Wíwo Ayé
Àwọn Onísìn Unitarian Fọwọ́ Sí Ìgbéyàwó Láàárín Ẹ̀yà Kan Náà
Ìwé ìròyìn Christian Century sọ pé, Ṣọ́ọ̀ṣì Unitarian ti di àkọ́kọ́ lára àwọn ẹ̀ya ìsìn ní United States láti fàṣẹ sí ìgbéyàwó láàárín ẹ̀yà kan náà. Àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n lọ sí àpéjọpọ̀ ọlọ́dọọdún ti ẹgbẹ́ ìsìn náà sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti “pòkìkí ìtóyeyẹ ìgbéyàwó láàárín ènìyàn méjì èyíkéyìí tí wọ́n ti bá ara wọn jẹ́jẹ̀ẹ́.” Ìwé ìròyìn onísìn náà sọ pé, “lábẹ́ ìdarí ṣọ́ọ̀ṣì, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn 1,040 ìjọ ṣọ́ọ̀ṣì náà lè pinnu fún ara rẹ̀ bóyá yóò fọwọ́ sí ìgbéyàwó àwọn abẹ́yàkan-náà-lò lọ́kùnrin àti lóbìnrin àti bóyá yóò gbà kí wọ́n ṣe irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì òun.”
Pípinnu Ẹ̀yà Ọmọ Jòjòló Ṣáájú Ìbí
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Popular Science ti sọ, “ó ti ṣeé ṣe báyìí láti pinnu ẹ̀yà ọmọ jòjòló kan ṣáájú ìbí nípa ṣíṣa àtọ̀ bàbá rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé irú àtọ̀ ló ń pinnu ẹ̀yà.” Lákọ̀ọ́kọ́, wọn da aró pípọ́n rekete sórí àtọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n lo ìgbì ìtànṣán kan láti fi dá àtọ̀ X (ti obìnrin) mọ̀ yàtọ̀ sí àtọ̀ Y (ti ọkùnrin). Kọ̀ǹpútà kan fi ìyàtọ̀ rẹ̀ hàn kedere, ohun èèlò ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a sábà ‘máa ń lò fiṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ gbé ìwọ̀n agbára mànàmáná tí ó gbéṣẹ́ gidi wá sára àtọ̀ X náà, ó sì gbé agbára mànàmánà tí kò gbéṣẹ́ wá sára àtọ̀ Y náà. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá lo òdì kejì orí àwọn agbára mànàmáná láti fa àtọ̀ náà sọ́tọ̀.’ Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ó kọ́kọ́ gbé ìlànà náà kalẹ̀ fún àwọn ilé iṣẹ́ ọ̀sìn ẹran ṣe sọ, ṣíṣà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ náà fi nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún péye. Nígbà tó yá, wọ́n da àtọ̀ tí wọ́n ṣà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ náà sórí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹyin, “lẹ́yìn náà, wọn gbé àwọn ọlẹ̀ ẹ̀yà tí a fẹ́ náà sínú ilé ọlẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, títí di báyìí, ẹ̀dá ènìyàn kan ṣoṣo ni a tí ì bí nípasẹ̀ ìlànà yí.
Sísọ̀rọ̀ Bí Ọmọdé Ń Ṣèpalára
A sábà máa ń ka àwọn ipá tí àwọn ọmọdé ń sà láti sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n kéré sí èyí tí ń fani mọ́ra, ọ̀pọ̀ òbí sì ń fi sísọ̀rọ̀ bí ọmọdé dáhùn pa dà lọ́nà onífẹ̀ẹ́. Ọmọ Brazil tí ó jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ ìsọ̀rọ̀, Eliane Regina Carrasco, sọ nínú ìwé ìròyìn Veja pé, bí ó ti wù kí ó rí, èyí lè fi mímú agbára ìsọ̀rọ̀ dàgbà ti àwọn ọmọ sínú ewu. Carrasco sọ pé, nígbà tí àwọn òbí bá ṣàtúnwí àṣìṣe ọmọ nínú pípe ọ̀rọ̀, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ “ń fún ìlànà tí kò tọ̀nà kan lókun ni.” Ó sọ pé, èyí lè ṣokùnfà ìṣòro ìsọ̀rọ̀. Ó fi kún un pé, ó tún lè ní ipa lórí bí ọmọ ṣe ń ṣe láàárín ẹgbẹ́. “Lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń ya anìkanwà, onítìjú, àti aláìdára-ẹni-lójú, tí ń yẹra fún àwọn ipò tí ó lè jẹ́ kí wọ́n gbé ara wọn sójútáyé [fún ìfiṣẹ̀sín].” Carrasco fi hàn pé, kò sí ohun tí ó burú nínú kí àwọn ọmọ kéékèèké ṣi ọ̀rọ̀ pè, kò sì pọn dandan láti máa tọ́ wọn sọ́nà léraléra. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì láti bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́ àti láti rántí pé, “wọ́n ní làákàyè, wọ́n sì ní agbára láti kẹ́kọ̀ọ́.”
