń sọ pé, “Kò sóhun tó burú níbẹ̀,”+

Ẹlẹgbẹ́ ẹni tó ń fa ìparun ni.+

25 Olójúkòkòrò* máa ń dá ìyapa sílẹ̀,

Àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò láásìkí.*+

26 Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn ara rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀,+

Àmọ́ ẹni tó ń fi ọgbọ́n rìn yóò yè bọ́.+

27 Ẹni tó bá ń fún aláìní ní nǹkan kò ní ṣaláìní,+

Àmọ́ ẹni tó bá ń gbójú kúrò lára wọn yóò gba ọ̀pọ̀ ègún.

28 Nígbà tí agbára bá dọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú, àwọn èèyàn á fara pa mọ́,

Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá ṣègbé, olódodo á pọ̀ sí i.+

29 Ẹni tó ń mú ọrùn rẹ̀ le* lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí +

Yóò pa run lójijì láìsí àtúnṣe.+

 2 Nígbà tí olódodo bá pọ̀, àwọn èèyàn á máa yọ̀,

Àmọ́ tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn èèyàn á máa kérora.+

 3 Ẹni tó fẹ́ràn ọgbọ́n ń mú bàbá rẹ̀ yọ̀,+

Àmọ́ ẹni tó ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ń fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò.+

 4 Ìdájọ́ òdodo ni ọba fi ń mú kí ilẹ̀ rẹ̀ tòrò,+

Àmọ́ ẹni tó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò da ibẹ̀ rú.

 5 Ẹni tó ń pọ́n ọmọnìkejì rẹ̀

Ń ta àwọ̀n fún ẹsẹ̀ rẹ̀.+

 6 Ẹ̀ṣẹ̀ èèyàn búburú ń dẹkùn mú un,+

Àmọ́ olódodo ń kígbe ayọ̀, inú rẹ̀ sì ń dùn.+

 7 Ẹ̀tọ́ àwọn aláìní jẹ olódodo lọ́kàn,+

Àmọ́ ẹni burúkú kì í ronú irú nǹkan bẹ́ẹ̀.+

 8 Àwọn tó ń fọ́nnu máa ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ nínú ìlú,+

Àmọ́ àwọn tó gbọ́n máa ń paná ìbínú.+

 9 Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá ń bá òmùgọ̀ fa ọ̀rọ̀,

Ariwo àti yẹ̀yẹ́ á gbòde kan, síbẹ̀ kò ní sí ìsinmi.+

10 Àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ máa ń kórìíra ẹni tó bá jẹ́ aláìṣẹ̀,*+

Wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí* àwọn adúróṣinṣin.*

11 Gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára* òmùgọ̀ ló máa ń sọ jáde,+

Àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń mú sùúrù.+

12 Tí alákòóso bá ti ń fetí sí irọ́,

Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò di ẹni burúkú.+

13 Ohun tí aláìní àti aninilára fi jọra* ni pé:

Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú àwọn méjèèjì.*

14 Tí ọba bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní bó ṣe tọ́,+

Ìtẹ́ rẹ̀ á fìdí múlẹ̀ títí lọ.+

15 Ọ̀pá* àti ìbáwí ń kọ́ni ní ọgbọ́n,+

Àmọ́ ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.

16 Tí àwọn ẹni burúkú bá ti ń pọ̀ sí i, ẹ̀ṣẹ̀ á máa pọ̀ sí i,

Àmọ́ àwọn olódodo yóò rí ìṣubú wọn.+

17 Kọ́ ọmọ rẹ, yóò fún ọ ní ìsinmi;

Yóò sì mú inú rẹ dùn* gan-an.+

18 Níbi tí kò bá ti sí ìran,* àwọn èèyàn á máa ṣe bó ṣe wù wọ́n,+

Àmọ́ aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa òfin mọ́.+

19 Ìránṣẹ́ kì í jẹ́ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ẹnu tọ́ òun sọ́nà,

Bó tiẹ̀ yé e, kò ní ṣègbọràn.+

20 Ṣé o ti rí ẹni tí kì í ronú kó tó sọ̀rọ̀?+

Ìrètí wà fún òmùgọ̀ ju fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ.+

21 Tí a bá kẹ́ ìránṣẹ́ kan ní àkẹ́jù látìgbà èwe rẹ̀,

Tó bá yá, kò ní mọ ọpẹ́ dá.

