Etiopia Fífani Mọ́ra
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ETIOPIA
FÚN ọ̀pọ̀ ọdún ni a mọ Etiopia gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ọba tí ó fara sin. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rúndún tí ó fi dá wà tí dópin, àwọn díẹ̀ lónìí ni wọ́n mọ̀ nípa ìtàn rẹ̀ fífani mọ́ra, onírúurú àwọn ènìyàn àti àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn ìrísí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀. Pẹ̀lú àwọn olùgbé tí ó ju 50 mílíọ̀nù lọ—tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ tó iye tí ó wà ní Faransé—kì í ṣe ilẹ̀ tí a lè gbójú fò dá.
Ó ṣe kedere pé àwọn ará Gíríìkì ìgbàanì ni wọ́n fún un ní orúkọ náà, “Etiopia,” èyí tí ó túmọ̀ sí “Ẹ̀kun Ojú Jíjóná.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ohun àràmàǹdà àti ìtàn àtijọ́ bo ìtàn ìṣèlú ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ sọ pé Etiopia jẹ́ apá kan lára Sheba ìgbàanì tí ó lókìkí nínú Bibeli, àti pé ọbabìnrin ibẹ̀ ni ọlọ́lá-ọlọ́là tí ó wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Ọba Solomoni. Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàkóso ìgbà láéláé Etiopia sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Menelik, tí wọ́n ronú pé ó jẹ́ ọmọ tí ó jẹ jáde láti inú àjọṣepọ̀ eléré-ìfẹ́ tí ó wà láàárín Solomoni àti ọbabìnrin náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbo ọ̀nà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ pé Sheba ní tirẹ̀ wà ní ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Lárúbáwá.a Àmọ́ Bibeli mẹ́nu kan Etiopia nínú apá rẹ̀ méjèèjì, Heberu (“Májẹ̀mú Láéláé”) àti Gíríìkì (“Májẹ̀mú Tuntun”). Fún àpẹẹrẹ, Ìṣe orí 8 sọ nípa “ìwẹ̀fà” ara Etiopia kan, tàbí òṣìṣẹ́ ìjọba kan, tí ó yí padà sí ìsìn Kristian. Ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú ààlà ilẹ̀ òde òní, Etiopia ti inú Bibeli lọ dé agbègbè tí a mọ̀ sí Sudan ní ti gidi gan-an.
Ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa, ìjọba Aksum ti fìdí múlẹ̀ ní Etiopia. Ó dé òtéńté agbára rẹ̀ nígbà tí Ọba ‛Ēzānā ń ṣàkóso ní ọ̀rúndún kẹrin. Níwọ̀n bí ‛Ēzānā fúnra rẹ̀ ti jẹ́ ẹni àyílọ́kànpadà, ó yí gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀ padà sínú “ìsìn Kristian.” Etiopia ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ já ní ọ̀rúndún keje. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana ṣàlàyé pé: “Fún nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,000 ọdún lẹ́yìn náà, Etiopia yà sọ́tọ̀ lára àwọn apá ayé yòókú tí ó jẹ́ Kristian, nínú ìsapá rẹ̀ láti gbèjà ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Musulumi tí wọ́n ń kọjá àyè wọn láti apá àríwá àti ìlà oòrùn, àti lọ́wọ́ àwọn abọ̀rìṣà akóguntini tí wọ́n wá láti ìhà gúúsù.” Ní pàtó, ṣíṣẹ́gun tí àwọn Musulumi tilẹ̀ ṣẹ́gun ilẹ̀ Egipti àti Nubia mú kí Etiopia já kúrò lára àwọn ilẹ̀ Kiriṣẹ́ńdọ̀mù yòókù.
Etiopia kò dà bí àwọn ilẹ̀ Áfíríkà míràn, kò pẹ́ púpọ̀ lábẹ́ ìsìnrú àwọn ara Europe, àyàfi ìgbà kúkurú tí àwọn ará Itali fi wà pẹ̀lú wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, láti ọdún 1935 sí 1941. Ní 1974, ìdìtẹ̀ àwọn ológun kan mú ilẹ̀ ọba àtayébáyé náà wá sí òpin rẹ̀ pẹ̀lú ìwà ipá. Láti 1991, ìjọba tuntun ti mú àtúnṣe wá ní mímú kí ilẹ̀ náà di ẹgbẹ́ àwùjọ tí ó ṣí sílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn. Nítorí èyí, ó ti ṣeé ṣe nísinsìnyí láti wo orílẹ̀-èdè tí ó fara sin tẹ́lẹ̀ yìí fínnífínní sí i.