China Ń Gbégbèésẹ̀ Láti Dín Sísọ Omi Deléèérí Kù
Agbẹnusọ kan fún Àjọ Aláàbò Àyíká Orílẹ̀-Èdè ní China sọ pé: “Sísọ omi deléèérí jẹ́ ìṣòro ńlá kan ní China, dídín sísọ omi deléèérí kù sì jẹ́ iṣẹ́ kánjúkánjú.” Ìwé ìròyìn China Today sọ pé, nípa bẹ́ẹ̀, ìjọba China ti ń gbégbèésẹ̀ láti dín sísọ omi deléèérí kù ní àwọn odò àti adágún omi tí a ti sọ deléèérí jù lọ ní China. Fún àpẹẹrẹ, láti darí àwọn pàǹtírí tí ń wọnú ọ̀kan lára àwọn odò tí a ti sọ deléèérí jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà, odò Huaihe, ìjọba ti “ti ilé iṣẹ́ kéékèèké 999 tí ń ṣe pépà ní àfonífojì Huaihe pa.” Ní ìfojúdíwọ̀n, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 154 ní ń gbé Àfonífojì Huaihe, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àgbègbè tí ń ṣèmújáde hóró ọkà àti ohun àmúṣagbára.
Àwọn Apániláyà “Mímọ́”
Ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà Compass Direct sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tí Willy Fautré kọ pé, nínú ìsapá láti “tún gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ṣọ́ọ̀ṣì orílẹ̀-èdè,” Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Romania ti “gbé ogun ìtẹ́ńbẹ́lú lábẹ́lẹ̀ kan jáde lòdì sí àwọn ẹ̀ya ìsìn míràn.” Fautré fi kún un pé: “Àwọn aṣáájú onípò gíga àti àwọn àlùfáà àdúgbò nínú ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Romania” ti kó àwọn ẹgbẹ́ bíi mélòó kan jọ láti “pá àwọn ẹgbẹ́ onísìn kíkéré jọjọ láyà, kí wọ́n sì fi àwọn ẹ̀tọ́ ìsìn tí ó ṣe pàtàkì dù wọ́n.” Ní pípe àwọn oníwàásù orí rédíò ní “olùtàbàwọ́n sí ìgbàgbọ́ àwọn baba ńlá wa,” bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìlú Suceava àti Rădăuţi kọ̀wé sí ààrẹ ẹgbẹ́ tí ń bójú tó ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n ní Romania, pé: “A bẹ̀ yín láti dá wọn dúró tàbí láti pààlà fún wọn, nítorí pé wọn kò lójútì rárá, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ète àtisọ àwọn ènìyàn di aláwọ̀ṣe ní ilẹ̀ wa.”
A Ń Wu Àwọn Ẹranko Afọ́mọlọ́mú Léwu Ju Àwọn Ẹyẹ Lọ
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú wà nínú ewu àkúrun tí ó pọ̀ ju ti àwọn ẹyẹ lọ.” Àwọn àwárí yìí, tí a gbé karí fígọ̀ tí Àkọsílẹ̀ Ìwuléwu ti Ẹgbẹ́ Ìdáàbòbò Ìṣẹ̀dá Àgbáyé gbé jáde, fi hàn pé, nígbà tí ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún lára irú ọ̀wọ́ ẹyẹ ń dojú kọ àkúrun kárí ayé, ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo irú ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú ni a ń wu léwu báyìí. Àwọn ẹ̀dá gíga jù ni ẹgbẹ́ tí a ń wu léwu jù lọ, tí tiwọn jẹ́ ìpín 46 nínú ọgọ́rùn-ún irú ọ̀wọ́ tí a ń fi àkúrun halẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn náà ló kan àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú tí wọ́n ń jẹ kòkòrò, tí tiwọn jẹ́ ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún, lẹ́yìn náà ni àwọn ẹlẹ́dẹ̀ àti àwọn ẹtu tí tiwọ́n jẹ́ ìpín 33 nínú ọgọ́rùn-ún. Ẹgbẹ́ àwọn ẹyẹ tí a ń halẹ̀ mọ́ jù lọ ni wádòwádò, tí tiwọn jẹ́ ìpín 26 nínú ọgọ́rùn-ún lára irú ọ̀wọ́ tí ń dojú kọ àkúrun. Ìdí kan tí ó fà á tí ìwọ̀n tí àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú fi ń dín kù gan-an ni pé, láìdà bí àwọn ẹyẹ, wọn kò lè fìrọ̀rùn kó lọ sí àgbègbè tí ó yàtọ̀ nígbà tí ibùgbé àdánidá wọn bá pòórá.