22 Ẹni tó bá ń tètè bínú máa ń dá wàhálà sílẹ̀;+

Onínúfùfù sì máa ń dá ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀.+

23 Ìgbéraga èèyàn ni yóò rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀,+

Àmọ́ ẹni tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò gba ògo.+

24 Ẹni tó ń bá olè kẹ́gbẹ́ kórìíra ara rẹ̀.*

Ó lè gbọ́ pé kí àwọn èèyàn wá jẹ́rìí,* àmọ́ kò ní sọ nǹkan kan.+

25 Ìbẹ̀rù* èèyàn jẹ́* ìdẹkùn,+

Àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò rí ààbò.+

26 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ bá alákòóso sọ̀rọ̀,*

Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èèyàn ti ń rí ìdájọ́ òdodo gbà.+

27 Aláìṣòótọ́ jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú olódodo,+

Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́ sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú èèyàn burúkú.+

30 Àwọn ohun pàtàkì tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ágúrì ọmọ Jákè sọ fún Ítíélì, ìyẹn fún Ítíélì àti Úkálì.

 2 Mo jẹ́ aláìmọ̀kan ju ẹnikẹ́ni lọ,+

Mi ò sì ní òye tó yẹ kí èèyàn ní.

 3 Mi ò tíì kọ́ ọgbọ́n,

Mi ò sì tíì ní ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.

 4 Ta ló ti gòkè lọ sí ọ̀run tó sì sọ̀ kalẹ̀ wá?+

Ta ló ti kó ẹ̀fúùfù jọ sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ méjèèjì?

Ta ló ti di omi sínú aṣọ rẹ̀?+

Ta ló ti fi ìdí gbogbo ìkángun ayé sọlẹ̀?*+

Kí ni orúkọ rẹ̀, kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀, tí o bá mọ̀ ọ́n?

 5 Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́.+

Ó* jẹ́ apata fún àwọn tó ń wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.+

 6 Má fi nǹkan kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,+

Nítorí á bá ọ wí,

Wàá sì di òpùrọ́.

 7 Ohun méjì ni mo béèrè lọ́wọ́ rẹ.

Má ṣàì fún mi kí n tó kú.

 8 Mú kí àìṣòótọ́ àti irọ́ jìnnà sí mi.+

Má ṣe fún mi ní òṣì tàbí ọrọ̀.

Ṣáà jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi,+

 9 Kí n má bàa yó tán, kí n sì sẹ́ ọ, kí n sọ pé, “Ta ni Jèhófà?”+

Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n wá jalè, kí n sì kó ìtìjú bá* orúkọ Ọlọ́run mi.

10 Má ṣe ba ìránṣẹ́ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀,

Nítorí ó lè gégùn-ún fún ọ, wàá sì jẹ̀bi.+

11 Ìran kan wà tó ń gégùn-ún fún bàbá rẹ̀,

Kì í sì í súre fún ìyá rẹ̀.+

12 Ìran kan wà tó mọ́ lójú ara rẹ̀+

Àmọ́ a kò tíì wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin* rẹ̀.

13 Ìran kan wà tó ní ojú ìgbéraga

Ó sì jọ ara rẹ̀ lójú gan-an!+

14 Ìran kan wà tí eyín rẹ̀ jẹ́ idà,

Egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀bẹ ìpẹran;

Wọ́n ń jẹ àwọn aláìní inú ayé run

Wọ́n sì ń jẹ àwọn òtòṣì run láàárín aráyé.+

15 Àwọn eṣúṣú* ní ọmọbìnrin méjì tó ń ké pé, “Mú wá! Mú wá!”

Ohun mẹ́ta wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,

Àní ohun mẹ́rin tí kì í sọ pé, “Ó tó!”

16 Isà Òkú*+ àti inú àgàn,*

Ilẹ̀ tí kò ní omi

Àti iná tí kì í sọ pé, “Ó tó!”

17 Ojú tó ń fi bàbá ṣẹ̀sín, tí kì í sì í ṣègbọràn sí ìyá,+

Àwọn ẹyẹ ìwò tó wà ní àfonífojì yóò yọ ọ́ jáde,

Àwọn ọmọ ẹyẹ idì yóò sì mú un jẹ.+

18 Ohun mẹ́ta wà tó kọjá òye mi,*

Àní ohun mẹ́rin tí kò yé mi:

19 Ọ̀nà ẹyẹ idì lójú ọ̀run,

Ọ̀nà ejò lórí àpáta,

Ọ̀nà ọkọ̀ òkun lójú agbami,

Àti ọ̀nà ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin.