Àwọn Ènìyàn Náà àti Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Wọn
Ó ṣòro láti kó gbogbo àwọn ènìyàn Etiopia pọ̀ nítorí pé oríṣiríṣi ni wọ́n. Àwọn Afar alárìnkiri, tí wọ́n máa ń rìn kiri Aṣálẹ̀ Danakil tí ń dún hánránhánrán wà. Ní apá ìhà ìwọ̀ oòrun ni àwọn ẹ̀yà Nile alára dúdú wà. Àwọn ẹ̀yà Oromo ló pọ̀ tí ń gbé ní apá ìhà gúúsù. Àwọn ẹ̀yà Amhara ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ gíga, níbi tí wọ́n ti ń fi àwọn ilẹ̀ orí òkè tí ẹ̀fúùfù pọ̀ sí dáko. Abájọ nígbà náà tí Etiopia fi ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 300 èdè. Àwọn ẹ̀yà náà ní ọ̀nà ìgbàṣerun, ọ̀nà ìgbàwọṣọ, àti ọ̀nà ìgbàkọ́lé tiwọn. Ọ̀nà ìgbàkọ́lé wọn bẹ̀rẹ̀ láti orí tukul tí ó rí kiriboto tí à ń fi ọparun ṣe, èyí tí ó wọ́pọ̀ ní ìhà gúúsù, dé orí àwọn ilé onípàálábà tí a fi koríko kọ́ tí ó wọ́pọ̀ ní àárín gbùngbùn Etiopia àti àwọn ilé onípẹ̀tẹ́ẹ̀sì tí a fi òkúta kọ́ ní ìhà àríwá.
Onírúurú orúkọ àwọn ènìyàn fífani mọ́ra ló tún wà. Àwọn orúkọ tí ń dún bí èyí tí ó ṣàjèjì náà kì í wulẹ̀ í ṣe ohun tí a fi ń dáni mọ̀ lásán, wọ́n ní ìtumọ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ló mọ̀ ọ́n ládùúgbò. Wọ́n lè sọ àwọn ọmọdébìnrin ní Fikre (Olùfẹ́ Mi), Desta (Ayọ̀), Senait (Inú Rere), Emnet (Ìgbàgbọ́), Ababa (Òdòdó), tàbí Trunesh (Ẹniire Ni Ọ́). Díẹ̀ lára orúkọ àwọn ọkùnrin ni Berhanu (Ìmọ́lẹ̀), Wolde Mariam (Ọmọ Maria), Gebre Yesus (Ìránṣẹ́ Jesu), Haile Sellassie (Agbára Mẹ́talọ́kan), tàbí Tekle Haimanot (Irúgbìn Ìsìn).
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn orúkọ yìí máa ń fi ẹ̀rí ipa tí ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní hàn kedere. Ní ti gidi, ó tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Etiopia ni ìsìn wọ̀! Kàlẹ́ńdà tí ó ní oṣù 13 kún fọ́fọ́ fún àwọn àjọ̀dún ìsìn. Àwọn tí ó gba iwájú jù lọ ni Meskel, tí ó jẹ́ “Àjọ̀dún Àgbélébùú,” àti Timkat, tí wọ́n máa ń ṣe pẹ̀lú ìwọ́de aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ láti ṣàjọyọ̀ ìrìbọmi Kristi. Kò sì gbọdọ̀ yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn iṣẹ́ ọnà àbáláyé Etiopia ló jẹ mọ́ ìsìn.
Ìrísí Ilẹ̀ Rẹ̀
Ìran Etiopia tí o óò kọ́kọ́ rí gbọ́dọ̀ ní ìrísí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó gọntiọ nínú. Ìrísí pàtàkì kan ni Great Rift Valley, tí ó la orílẹ̀-èdè náà sí méjì pẹ̀rẹ́ níbi tí ó ti já pọ̀ mọ́ Kenya. Àwọn ṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná àti ihò àpáta pọ̀ léteetí rẹ̀. Àwọn adágún rírẹwà méje fọ́n káàkiri ilẹ̀ náà. Àwọn ilẹ̀ tí ó ga ju 2,000 mítà lọ sókè ní ìhà méjèèjì, èyí tí ó para pọ̀ di Òkè Ńlá Simyen ní ìhà àríwá. Wọ́n máa ń pe àwọn wọ̀nyí ní Òrùlé Ilẹ̀ Áfíríkà pẹ̀lú ṣóńṣó rẹ̀ tí ó ga ju 4,600 mítà lọ! Àwọn ṣóńṣó òkè gàgàrà-gàgàrà àti àwọn ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tóóró-tóóró tí ó wà ní agbègbè yìí jẹ́ àrímálèlọ ní tòótọ́. Adágún Tana àti orísun odò Blue Nile kò jìnnà síbẹ̀. Èyí ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tóóró fífani mọ́ra tirẹ̀ tí ó ṣe kọ́rọkọ̀rọ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ní Sudan. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Adágún Tana, odò Blue Nile tún jẹ́ àwòpadàsẹ́yìn—Ìtàkìtì Omi Tisissat, tí ń dà pàtàpàtà sórí àpáta bí ẹ̀dàyà kékeré Ìtàkìtì Omi Victoria lílókìkí. Ní apá àríwá ìlà oòrùn, àwọn kòtò oníyọ̀ tí ó ní oríṣiríṣi àwọ̀ ṣe Danakil, aṣálẹ̀ tí ó para pọ̀ di ilẹ̀ tí ó relẹ̀ jù lọ ní Áfíríkà, lọ́ṣọ̀ọ́. Ó rẹlẹ̀ sí ìtẹ̀jú òkun.
