Cuzco—Olú Ìlú Ìgbàanì Ti Àwọn Ará Inca
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Peru
ÌMỌ̀LÁRA wa ru sókè bí ọkọ̀ òfuurufú wa ṣe yí orí sẹ́gbẹ̀ẹ́, tí ó sì lọ síbàǹbalẹ̀ sáàárín àfonífojì tóóró náà. Ìlú ńlá ọlọ́rọ̀ ìtàn náà, Cuzco, Peru, ni a fẹ́ balẹ̀ sí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ńlá náà wà ní ibi tí ó ga ju 3,400 mítà lọ, àwọn òkè ńlá págunpàgun yọrí jù ú lọ, tí ó mú kí bí a ṣe ń sún mọ́ ibi tí ọkọ̀ òfuurufú ti ń gbéra, tí ó sì ń balẹ̀ náà dà bí èyí tí ó léwu gan-an. Inú wa dùn pé a balẹ̀ láìséwu. Ìdùnnú ni yóò jẹ́ láti rí ìlú ńlá olókìkí yìí tí ó ní 275,000 olùgbé, tí ó jẹ́ olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Inca kíkàmàmà nígbà kan rí.
Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Inca ìgbàanì ṣì hàn kedere ní Cuzco. Ọ̀pọ̀ lára àwọn olùgbé ìlú ńlá náà ṣì ń sọ èdè Quechua. Ní gidi, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ ènìyàn tí ń gbé àárín ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Andes náà ṣì ń sọ èdè ìgbàanì yí. Láìpẹ́ yìí, àwùjọ àwọn Quechua náà rọ àwọn aláṣẹ láti yí orúkọ náà Cuzco pa dà sí Qosqo, nítorí pé bí Qosqo ṣe ń dún tí a bá pè é sún mọ́ orúkọ àtilẹ̀wá náà, Quechua.
Ìlú Ńlá Ìgbàanì Kan
Àwọn òpìtàn sọ pé, ìlú ńlá yìí pilẹ̀ṣẹ̀ ní nǹkan bí 1,500 ọdún ṣáájú ìbí Kristi. Ìyẹn sún mọ́ ìgbà tí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní Íjíbítì. Àmọ́, ní nǹkan bí 600 ọdún sẹ́yìn, Pachacuti, olú ọba kẹsàn-án ní ilẹ̀ Inca, bu amọ̀ díẹ̀, ó sì fi mọ ẹ̀dà àwòṣe ìlú ńlá Cuzco tuntun kan, tí a tún ìgbékalẹ̀ rẹ̀ ṣe. Pachacuti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso ní ọdún 89 ṣáájú kí àwọn aṣẹ́gun ará Sípéènì tó dé ní nǹkan bí ọdún 1527. Lábẹ́ ìdarí rẹ̀, a yí ìlú ńlá náà pa dà sí ìlú ńlá pàtàkì tí a ṣètò dáradára, tí ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibùgbé nínú, tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ Cuzco òde òní.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ kan ti sọ, wọ́n pín ìlú ńlá náà sí ìsọ̀rí mẹ́rin, bẹ̀rẹ̀ láti àárín gbùngbùn rẹ̀ níbi tí gbàgede ìlú ńlá náà wà. Ní Quechua, wọ́n mọ gbàgede yìí sí huacaypata, ibi ìṣayẹyẹ, ìṣefàájì, àti ìmutí. Àwọn kan tí wọ́n mọ èdè Quechua lámọ̀ dunjú sọ pé, “Cuzco,” tàbí “Qosqo,” túmọ̀ sí “Agbedeméjì Ayé.” Nítorí náà, àárín gbùngbùn gbàgede Cuzco wá di chawpi, tàbí “agbedeméjì àárín gbùngbùn Ilẹ̀ Ọba Inca.”
Láti Cuzco, olú ọba Inca ṣàkóso lórí àwọn apá kan Ajẹntínà, Bolivia, Chile, Colombia, Ecuador, àti Peru òde òní—ọ̀pọ̀ lára rẹ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ tí ó sì lọ́ràá. Àwọn ènìyàn náà ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ nípa ṣíṣe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilẹ̀ títẹ́jú ní onírúurú ìpele gíga. Wọ́n gbin díẹ̀ lára àwọn irúgbìn tí ó ṣì ń ṣèmújáde ọ̀pọ̀ lára àwọn oúnjẹ àgbáyé, bí ọ̀dùnkún funfun àti ẹ̀wà lima, sórí àwọn ilẹ̀ amésojáde wọ̀nyí.
Rírìnrìn-àjò káàkiri àgbègbè Inca ì bá má ṣeé ṣe láìsí ètò ọ̀nà dídára ta yọ, tí ó wà káàkiri ilẹ̀ ọba náà. Nínú Cuzco dídára lójú yìí, ó rọrùn fún ẹnì kan láti finú wòye àwọn ará Inca ìgbàanì tí wọ́n ń dé nínú agbo àwọn arìnrìn-àjò nínú aṣálẹ̀ tí ń lo àwọn ẹranko llama, ẹranko tí àwọn ará Andes fi ń kẹ́rù. Àwọn òkúta iyebíye, bàbà, fàdákà, àti góòlù wà lára àwọn ẹrù ṣíṣeyebíye tí wọ́n ń dì.