20 Ọ̀nà obìnrin alágbèrè nìyí:

Ó jẹun, ó nu ẹnu rẹ̀;

Ó sì sọ pé, “Mi ò ṣe nǹkan kan tó burú.”+

21 Ohun mẹ́ta wà tó ń mú kí ayé mì jìgìjìgì,

Àní ohun mẹ́rin tí ayé kò lè fara dà:

22 Tí ẹrú bá di ọba,+

Tí òmùgọ̀ bá jẹun yó,

23 Tí obìnrin tí wọ́n kórìíra* bá di ìyàwó,

Àti nígbà tí ìránṣẹ́bìnrin bá gba ipò ọ̀gá rẹ̀ obìnrin.*+

24 Àwọn ohun mẹ́rin kan wà lára àwọn ohun tó kéré jù lọ ní ayé,

Àmọ́ tí wọ́n ní ọgbọ́n àdámọ́ni:*+

25 Àwọn èèrà jẹ́ ẹ̀dá* tí kò lágbára,

Síbẹ̀, wọ́n ń kó oúnjẹ wọn jọ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn.+

26 Àwọn gara orí àpáta*+ jẹ́ ẹ̀dá* tí kò lágbára,

Síbẹ̀, wọ́n ń kọ́ ilé wọn sínú àpáta.+

27 Àwọn eéṣú+ kò ní ọba,

Síbẹ̀, gbogbo wọn máa ń jáde lọ létòlétò.*+

28 Ọmọńlé+ máa ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ̀ mọ́ nǹkan,

Ó sì ń wọnú ààfin ọba.

29 Àwọn ohun mẹ́ta wà tí ìṣísẹ̀ wọn jọni lójú,

Àní ohun mẹ́rin tí ìrìn wọn dùn-ún wò:

30 Kìnnìún, tó jẹ́ pé òun ló lágbára jù nínú àwọn ẹranko,

Tí kì í sì í yíjú pa dà níwájú ẹnikẹ́ni;+

31 Ajá ọdẹ; òbúkọ;

Àti ọba tí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

32 Tí o bá ti jẹ́ kí ìwà òmùgọ̀ mú kí o gbéra ga+

Tàbí tí o bá ti gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀,

Fi ọwọ́ bo ẹnu rẹ.+

33 Nítorí bí pípo wàrà pọ̀ ṣe ń mú bọ́tà jáde,

Tí fífún imú pọ̀ sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,

Bẹ́ẹ̀ ni mímú inú bíni máa ń dá ìjà sílẹ̀.+

31 Àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Lémúẹ́lì, ọ̀rọ̀ pàtàkì tí ìyá rẹ̀ fi dá a lẹ́kọ̀ọ́:+

 2 Kí ni kí n sọ fún ọ, ọmọ mi,

Kí ni kí n sọ, ìwọ ọmọ ikùn mi,

Kí sì ni kí n sọ, ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi?+

 3 Má fi okun rẹ fún àwọn obìnrin,+

Má sì tọ ọ̀nà tó ń fa ìparun bá àwọn ọba.+

 4 Lémúẹ́lì, kò tọ́ sí àwọn ọba,

Kò tọ́ kí àwọn ọba máa mu wáìnì

Tàbí kí àwọn alákòóso máa sọ pé, “Ọtí mi dà?”+

 5 Kí wọ́n má bàa mutí tán, kí wọ́n wá gbàgbé àṣẹ tó wà nílẹ̀,

Kí wọ́n sì fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n.

 6 Fún àwọn tó ń kú lọ ní ọtí+

Àti wáìnì fún àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn bá.*+

 7 Kí wọ́n mu, kí wọ́n gbàgbé ipò òṣì wọn;

Kí wọ́n má sì rántí ìdààmú wọn mọ́.

 8 Gba ọ̀rọ̀ sọ fún ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀;

Gbèjà ẹ̀tọ́ gbogbo àwọn tó ń kú lọ.+

 9 Sọ̀rọ̀, kí o sì dájọ́ lọ́nà òdodo;

Gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ti tálákà.*+

א [Áléfì]

10 Ta ló ti rí aya tó dáńgájíá?*+

Ó níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju iyùn.*

ב [Bétì]

11 Ọkọ rẹ̀ fọkàn tán an,

Kò* sì ṣaláìní ohun tó yẹ.

ג [Gímélì]

12 Ohun rere ni obìnrin náà fi ń san án lẹ́san, kì í ṣe búburú,

Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.*

ד [Dálétì]

13 Obìnrin náà wá òwú àti aṣọ ọ̀gbọ̀* kàn;

Ó sì fẹ́ràn láti máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́.+

ה [Híì]

14 Ó dà bí àwọn ọkọ̀ òkun oníṣòwò,+

Ó ń kó oúnjẹ rẹ̀ wọlé láti ọ̀nà jíjìn.

ו [Wọ́ọ̀]

15 Bákan náà, ó máa ń dìde nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́,

Láti wá oúnjẹ sílẹ̀ fún agbo ilé rẹ̀

Àti èyí tó máa fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.+

ז [Sáyìn]

16 Ó ronú nípa oko kan, ó sì rà á;

Ó gbin ọgbà àjàrà látinú èrè iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.*

ח [Hétì]

17 Ó múra sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ àṣekára,*+

Ó sì fún apá rẹ̀ lókun.