Ètò Ìwé Kíkà Ṣèrànwọ́ Láti Dín Ìwà Ọ̀daràn Kù
Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Britain náà, The Independent, sọ pé, ní Bradford, England, ètò ìwé kíkà kan tí ìjọba ń ṣagbátẹrù rẹ̀, tí a pète láti mú agbára ìwé kíkà àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sunwọ̀n sí i, ń ní àbájáde tí ó gba àfiyèsí. Kì í ṣe pé ètò ìwé kíkà náà ràn wá lọ́wọ́ láti mú agbára ìwé kíkà sunwọ̀n sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún ti gba ìyìn fún ṣíṣèrànwọ́ láti dín ìwà ọ̀daràn kù! John Watson, olórí Ẹgbẹ́ Ìkàwé Lọ́nà Dídára Jù, sọ pé: “A ti fìdí ìsopọ̀ tí ó wà láàárín iye àwọn ọ̀dọ́ tí ń fọ́lé múlẹ̀ ní tààràtà pẹ̀lú ti ìwọ̀n àwọn tí ń sá nílé ẹ̀kọ́ láìgbàṣẹ. Bí àwọn ọmọ náà bá lè kàwé, ó lè túbọ̀ ṣeé ṣe pé kí wọ́n lọ́kàn ìfẹ́ nínú ohun tí ń lọ ní ilé ẹ̀kọ́, kí wọ́n má sì máa sá nílé ẹ̀kọ́ láìgbàṣẹ. Nítorí pé wọn kò sí ní àwọn òpópónà, kò fi bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe fún wọn láti fọ́lé.”
Ìdíje Olympics àti Ipò Òṣì
Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin ti Switzerland sọ pé: “Iye àmì ẹ̀yẹ tí àwọn orílẹ̀-èdè kan gbà níbi ìdíje Olympics àti iye owó tí a ná lórí ohun èèlò ìṣeré àti ìṣonígbọ̀wọ́ tí àwọn àjọ kan ṣe nígbà ìdíje náà gbé ìbéèrè dìde nípa ìmúratán ayé láti fòpin sí ipò òṣì.” Greg Foot, láti àjọ World Vision ní Australia, sọ pé: “Èyí kì í ṣe láti sọ pé a kò gbọ́dọ̀ yọ̀ fún àṣeyọrí tàbí kí a má pàtẹ́wọ́ fún àṣeyọrí àrà ọ̀tọ̀ kan tí a fi òye ẹ̀dá àti ìforítì ṣe.” Ó fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n, a ní láti béèrè bóyá a ní ohun àkọ́múṣe tí ó tọ́ nígbà tí a bá ń náwó tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ sórí mímú kí irú oúnjẹ tí àwọn eléré ìje wa tí wọ́n jẹ́ ọ̀tọ̀kùlú ọlọ́lá ń jẹ sunwọ̀n sí i nígbà tí ó jẹ́ pé agbára káká ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn aládùúgbò wa fi ń rí oúnjẹ tí ó tó jẹ́ láti lè rìn.” A fojú díwọ̀n pé láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n fi ṣe ìdíje Olympics náà ní Atlanta, àwọn 490,000 ọmọdé ni ebi àti àwọn àrùn tí ó ṣeé dènà pa kú yíká ayé.