Góòlù pọ̀ yanturu, àmọ́ àwọn ará Inca kì í lò ó bí owó. Nítorí ìkọmànà aláwọ̀ ìyeyè mímọ́ rekete tí góòlù ní, a gbà pé ó tan mọ́ ọlọ́run àwọn ará Inca, oòrùn. Níbi púpọ̀, wọ́n fi ègé góòlù ṣe àwọn tẹ́ńpìlì àti àwọn ààfin wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n tilẹ̀ fi góòlù gbẹ́ ọgbà kan, tí ó ní àwọn ẹranko àti irúgbìn tí wọ́n fi góòlù gidi gbẹ́. Finú wòye ìran gbígbádùnmọ́ni ti Cuzco ìgbàanì, àwọn ilé tí wọ́n lẹ ègé góòlù mọ́ lára, tí ń kọ mànà nínú oòrùn! Ó ṣeé lóye pé bí góòlù ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ló wọ àwọn oníwọra akótini ará Sípéènì, tí wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀, tí wọ́n sì kó ìkógun níbẹ̀ ní 1533, lójú.
Ọ̀nà Ìkọ́lé Aláìlẹ́gbẹ́ ti Cuzco
Àwọn ará Inca fi oríṣi ọ̀nà ìkọ́lé olókùúta rírẹwà tí kò sì lẹ́gbẹ́ kan sílẹ̀ fún Cuzco òde òní. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé òde òní ni wọ́n kọ́ sórí àwọn ògiri tí wọ́n fi òkúta tò tí ó ti wà tepé fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Wọ́n gé àwọn òkúta kan tí ó lè wọ àwọn ibi kan pàtó lára àwọn ògiri náà. Ògiri kan, tí ó ti di èyí tí ń fa àfiyèsí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, ní irú òkúta bẹ́ẹ̀, tí ó ní igun méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀! Nítorí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ igun tí àwọn òkúta wọ̀nyí ní, ńṣe ni wọ́n dà bí àwọn kọ́kọ́rọ́ tí ó bá kìkì ojú ìyá wọn mu.
Àgbà mọlémọlé ni àwọn ará Inca tí ń to òkúta. Láìlo àrànṣe ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní, wọ́n lè gé àwọn òkúta lọ́nà ṣíṣerẹ́gí gan-an débi pé bí wọ́n bá ti tò ó, a kò tilẹ̀ lè ráyè ki irin ọ̀bẹ sáàárín wọn! Àwọn kan lára àwọn òkúta wọ̀nyí wọn tọ́ọ̀nù bíi mélòó kan. Bí àwọn ènìyàn ìgbàanì wọ̀nyí ṣe ní irú òye iṣẹ́ yẹn ṣì jẹ́ àwámáàrídìí.
Ìsìn ní Cuzco
Níwọ̀n bí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Quechua ti gba ìsìn Kátólíìkì, a kò ka gbogbo wọn lápapọ̀ sí olùjọ́sìn oòrùn mọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì ní àwọn ìgbàgbọ́ kèfèrí onímọlẹ̀ tí ó tilẹ̀ ti wà ṣáájú ìjọsìn oòrùn ti àwọn ará Inca pàápàá. Wọ́n ṣì ń ṣayẹyẹ ìgbà ìkórè ní rírúbọ sí ohun tí wọ́n pè ní Pacha-Mama, tí ó wá láti inú ọ̀rọ̀ èdè Quechua kan tí ó túmọ̀ sí “yèyé ilẹ̀ ayé.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ìgbòkègbodò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lọ ní Peru pẹ̀lú àṣeyọrí púpọ̀. Láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn, Watch Tower Society ti ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Quechua kí àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Quechua lè gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ní èdè àbínibí wọn. Ibi mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a ti ń fi èdè yẹn darí àwọn ìpàdé Kristẹni.
A kò tún ní èrò pé Cuzco jẹ́ agbedeméjì ayé mọ́, àmọ́ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ń rọ́ lọ bẹ ìlú ńlá aláìlẹ́gbẹ́ yìí wò. Bóyá ìwọ pẹ̀lú yóò lọ bẹ Peru fífani-lọ́kànmọ́ra wò lọ́jọ́ kan!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
1. Cuzco àti gbàgede ìlú rẹ̀ tí a wò látòkè
2. Àwọn ará Inca máa ń gé òkúta lọ́nà ṣíṣerẹ́gí gan-an débi pé irin ọ̀bẹ kò lè ráyè wọ àárín wọn
3. Irú aṣọ kan ní Peru
4. Àwọn ẹranko llama ni àwọn ará Andes fi ń kẹ́rù