ט [Tétì]

18 Ó rí i pé òwò òun ń mérè wọlé;

Fìtílà rẹ̀ kì í kú ní òru.

י [Yódì]

19 Ọwọ́ rẹ̀ gbá ọ̀pá ìrànwú mú,

Ọwọ́ rẹ̀ sì di ìrànwú* mú.+

כ [Káfì]

20 Ó la àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí aláìní,

Ó sì la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà.+

ל [Lámédì]

21 Kò dààmú nípa agbo ilé rẹ̀ pé yìnyín ń já bọ́,

Nítorí pé gbogbo agbo ilé rẹ̀ ti wọ ẹ̀wù òtútù.*

מ [Mémì]

22 Ó ṣe àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn rẹ̀.

Aṣọ rẹ̀ jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* àti olówùú pọ́pù.

נ [Núnì]

23 Àwọn èèyàn mọ ọkọ rẹ̀ dáadáa ní àwọn ẹnubodè ìlú,+

Níbi tó máa ń jókòó sí láàárín àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà.

ס [Sámékì]

24 Ó máa ń fi ọ̀gbọ̀* ṣe aṣọ,* ó sì máa ń tà á,

Ó tún máa ń ta àmùrè fún àwọn oníṣòwò.

ע [Áyìn]

25 Ó fi agbára àti ògo ṣe aṣọ wọ̀,

Ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀* bó ṣe ń wo ọjọ́ iwájú.

פ [Péè]

26 Tó bá la ẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ló ń jáde,+

Òfin inú rere* sì wà ní ahọ́n rẹ̀.

צ [Sádì]

27 Ó ń ṣọ́ ohun tó ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀,

Kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.+

ק [Kófì]

28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì pè é ní aláyọ̀;

Ọkọ rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.

ר [Réṣì]

29 Ọ̀pọ̀ obìnrin tó dáńgájíá* ló wà,

Àmọ́ ní tìrẹ, o ta gbogbo wọn yọ.

ש [Ṣínì]

30 Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè má tọ́jọ́,*+

Àmọ́ obìnrin tó bẹ̀rù Jèhófà ló máa gba ìyìn.+

ת [Tọ́ọ̀]

31 Ẹ fún un ní èrè ohun tó ṣe,*+

Kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè ìlú.+

Ní Héb., “mọ.”

Tàbí “ohun tó tọ́.”

Tàbí “àìṣègbè.”

Tàbí “àkàwé.”

Tàbí “Ọ̀wọ̀ fún.”

Tàbí “òfin.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ tiwa.”

Tàbí “jọ lo àpò (pọ́ọ̀sì) kan náà.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “orí.”

Tàbí “Yí pa dà tí mo bá bá ọ wí.”

Ní Héb., “jẹ nínú èso.”

Tàbí “Ètekéte; èrò.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Tàbí “ìdúróṣinṣin.”

Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Ó ṣe kedere pé èyí tí ìwà rẹ̀ kò bá ti Ọlọ́run mu mọ́ ni.

Tàbí “fífanimọ́ra.”

Ní Héb., “obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.” Ó ṣe kedere pé èyí tí ìwà rẹ̀ jìnnà sí ti Ọlọ́run ni.

Tàbí “ọkọ.”

Ní Héb., “Àwọn ipa ọ̀nà.”

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Ní Héb., “wọlé sọ́dọ̀ rẹ̀.”

Tàbí “Àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”

Tàbí “òfin.”

Tàbí “òtítọ́.”

Ní Héb., “ìdodo.”

Tàbí “èyí tó dára jù lọ nínú.”

Tàbí “owó tó ń wọlé fún ọ.”

Tàbí “àwọn ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ó ṣe kedere pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí àwọn ẹsẹ tó ṣáájú mẹ́nu bà ló ń tọ́ka sí.

Tàbí “ọkàn rẹ.”

Tàbí “gbá.”

Tàbí “àwọn tí ó tọ́ sí.”

Tàbí “Tí o bá lágbára.”

Tàbí “òfin.”

Tàbí “ṣe kókó.”

Tàbí “ìdúróṣinṣin.”

Ní Héb., “Dẹ etí rẹ.”

Ní Héb., “ẹran ara.”

Tàbí “ranjú.”

Tàbí kó jẹ́, “Fara balẹ̀ kíyè sí ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ ń gbà.”

Ní Héb., “Dẹ etí rẹ.”

Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.

Ní Héb., “Ẹnu.”

Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “agbára.”

Ní Héb., “Ní àárín àpéjọ àti ìjọ.”