Etiopia máa ń mú àwọn àgbàyanu onírúurú irè oko jáde, bẹ̀rẹ̀ láti orí wheat, ọkà bálì, ọ̀gẹ̀dẹ̀, àgbàdo, àti òwú, dé orí àjàrà, ọsàn, àti àìlóǹkà àwọn èròjà atansánsán. Etiopia tún sọ pé òún jẹ́ ojúlówó ilé ọ̀gbìn kọfí, títí tí ó sì fi di òní, òun ni òléwájú nínú àwọn tí ń mú hóró kọfí jáde. Lẹ́yìn ìyẹn tún ni hóró ṣíṣàjèjì kan tí wọ́n ń pè ní teff. Ó dà bíi koríko, wọ́n sì ń lọ hóró rẹ̀ wẹẹrẹ láti fi ṣe injera, lájorí oúnjẹ Etiopia àti ọbẹ̀ orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n máa ń ṣe injera nínú àdògán àrà ọ̀tọ̀ kan, wọ́n sì máa ń jẹ ẹ́ nínú agbọ̀n rìbìtì ńlá kan, tí ń jẹ́ mesob tí a ṣọnà sí. A máa ń gbé mesob kalẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilé àwọn ará Etiopia, mesob jẹ́ ohun tí ó wúlò gan-an, ó sì tún jẹ́ kòṣeémánìí ẹwà àyíká ilé!
Àwọn Ẹranko Ìgbẹ́
Báwo ni Etiopia ti rí bí ó bá di ọ̀ràn àwọn ẹranko ìgbẹ́? Wọ́n pọ̀ síbẹ̀. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, Etiopia ní ọ̀pọ̀ ọgbà àwọn ẹran ìgbẹ́ tí kò sí ní ojútáyé, tí onírúurú àwọn ẹtu àti kìnnìún kún fọ́fọ́. Ohun tí ó ju 830 irú ẹ̀yà ẹyẹ ni wọ́n sọ pé ó wà ní orílẹ̀-èdè náà, èyí tí ó jẹ́ pé kìkì Etiopia nìkan ni a ti lè rí díẹ̀ nínú wọn.
Ẹranko walia ibex gàgàrà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹranko tí ó ṣàjèjì pátápátá, ó jẹ́ ewúrẹ́ ìgbẹ́ pípinmirin kan tí ó ṣẹ́ kù ní kìkì ibi gíga fíofío Òkè Ńlá Simyen. Ìwọ̀nba àwọn ọgọ́rùn-ún bíi mélòó kan ṣì wà tí wọ́n ń gbé ní àárín àwọn orí àpáta tí ènìyàn kò lè dé. Wọ́n lè fò gba orí ọ̀gbun tí ó dà bí àìnísàlẹ̀ kan tí ẹsẹ̀ wọn kò sì ní yọ̀. Ẹranko gelada rírẹwà tún wà pẹ̀lú. Nítorí irun rẹ̀ tí ó gùn àti àwọn tóótòòtó pupa tí ń pàfiyèsí tí ó wà ní igbáàyà rẹ̀, àwọn ènìyàn tún máa ń pè é ní ọ̀bọ kìnnìún àti ìnàkí ọlọ́kàn ṣíṣẹ̀jẹ̀. Kò di dandan kí o rìn jìnnà kí o tóó rí ìgbésí ayé àwọn ẹranko. Kódà, fọ́fọ́ ni àwọn ọ̀nà Etiopia máa ń kún fún àwọn ràkúnmí, ìbàákà, màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́!
Òtítọ́ ni pé kì í ṣe pé orílẹ̀-èdè náà kò ní àwọn ìṣòro tirẹ̀. Addis Ababa, tí ó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà jẹ́ ìlú ńlá ìgbàlódé tí ó ní ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ. Àmọ́ ìṣòro àìrílégbé àti àìríṣẹ́ṣe ń dà á láàmú. Ọ̀dá àti ogun abẹ́lé ti ṣamọ̀nà sí àìrílégbé, yíyarọ, àti kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn di opó àti ọmọ òrukàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè yìí ń ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn ará Etiopia lọ́wọ́ láti rí i pé ojútùú pátápátá sí àwọn ìṣòro wọn ni Ìjọba Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi Jesu.—Matteu 6:9, 10.
Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ná, Etiopia jẹ́ ilẹ̀ kan tí ó yẹ kí ènìyàn gbìyànjú láti mọ̀. A lérò pé àyẹ̀wò fírí yìí ti ru ìfẹ́ ọkàn rẹ sókè, kí o baà lè ṣe àyẹ̀wò fírí mìíràn, bóyá kí o tilẹ̀ mójú dé ilẹ̀ fífani mọ́ra yìí lọ́jọ́ kan.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Sheba” nínú ìwé Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde.
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Wọ́n máa ń jẹ “injera,” oúnjẹ orílẹ̀-èdè Etiopia, nínú agbọ̀n “mesob”