Ìsinmi Ìmukọfí Tí A Fà Gùn
Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, àwọn òṣìṣẹ́ kan máa ń jáde lọ ní gidi láti lọ mu ife kọfí kan ní ọwọ́ òwúrọ̀. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn ní ń kúrò níbi iṣẹ́ pátápátá. Bí àwọn búkà kọfí ti ń gbé ojúlówó kọfí jáde, àwọn òṣìṣẹ́ ń yára kúrò ní ọ́fíìsì láti lọ ra irú èyí tí wọ́n gbádùn jù lọ. Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal sọ pé, ní àbájáde rẹ̀, “ìsinmi ìmukọfí níbi iṣẹ́ ti ń di jíjáde lọ mu kọfí ní búkà.” Ṣùgbọ́n iye àkókò tí ó ń gbà láti lọ sí àwọn ilé kọfí ládùúgbò ń kọ àwọn agbanisíṣẹ́ lóminú. Ìwé agbéròyìnjáde Journal náà sọ pé, nínú ìsapá láti dín iye àwọn olólùfẹ́ kọfí tí ń kúrò lẹ́nu iṣẹ́ kù, àwọn ilé iṣẹ́ kan ń gbìyànjú láti ṣẹ́pá àṣà náà nípa gbígbé àwọn ẹ̀rọ ìṣekọfí tiwọn kalẹ̀.
Irúgbìn Tí Ń Mú Ooru Jáde
Àwọn olùṣèwádìí méjì tí wọ́n jẹ́ ará Australia ti ṣàwárí pé àwọn òdòdó lotus ní agbára àgbàyanu láti mú ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù wọn wà déédéé. Láìpẹ́ yìí, àwọn ẹranko ẹlẹ́jẹ̀ lílọ́wọ́ọ́wọ́ nìkan ni a lérò pé wọ́n ní agbára yìí. Nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Roger Seymour àti Ọ̀mọ̀wé Paul Shultze-Motel ń ṣiṣẹ́ ní Ọgbà Ìtọ́jú Ohun Ọ̀gbìn Adelaide, wọ́n so àwọn ìhùmọ̀ ahùwàpadà-sí-ìmọ̀lára mọ́ òdòdó lotus tí ń tanná láti ṣàkọsílẹ̀ ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù wọn àti àwọn ànímọ́ aṣeéfojúrí mìíràn. Kí ni wọ́n ṣàwárí rẹ̀? Kódà, nígbà tí ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù inú afẹ́fẹ́ bá lọ sílẹ̀ sí ìwọ̀n 10, ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ìtànná òdòdó lotus ṣì máa ń wà láàárín ìwọ̀n 30 sí 35 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Àwọn olùṣèwádìí kò tí ì rí àlàyé ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àrà yí. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ṣe sọ, Ọ̀mọ̀wé Hanna Skubatz, onímọ̀ nípa ìṣesí èròjà kẹ́míkà inú ewéko láti Yunifásítì Washington, U.S.A., sọ pé, “ìmújáde ooru [láàárín àwọn ewéko] lè ti wà káàkiri ní gidi, ó wulẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti mọ̀ ni.”
Àwọn Ajíhìnrere Gba Ẹ̀bi
Àkọsílẹ̀ náà, “Ìpolongo Nípa Àjọ Àwọn Ajíhìnrere Tí Ń Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ ní Cambridge,” sọ pé: “Àwọn ajíhìnrere òde òní ń pàdánù ìṣòtítọ́ wọn sí Bíbélì, ọ̀nà ìwà rere àti ìtara ẹ̀mí míṣọ́nnárì.” Ibo ni ìṣelámèyítọ́ adánilágara yìí ti wá? Bóyá ṣọ́ọ̀ṣì abánidíje rẹ̀ kan ló ṣe é? Rárá, ọ̀dọ̀ àwọn ajíhìnrere fúnra wọn ló ti wá. Àwọn aṣáájú ajíhìnrere tí wọ́n lé ní 100, tí wọ́n pàdé láìpẹ́ yìí ní Cambridge, Massachusetts, ni wọ́n gbé àkọsílẹ̀ náà jáde. Àwọn tí wọ́n kọ àkọsílẹ̀ náà gbà pé àwọn àti àwọn aṣáájú ìsìn ní láti “ronú pìwà dà nítorí fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ kí àwọn ohun tí ó wọ́pọ̀ nínú àwọn èrò ìgbàgbọ́ tí ó ṣètẹ́wọ́gbà láàárín ẹgbẹ́ àwùjọ máa ṣàkóso wọn.” Àkọsílẹ̀ náà tún gbà pé, “àwọn ìlànà ìṣètọ́jú àrùn, àwọn ìwéwèé ìtajà, àti ipá ìsúnniṣe eré ìnàjú ayé sábà máa ń ní ipa púpọ̀ lórí ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì ń fẹ́, bí ó ti ń ṣe nǹkan àti ohun tí ó ń pèsè, ju bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń ṣe lọ.”