Tàbí “omi tó mọ́ lóló.”

Tàbí “ìsun omi.”

Tàbí “pa ọ́ bí ọtí.”

Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.

Ní Héb., “obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.” Wo Owe 2:16.

Tàbí “onígbọ̀wọ́.”

Ìyẹn, nínú ẹ̀jẹ́.

Tàbí “ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “òfin.”

Tàbí “kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́.”

Ní Héb., “ilẹ̀ òkèèrè.” Wo Owe 2:16.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ara.”

Ní Héb., “jẹ́ ẹni tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ìràpadà.”

Tàbí “òfin.”

Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.

Ní Héb., “ilẹ̀ òkèèrè.” Wo Owe 2:16.

Tàbí “fífanimọ́ra.”

Tàbí “wíńdò.”

Ìyẹn, fèrèsé tó ní asẹ́ onígi.

Tàbí “aláìní ìrírí.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “wọṣọ.”

Ní Héb., “Ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í.”

Tàbí “Aṣọ àtàtà.”

Tàbí “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “Ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”

Ní Héb., “lóye ọkàn.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ohun àjogúnbá tó ṣeyebíye.”

Tàbí “Láti ayérayé.”

Tàbí “a bí mi nínú ìrora ìbímọ.”

Ní Héb., “àmì òbìrìkìtì.”

Ní Héb., “tó mú kí àwọsánmà lágbára lókè.”

Tàbí “tó fi àṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ayé kalẹ̀.”

Tàbí “aráyé.”

Tàbí “Tó ń wà lójúfò lẹ́nu.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “Ó ti pa ohun pípa rẹ̀.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “àwọn aláìmọ̀kan.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn olódodo.”

Tàbí “Orúkọ.”

Ní Héb., “àṣẹ.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “Ohun iyebíye.”

Tàbí kó jẹ́, “wà ní.”

Tàbí “àhesọ ọ̀rọ̀.”

Tàbí “tọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sọ́nà.”

Tàbí “ìbànújẹ́; ìṣòro.”

Tàbí “ẹni tó gbà á síṣẹ́.”

Tàbí “Ìrètí.”

Tàbí “so èso.”

Tàbí “ìrẹ́nijẹ.”

Tàbí “òkúta ìwọ̀n.”

Tàbí “Àwọn ohun iyebíye.”

Tàbí “ẹni tí kò gba Ọlọ́run gbọ́.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “pẹ̀gàn.”

Ní Héb., “olóòótọ́ ní ẹ̀mí.”

Ní Héb., “bo ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀.”

Tàbí “olùdámọ̀ràn.”

Tàbí “ìgbàlà.”

Tàbí “onígbọ̀wọ́.”

Ní Héb., “kórìíra.”

Tàbí “tó rẹwà.”

Tàbí “Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Tàbí “ń ṣe ọkàn rẹ̀ lóore.”

Tàbí “ìtìjú.”

Ní Héb., “Ọwọ́ sí ọwọ́.”

Ní Héb., “tó ń fọ́n ká.”

Tàbí “Ọkàn.”

Ní Héb., “ni a ó mú sanra.”

Ní Héb., “bomi rin àwọn míì fàlàlà.”

Tàbí “kó ìtìjú.”

Ní Héb., “ẹ̀fúùfù.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kò ní ọgbọ́n.”

Ní Héb., “lílúgọ deni fún ẹ̀jẹ̀.”

Ní Héb., “búrẹ́dì.”

Tàbí “ọkàn ẹran.”

Ní Héb., “jẹ́ ẹni tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “àmọ̀ràn.”

Tàbí “lọ́jọ́ kan náà.”

Ní Héb., “ń bo.”

Ní Héb., “ohun tó jẹ́ òdodo.”

Ní Héb., “àwọn agbani-nímọ̀ràn àlàáfíà.”

Tàbí “banú jẹ́.”

Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”

Tàbí “ohun tó ń sọ.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀ kò.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ni a ó mú sanra.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “aláìní kì í gbọ́ ìbáwí.”

Ní Héb., “ń yọ̀.”

Tàbí “fèrò wérò.”

Tàbí “Ọrọ̀ tó wá látinú asán.”

Ní Héb., “ń fi ọwọ́ kó jọ.”

Tàbí “Ìfojúsọ́nà.”

Tàbí “ọ̀rọ̀.”

Tàbí “Òfin.”

Tàbí “ìbáwí.”

Tàbí “mọ́ ọkàn.”

Tàbí “aláìní.”

Tàbí “ìbáwí; ìfìyàjẹni.”

Tàbí kó jẹ́, “kánmọ́kánmọ́.”

Tàbí “Olódodo ń jẹ, ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn.”

Tàbí “tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́.”

Tàbí “màlúù.”

Tàbí kó jẹ́, “ni wọ́n fi ń ṣi àwọn míì lọ́nà.”

Tàbí “ṣíṣe àtúnṣe.”

Tàbí “máa ń wá ire.”

Tàbí “ìkorò ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “Aláìní ìrírí.”

Tàbí “máa ń bínú fùfù.”

Tàbí “aláròjinlẹ̀.”

Tàbí “aláìní ìrírí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ní ìlera.”

Tàbí “Ọ̀rọ̀ tútù.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ tó ń dunni.”

Tàbí “Ahọ́n tó ń woni sàn.”

Ní Héb., “ń wó ẹ̀mí palẹ̀.”

Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”

Tàbí “owó tó ń wọlé fún.”

Tàbí “ohun tó le jù.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àti Ábádónì.”

Tàbí “tó ń bá a wí.”

Tàbí “ń wá.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀ ń yọ̀.”

Tàbí “ìdàrúdàpọ̀.”

Ní Héb.,“tí wọ́n bọ́ ní ibùjẹ ẹran.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “pé àwọn èèyàn bára wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.”

Tàbí “olùdámọ̀ràn.”

Ní Héb., “nínú ìdáhùn ẹnu rẹ̀.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ń kó ìtìjú.”

Tàbí “ń fara balẹ̀ ro bó ṣe máa dáhùn; máa ń ronú kí ó tó sọ̀rọ̀.”

Tàbí “Ẹ̀rín músẹ́.”

Ní Héb., “sanra.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Ní Héb., “Èèyàn ló máa ń ṣètò ọkàn.”

Tàbí “ìdáhùn tí ó tọ́.” Ní Héb., “ìdáhùn ahọ́n.”

Ní Héb., “mọ́.”

Ní Héb., “ẹ̀mí.”

Ní Héb., “Yí àwọn iṣẹ́ rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”

Ní Héb., “Ọwọ́ sí ọwọ́.”

Tàbí “Ìpinnu àtọ̀runwá.”

Tàbí “ń yẹra fún un.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ẹni tó rẹlẹ̀ ní ẹ̀mí.”

Ní Héb., “rí ire.”

Tàbí “tó ń tuni lára.” Ní Héb., “tó sì ní ètè dídùn.”

Tàbí “Ó dùn lẹ́nu.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Tàbí “Ọkàn.”

Ní Héb., “Ẹnu rẹ̀.”

Tàbí “Elétekéte.”

Tàbí “ògo.”

Ní Héb., “ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀.”

Ní Héb., “Búrẹ́dì.”

Tàbí “tí kò sí ìyọlẹ́nu.”

Ní Héb., “ẹbọ.”

Tàbí “ọmọ.”

Tàbí “òbí.”

Tàbí “rere.”

Tàbí “èèyàn pàtàkì.”

Tàbí “òkúta tó ń mú kéèyàn rójú rere.”

Ní Héb., “bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”

Tàbí “àgbájọ omi.” Ní Héb., “jẹ́ kí omi tú jáde.”

Ní Héb., “Nígbà tí kò ní ọkàn láti ní in.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Tàbí “onígbọ̀wọ́.”

Ní Héb., “rí ire.”

Tàbí “tó ń woni sàn.”

Tàbí “ń mú kí egungun gbẹ.”

Ní Héb., “àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti oókan àyà.”

Ní Héb., “ìkorò.”

Tàbí “bu owó ìtanràn lé.”

Ní Héb., “máa ń tutù ní ẹ̀mí.”

Tàbí “yóò kórìíra.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ohun téèyàn fẹ́ fi ojú kòkòrò gbé mì.”

Ní Héb., “a sì gbé e ga sókè,” ìyẹn ni pé, ọwọ́ kò lè tó o, kò sí ohun tó máa ṣe é.

Tàbí “ta ló lè fara dà á tí nǹkan bá tojú súni pátápátá?”

Tàbí “wádìí rẹ̀ wò látòkèdélẹ̀.”

Ní Héb., “ṣe ìyàsọ́tọ̀.”

Tàbí “ìtẹ́wọ́gbà.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “kí ẹsẹ̀ èèyàn yá.”

Tàbí “ẹni tó lawọ́.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “rí ire.”

Ní Héb., “mójú kúrò nínú.”

Tàbí “ìṣìnà.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí “Ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “èrè.”

Tàbí “fẹ́.” Ní Héb., “gbé ọkàn rẹ sí.”

Tàbí “ìpinnu.”

Tàbí “Ìpayà.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí kó jẹ́, “Á máa wá nǹkan nígbà ìkórè, àmọ́ kò ní rí nǹkan kan.”

Ní Héb., “Ìmọ̀ràn.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Tàbí “Òkúta ìwọ̀n oríṣi méjì àti ohun èèlò ìdíwọ̀n oríṣi méjì.”

Tàbí “ọmọdékùnrin.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àjèjì kan.”

Tàbí “Àmọ̀ràn.”

Tàbí “fẹsẹ̀ múlẹ̀.”

Tàbí “ẹni tó máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ fajú èèyàn mọ́ra.”

Tàbí “òkúta ìwọ̀n oríṣi méjì.”

Tàbí “ọ̀nà tó yẹ kó gbà?”

Tàbí “nu.”

Tàbí “èrò ọkàn.”

Tàbí “àǹfààní.”

Tàbí kó jẹ́, “fún àwọn tó ń wá ikú.”

Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”

Tàbí “ọkàn ẹni.”

Tàbí “mọ ohun tó yẹ kó ṣe.”

Ní Héb., “ní àyà.”

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Tàbí “ìgbádùn.”

Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”

Ní Héb., “gbé ohun tó ní mì.”

Tàbí “borí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “pẹ̀lú ìwà tó ń tini lójú.”

Ní Héb., “ẹni tó ń fetí sílẹ̀ yóò máa sọ̀rọ̀ títí láé.”

Tàbí “ló ń mú kí ọ̀nà rẹ̀ dájú.”

Ní Héb., “Orúkọ.”

Ní Héb., “Ojú rere.”

Ní Héb., “bára pàdé.”

Tàbí “Aláròjinlẹ̀.”

Tàbí “jìyà àbájáde rẹ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”

Ní Héb., “Ẹni tó ní ojú tó dára.”

Tàbí “Ẹjọ́.”

Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.

Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Kó ara rẹ níjàánu.”

Tàbí “pé ọkàn rẹ ń fẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan.”

Tàbí kó jẹ́, “Jáwọ́ nínú lílo òye tìrẹ.”

Tàbí “ẹni tó ń fojú burúkú wo èèyàn.”

Tàbí “tó ń ṣe ìṣírò nínú ọkàn rẹ̀.”

Ní Héb., “ọkàn rẹ̀ kò wà pẹ̀lú rẹ.”

Ní Héb., “Olùràpadà.”

Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “kíndìnrín mi.”

Tàbí “Ní.”

Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.

Tàbí “tó tín-ín-rín.”

Tàbí “Àwọn tó ń kóra jọ láti wo bí àdàlù wáìnì ṣe ń rí lára.”

Tàbí “kò dùn mí.”

Tàbí “Màá wá a lẹ́ẹ̀kan sí i.”

Tàbí “agbo ilé.”

Tàbí “olùdámọ̀ràn.”

Tàbí “àṣeyọrí; ìgbàlà.”

Ìyẹn, òmùgọ̀.

Tàbí “Ohun tí òmùgọ̀ ń gbèrò.”

Tàbí “lásìkò ìdààmú.”

Tàbí “èrò.”

Tàbí “wo ọkàn rẹ.”

Tàbí “dùn mọ́ ọkàn rẹ.”

Ìyẹn, ọ̀tá náà.

Tàbí “gbaná jẹ.”

Tàbí “àwọn tó ń wá ìyípadà.”

Ìyẹn, Jèhófà àti ọba.

Tàbí kó jẹ́, “Fífèsì lọ́nà tó tọ́ dà bí fífi ẹnu koni lẹ́nu.”

Tàbí “agbo ilé.”

Tàbí “Màá ṣe bákan náà sí i.”

Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”

Ní Héb., “gba ìbáwí.”

Tàbí “dà kọ, tí wọ́n sì kó jọ.”

Tàbí “àṣírí ẹlòmíì.”

Tàbí “Àhesọ ọ̀rọ̀ tó ń bani lórúkọ jẹ́.”

Tàbí “férémù.”

Tàbí “ó ń tu ọkàn ọ̀gá rẹ̀ lára.”

Ní Héb., “ẹ̀bùn èké.”

Tàbí “Ọ̀rọ̀ tútù.”

Tàbí kó jẹ́, “oníbékebèke.”

Tàbí “ákáláì.”

Ní Héb., “ẹni tó kórìíra rẹ.”

Ìyẹn, láti mú kí ọkàn ẹni náà rọ̀, kí inú rẹ̀ sì yọ́.

Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”

Ní Héb., “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “tó fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú.” Ní Héb., “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ níwájú.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí kó jẹ́, “ègún tí kò tọ́ síni kì í mọ́ni.”

Tàbí “Kí o má bàa mú ara rẹ bá a dọ́gba.”

Ní Héb., “tó sì ń mu ìwà ipá.”

Tàbí “dirodiro.”

Tàbí “tó ń ṣe gbogbo èèyàn léṣe.”

Tàbí “ìkọ́ aláyìípo.”

Tàbí kó jẹ́, “tó sì ń dá sí.”

Tàbí “ọfà tó ń ṣekú pani.”

Tàbí “ohun téèyàn fẹ́ fi ojú kòkòrò gbé mì.”

Ní Héb., “ètè tó ń jó belebele pẹ̀lú.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀ jẹ́ ohun ìríra látòkèdélẹ̀.”

Ní Héb., “ohun tí ọ̀la máa bí.”

Ní Héb., “Àjèjì.”

Ní Héb., “Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.”

Tàbí kó jẹ́, “kò dénú; jẹ́ tipátipá.”

Tàbí “Ọkàn.”

Ní Héb., “ló ń tẹ oyin inú afárá mọ́lẹ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “tó sá kúrò ní.”

Tàbí “Aláròjinlẹ̀.”

Tàbí “jìyà àbájáde rẹ̀.”

Tàbí “àjèjì kan.”

Tàbí “ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”

Ní Héb., “pọ́n ojú.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù àti Ábádónì.”

Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe rí ní ti ìyìn tó gbà.”

Tàbí “Fi ọkàn rẹ sí; Kíyè sí.”

Tàbí “dáyádémà.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún.”

Tàbí “ọ̀tẹ̀.”

Ní Héb., “òun.”

Tàbí “ẹni tó bá ń bẹ̀rù.”

Tàbí “tí ẹ̀jẹ̀ ọkàn kan bá wọ̀ lọ́rùn.”

Tàbí “kòtò.”

Tàbí “Olójúkòkòrò.”

Tàbí kó jẹ́, “Agbéraga ẹ̀dá.”

Ní Héb., “ni a ó mú sanra.”

Tàbí “tó ń ṣorí kunkun.”

Tàbí “aláìlẹ́bi.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí kó jẹ́, “Àmọ́ adúróṣinṣin máa ń wá ọ̀nà láti dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀. ”

Ní Héb., “Gbogbo ẹ̀mí.”

Ní Héb., “bára pàdé.”

Ìyẹn ni pé, Òun ló fún wọn ní ẹ̀mí.

Tàbí “Ìbáwí; Ìfìyàjẹni.”

Tàbí “mú ọkàn rẹ yọ̀.”

Tàbí “ìran alásọtẹ́lẹ̀; ìfihàn.”

Tàbí “ọkàn òun fúnra rẹ̀.”

Tàbí “gbọ́ ìbúra kan tó ní ègún nínú.”

Ní Héb., “Wíwárìrì nítorí.”

Tàbí “ń dẹ.”

Tàbí kó jẹ́, “ń wá ojú rere alákòóso.” Ní Héb., “ń wá ojú alákòóso.”

Ní Héb., “gbé gbogbo ìkángun ayé dìde.”

Ìyẹn, Ọlọ́run.

Tàbí “dojú ìjà kọ.”

Ní Héb., “ìgbọ̀nsẹ̀.”

Tàbí “kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ilé ọmọ tí kò lè gba oyún dúró.”

Tàbí “tó jẹ́ àgbàyanu fún mi.”

Tàbí “tí wọn ò fẹ́ràn.”

Tàbí “bá lé ọ̀gá rẹ̀ obìnrin jáde.”

Tàbí “ọgbọ́n tó ga gan-an.”

Ní Héb., “èèyàn.”

Ìyẹn, ẹranko kan tó jọ ehoro tó máa ń gbé níbi tí àpáta wà.

Ní Héb., “èèyàn.”

Tàbí “ní àwùjọ-àwùjọ.”

Tàbí “tí ọkàn wọn gbọgbẹ́.”

Tàbí “Gba ẹjọ́ àwọn aláìní àti ti tálákà rò.”

Tàbí “aya àtàtà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, ọkọ rẹ̀.

Ìyẹn, obìnrin náà.

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “owó ara rẹ̀.” Ní Héb., “èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Ní Héb., “Ó fi agbára di ìbàdí rẹ̀ lámùrè.”

Ọ̀pá ìrànwú àti ìrànwú ni igi tí wọ́n fi ń yí òwú àti fọ́nrán pọ̀ tàbí kí wọ́n fi ṣe é.

Ní Héb., “ẹ̀wù oníṣẹ̀ẹ́po.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “Ó sì ń rẹ́rìn-ín.”

Tàbí “Ẹ̀kọ́ onífẹ̀ẹ́; Òfin ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Tàbí “obìnrin àtàtà.”

Tàbí “lè jẹ́ òfo; asán.”

Ní Héb., “Ẹ fún un látinú èso ọwọ́ rẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́